Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

ÀWỌN Ọ̀DỌ́ BÉÈRÈ PÉ

Ṣó Burú Kí Ọkùnrin Máa Fẹ́ Ọkùnrin àbí Kí Obìnrin Máa Fẹ́ Obìnrin?

Ṣó Burú Kí Ọkùnrin Máa Fẹ́ Ọkùnrin àbí Kí Obìnrin Máa Fẹ́ Obìnrin?

 “Ọ̀kan lára àwọn ohun tó nira jù fún mi bí mo ṣe ń dàgbà ni bí ọkàn mi ṣe máa ń fà sí àwọn tó jẹ́ ọkùnrin bíi tèmi. Ohun tí mo máa ń rò tẹ́lẹ̀ ni pé tí mo bá dàgbà díẹ̀ sí i, kò ní ṣe mí bẹ́ẹ̀ mọ́, àmọ́ ọ̀rọ̀ ò rí bẹ́ẹ̀, ó ṣì máa ń ṣe mí.”​—David, 23.

 Kristẹni ni David, ó sì fẹ́ máa ṣe ohun tó máa múnú Ọlọ́run dùn. Àmọ́ ṣé ó lè máa ṣe bẹ́ẹ̀ pẹ̀lú bí ọkàn ẹ̀ ṣe ń fà sí àwọn tó jẹ́ ọkùnrin bíi tiẹ̀ yìí? Ojú wo ni Ọlọ́run fi ń wo àwọn ọkùnrin tó ń fẹ́ ọkùnrin àtàwọn obìnrin tó ń fẹ́ obìnrin?

 Kí ni Bíbélì sọ?

 Ojú tí àwọn èèyàn láti onírúurú ẹ̀yà fi ń wo kí ọkùnrin máa fẹ́ ọkùnrin tàbí kí obìnrin máa fẹ́ obìnrin máa ń yàtọ̀ síra, bọ́rọ̀ yìí sì ṣe máa ń rí lára àwọn èèyàn láyé àtijọ́ àti lóde òní lè yàtọ̀ síra. Àmọ́ kì í ṣe dandan kó jẹ́ pé ohun tí gbogbo ayé bá ń ṣe làwọn Kristẹni á máa ṣe, bẹ́ẹ̀ ni “afẹ́fẹ́ oríṣìíríṣìí ẹ̀kọ́” kì í “fẹ́ [wọn] káàkiri.” (Éfésù 4:​14, Bibeli Ìròyìn Ayọ̀) Àwọn ìlànà Bíbélì ni wọ́n máa ń tẹ̀ lé, tó máa ń jẹ́ kí wọ́n mọ ojú tó yẹ kí wọ́n fi wo kí ọkùnrin máa fẹ́ ọkùnrin tàbí kí obìnrin máa fẹ́ obìnrin, títí kan àwọn ọ̀rọ̀ míì.

 Ìlànà Bíbélì lórí ọ̀rọ̀ yìí ò lójú pọ̀ rárá. Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run sọ pé:

  •  “Ìwọ kò gbọ́dọ̀ sùn ti ọkùnrin bí ìwọ yóò ṣe sùn ti obìnrin.”​—Léfítíkù 18:22.

  •  “Ní ìbámu pẹ̀lú ìfẹ́-ọkàn tí ó wà nínú ọkàn-àyà wọn, Ọlọ́run . . . jọ̀wọ́ wọn lọ́wọ́ fún ìdálọ́rùn fún ìbálòpọ̀ takọtabo tí ń dójú tini, nítorí àwọn obìnrin wọn yí ìlò ara wọn lọ́nà ti ẹ̀dá padà sí èyí tí ó lòdì sí ìwà ẹ̀dá.”​—Róòmù 1:​24, 26.

  •  “Kí a má ṣì yín lọ́nà. Kì í ṣe àwọn àgbèrè, tàbí àwọn abọ̀rìṣà, tàbí àwọn panṣágà, tàbí àwọn ọkùnrin tí a pa mọ́ fún àwọn ète tí ó lòdì sí ti ẹ̀dá, tàbí àwọn ọkùnrin tí ń bá ọkùnrin dà pọ̀, tàbí àwọn olè, tàbí àwọn oníwọra, tàbí àwọn ọ̀mùtípara, tàbí àwọn olùkẹ́gàn, tàbí àwọn alọ́nilọ́wọ́gbà ni yóò jogún ìjọba Ọlọ́run.”​—1 Kọ́ríńtì 6:​9, 10.

 Ká sòótọ́, gbogbo èèyàn ló yẹ kó máa tẹ̀ lé àwọn ìlànà Ọlọ́run, ì báà jẹ́ pé ọkùnrin bíi tiwọn ni ọkàn wọn ń fà sí tàbí ẹlòmíì tí kì í ṣe ọkùnrin tàbí obìnrin bíi tiwọn. Gbogbo wa la gbọ́dọ̀ máa séra ró tó bá ń wù wá ká ṣe ohun tí Ọlọ́run ò fẹ́.​—Kólósè 3:5.

 Ṣé ó wá túmọ̀ sí pé . . . ?

 Ṣé ó wá túmọ̀ sí pé Bíbélì ní ká kórìíra àwọn ọkùnrin tó ń fẹ́ ọkùnrin àti àwọn obìnrin tó ń fẹ́ obìnrin?

 Rárá o. Bíbélì ò tiẹ̀ fẹ́ ká kórìíra ẹnikẹ́ni, ì báà jẹ́ ọkùnrin tó ń fẹ́ ọkùnrin tàbí ọkùnrin tó ń fẹ́ obìnrin. Ohun tó ní ká máa ṣe ni pé ká “máa lépa àlàáfíà pẹ̀lú gbogbo ènìyàn,” láìka irú ìwà tí wọ́n ń hù. (Hébérù 12:14) Torí náà, kò tọ́ ká máa halẹ̀ mọ́ àwọn ọkùnrin tó ń fẹ́ ọkùnrin àti àwọn obìnrin tó ń fẹ́ obìnrin, kò tọ́ ká máa hùwà ipá sí wọn torí pé a kórìíra wọn tàbí ká hùwà ìkà sí wọn lọ́nàkọnà.

 Ṣé ó wá túmọ̀ sí pé ó yẹ káwọn Kristẹni máa ta ko òfin ìjọba tó fọwọ́ sí i kí ọkùnrin máa fẹ́ ọkùnrin tàbí kí obìnrin máa fẹ́ obìnrin?

 Bíbélì jẹ́ ká mọ̀ pé ohun tí Ọlọ́run fọwọ́ sí ni pé ọkùnrin kan àti obìnrin kan ni kó máa fẹ́ra. (Mátíù 19:​4-6) Àmọ́ Bíbélì kọ́ ni àwọn ìjọba tó fọwọ́ sí i kí ọkùnrin máa fẹ́ ọkùnrin tàbí kí obìnrin máa fẹ́ obìnrin gbé òfin wọn kà, ọ̀rọ̀ òṣèlú ni. Bíbélì sì sọ pé káwọn Kristẹni má ṣe dá sí òṣèlú. (Jòhánù 18:36) Torí náà, àwọn Kristẹni kì í kọ́wọ́ ti òfin tí ìjọba ṣe pé kí ọkùnrin máa fẹ́ ọkùnrin tàbí kí obìnrin máa fẹ́ obìnrin, bẹ́ẹ̀ ni wọn kì í ta kò ó.

 Àmọ́ tí . . . ?

 Àmọ́ tí ọkùnrin kan bá ń fẹ́ ọkùnrin. Ṣé ẹni náà lè yí pa dà?

 Bẹ́ẹ̀ ni. Kódà, ní ọgọ́rùn-ún ọdún kìíní, àwọn kan tó ń hu irú ìwà yẹn yí pa dà! Lẹ́yìn tí Bíbélì sọ pé àwọn ọkùnrin tó ń fẹ́ ọkùnrin tàbí ọkùnrin tó ń fẹ́ obìnrin ò ní jogún Ìjọba Ọlọ́run, ó wá sọ pé: “Ohun tí àwọn kan lára yín ti jẹ́ rí nìyẹn.”​—1 Kọ́ríńtì 6:​11.

 Ṣé ìyẹn wá túmọ̀ sí pé kì í wu àwọn tó jáwọ́ nínú ìwà yẹn mọ́ kí wọ́n tún pa dà sídìí ẹ̀? Rárá. Bíbélì sọ pé: “Ẹ . . . fi àkópọ̀ ìwà tuntun wọ ara yín láṣọ, èyí tí a ń sọ di tuntun.” (Kólósè 3:​10) Ẹ̀ẹ̀kan náà kọ́ lèèyàn máa ń yí pa dà.

 Tí ẹnì kan bá fẹ́ ṣe ohun tí Ọlọ́run fẹ́, àmọ́ tó ṣì ń ṣe é bíi kó máa fẹ́ ọkùnrin tàbí obìnrin bíi tiẹ̀ ńkọ́?

 Tí èròkerò bá wá síni lọ́kàn, èèyàn lè yàn láti gbé e kúrò lọ́kàn tàbí kó séra ró. Ohun tí irú ẹni tó bá ṣì ń ṣe bíi kó máa fẹ́ ọkùnrin tàbí obìnrin bíi tiẹ̀ lè ṣe náà nìyẹn. Báwo ló ṣe lè ṣe é? Bíbélì sọ pé: “Ẹ máa rìn nípa ẹ̀mí, ẹ kì yóò sì ṣe ìfẹ́-ọkàn ti ẹran ara rárá.”​—Gálátíà 5:​16.

 Kíyè sí i pé ẹsẹ Bíbélì yẹn ò sọ pé ẹni náà ò ní ìfẹ́ ọkàn ti ẹran ara. Àmọ́ tó bá ń rìn nípa ẹ̀mí, ìyẹn ni pé, tó ń ka Bíbélì, tó sì ń gbàdúrà déédéé, ó máa lókun láti borí ìfẹ́kúfẹ̀ẹ́ yẹn.

 David, tá a sọ̀rọ̀ rẹ̀ lẹ́ẹ̀kan, rí i pé òótọ́ ni. Ó sọ ohun tó ń ṣe é fún àwọn òbí ẹ̀ tí wọ́n jẹ́ Kristẹni. Nígbà tó sọ fún wọn, ó sọ pé, “Ṣe ló dà bí ìgbà tí wọ́n gbé ẹrù ńlá kan kúrò lórí mi, ara sì tù mí. Ká sọ pé mo tètè sọ fún wọn ni, mi ò bá gbádùn ìgbà ọ̀dọ́ mi dáadáa ju bí mo ṣe gbádùn ẹ̀ lọ.”

 Tá a bá ń tẹ̀ lé àwọn ìlànà Jèhófà, ayé wa máa dùn gan-an. Ó dá wa lójú pé àwọn ìlànà Ọlọ́run “dúró ṣánṣán, wọ́n ń mú ọkàn-àyà yọ,” àti pé “èrè ńlá wà nínú pípa wọ́n mọ́.”​—Sáàmù 19:​8, 11.