Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

ÀWỌN Ọ̀DỌ́ BÉÈRÈ PÉ

Kí Nìdí Tó Fi Dáa Kéèyàn Kọ́ Èdè Míì?

Kí Nìdí Tó Fi Dáa Kéèyàn Kọ́ Èdè Míì?

 Tó o bá ń kọ́ èdè míì, ó máa jẹ́ kó o mọ̀ bóyá o máa ń fọwọ́ pàtàkì mú nǹkan, á sì jẹ́ kó o mọ bó o ṣe nírẹ̀lẹ̀ tó. Àmọ́ ṣé ó lérè ṣá? Ọ̀pọ̀ ọ̀dọ́ ló máa dáhùn pé bẹ́ẹ̀ ni! Àpilẹ̀kọ yìí máa ṣàlàyé ìdí táwọn ọ̀dọ́ fi ń kọ́ èdè míì.

 Kí ló lè mú kó o kọ́ èdè míì?

 Ohun tó máa ń mú kí ọ̀pọ̀ kọ́ èdè míì ni pé ó wà lára ohun tí wọ́n gbọ́dọ̀ kọ́ níléèwé wọn. Bẹ́ẹ̀ sì rèé, ṣe ló wu àwọn kan kí wọ́n kọ́ èdè míì. Bí àpẹẹrẹ:

  •   Obìnrin kan tó ń jẹ́ Anna lórílẹ̀-èdè Ọsirélíà pinnu pé òun máa kọ́ èdè ìbílẹ̀ ìyá òun, ìyẹn èdè Latvian. Anna sọ pé, “Ìdílé wa fẹ́ rìnrìn àjò lọ sórílẹ̀-èdè Latvia, á sì wù mí kí n lè bá àwọn mọ̀lẹ́bí mi sọ̀rọ̀ tá a bá débẹ̀.”

  •   Gina, tó jẹ́ Ẹlẹ́rìí Jèhófà láti orílẹ̀-èdè Amẹ́ríkà kọ́ Èdè Àwọn Adití lọ́nà ti Amẹ́ríkà (ìyẹn ASL), ó sì kó lọ sórílẹ̀-èdè Belize kó lè lọ wàásù níbẹ̀. Ó sọ pé, “Àwọn adití kì í rí èèyàn púpọ̀ bá wọn sọ̀rọ̀ torí ìwọ̀nba èèyàn ló gbọ́ èdè wọn. Torí náà, àwọn èèyàn máa ń mọrírì ẹ̀ gan-an tí mo bá sọ fún wọn pé torí kí n lè máa kọ́ àwọn adití lóhun tó wà nínú Bíbélì ni mo ṣe kọ́ èdè wọn!”

 Ṣé o mọ̀ pé . . . Bíbélì sọ tẹ́lẹ̀ pé a máa wàásù ìròyìn ayọ̀ nípa Ìjọba Ọlọ́run fáwọn èèyàn ní “gbogbo orílẹ̀-èdè àti ẹ̀yà àti ahọ́n.” (Ìṣípayá 14:6) Àsọtẹ́lẹ̀ yìí sì ti ń ṣẹ, ọ̀pọ̀ àwọn ọ̀dọ́ tó jẹ́ Ẹlẹ́rìí Jèhófà ló ti kọ́ èdè míì kí wọ́n lè wàásù fáwọn míì nílùú wọn tàbí ní ilẹ̀ míì.

 Ìṣòro wo lo máa kojú?

 Kò rọrùn kéèyàn kọ́ èdè tuntun. Ọ̀dọ́bìnrin kan tó ń jẹ́ Corrina sọ pé, “Mo rò pé kò ju kéèyàn kọ́ bí wọ́n ṣe ń sọ èdè yẹn ni, àmọ́ mo wá rí i pé ó tún máa gba kéèyàn kọ́ àṣà wọn, kéèyàn sì mọ bí àwọn tó ń sọ èdè náà ṣe ń ronú. Ká sòótọ́, ó máa gba àkókò téèyàn bá fẹ́ kọ́ èdè.”

 Ó tún gba kéèyàn nírẹ̀lẹ̀. Ọ̀dọ́kùnrin kan tó ń jẹ́ James, tó kọ́ èdè Spanish sọ pé, “Gbà pé wàá máa fi ara ẹ rẹ́rìn-ín, torí àìmọye ìgbà ni wàá ṣàṣìṣe. Kò sí kírú ẹ̀ máà wáyé téèyàn bá ń kọ́ èdè.”

 Òótọ́ ibẹ̀ ni pé: Tí nǹkan ò bá lọ geere bó o ṣe ń kọ́ èdè tàbí tí àṣìṣe ń wáyé lẹ́ẹ̀kọ̀ọ̀kan, bó tiẹ̀ kó ìtìjú bá ẹ, àmọ́ tó ò jẹ́ kó sú ẹ, ẹ̀rí wà pé ó ṣeéṣe kó o mọ èdè tó ò ń kọ́ bópẹ́ bóyá.

 Àbá: Tó bá tiẹ̀ dà bíi pé àwọn míì ti ń mọ èdè náà jù ẹ́ lọ, fọkàn balẹ̀. Bíbélì sọ pé: “Kí olúkúlùkù máa wádìí ohun tí iṣẹ́ tirẹ̀ jẹ́, nígbà náà ni yóò ní ìdí fún ayọ̀ ńláǹlà ní ti ara rẹ̀ nìkan, kì í sì í ṣe ní ìfiwéra pẹ̀lú ẹlòmíràn.”​—Gálátíà 6:4.

 Èrè wo ló wà níbẹ̀?

 Ọ̀pọ̀ àǹfààní ló wà nínú kéèyàn kọ́ èdè míì. Bí àpẹẹrẹ, ọ̀dọ́ kan tó ń jẹ́ Olivia sọ pé, “Tó o bá kọ́ èdè míì, wàá mọ àwọn èèyàn sí i, wàá sì láwọn ọ̀rẹ́ tuntun.”

 Ọ̀dọ́bìnrin kan tó ń jẹ́ Mary rí i pé bóun ṣe ń kọ́ èdè míì kò jẹ́ kóun máa fojú kéré ara òun mọ́. Ó sọ pé, “Mi ò kí í lè fi ohunkóhun tí mo bá ṣe yangàn, àmọ́ ní báyìí tí mo ti ń kọ́ èdè kan, ṣe ni inú mi máa ń dùn tí mo bá ti mọ ọ̀rọ̀ kan. Kì í jẹ́ kí n wo ara mi pé mi ò mọ nǹkan kan ṣe, ó jẹ́ kí n rí i pé èmi náà wúlò láwùjọ.”

 Gina, tá a sọ̀rọ̀ rẹ̀ lẹ́ẹ̀kan ti rí i pé bóun ṣe ń fi èdè adití kọ́ àwọn èèyàn lẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì ti mú kóun túbọ̀ láyọ̀ bóun ṣe ń wàásù. Ó ní, “Kò sóhun tó dà bíi kéèyàn máa rí i pé àwọn èèyàn ń láyọ̀ torí pé wọ́n rẹ́ni bá wọn sọ̀rọ̀ lédè wọn!”

 Òótọ́ ibẹ̀ ni pé: Tó o bá kọ́ èdè míì, wàá lọ́rẹ̀ẹ́ tuntun, wàá níyì lójú ara ẹ, wàá sì túbọ̀ láyọ̀ bó o ṣe ń wàásù. Téèyàn bá kọ́ èdè míì, ọ̀nà pàtàkì ló jẹ́ láti wàásù ìhìn rere fún “gbogbo àwọn orílẹ̀-èdè àti ẹ̀yà àti ènìyàn àti ahọ́n.”​—Ìṣípayá 7:9.