Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

ÀWỌN Ọ̀DỌ́ BÉÈRÈ PÉ

Ṣé Ó Fi Bẹ́ẹ̀ Burú Kéèyàn Máa Ṣépè?

Ṣé Ó Fi Bẹ́ẹ̀ Burú Kéèyàn Máa Ṣépè?

“Mi ò ṣẹ̀ṣẹ̀ máa gbọ́ káwọn èèyàn máa ṣépè, ó ti mọ́ra. Mi ò tiẹ̀ wá kà á sí bàbàrà mọ́.”​—Christopher, 17.

“Mo máa ń ṣépè gan-an nígbà tí mo ṣì kéré. Àṣà yẹn tètè mọ́ mi lára, àmọ́ kò rọrùn fún mi rárá láti jáwọ́ nínú ẹ̀.”​—Rebecca, 19.

 Ìbéèrè

  •   Báwo ló ṣe máa ń rí lára ẹ tí àwọn míì bá ń ṣépè?

    •  Kì í ṣe mí ní nǹkan kan, ó ti mọ́ra.

    •  Ó máa ń ṣe mí bákan, àmọ́ mo kàn máa ń gbójú fò ó.

    •  Kì í bá mi lára mu rárá, torí ohun tí ò dáa ni mo kà á sí.

  •   Báwo lo ṣe máa ń ṣépè tó?

    •  Mi ò kí í ṣépè rárá

    •  Mo máa ń ṣépè lẹ́ẹ̀kọ̀ọ̀kan

    •  Mo sábà máa ń ṣépè

  •   Ojú wo ni ìwọ fi ń wo kéèyàn máa ṣépè?

    •  Kò fi bẹ́ẹ̀ burú

    •  Kò dáa rárá

 Ìdí tí ọ̀rọ̀ yìí fi ṣe pàtàkì

 Ṣé o rò pé ó burú kéèyàn máa ṣépè? O lè máa wò ó pé, ‘Kò le tóyẹn jàre. Kékeré nìyẹn lẹ́gbẹ̀ẹ́ àwọn ìṣòro míì tó wà láyé yìí. Ṣé ẹnì kan tiẹ̀ wà tí kì í ṣépè ni!’ Ṣé bẹ́ẹ̀ lọ̀rọ̀ rí lóòótọ́?

 Ṣó o fẹ́ gbọ́, ọ̀pọ̀ èèyàn ló wà tí kì í ṣépè. Ó nídìí tí wọn kì í fí ṣe bẹ́ẹ̀, ọ̀pọ̀ èèyàn sì lè tíì rò ó débẹ̀. Bí àpẹẹrẹ:

  •  Téèyàn bá ń ṣépè, ó ń jẹ́ ká mọ irú ẹni tó jẹ́. Ohun tó bá ń tẹnu ẹnì kan jáde máa jẹ́ ká mọ irú ẹni tó jẹ́. Téèyàn bá ń sọ̀rọ̀ tí ò dáa sáwọn míì, ó lè túmọ̀ sí pé ọ̀rọ̀ àwọn ẹlòmíì ò jọ ẹ́ lójú. Ṣé irú ẹni tó o jẹ́ nìyẹn?

     Bíbélì sọ pé: “Àwọn ohun tí ń jáde láti ẹnu ń jáde láti inú ọkàn-àyà.”​—Mátíù 15:18.

    Téèyàn bá ń ṣépè, ṣe ló dà bí ẹni ń tú èéfín burúkú sáfẹ́fẹ́. Irú òórùn bẹ́ẹ̀ lé kó bá àwọn míì, àti ìwọ fúnra ẹ gan-an

  •  Tó o bá ń ṣépè, àwọn èèyàn lè máa fojú tí ò dáa wò ẹ́. Ìwé Cuss Control sọ pé: “Ọ̀rọ̀ tó ń tẹnu wa jáde máa ń pinnu irú àwọn tó máa jẹ́ ọ̀rẹ́ wa, bí ìdílé wa àtàwọn tá à ń bá ṣiṣẹ́ á ṣe bọ̀wọ̀ fún wa tó, bí àjọṣe wa ṣe máa rí pẹ̀lú àwọn míì, ó máa ń pinnu báwọn èèyàn ṣe máa kà wá sí tó, bóyá wọ́n á gbà wá síṣẹ́ tó bá ṣẹlẹ̀ pé à ń wáṣẹ́ àbí bóyá àá rí ìgbéga lẹ́nu iṣẹ́ àti báwọn tá ò mọ̀ rí ṣe máa ṣe sí wa.” Ìwé náà tún sọ pé: “Rò ó wò ná, bóyá ká sọ pé o kì í ṣépè, àjọṣe ẹ pẹ̀lú àwọn míì ò bá dáa jù báyìí lọ.”

     Bíbélì sọ pé: “Ẹ mú . . . ọ̀rọ̀ èébú kúrò.”​—Éfésù 4:31.

  •  Tó o bá ń ṣépè, àwọn èèyàn ò ní gba tìẹ tó bó o ṣe rò. Nínú ìwé tí Dr. Alex Packer kọ, ìyẹn ìwé How Rude! ó sọ pé: “Ọ̀rọ̀ àwọn tó máa ń ṣépè kì í tà létí àwọn èèyàn.” Ó tún sọ pé àwọn tí ọ̀rọ̀ tí ò dáa kún ẹnu wọn “kì í sábà sọ̀rọ̀ ọgbọ́n, bí ẹni tó ní làákàyè, wọn kì í sì í káàánú àwọn ẹlòmíì. Tó ò bá lọ́rọ̀ gidi lẹ́nu, tọ́rọ̀ ẹ kì í nítumọ̀ sáwọn èèyàn, ó máa nípa lórí ìwọ fúnra ẹ pàápàá.”

     Bíbélì sọ pé: “Kí àsọjáde jíjẹrà má ti ẹnu yín jáde.”​—Éfésù 4:​29.

 Ohun tó o lè ṣe

  •  Fi ṣe àfojúsùn. O lè fi ṣe àfojúsùn rẹ pé láàárín oṣù kan tàbí kó máà tó bẹ́ẹ̀, o fẹ́ yíwà ẹ pa dà, o ò fẹ́ máa sọ̀rọ̀ burúkú lẹ́nu mọ́. O lè máa fi kàlẹ́ńdà wo déètì, kó o lè mọ bó o ṣe ń ṣe sí. Àmọ́ kó o lè rí i ṣe délẹ̀délẹ̀, ó ṣì láwọn nǹkan kan tó yẹ kó o ṣe. Bí àpẹẹrẹ:

  •  Máa yẹra fún fíìmù tàbí orin tó lè kó ọ̀rọ̀ burúkú sí ẹ lórí. Bíbélì sọ pé: “Ẹgbẹ́ búburú a máa ba ìwà rere jẹ́.” (1 Kọ́ríńtì 15:33) Kì í ṣe èèyàn nìkan lèèyàn lè bá kẹ́gbẹ́, èèyàn lè máa kẹ́gbẹ́ látinú fíìmù tó ń wò, géèmù tó ń gbá àti orin tó ń gbọ́. Kenneth, tó jẹ́ ọmọ ọdún mẹ́tàdínlógún [17] sọ pé: “Torí pé orin kan dùn, tó sì ṣeé jó sí, èèyàn lè bẹ̀rẹ̀ sí í bá wọn kọ ọ́, kó wá máa rò ó pé àwọn ọ̀rọ̀kọrọ̀ tó wà nínú orin náà kì í ṣe nǹkan bàbàrà.

  •  Fi hàn pé o dàgbà dénú. Ohun tí ọ̀pọ̀ èèyàn máa ń rò ni pé àwọn tó ti dàgbà ló máa ń sọ ọ̀rọ̀kọrọ̀. Àmọ́ irọ́ gbáà ni. Bíbélì sọ pé àwọn tó dàgbà dénú “tipasẹ̀ lílò kọ́ agbára ìwòye wọn láti fi ìyàtọ̀ sáàárín ohun tí ó tọ́ àti ohun tí kò tọ́.” (Hébérù 5:​14) Wọn kì í tìtorí pé àwọn fẹ́ gborúkọ lọ́dọ̀ àwọn míì ṣe ohun tí ò dáa.

 Bí òórùn burúkú ṣe ń ba afẹ́fẹ́ jẹ́ ni ọ̀rọ̀kọrọ̀ rí, ṣe ló máa ń gbin èròkerò síni lọ́kàn. Ọ̀rọ̀kọrọ̀ tiẹ̀ kún ẹnu àwọn èèyàn nínú ayé yìí! Ìwé Cuss Control ní: “Má fi tìẹ kún un. Ọ̀rọ̀kọrọ̀ ti kún ìgboro ná, ṣe ni kíwọ máa sọ̀rọ̀ tó dáa lẹ́nu. Inú tìẹ gan-an máa dùn síra ẹ, àwọn míì á sì máa fojú tó dáa wò ẹ́.”