Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

ÀWỌN Ọ̀DỌ́ BÉÈRÈ PÉ

Kí Ló Yẹ Kí N Mọ̀ Nípa Ọtí?

Kí Ló Yẹ Kí N Mọ̀ Nípa Ọtí?

 Bíbélì ò sọ pé ká má mu ọtí níwọ̀n, pàápàá tí òfin ilẹ̀ wa bá fọwọ́ sí i. Ṣùgbọ́n Bíbélì dẹ́bi fún ìmutípara.​—Sáàmù 104:15; 1 Kọ́ríńtì 6:​10.

 Àmọ́ kí ló yẹ kó o ṣe tí wọ́n bá fẹ́ sún ẹ mutí, tó o sì mọ̀ pé ó ta ko òfin láti ṣe bẹ́ẹ̀ lásìkò yẹn tàbí pé àwọn òbí ẹ ò fọwọ́ sí i?

 Ronú ohun tó lè ṣẹlẹ̀

 Àwọn ojúgbà ẹ kan lè máa wò ó pé ó yẹ kí ọtí wà níbi tẹ́ ẹ ti fẹ́ gbafẹ́. Àmọ́ tẹ́ ẹ bá mutí tán, kí ló lè ṣẹlẹ̀?

  •  Ọwọ́ òfin lè tẹ̀ yín. Tó o bá ṣe ohun tó ta ko òfin orílẹ̀-èdè yín lórí ọ̀rọ̀ ọtí mímu, wọ́n lè bu owó ìtanràn lé ẹ tàbí kí wọ́n fẹ̀sùn ọ̀daràn kàn ẹ́, wọ́n lè gba ìwé àṣẹ tó o fi ń wakọ̀ tàbí kí wọ́n fìyà jẹ ẹ́ pé kó o wá ṣiṣẹ́ sìnlú, wọ́n tiẹ̀ lè rán ẹ lọ sẹ́wọ̀n.​—Róòmù 13:3.

  •  Orúkọ ẹ lè bà jẹ́. Téèyàn bá ti mutí, ó lè bẹ̀rẹ̀ sí í ṣe bó ṣe wù ú. Ọtí lè mú kéèyàn bẹ̀rẹ̀ sí í sọ ìsọkúsọ tàbí kó máa ṣe ohun tí ò dáa, irú ẹ̀ sì máa ń duni tójú èèyàn bá ti wálẹ̀. (Òwe 23:31-​33) Níbi táyé sì lajú dé yìí, tí wọ́n ti ń gbé gbogbo nǹkan sórí íńtánẹ́ẹ̀tì, ohun tó o bá ṣe lè bà ẹ́ lórúkọ jẹ́.

  •  O lè má lè gbèjà ara ẹ. Tó o bá ti mutí, o lè má lè gbèjà ara ẹ tí wọ́n bá ń lù ẹ́ tàbí tí wọ́n bá fẹ́ fipá bá ẹ lòpọ̀. Ó tún lè mú káwọn míì máa tì ẹ́ ṣe ohun tí wọ́n ń ṣe, ìyẹn sì lè kó ẹ sí wàhálà tàbí kó o rúfin.

  •  Ó lè di bárakú. Ìwádìí kan fi hàn pé téèyàn bá ti ń ti kékeré mutí, ó ṣeé ṣe kó mọ́ ọn lára bó ṣe ń dàgbà. Téèyàn bá ń mutí torí pé ó ti rẹ̀ ẹ́, torí pé ó dá nìkan wà tàbí tó ń fi pàrònú rẹ́, ó máa mọ́ ọn lára, á sì ṣòro gan-an láti jáwọ́.

  •  Ó lè yọrí sí ikú. Lọ́dún kan lẹ́nu àìpẹ́ yìí, ìwádìí kan tí wọ́n ṣe lórílẹ̀-èdè Amẹ́ríkà fi hàn pé ẹnì kan máa ń kú ní nǹkan bíi wákàtí kọ̀ọ̀kan torí ìwàkuwà táwọn tó ti mutí máa ń wà. Nígbà kan, láàárín ọdún márùn-ún, àwọn ọ̀dọ́ tó lé ní ẹgbẹ̀rún kan ààbọ̀ [1500] tí wọn ò tíì pé ọmọ ọdún mọ́kànlélógún [21] ló ń kú lọ́dọọdún nínú jàǹbá ọkọ̀ torí àwọn tó wa ọkọ̀ ti mutí. Tí ìwọ ò bá tiẹ̀ mu ọtí, ẹ̀mí ara ẹ lo fi ń wewu tó bá jẹ́ ẹni tó ti mutí ló fẹ́ wa ọkọ̀ tó o máa wọ̀.

 Pinnu ohun tí wàá ṣe

 Tó o bá ti pinnu ohun tí wàá ṣe ṣáájú, o ò ní kóra ẹ sí wàhálà, o ò sì ní kó sínú ewu tí ọtí mímu máa ń fà.

 Ìlànà Bíbélì: “Afọgbọ́nhùwà ni ẹni tí ó ti rí ìyọnu àjálù, tí ó sì bẹ̀rẹ̀ sí fi ara rẹ̀ pa mọ́.” (Òwe 22:3) Kò bọ́gbọ́n mu kéèyàn mutí kó tó wakọ̀ tàbí kó tó ṣe ohun míì tó máa gbà pé kó pọkàn pọ̀.

 Ìpinnu: ‘Tí mo bá máa mutí, mi ò ní ṣe é lọ́nà tó máa ta ko òfin, àsìkó tó tọ́ ni màá sì mú.’

 Ìlànà Bíbélì: “Ẹ̀yin jẹ́ ẹrú rẹ̀ nítorí ẹ ń ṣègbọràn sí i.” (Róòmù 6:​16) Tó o bá mu ọtí torí àwọn ojúgbà ẹ ń mu ún, o ti ń jẹ́ káwọn míì máa darí ẹ nìyẹn. Tó o bá sì ń mu ọtí torí kó o lè pàrònú rẹ́ tàbí torí pé ó ti rẹ̀ ẹ́, ohun tí ò dáa lo fi ń kọ́ra, torí o ò ní mọ bó ṣe yẹ kó o máa yanjú ìṣòro.

 Ìpinnu: ‘Mi ò ní jẹ́ káwọn ojúgbà mi tì mí mu ọtí.’

 Ìlànà Bíbélì: “Má ṣe wá wà lára àwọn tí ń mu . . . àmuyó kẹ́ri.” (Òwe 23:20) Tó o bá ń bá àwọn ọ̀rẹ́ tí ò dáa rìn, wọ́n lè mú kó o yẹ ìpinnu ẹ. Wàhálà lo fẹ́ tọrùn ara ẹ bọ̀ tó o bá ń bá àwọn tó ń mu ọtí nímukúmu rìn.

 Ìpinnu: ‘Mi ò ní máa bá àwọn tó ń mu ọtí nímukúmu rìn.’