Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

ÀWỌN Ọ̀DỌ́ BÉÈRÈ PÉ

Kí Ló Yẹ Kí N Ṣe Táwọn Òbí Mi Bá Sọ Pé Kí N Má Lo Ìkànnì Àjọlò?

Kí Ló Yẹ Kí N Ṣe Táwọn Òbí Mi Bá Sọ Pé Kí N Má Lo Ìkànnì Àjọlò?

 Ṣé ó jọ pé gbogbo àwọn ọ̀rẹ́ ẹ ló ń lo ìkànnì àjọlò, tí wọ́n sì máa sọ̀rọ̀ nípa ẹ̀ ṣáá? Bóyá wọ́n tiẹ̀ ń fi ẹ́ ṣe yẹ̀yẹ́ pé o kì í lo ìkànnì àjọlò. Kí ló yẹ kó o fi sọ́kàn? Kí ló sì yẹ kó o ṣe tí irú ẹ̀ bá ṣẹlẹ̀?

Ohun tó yẹ kó o fi sọ́kàn

 Máa ṣe rò pé ìwọ nìkan ni kò lo ìkànnì àjọlò. Ọ̀pọ̀ òbí ni kò jẹ́ kí ọmọ wọn lo ìkànnì àjọlò. Ó ṣeé ṣe kó jẹ́ torí pé:

  •   ìkànnì àjọlò lè fa ìrẹ̀wẹ̀sì tàbí kéèyàn máa ro ara ẹ̀ pin.

  •   ó lè jẹ́ kí èèyàn máa wo àwòrán ìṣekúṣe, kó máa fi ọ̀rọ̀ tàbí àwòrán ìṣekúṣe ránṣé tàbí kí wọ́n máa halẹ̀ mọ́ ọn.

  •   ó máa ń jẹ́ kí àwọn nǹkan tí kò nítumọ̀ dá wàhálà sílẹ̀ láàárín àwọn ọ̀rẹ́.

 Ọ̀pọ́ ọ̀dọ́ ni kò lo ìkànnì àjọlò mọ́. Wọ́n rí i pé ìṣòro tó ń fà ju àǹfàànì táwọn rí níbẹ̀ lọ. Ẹ jẹ́ ká wo àpẹẹrẹ àwọn ọ̀dọ́ kan:

  •   Priscilla rí i pé àkókò tó yẹ kí òun máa fi ṣe àwọn nǹkan gidi ni òun máa ń lò lórí ìkànnì àjọlò.

  •   Jeremy sọ pé òun kò nífẹ̀ẹ́ sí bí ìkànnì àjọlò ṣe ń gbé oríṣiríṣi àwọn nǹkan tí ò bójú mu wá, tóun ò sì lè dá a dúró.

  •   Bethany rí i pé ìkànnì àjọlò máa ń jẹ́ kóun da ara òun láàmú nípa ohun táwọn míì ń ṣe.

 “Mo yọ ìkànnì àjọlò mi kúrò lórí fóònù àti kọ̀ǹpútà, inú mi sì dùn pé mo ṣe bẹ́ẹ̀. Mi ò tiẹ̀ mọ̀ ọ́n lára. Ní báyìí, mo ti wá ráyè ṣe àwọn nǹkan míì tó ṣe pàtàkì sí mi.”​—Sierra.

 “Ìṣẹ́jú ìṣẹ́jú ni mo máa ń yẹ ìkànnì àjọlò mi wò, mo sì máa ń da ara mi láàmú nípa ohun táwọn èèyàn bá sọ sí ohun tí mo gbé síbẹ̀. Kò rọrùn fún mi láti yọ ìkànnì àjọlò mi kúrò, àmọ́ nígbà tí mo ṣe bẹ́ẹ̀, ara tù mí, ọkàn mi sì balẹ̀.”​—Kate.

Ohun tó yẹ kó o ṣe

 Ṣègbọràn sáwọn òbí ẹ. Jẹ́ káwọn òbí ẹ rí i pé o ṣe tán láti ṣe ohun tí wọ́n bá sọ láìjẹ́ pé o kọ́kọ́ bínú tàbí ṣàríwísí wọn.

 Ìlànà Bíbélì: “Òmùgọ̀ eniyan a máa bínú, ṣugbọn ọlọ́gbọ́n a máa mú sùúrù.”​—Òwe 29:11, Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní.

 Àwọn kan lè sọ fún ẹ pé kó o ṣí ìkànnì àjọlò láìjẹ́ káwọn òbí ẹ mọ̀ tàbí kó o máa dọ́gbọ́n lò ó lẹ́yìn wọn. Tó o bá ṣe bẹ́ẹ̀, ó máa kó ẹ sí wàhálà. Torí pé ọkàn ẹ ò ní balẹ̀, ẹ̀rí ọkàn á sì máa dá ẹ lẹ́bi. Táwọn òbí ẹ bá sì pa dà mọ̀, inú wọn ò ní dùn sí ẹ, wọn ò sì ní fọkàn tán ẹ mọ́.

 Ìlànà Bíbélì: Ó “wù wá láti jẹ́ olóòótọ́ nínú ohun gbogbo.”​—Hébérù 13:18.

 Ronú nípa ìdí tí ìwọ náà ò fi ní lò ó. Bíi tàwọn ọ̀dọ́ tá a sọ̀rọ̀ wọn lókè, ìwọ náà lè ronú àwọn nǹkan tó lè mú kó o pinnu láti má ṣe lo ìkànnì àjọlò. Yàtọ̀ sí pé àwọn òbí ẹ sọ pé kó o má lo ìkànnì àjọlò, tó bá dá ìwọ fúnra ẹ lójú pé kò ṣe ẹ́ láǹfààní kankan, o lè pinnu pé o ò ní lò ó. Tó bá rí bẹ́ẹ̀, ojú ò ní tì ẹ́ láti sọ fáwọn ojúgbà ẹ pé o ò lo ìkànnì àjọlò, ó sì ṣeé ṣe kí wọ́n má fi ẹ́ ṣe yẹ̀yẹ́.

 Kókó ibẹ̀ ni pé: Ṣègbọràn sáwọn òbí ẹ, kó o sì ronú nípa àǹfààní tí ohun tí wọ́n sọ máa ṣe ẹ́. Ó ṣe tán, o ò ní kú tó o bá lo ìkànnì àjọlò nísinsìnyí.