Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

ÀWỌN Ọ̀DỌ́ BÉÈRÈ PÉ

Báwo Ni Mo Ṣe Ní Ìforítì Tó?

Báwo Ni Mo Ṣe Ní Ìforítì Tó?

 Báwo ni o ṣe ní ìforítì tó? Ṣé . . .

  •   ẹnì kan tó o fẹ́ràn ti kú rí?

  •   o ti ṣàìsàn ọlọ́jọ́ tó pẹ́ rí?

  •   àjálù ti dé bá ẹ rí?

 Àwọn olùṣèwádìí sọ pé kì í ṣe ìgbà tí ìṣòro ńlá bá dé báni nìkan ló yẹ kéèyàn ní ìforítì. Béèyàn ṣe ń sá sókè, sá sódò lójoojúmọ́ pàápàá lè múni ṣàìsàn. Ìdí nìyẹn tó fi jẹ́ pé yálà ìṣòro tó ń bá ẹ fínra kéré tàbí ó pọ̀, ó yẹ kó o ní ìforítì.

 Kí ni ìforítì?

 Ìforítì ni ohun tó ń mú kéèyàn lè fara dà á bí ipò nǹkan bá yí pa dà, ó sì máa ń jẹ́ kéèyàn fàyà rán ìṣòro. Àwọn tó ní ìforítì náà ò bọ́ lọ́wọ́ ìṣòrò tó ń bá gbogbo èèyàn fínra. Ṣùgbọ́n kàkà kí wọ́n bọ́hùn, ṣe ló máa ń sọ wọ́n di alágbára.

Bó ṣe jẹ́ pé àwọn igi kan máa ń tẹ̀ síbi tí ìjì bá darí wọn sí, ṣùgbọ́n tí wọ́n á nàró pa dà lẹ́yìn tí ìjì bá rọlẹ̀, bẹ́ẹ̀ náà lo ṣe lè kọ́fẹ pa dà lẹ́yìn ìṣòro

 Kí nìdí tó fi yẹ kó o ní ìforítì?

  •   Ìdí ni pé kò sọ́gbọ́n kí ìṣòro má wà. Bíbélì sọ pé: “Ìgbà gbogbo kọ́ ni ẹni tí ẹsẹ̀ rẹ̀ yá máa ń mókè nínú eré ìje, . . . bákan náà àwọn tó ní ìmọ̀ kì í fìgbà gbogbo ṣe àṣeyọrí, nítorí ìgbà àti èèṣì ń ṣẹlẹ̀ sí gbogbo wọn.” (Oníwàásù 9:11) Kí nìyẹn kọ́ wa? Ó kọ́ wa pé àwọn ẹni rere pàápàá máa ń jìyà, bó tiẹ̀ jẹ́ pé lọ́pọ̀ ìgbà wọn ò ṣe ohun tí kò dá, ó ṣe tán, inúnibíni ò kan tàì mọ̀wá hù.

  •   Torí pé ìforítì máa dáàbò bò ẹ́. Agbaninímọ̀ràn ilé ẹ̀kọ́ gíga kan sọ pé: “Ju ti ìgbàkigbà rí lọ, àìmọye àwọn ọ̀dọ́ ló ti fara ya ní ọ́fíìsì mi torí pé wọn ò gba máàkì tó dáa nínú ìdánwò tí wọ́n ṣe tàbí torí pé ẹnì kan sọ̀rọ̀ wọn láìdáa lórí ìkànnì àjọlò.” Ó sọ pé kódà lórí irú ọ̀rọ̀ tó dà bíi pé kò tó nǹkan yẹn, àìní ìforítì lè mú “kéèyàn bara jẹ́ kó sì tún ṣìwà hù.” a

  •   Torí pé ìforíti á ràn ẹ́ lọ́wọ́ ní báyìí àti nígbà tó o bá dàgbà. Nígbà tí Ọ̀mọ̀wé Richard Lerner ń kọ̀wé nípa àwọn ìṣòro tó lè fẹjú mọ́ni, ó ní: “Lara ohun tá a fi lè mọ̀ tá a bá jẹ́ àgbà tó lè fàyà rán ìṣòro ni pé ká má ṣe jẹ́ kí irú ìṣòro bẹ́ẹ̀ borí wa, ká tún èrò ara wa pa tàbí ká wá ọ̀nà míì tá a lè gbà yanjú ìṣòro náà.” b

 Báwo lo ṣe lè ní ìforítì?

  •   Mọ bí ìṣòro rẹ ṣe le tó. Mọ ìyàtọ̀ tó wà láàárín ìṣòro ńlá àti ìṣòro tí kò tó nǹkan. Bíbélì sọ pé: “Òmùgọ̀ máa ń fi ìbínú rẹ̀ hàn lójú ẹsẹ̀, àmọ́ aláròjinlẹ̀ máa ń gbójú fo àbùkú tí wọ́n fi kàn án.” (Òwe 12:16) Kò pọn dandan kí gbogbo ìṣòro máa mu ẹ́ lómi.

     Níléèwé, àwọn ọmọ kíláàsì mi máa ń fẹ ọ̀rọ̀ tí kò tó nǹkan lójú bíi pé nǹkan bàbàrà ni. Lẹ́yìn náà, tí wọ́n bá bá àwọn ọ̀rẹ́ wọn sọ̀rọ̀ lórí ìkànnì àjọlò, àwọn yẹn á tún tanná ran ọ̀rọ̀ náà bíi pé ó jù bẹ́ẹ̀ lọ, ìyẹn ò wá ní lè jẹ́ kí wọ́n rí i pé ọ̀rọ̀ náà ò le tó bí wọ́n ṣe rò.”​—⁠Joanne.

  •   Kẹ́kọ̀ọ́ lára àwọn míì. Òwe inú Bíbélì kan sọ pé: “Bí irin ṣe ń pọ́n irin, bẹ́ẹ̀ ni èèyàn ṣe ń pọ́n ọ̀rẹ́ rẹ̀.” (Òwe 27:17) A lè kọ́ ẹ̀kọ́ tó ṣeyebíye lára àwọn tó ti fojú winá ìṣòro rí.

     Bó o ṣe ń bá àwọn míì sọ̀rọ̀, wàá rí i pé wọ́n ti la ọ̀pọ̀ àdánwò tó le koko kọjá, àmọ́ wọ́n ti borí àwọn àdánwò náà báyìí. Bá wọn sọ̀rọ̀, kó o sì wádìí ohun tí wọ́n ṣe tí wọ́n fi borí àdánwò náà àti ohun tí wọ́n ṣọ́ra fún.”​—⁠Julia.

  •   Ní sùúrù. Bíbélì sọ pé: “Olódodo lè ṣubú ní ìgbà méje, á sì tún dìde.” (Òwe 24:16) Ó máa ń pẹ́ ká tó gbà pé àwọn nǹkan ò rí bá a ṣe fẹ́ kí wọ́n rí, torí náà má ṣe jẹ́ kó yà ẹ́ lẹ́nu bí àwọn nǹkan kan bá kó ìbànújẹ́ bá ẹ nígbà míì. Ohun tó ṣe pàtàkì ni pé kó o “tún dìde.”

     Tó o bá ṣẹ̀ṣẹ̀ ń gbé ìṣòro kan kúrò lára, ó yẹ kó o gbọ́kàn kúrò nínú ìdààmú tí ìṣòro náà ti fà fún ẹ. Díẹ̀díẹ̀ ni wàá máa gbé e kúrò lọ́kàn, ó sì máa ń gba àkókò. Mo ti wá mọ̀ pé bí ọjọ́ ṣe ń gorí ọjọ́ bẹ́ẹ̀ ni á túbọ̀ máa rọrùn fún mi láti kọ́fẹ pa dà.”​—⁠Andrea.

  •   Máa dúpẹ́. Bíbélì sọ pé: “Ẹ máa dúpẹ́.” (Kólósè 3:15) Bó ti wù kí ara ni ẹ́ tó, wàá ṣì rí nǹkan tó yẹ kó o torí ẹ̀ dúpẹ́, ó ṣe tán, ẹni tó bá mọnú rò, á mọpẹ́ dá. Ronú nípa ohun mẹ́ta tí kò ní mú káyé sú ẹ.

     Bí ìnira bá dé bá ẹ, àfàìmọ̀ lo ò ní sọ pé, ‘Kí ló fà á tí èyí fi ń ṣẹlẹ̀ sí mi?’ Ohun pàtàkì kan tí ìforítì máa ṣe ni pé kò ní jẹ́ kó o máa ro àròkàn, kò ní jẹ́ kó o sọ̀rètí nù, á sì jẹ́ kó o máa dúpẹ́ torí ohun tó o ní tàbí torí ohun tó o lè ṣe.”​—⁠Samantha.

  •   Ní ìtẹ́lọ́rùn. Àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù sọ pé: “Mo ti kọ́ bí èèyàn ṣe ń nítẹ̀ẹ́lọ́rùn pẹ̀lú ohun tó bá ní.” (Fílípì 4:11) Pọ́ọ̀lù ò lè dáwọ́ ìnira tó dé bá a dúró. Amọ́, ó mọ ohun tó ṣe nípa rẹ̀. Pọ́ọ̀lù pinnu pé òun á ní ìtẹ́lọ́rùn.

     Ohun kan tí mo ti wá mọ̀ nípa ara mi ni pé, mo máa ń kọ́kọ́ bara jẹ́ tí ìnira bá dé bá mi. Mo fẹ́ máa ní in lọ́kàn nígbà gbogbo pé kò sóhun tó le tí kò ní rọ̀. Ìyẹn á fi mí lára balẹ̀, kò sí ní kó àwọn tá a jọ wà pa pọ̀ lọ́kàn sókè.”​—⁠Matthew.

  •   Gbàdúrà. Bíbélì sọ pé: “Ju ẹrù rẹ sọ́dọ̀ Jèhófà, yóò sì gbé ọ ró. Kò ní jẹ́ kí olódodo ṣubú láé.” (Sáàmù 55:22) Àdúrà kì í wulẹ̀ ṣe ohun téèyàn ń ṣe kára lè tuni. Tó o bá ń gbàdúrà, Ẹlẹ́dàá rẹ tó ‘n bójú tó ẹ’ lò ń bá sọ̀rọ̀ ní tààràtà.”​—⁠1 Pétérù 5:⁠7.

     Kò yẹ kí n máa dánìkan forí rọ́ àwọn ìṣòro mi. Bí mo ṣe ń sọ ìṣòro mi fún Jèhófà láìfi ohunkóhun pa mọ́, tí mo sì ń dúpẹ́ lọ́wọ́ rẹ̀ torí ìbùkún tí mò ń rí gbà, ń jẹ́ kí n pọkàn pọ̀ sórí bí Jèhófà ṣe ń bù kún mi, ó sì n jẹ́ kí n lè gbọ́kàn kúrò lórí ohun tó ń bà mí nínú jẹ́. Àdúrà ṣe pàtàkì gan-an ni o!”​—⁠Carlos.

a Látinú ìwé Disconnected, látọwọ́ Thomas Kersting.

b Látinú ìwé The Good Teen​—Rescuing Adolescence From the Myths of the Storm and Stress Years.