Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

ÀWỌN Ọ̀DỌ́ BÉÈRÈ PÉ

Ìfẹ́sọ́nà—Apá Kejì: Kí Ló Yẹ Kí N Fi Sọ́kàn Tí Mo Bá Ń Fẹ́ Ẹnì Kan Sọ́nà?

Ìfẹ́sọ́nà—Apá Kejì: Kí Ló Yẹ Kí N Fi Sọ́kàn Tí Mo Bá Ń Fẹ́ Ẹnì Kan Sọ́nà?

 O ti wá rí ẹni tó wù ẹ́ báyìí, ẹ̀yin méjèèjì sì ti gbà láti máa fẹ́ra sọ́nà kẹ́ ẹ lè yẹ ara yín wò bóyá lọ́jọ́ kan ẹ̀ẹ́ fẹ́ra yín sílé. Kí ló yẹ kó o fi sọ́kàn bẹ́ ẹ ṣe ń fẹ́ra yín sọ́nà?

Nínú àpilẹ̀kọ yìí

 Fi sọ́kàn pé ẹ gbọ́dọ̀ máa bá ara yín sòótọ́ ọ̀rọ̀

 Ọ̀pọ̀ nǹkan ni ìwọ àti àfẹ́sọ́nà rẹ máa mọ̀ nípa ara yín bẹ́ ẹ ṣe ń wà pa pọ̀. Àwọn nǹkan kan sì wà tó o máa mọ̀ bó o ṣe ń kíyè sí ìwà àti ìṣe ẹnì kejì ẹ.

 Àmọ́, àwọn nǹkan kan wà tó yẹ kẹ́ ẹ bá ara yín sọ láì fọ̀rọ̀ pa mọ́ fúnra yín. Nírú àsìkò bẹ́ẹ̀, má ṣe jẹ́ kí ìfẹ́ kó sí ẹ lórí débi tí wàá fi ṣi ìpinnu ṣe. Dípò bẹ́ẹ̀, fara balẹ̀ ronú jinlẹ̀ kó o lè pinnu ohun tó yẹ kó o ṣe.

 Àwọn nǹkan tó yẹ kẹ́ ẹ sọ̀rọ̀ nípa ẹ̀ ni:

  •   Ìnáwó. Ṣé gbèsè wà lọ́rùn ẹ? Ṣé o kì í náwó ní ìnákúnàá? Tẹ ẹ bá ṣègbéyàwó, báwo lẹ̀ ẹ́ ṣe máa ná owó tó bá ń wọlé?

  •   Ìlera. Ṣé ìlera rẹ dáa? Ṣé àìsàn kan tó lágbára ti ṣe ẹ́ rí?

  •   Ohun tó o fẹ́ kọ́wọ́ rẹ tẹ̀. Kí lo fẹ́ fi ayé rẹ ṣe? Ṣé ohun tó o fẹ́ náà ni ọ̀rẹ́kùnrin tàbí ọ̀rẹ́bìnrin rẹ fẹ́? Ká sọ pé ọwọ́ ẹ ò tẹ ohun tó o fẹ́ lẹ́yìn ìgbeyàwó, ṣé wàá ṣì máa láyọ̀?

  •   Ìdílé. Ṣé o lẹ́ni tó ò ń gbọ́ bùkátà rẹ̀ nínú ìdílé ẹ? Bùkátà míì wo ló ṣeé ṣe kó já lé ẹ lọ́rùn lọ́jọ́ iwájú? Ṣé o fẹ́ bímọ? Tó bá jẹ́ bẹ́ẹ̀, ọmọ mélòó ló wù ẹ́ kó o bí?

 Tẹ́ ẹ bá ń jíròrò àwọn ọ̀rọ̀ yìí, gbogbo bọ́rọ̀ bá ṣe rí ni kó o sọ, má ṣe fọ̀rọ̀ sábé ahọ́n sọ. Má fi òótọ́ pa mọ́ torí kó o lè dà bí èèyàn dáadáa lójú ẹnì keji ẹ.​—Hébérù 13:18.

 Ohun tó yẹ kó o ronú lé: Kí ló yẹ kí n mọ̀ nípa ẹni tí mò ń fẹ́ sọ́nà? Kí ló yẹ kó mọ̀ nípa mi? Tẹ́ ẹ bá ń fọ̀rọ̀ pa mọ́ fún ara yín báyìí, ìyẹn lè mú kó ṣòro fún yín láti máa bára yín sòótọ́ ọ̀rọ̀ lèyín ìgbeyàwó.

 Ìlànà Bíbélì: “Ki olúkúlùkù yín kí ó máa ba ọmọnìkejì rẹ̀ sọ òtítọ́.”​—Éfésù 4:25, Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní.

 “Ó lè máa ṣe obìnrin bíi pé láàárín ‘oṣù mẹ́fà ó yẹ ká ti máa múra ìgbéyàwó,’ àmọ́ kí ọkùnrin máa rò pé ó ti yá jù, ó yẹ kó tó bí ọdún kan. Ní irú ipò yẹn, obìnrin lè rẹ̀wẹ̀sì kó máa ronú pé ọkìnrin yẹn ò nífẹ̀ẹ́ òun àti pé ó ń fi nǹkan falẹ̀. Torí náà, ó ṣe pàtàkì kí èrò àwọn méjèèjì ṣòkan lórí ọ̀rọ̀ náà.”​—Ariana, tó ti lo ọdún kan nílé ọkọ.

 Fi sọ́kàn pé èrò yín lè má bára mu nígbà míì

 Ìwà ẹni méjì ò le jọra. Torí náà, má ṣe ronú pé èrò ẹ àti bí nǹkan ṣe ń rí lára ìwọ àti àfẹ́sónà ẹ máa rí bákan náà. Bí àpẹẹrẹ, ibi tẹ́ ẹ dàgbà sí àti bí wọ́n ṣe tọ́ yín lè mú kí èró yín yàtọ̀.

 Ohun tó yẹ kó o ronú lé: Tí èrò ẹ̀yin méjèèjì bá yàtọ̀ lórí ọ̀rọ̀ tí kò tó nǹkan, tí ò sì sí ìlànà Bíbélì kan pàtó tó sọ̀rọ̀ nípa nǹkan náà, ṣé ẹ̀yin méjèèjì ṣe tán láti gbà fún ara yín kí àlàáfía lè wà?

 Ìlànà Bíbélì: “Ẹ jẹ́ kí gbogbo èèyàn rí i pé ẹ̀ ń fòye báni lò.”​—Fílípì 4:5.

 “Kò sí bẹ́ ẹ ṣe mọwọ́ ara yín tó, ó máa ní àwọn ìgbà kan tí ọ̀rọ̀ yín ò ní bára mu. Ó ṣe pàtàkì kẹ́ ẹ mọwọ́ ara yín lóòótó, àmọ́ ohun tó ṣe pàtàkì jù tó yẹ kó o kíyè sí ni bí ẹnì kejì ṣe máa ń hùwà nígbà tí ọ̀rọ̀ yín ò bá jọra.”​—Matthew, tó ti ṣègbéyàwó fún ọdún márùn-ún.

 Fi sọ́kan pé ìfẹ́sọ́nà máa ní àwọn ìṣòro tiẹ̀

 Kò sí àní-àní pé fífẹ́ ẹnì kan sọ́nà máa gba àkókó ẹ gan-an, ìyẹn sì le fa àwọn ìṣòro kan. Àmọ́ kí ló lè ràn ẹ́ lọ́wọ́?

 Má ṣe pa àwọn nǹkan pàtàkì míì tì. Má ṣe tìtorí pé ò ń fẹ́ ẹnì kan sọ́nà kó o wá pa àwọn nǹkan míì tó ṣe pàtàkì tì tàbí kó o pa àwọn ọ̀rẹ́ rẹ tì. Alana tó ti lo ọdún márùn-ún (5) nílé ọkọ sọ pé: “O ṣì máa nílò àwọn ọ̀rẹ́ rẹ lẹ́yìn tó o bá ṣe ìgbéyàwó, àwọn náà sì máa nílò rẹ. Má pa wọ́n tì torí pé ò ń fẹ́ ẹnì kan sọ́nà.”

 Rántí pé tó o bá ṣègbéyàwó, ìyẹn ò túmọ̀ sí pé wàá pa gbogbo nǹkan míì tó wà nígbèésí ayé rẹ tì. Torí náà, àtìgbà tó o bá ti ń fẹ́ ẹnì kan sọ́nà ló ti yẹ kó o kọ́ bó o ṣe lè máa wáyè fáwọn nǹkan pàtàkì míì.

 Ohun tó yẹ kó o ronú lé: Ṣé kì í ṣe pé o máa ń fẹ́ kí ẹnì kejì ẹ máa wáyè fún ẹ ní gbogbo ìgbà? Ṣé ó máa ń ṣe ẹ́ bíi pé ohun tí ẹnì kejì ẹ ń fẹ́ látọ̀dọ̀ ẹ ti pọ̀ jù? Báwo lẹ̀yin méjèèjì ṣe lè ṣe é, tí ẹ ò fi ní máyé sú ara yín?

 Ìlànà Bíbélì: “Ohun gbogbo ni àkókò wà fún, àkókò wà fún gbogbo iṣẹ́.”​—Oníwàásù 3:1.

 “Tó bá jẹ́ pé fàájì àti ìgbádùn nìkan lẹ máa ń fi àkókó yín ṣe nígbà tí ẹ̀ ń fẹ́ra yín sọ́nà, nǹkan lè nira díẹ̀ nígbà tẹ́ ẹ bá ṣégbéyàwó. Torí náà, ó dáa káwọn tó ń fẹ́ra wọn sọ́nà jọ máa ṣe àwọn nǹkan pàtàkì pa pọ̀ bíi lílọ sọ́jà, títún ilé ṣe, kí wọ́n sì jọ máa lọ́wọ́ nínú ìjọsìn Jèhófà. Ìyẹn á jẹ́ káwọn nǹkan yìí rọrùn fún wọn láti máa ṣe lẹ́yìn ìgbéyàwó.”​—Daniel, tó ti ṣègbéyàwó fún ọdún méjì.

 Ẹ má gbàgbé pé, ìdí tẹ́ ẹ fi ń fẹ́ra yín sọ́nà ni kẹ́ ẹ lè wo ara yín fún ìgbà díẹ̀, ìyẹn á jẹ́ kẹ́ ẹ lè pinnu bóyá kẹ́ ẹ ṣègbéyàwó tàbí kẹ́ ẹ má ṣe bẹ́ẹ̀. Ní apá kẹta, a máa sọ̀rọ̀ nípa àwọn nǹkan tó yẹ kó o ronú lé kó o tó ṣèpinnu yẹn.