Lẹ́tà Jémíìsì 1:1-27

  • Ìkíni (1)

  • Ìfaradà ń jẹ́ ká láyọ̀ (2-15)

    • A máa ń dán ìgbàgbọ́ wò ní ti bó ṣe jẹ́ ojúlówó tó (3)

    • Ẹ máa fi ìgbàgbọ́ béèrè (5-8)

    • Ìfẹ́ ọkàn máa ń yọrí sí ẹ̀ṣẹ̀ àti ikú (14, 15)

  • Gbogbo ẹ̀bùn rere wá láti òkè (16-18)

  • Olùgbọ́ àti olùṣe ọ̀rọ̀ náà (19-25)

    • Ẹni tó ń wo ara rẹ̀ nínú dígí (23, 24)

  • Ìjọsìn tó mọ́, tí kò sì ní ẹ̀gbin (26, 27)

1  Jémíìsì,+ ẹrú Ọlọ́run àti ti Jésù Kristi Olúwa, sí ẹ̀yà méjìlá (12) tó wà káàkiri: Mo kí yín!  Ẹ̀yin ará mi, tí oríṣiríṣi àdánwò bá dé bá yín, ẹ ka gbogbo rẹ̀ sí ayọ̀,+  kí ẹ mọ̀ pé ìgbàgbọ́ yín tí a dán wò ní ti bó ṣe jẹ́ ojúlówó tó máa mú kí ẹ ní ìfaradà.+  Àmọ́ ẹ jẹ́ kí ìfaradà ṣe iṣẹ́ rẹ̀ láṣeparí, kí ẹ lè pé pérépéré, kí ẹ sì máa ṣe ohun tó tọ́ nínú ohun gbogbo, láìkù síbì kan.+  Torí náà, tí ẹnikẹ́ni nínú yín ò bá ní ọgbọ́n, kó máa béèrè lọ́wọ́ Ọlọ́run,+ ó sì máa fún un,+ torí ó lawọ́ sí gbogbo èèyàn, kì í sì í pẹ̀gàn*+ tó bá ń fúnni.  Àmọ́ kó máa fi ìgbàgbọ́ béèrè,+ kó má ṣiyèméjì rárá,+ torí ẹni tó ń ṣiyèméjì dà bí ìgbì òkun tí atẹ́gùn ń fẹ́ káàkiri.  Kódà, kí ẹni náà má rò pé òun máa rí ohunkóhun gbà lọ́dọ̀ Jèhófà;*  aláìnípinnu ni onítọ̀hún,+ kò sì dúró sójú kan ní gbogbo ọ̀nà rẹ̀.  Àmọ́ kí arákùnrin tó rẹlẹ̀ máa yọ̀* torí a gbé e ga,+ 10  àti ọlọ́rọ̀ torí a ti rẹ̀ ẹ́ sílẹ̀,+ torí ó máa kọjá lọ bí òdòdó inú pápá. 11  Bí oòrùn ṣe máa ń mú ooru tó ń jóni jáde tó bá yọ, tó sì máa mú kí ewéko rọ, tí òdòdó rẹ̀ á já bọ́, tí ẹwà rẹ̀ tó tàn sì máa ṣègbé, bẹ́ẹ̀ náà ni ọlọ́rọ̀ máa pa rẹ́ bó ṣe ń lépa ọrọ̀.+ 12  Aláyọ̀ ni ẹni tó ń fara da àdánwò,+ torí tó bá rí ìtẹ́wọ́gbà, ó máa gba adé ìyè,+ tí Jèhófà* ṣèlérí pé òun máa fún àwọn tí ò yéé nífẹ̀ẹ́ Rẹ̀.+ 13  Tí àdánwò bá dé bá ẹnikẹ́ni, kó má ṣe sọ pé: “Ọlọ́run ló ń dán mi wò.” Torí a ò lè fi ibi dán Ọlọ́run wò, òun náà kì í sì í dán ẹnikẹ́ni wò. 14  Àmọ́ àdánwò máa ń dé bá kálukú nígbà tí ìfẹ́ ọkàn rẹ̀ bá fà á mọ́ra, tó sì tàn án jẹ.*+ 15  Tí ìfẹ́ ọkàn náà bá ti gbilẹ̀,* ó máa bí ẹ̀ṣẹ̀; tí ẹ̀ṣẹ̀ náà bá sì ti wáyé, ó máa yọrí sí ikú.+ 16  Ẹ̀yin ará mi ọ̀wọ́n, ẹ má ṣe jẹ́ kí ẹnikẹ́ni ṣì yín lọ́nà. 17  Gbogbo ẹ̀bùn rere àti gbogbo ọrẹ pípé wá láti òkè,+ ó ń wá látọ̀dọ̀ Baba àwọn ìmọ́lẹ̀ àtọ̀runwá,+ ẹni tí kì í yí pa dà, tí kì í sì í sún kiri bí òjìji.*+ 18  Ìfẹ́ rẹ̀ ni pé kó fi ọ̀rọ̀ òtítọ́ mú wa wá,+ ká lè di oríṣi àkọ́so kan nínú àwọn ohun tó dá.+ 19  Ẹ̀yin ará mi ọ̀wọ́n, ẹ mọ èyí: Ó yẹ kí gbogbo èèyàn yára láti gbọ́rọ̀, kí wọ́n lọ́ra láti sọ̀rọ̀,+ kí wọ́n má sì tètè máa bínú,+ 20  torí ìbínú èèyàn kì í mú òdodo Ọlọ́run wá.+ 21  Torí náà, ẹ mú gbogbo èérí àti gbogbo ohun tó jẹ mọ́ ìwà burúkú* kúrò,+ kí ìwà tútù yín sì mú kí ọ̀rọ̀ tó lè gbà yín là* fìdí múlẹ̀ nínú yín. 22  Àmọ́, ẹ máa ṣe ohun tí ọ̀rọ̀ náà sọ,+ ẹ má kàn máa gbọ́ ọ lásán, kí ẹ wá máa fi èrò èké tan ara yín jẹ. 23  Torí tí ẹnikẹ́ni bá ń gbọ́ ọ̀rọ̀ náà, àmọ́ tí kò ṣe é,+ ẹni yìí dà bí èèyàn tó ń wo ojú ara rẹ̀* nínú dígí. 24  Torí ó wo ara rẹ̀, ó lọ, ó sì gbàgbé irú ẹni tí òun jẹ́ lẹ́sẹ̀kẹsẹ̀. 25  Àmọ́ ẹni tó bá ń fara balẹ̀ wo inú òfin pípé+ tó jẹ́ ti òmìnira, tí kò sì yéé wò ó, kì í ṣe olùgbọ́ tó ń gbàgbé, àmọ́ ó ti di olùṣe iṣẹ́ náà; ohun tó ń ṣe á sì máa múnú rẹ̀ dùn.+ 26  Tí ẹnikẹ́ni bá rò pé òun ń jọ́sìn Ọlọ́run,* àmọ́ tí kò ṣọ́ ahọ́n rẹ̀ gidigidi,*+ ṣe ló ń tan ọkàn ara rẹ̀ jẹ, asán sì ni ìjọsìn rẹ̀. 27  Ìjọsìn* tó mọ́, tí kò sì ní ẹ̀gbin lójú Ọlọ́run àti Baba wa nìyí: láti máa bójú tó àwọn ọmọ aláìlóbìí+ àti àwọn opó+ nínú ìpọ́njú wọn,+ ká sì máa pa ara wa mọ́ láìní àbààwọ́n nínú ayé.+

Àlàyé Ìsàlẹ̀ Ìwé

Tàbí “dáni lẹ́bi.”
Ní Grk., “yangàn.”
Tàbí “mú un bí ìdẹ.”
Ní Grk., “lóyún.”
Tàbí “ẹni tí kò sí ìyípadà òjìji lọ́dọ̀ rẹ̀.”
Tàbí kó jẹ́, “ọ̀pọ̀ rẹpẹtẹ ìwà burúkú.”
Tàbí “gba ọkàn yín là.”
Tàbí “ojú àdánidá rẹ̀.”
Tàbí “òun gba Ọlọ́run gbọ́.”
Tàbí “kó ahọ́n rẹ̀ níjàánu.”
Tàbí “Ẹ̀sìn.”