Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

ÀWỌN Ọ̀DỌ́ BÉÈRÈ PÉ

Kí Nìdí Tí Mo Fi Ń Gba Òdo Nílé Ìwé?

Kí Nìdí Tí Mo Fi Ń Gba Òdo Nílé Ìwé?

 “Ọ̀pọ̀ àwọn ọmọ kíláàsì mi máa wá sí ilé ìwé láì mú ìwé kankan dání, wọ́n á sì máa gbọ́ orín látinú ẹ̀rọ gbohùngbohùn tí wọ́n kí okùn rẹ̀ bọ́ etí nígbà tí olùkọ́ ń kọ́ wa níṣẹ́. Tó bá yá, àwọn akẹ́kọ̀ọ́ yìí á sọ pé àwọn ò mọ ìdí tí àwọn ò fi yege ìdánwò! Àmọ́, àwọn kan wá bí irú èmi báyìí tó máa kàwé bí ẹni máa kù, síbẹ̀ tó tún máa fìdí rẹmi nígbà tí èsì ìdánwò bá dé. Kí n sòótọ́, kò yé mi. Ó máa ń dún mí gan-an pé mo fìdí rẹmi lẹ́yìn tí mó ti kàwé ní gbogbo òru fún odindi ọ̀sẹ̀ kàn.”​—Yolanda.

 Ṣé bó ṣe rí lára Yolanda ló ṣe ń ṣèwọ náà? Òótọ́ ibẹ̀ ni pé, ó máa ń dún èèyàn gan-an téèyàn bá fìdí rẹmi tàbí tó ń gba òdo jọ.

 Àwọn ọ̀dọ́ kan ò gbìyànjú láti ṣé dáadáa mọ kí máàkì wọn lè lọ sókè sí i torí pé ó ti sú wọn. Àwọn kan tiẹ̀ lè pinnu pé àwọn ò lọ sílé ìwé mọ́. Ọ̀nà méjì tá a sọ yìí lè dà bí ojútùú àmọ́ ọ̀nà míì wà téèyàn lè gbà bójú tó o. Kíyè sí ohun mẹ́fà tó máa ràn ẹ̀ lọ́wọ́ kó o lè ṣàṣeyege.

 Ohun tó o lè ṣe

  •   Máa lọ sí ilé ẹ̀kọ́ déédéé. O lè rò pé kò sẹ́ni tí kò mọ̀ bẹ́ẹ̀, àmọ́ tó bá jẹ́ pé ó kì í lọ sí ilé ẹ̀kọ́ lọ́pọ̀ ìgbà, máàkì rẹ máa lọ sílẹ̀ gan-an.

     “Nílé ìwé mi, àwọn ọmọ tí ọ̀rọ̀ nípa bí máàkì wọn ṣe ń lọ sílẹ̀ ò kà lára ni kì í sábà wá sílé ìwé, èyí sì túbọ̀ máa ń kò bá wọn sí i.”​—Matthew.

     Ìlànà Bíbélì: “Ohun tí èèyàn bá gbìn, òun ló máa ká.”​—Gálátíà 6:7.

  •   Rí i pé àwọn ohun tí wọ́n ń kọ́ ẹ yé ẹ. Ti pé ò ń lọ sílé ẹ̀kọ́ déédéé nìkan ò tó, o tún gbọ́dọ̀ rí i pé ò ń ṣe gbogbo ohun tó yẹ kó o ṣe kó o lè jàǹfààní lẹ́kùn-ún-rẹ́rẹ́. Máa kọ́ ohun tí wọ́n bá ń kọ́ ẹ sílẹ̀. Sapá kí ohun tí olùkọ́ ń kọ́ ẹ lè yẹ́ ẹ. Tí wọ́n bá sì gbà bẹ́ẹ̀, béèrè ìbéèrè nígbà tí wọ́n ń kọ́ yín lọ́wọ́.

     “Mo máa ń béèrè ọ̀pọ̀ ìbéèrè lọ́wọ́ àwọn olùkọ́ wa nígbà tí wọ́n bá ń kọ́ wa torí mo mọ̀ pé olùkọ́ wa máa túbọ̀ ṣàlàyé ẹ̀kọ́ náà tó bá mọ pé kò tíì ye ọ̀kan lára àwọn akẹ́kọ̀ọ́ òun.”​—Olivia.

     Ìlànà Bíbélì: “Ẹ kíyè sí bí ẹ ṣe ń fetí sílẹ̀.”​—Lúùkù 8:18.

  •   Má ṣe jí ìwé wò. Ìwà àìṣòótọ́ ni kéèyàn máa jí ìwé wò. Onírúurú ọ̀nà lèèyàn sì lè gbà ṣe bẹ́ẹ̀ nílé ìwé. Ọ̀nà kan ni kéèyàn máa da iṣẹ́ ẹlòmíì kọ. Yàtọ̀ sí pé ó jẹ́ ìwà àìṣòótọ́, kì í jẹ́ kéèyàn mọ̀wé.

     “Tí ohun kan ò bá yé ẹ, má ṣe da iṣẹ́ àwọn akẹ́kọ̀ọ́ ẹlẹgbẹ́ rẹ kọ. Tó o bá ń jí ìwé wo, ṣe ló ń túbọ̀ kó bá ara rẹ. Dípò kó o wá bó o ṣe máa yanjú ìṣòro rẹ fúnra rẹ, ńṣe ló ń kọ́ ara rẹ láti jẹ́ kí àwọn míì pinnu ohun tó o máa ṣe fún ẹ.”​—Jonathan.

     Ìlànà Bíbélì: “Kí kálukú máa yẹ ohun tó ń ṣe wò, nígbà náà, yóò láyọ̀ nítorí ohun tí òun fúnra rẹ̀ ṣe.”​—Gálátíà 6:4.

  •   Jẹ́ kí iṣẹ́ àṣetiléwá gbá ipò àkọ́kọ́. Tó bá ṣeé ṣe, ṣe iṣẹ́ àṣetiléwá rẹ̀ ṣáájú kó o tó ṣe àwọn nǹkan míì, ní pàtàkì eré ìmárale. a Tó o bá ṣe bẹ́ẹ̀, wàá gbádùn àsìkò tó o fi ń ṣeré!

     “Àtìgbà tí mo ti máa ń ṣe iṣẹ́ àṣetiléwá mi ṣáájú kí n tó ṣe ohun èyíkéyìí ni máàkì mi ti dáa sí i. Tí mo bá dé ilé lẹ́yìn tí mo kúrò nílé ẹ̀kọ́, ó kọ́kọ́ máa ń ṣe mi bíi pé kí ń sùn àbí kí n gbọ́ orín. Ṣùgbọ́n, mo máa ń rí sí i pé iṣẹ́ àṣetiléwá ni mo kọ́kọ́ ṣe, lẹ́yìn náà ni màá tó wá sinmi.”—Calvin.

     Ìlànà Bíbélì: “Máa wádìí dájú àwọn ohun tó ṣe pàtàkì jù.”​—Fílípì 1:10.

  •   Ní kí àwọn míì ràn ẹ́ lọ́wọ́. Má jẹ́ kí ojú tì ẹ́ débi tó ò fi ní sọ pé káwọn èèyàn ràn ẹ́ lọ́wọ́. Ní káwọn òbí ẹ̀ fún ẹ nímọ̀ràn. Bi olùkọ́ rẹ̀ pé kí làwọn ohun tó o lè ṣe kí máàkì rẹ lè túbọ̀ dáa sí i. Nígbà míì, o lè ní káwọn tó mọ̀wé jù ẹ lọ ràn ẹ́ lọ́wọ́.

     “Lọ́ bá olùkọ́ ẹ ní níwọ nìkan. Sọ fún un pé kó ràn ẹ́ lọ́wọ́ kó o lè lóye iṣẹ́ tó ń kọ́ ẹ, kó o sì lè túbọ̀ gba máàkì tó dáa sí i. Inú olùkọ́ rẹ máa dùn tó bá rí i pé ó wù ẹ́ láti ṣe dáadáa sí i, ó sì máa ràn ẹ́ lọ́wọ́.”​—David.

     Ìlànà Bíbélì: “Nípasẹ̀ ọ̀pọ̀ agbani-nímọ̀ràn, àṣeyọrí á wà.”​—Òwe 15:22.

  •   Lo gbogbo àǹfààní tó bá yọjú. Láwọn orílẹ̀-èdè kan, àwọn ìdánwò kan wa tó lè jẹ́ kí máàkì rẹ dáa sí i. O tiẹ̀ lè ní kí wọn fún ẹ láwọn iṣẹ́ àṣetiléwá tó máa túbọ̀ jẹ́ kí máàkì rẹ lọ sókè. Tó o bá tiẹ̀ fìdí rẹmi nínú ìdánwò, o lè ní kí wọ́n fún ẹ láǹfààní kó o lè tún un ṣe.

    Tó o bá ń sapá kí máàkì rẹ lè sunwọ̀n sí i dà bí ìgbà tó ò ń kọ́ bó o ṣe máa mọ ohun èlò kan lò dáádáá. Iṣẹ́ àṣekára ni, àmọ́ èrè tó wà níbẹ̀ tó bẹ́ẹ̀ ó jù bẹ́ẹ̀ lọ

     “Tí mo bá fẹ́ kí máàkì mi dáa sí i nínú iṣẹ́ ilé ẹ̀kọ́ kan, mo gbọ́dọ̀ kọ́kọ́ gbé ìgbésẹ̀. Màá bi àwọn olùkọ́ mi bóyá ọ̀nà kan wa tí mo lè gbé e gbà, bíi kí ńnṣe iṣẹ́ àṣetiléwá tó máa jẹ́ kí máàkì mi ga díẹ̀ sí i tàbí bóyá mó lè tún àwọn iṣẹ́ tí wọ́n gbé fún mi ṣe kí máàkì mi lè sunwọ̀n sí i.”​—Mackenzie.

     Ìlànà Bíbélì: “Gbogbo iṣẹ́ àṣekára ló ní èrè.”​—Òwe 14:23.

a Wàá rí àwọn àbá tó máa ràn ẹ́ lọ́wọ́ kó o lè túbọ̀ gbájú mọ́ ẹ̀kọ́ rẹ nínú àpilẹ̀kọ náà, “Àwọn Ọ̀dọ́ Béèrè Pé . . . Ṣé Apá Mi Á Ká Àwọn Iṣẹ́ Àṣetiléwá Báyìí?