Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

ÀWỌN Ọ̀DỌ́ BÉÈRÈ PÉ

Kí Ló Yẹ Kí N Ṣe Lẹ́yìn Tí Mo Bá Ṣèrìbọmi?​​—Apá 2: Máa Ṣe Ohun Tó Tọ́ Lójú Ọlọ́run

Kí Ló Yẹ Kí N Ṣe Lẹ́yìn Tí Mo Bá Ṣèrìbọmi?​​—Apá 2: Máa Ṣe Ohun Tó Tọ́ Lójú Ọlọ́run

 Bíbélì sọ pé “Jèhófà kò ní fawọ́ ohun rere sẹ́yìn lọ́dọ̀ àwọn tó ń rìn nínú ìwà títọ́.” (Sáàmù 84:11) Kí ló túmọ̀ sí láti máa “rìn nínú ìwà títọ́”? Ohun tó túmọ̀ sí ni pé kó o máa ṣe ohun tó o ṣèlérí fún Jèhófà nígbà tó ya ara ẹ sí mímọ́ fún un. (Oníwàásù 5:​4, 5) Báwo lo ṣe lè máa rìn nínú ìwà títọ́ lẹ́yìn tó o ṣèrìbọmi?

Nínú àpilẹ̀kọ yìí

 Máa fara da ìṣòro

 Ẹsẹ Bíbélì: “A gbọ́dọ̀ ti inú ọ̀pọ̀ ìpọ́njú wọ Ìjọba Ọlọ́run.”​—Ìṣe 14:22.

 Ohun tó túmọ̀ sí: Ó dájú pé gbogbo Kristẹni ló máa dojú kọ ìṣòro nígbèésí ayé. Lára àwọn ìṣòro tó o máa dojú kọ torí pé o jẹ́ Kristẹni ni àtakò tàbí kí wọ́n máa fi ẹ́ ṣe yẹ̀yẹ́. Yàtọ̀ síyẹn, àwọn ìṣòro míì wa tó ń bá gbogbo èèyàn fínra tí ò sì ní yọ ìwọ náà sílẹ̀. Lára àwọn ìṣòro yìí ni àìlówó lọ́wọ́, àìsàn àti bẹ́ẹ̀ bẹ́ẹ̀ lọ.

 Ohun tó ṣeé ṣe kó ṣẹlẹ̀: Nǹkan á máa yí pa dà fún ẹ látìgbàdégbà, o sì lè bára ẹ nípò tí ò bára dé. Bíbélì sọ pé nǹkan burúkú lè ṣẹlẹ̀ sí ẹni kẹ́ni nígbàkigbà yálà ẹni náà jẹ́ Kristẹni tàbí bẹ́ẹ̀ kọ́.​—Oníwàásù 9:11.

 Ohun tó o lè ṣe: Múra sílẹ̀ láti kojú ìṣòro torí pé kò sígbà tíṣòro ò ní dé. Máa wo ìṣòro ẹ bí ohun tó máa jẹ́ kó o túbọ̀ gbẹ́kè lé Jèhófà kí ìgbàgbọ́ ẹ sì lágbára sí i. (Jémíìsì 1:​2, 3) Bọ́jọ́ ṣe ń gorí ọjọ́, ìwọ náà á lè sọ bíi ti àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù pé: “Mo ní okun láti ṣe ohun gbogbo nípasẹ̀ ẹni tó ń fún mi lágbára.”​—Fílípì 4:13.

 OHUN TÓ ṢẸLẸ̀ LÓÒÓTỌ́. “Kò pẹ́ lẹ́yìn tí mo ṣèrìbọmi ni ẹ̀gbọ́n mi fi òtítọ́ sílẹ̀, ara àwọn òbí mi ò tún yá. Àfi bíi pé ìyẹn ò tó, lèmi náà bá tún bẹ̀rẹ̀ àìsàn. Bí mo ṣe ya ara mi sí mímọ́ fún Jèhófà ló jẹ́ kí n lè fara da àwọn ìṣòro yìí, ká ní kì í ṣe ìyẹn ni, mi ò bá ti juwọ́ sílẹ̀ kí n sì gbàgbé ìlérí tí mo ṣe láti fi gbogbo ìgbésí ayé mi sìn ín.”​—Karen

 Àbá: Kẹ́kọ̀ọ́ lára Jósẹ́fù. O lè kà ìtàn ẹ̀ nínú Jẹ́nẹ́sísì orí 37 àti orí 39 sí 41. Bi ara ẹ pé: Àwọn ìṣòro tí ò rò tẹ́lẹ̀ wo ló dojú kọ, báwo ló sì ṣe borí wọn? Báwo ni Jèhófà ṣe rán Jósẹ́fù lọ́wọ́?

 Tó o bá fẹ́ mọ̀ sí i

 Máa sá fún ìdẹwò

 Ẹsẹ Bíbélì: “Àdánwò máa ń dé bá kálukú nígbà tí ìfẹ́ ọkàn rẹ̀ bá fà á mọ́ra, tó sì tàn án jẹ.”​—Jémíìsì 1:14.

 Ohun tó túmọ̀ sí: Gbogbo wa ni èròkerò máa ń wá sí lọ́kàn lẹ́ẹ̀kọ̀ọ̀kan, àmọ́ tá ò bá kíyè sára, wọ́n lè mú ká ṣe ohun tí kò tọ́.

 Ohùn tó ṣeé ṣe kó ṣẹlẹ̀: Lẹ́yìn tó o bá ṣèrìbọmi, á ṣì máa ṣe ẹ́ bíi pé kó o tẹ́ “ìfẹ́kúfẹ̀ẹ́ ti ara” lọ́rùn. (2 Pétérù 2:18) Ó tiẹ̀ lè máa ṣe ẹ́ bíi pé kó o ní ìbálòpọ̀ kó o tó ṣègbéyàwó.

 Ohun tó o lè ṣe: Tó o ba fẹ́ borí ìdẹwò, àsìkò yìí gan-an ló yẹ kó o múra sílẹ̀ kí ìdẹwò tó dé, kó o lè ṣe ìpinnu tó tọ́. Rántí ohun tí Jésù sọ pé: “Kò sí ẹni tó lè sin ọ̀gá méjì.” (Mátíù 6:24) Ìwọ lo máa pinnu ẹni tó o máa sìn. Àmọ́, ohun tó bọ́gbọ́n mu ni pé kó o yàn láti sin Jèhófà. Fi sọ́kàn pé, tó bá tiẹ̀ ń wù ẹ́ gan-an láti ṣe ohun tí kò dáa, o lè ṣèpinnu tó tọ́.​—Gálátíà 5:16.

 Àbá: Mọ ibi tí agbára ẹ mọ àti ibi tó o kù sí. Yàtọ̀ síyẹn, àwọn ọ̀rẹ́ gidi ni kó o máa bá rìn. Yẹra fáwọn èèyàn ti ìwà wọn ò dáa, ibi tó léwu, àtàwọn ipò tó lè mú kó ṣòro láti ṣe ohun tó tọ́.​—Sáàmù 26:​4, 5.

 Tó o bá fẹ́ mọ̀ sí i

 Jẹ́ kí ìtara ẹ máa pọ̀ sí i

 Ẹsẹ Bíbélì: “Máa ṣiṣẹ́ kára . . . títí dé òpin, kí ẹ má bàa máa lọ́ra.”​—Hébérù 6:​11, 12.

 Ohun tó túmọ̀ sí: Téèyàn ò bá gbájú mọ́ṣẹ́, ó lè bẹ̀rẹ̀ sí í fiṣẹ́ falẹ̀.

 Ohùn tó ṣeé ṣe kó ṣẹlẹ̀: Ó dájú pé inú ẹ dùn gan-an lẹ́yìn tó o ṣèrìbọmi, ó sì nítara. Bákan náà, tọkàntọkàn lo nífẹ̀ẹ́ Jèhófà. Àmọ́, bọ́jọ́ ṣe ń gorí ọjọ́, ó lè má rọrùn fún ẹ láti máa pa gbogbo òfin Jèhófà mọ́, ìyẹn lè mú kí nǹkan tojú sú ẹ, kí ìtara ẹ sì dínkù.​—Gálátíà 5:7.

 Ohun tó o lè ṣe: Máa ṣe ohun tó tọ́, kódà tí kò bá rọrùn. (1 Kọ́ríńtì 9:27) Máa kẹ́kọ̀ọ́ nípa Jèhófà bàbá rẹ ọ̀run kó o sì máa gbàdúrà sí i látìgbàdégbà, ìyẹn á jẹ́ kó o túbọ̀ sún mọ́ ọn. Bákan náà, àwọn tó ń fòótọ́ ọkàn sin Jèhófà ni kó o yàn lọ́rẹ̀ẹ́.

 Àbá: Fi sọ́kàn pé Jèhófà nífẹ̀ẹ́ ẹ, ó sì ṣe tán láti ràn ẹ́ lọ́wọ́. Má ronú pé ó ń bínú sí ẹ láwọn ìgbà tí ìtara ẹ bá dín kù. Bíbélì sọ pé: “Ó ń fún ẹni tó ti rẹ̀ ní agbára, ó sì ń fún àwọn tí kò lókun ní ẹ̀kúnrẹ́rẹ́ okun.” (Àìsáyà 40:29) Ó dájú pé, Jèhófà máa ràn ẹ́ lọ́wọ́ kó o lè nítara pa dà.

 Tó o bá fẹ́ mọ̀ sí i

 Kókó ibẹ̀ ni pé: Tó o bá ń rìn nínú ìwà títọ́, wà á múnú Jèhófà dùn. (Òwe 27:11) Inú Jèhófà máa dùn tó o bá pinnu láti sìn ín, ó sì máa tì ẹ́ lẹ́yìn kó o lè borí àwọn àtakò Sátánì.