Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

ÀWỌN Ọ̀DỌ́ BÉÈRÈ PÉ

Kí Ni Mo Lè Ṣe Tí Mi Ò Fi Ní Máa Tijú Mọ́?

Kí Ni Mo Lè Ṣe Tí Mi Ò Fi Ní Máa Tijú Mọ́?

 Ohun tó jẹ́ ìṣòro: Tí ẹnì kan bá ń tijú, onítọ̀hún lè má ní àwọn ọ̀rẹ́ tòótọ́ tàbí kó má fi bẹ́ẹ̀ ní ìrírí.

 Ohun tó yẹ kó o mọ̀: Kéèyàn máa tijú ò fìgbà gbogbo burú. Torí nígbà míì, ó lè mú kéèyàn ronú kó tó sọ̀rọ̀, ó sì lè mú kéèyàn tẹ́tí sáwọn míì kó sì lákìíyèsí.

 Òótọ́ ibẹ̀: Tó o bá ń tijú báyìí, ìyẹn ò túmọ̀ sí pé bẹ́ẹ̀ láá ṣe máa rí títí lọ. O lè ṣe àwọn ohun tí ò ní jẹ́ kó o máa tijú. Àpilẹ̀kọ yìí máa ràn ẹ́ lọ́wọ́.

 Mọ ohun tó ń bà ẹ́ lẹ́rù

 Ẹni tó bá ń tijú máa ń bẹ̀rù láti bá àwọn èèyàn sọ̀rọ̀ lójúkojú. Ẹni náà tiẹ̀ lè bẹ̀rẹ̀ sí í yẹra fáwọn èèyàn, kó máa ṣe é bíi pé ó dá wà nínú yàrá tó ṣókùnkùn. Ìyẹn sì léwu gan-an. Àmọ́ tó o bá mọ àwọn ohun tó ń bà ẹ́ lẹ́rù, wàá rí i pé kò sídìí tó fi yẹ kó o máa bẹ̀rù. Wo ohun mẹ́ta tó lè jẹ́ kẹ́rù máa bà ẹ́.

  •   Àkọ́kọ́: “Mi ò mọ ohun tí màá sọ.”

     Òótọ́ ibẹ̀: Àwọn èèyàn kì í sábà rántí ohun tẹ́nì kan sọ, àmọ́ wọn ò lè gbàgbé ohun tẹ́ni náà ṣe sí wọn. Tẹ́rù bá ń bà ẹ́, o ò ṣe túbọ̀ máa fara balẹ̀ tẹ́tí sáwọn èèyàn tí wọ́n bá ń sọ̀rọ̀.

     Rò ó wò ná: Irú ọ̀rẹ́ wo ló wù ẹ́ kó o ní? Ṣé ẹlẹ́jọ́ ni, tí ò lè ṣe kó má rí nǹkan sọ, àbí ẹni tó máa ń fara balẹ̀ tẹ́tí sáwọn míì?

  •   Ìkejì: “Àwọn èèyàn lè máa rò pé mi ò lọ́yàyà.”

     Òótọ́ ibẹ̀: Kò sí káwọn èèyàn má rí nǹkan sọ nípa ẹ, bóyá o máa ń tijú ni o àbí o kì í tijú. Tó o bá jẹ́ káwọn èèyàn mọ irú ẹni tó o jẹ́, ìyẹn á jẹ́ kí wọ́n ní èrò tó dáa nípa ẹ, wàá sì lè borí ìbẹ̀rù.

     Rò ó wò ná: Tó o bá ń wò ó pé àwọn èèyàn ò gba tìẹ, èyí lè má jóòótọ́ torí ó lè jẹ́ pé ìwọ lò ń rò ó bẹ́ẹ̀

  •   Ìkẹ́ta: “Tí mo bá sọ ohun tí kò yẹ kí n sọ, ojú á tì mí.”

     Òótọ́ ibẹ̀: Kò sẹ́ni tírú ẹ̀ ò lè ṣẹlẹ̀ sí, ó ṣe tán, a kì í mọ̀ ọ́n rìn kórí má mì. Torí náà, tó o bá ṣi ọ̀rọ̀ sọ, jẹ́ kí àwọn èèyàn mọ̀ pé aláìpé nìwọ náà, èyí á jẹ́ kó o lè borí ìbẹ̀rù.

     Rò ó wò ná: Ṣé ó má a ń wù ẹ́ kó o wà láàárín àwọn èèyàn tó gbà pé àwọn náà máa ń ṣàṣìṣe?

 Ǹjẹ́ o mọ̀? Àwọn kan rò pé àwọn kì í tijú torí àtẹ̀jíṣẹ́ ni wọ́n sábà máa ń fi ránṣẹ́ sáwọn ọ̀rẹ́ wọn. Àmọ́ tó o bá fẹ́ ní ọ̀rẹ́ tòótọ́, ó yẹ kó o máa bá àwọn èèyàn sọ̀rọ̀ lójúkojú. Kódà, ọ̀gbẹ́nì Sherry Turkle tó jẹ́ onímọ̀ ẹ̀rọ àti afìṣemọ̀rònú ẹ̀dá sọ pé: “Àwa èèyàn máa ń mọwọ́ ara wa dáadáa tá a bá ríra wa tàbí tá a gbóhùn ara wa.” a

Tó o bá mọ ohun tó ń bà ẹ́ lẹ́rù, ó máa rọrùn fún ẹ láti máa bá àwọn èèyàn sọ̀rọ̀ lójúkojú, o ò sì ní máa tijú mọ́

 Ohun tó o lè ṣe

  •   Má ṣe fi ara ẹ wé ẹlòmíì. Kò di dandan kó o máa fi ara ẹ wé àwọn tó mọ̀rọ̀ sọ gan-an. Ohun tó o yẹ kó o máa wá ni bí wàá ṣe lè máa sọ̀rọ̀ nígbà tó bá yẹ bẹ́ẹ̀, èyí á jẹ́ kó o láwọn ìrírí tó dáa kó o sì láwọn ọ̀rẹ́ tòótọ́.

     “Kò di dandan kó jẹ́ pé ìwọ ni wàá máa pa àwọn ọ̀rẹ́ ẹ lẹ́rìn-ín. Jẹ́ kí ọ̀rọ̀ ẹ mọ níwọ̀n, tó o bá ṣẹ̀ṣẹ̀ pàdé ẹni kan, o lè sọ orúkọ ẹ fún un kó o sì bi ẹni náà ní ìbéèrè díẹ̀, ìyẹn náà ti tó.”—Alicia.

     Ìlànà Bíbélì: “Kí kálukú máa yẹ ohun tó ń ṣe wò, nígbà náà, yóò láyọ̀ nítorí ohun tí òun fúnra rẹ̀ ṣe, kì í ṣe torí pé ó fi ara rẹ̀ wé ẹlòmíì.”​—Gálátíà 6:4.

  •   Máa kíyè sí bí àwọn èèyàn ṣe ń ṣe. Máa kíyè sí bí àwọn tí kì í tijú ṣe ń ṣe tí wọ́n bá wà láàárín àwọn èèyàn. Wo ohun tí wọ́n máa ń ṣe àti ohun tí wọn kì í ṣe tí wọ́n bá kọ́kọ́ pàdé ẹnì kan, irú ìwà wo ni wọ́n ní tó wu ìwọ náà kó o ní?

     “Kẹ́kọ̀ọ́ lára àwọn tó máa ń rọrùn fún láti lọ́rẹ̀ẹ́ tuntun. Tí wọ́n bá kọ́kọ́ pàdé ẹnì kan, kíyè sí ohun tí wọ́n ṣe àti bí wọ́n ṣe bá onítọ̀hún sọ̀rọ̀.”​—Aaron.

     Ìlànà Bíbélì: “Bí irin ṣe ń pọ́n irin, bẹ́ẹ̀ ni èèyàn ṣe ń pọ́n ọ̀rẹ́ rẹ̀.”​—Òwe 27:17.

  •   Máa béèrè ìbéèrè. Ọ̀pọ̀ èèyàn ló máa ń fẹ́ sọ èrò wọn lórí nǹkan, torí náà tó o bá bi ẹnì kan ní ìbéèrè, ìyẹn lè jẹ́ kẹ́ ẹ bẹ̀rẹ̀ sí í sọ̀rọ̀ dáadáa. Tẹ́ ẹ bá sì ti ń sọ̀rọ̀ lọ, o ò ní máa dààmú jù nípa ohun tó o máa sọ.

     “Kó tó di pé o lọ síbi ìkórajọ kan, o lè múra ohun tó o fẹ́ sọ sílẹ̀ àbí kó o ti mọ àwọn ìbéèrè tó o lè bi ẹni tó ṣeé ṣe kó o bá pàdé, èyí á jẹ́ kó rọrùn fún ẹ láti bá àwọn èèyàn sọ̀rọ̀.”—Alana.

     Ìlànà Bíbélì: ‘Ẹ máa wá ire àwọn ẹlòmíì, kì í ṣe tiyín nìkan.’—Fílípì 2:4.

a Látinú ìwé Reclaiming Conversation.