Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

ÀWỌN Ọ̀DỌ́ BÉÈRÈ PÉ

Kí Ló Yẹ Kí N Mọ̀ Nípa Ìfipá Báni Ṣèṣekúṣe?​—Apá 1: Bó O Ṣe Lè Yẹra Fún un

Kí Ló Yẹ Kí N Mọ̀ Nípa Ìfipá Báni Ṣèṣekúṣe?​—Apá 1: Bó O Ṣe Lè Yẹra Fún un

 Kí ni ìfipá báni ṣèṣekúṣe?

 Bó tilẹ̀ jẹ́ pé oríṣiríṣi ọ̀nà ni wọ́n gbà ń túmọ̀ rẹ̀, àmọ́ “ìfipá báni ṣèṣekúṣe” ni ọ̀nà tí wọ́n lè gbà fi ipá bá ẹnì kan lòpọ̀ láì jẹ́ pé ẹni náà nífẹ̀ẹ́ sí i. Ó ní nínú bíbá àwọn ọmọdé lò pọ̀ lọ́nà àìtọ́, ìbálòpọ̀ láàárín ìbátan, ìfipá báni lòpọ̀, àti kí “àwọn tá a gbára lé” bíi àwọn dókítà, olùkọ́, tàbí olórí ìsìn fipá báni lòpọ̀. Ọ̀pọ̀ nínú àwọn tó bá ṣẹlẹ̀ sí, ni àwọn tó bá fipá bá wọn ṣèṣekúṣe máa ń halẹ̀ mọ́ pé wọn ò gbọ́dọ̀ sọ fún ẹnikẹ́ni.

 Ìwádìí kan tí wọ́n ṣe lórílẹ̀-èdè Amẹ́ríkà, fi hàn pé lọ́dọọdún nǹkan bí ẹgbàá márùnlélọ́gọ́fà [250,000] èèyàn ni wọ́n ń fipá bá lòpọ̀. Èyí tó sì pọ̀ jù nínú wọn ló wà láàárín ọmọ ọdún méjìlá [12] sí méjìdínlógún [18].

 Ohun tó yẹ kó o mọ̀ nípa rẹ̀

  •   Bíbélì dẹ́bi fún ìfipá báni ṣèṣekúṣe. Bíbélì sọ̀rọ̀ nípa ìṣẹ̀lẹ̀ kan tó wáyé ní nǹkan bí ẹgbẹ̀rún mẹ́rin [4,000] ọdún sẹ́yìn ní ìlú Sódómù, nígbà yẹn àwọn kan tí ìbálòpọ̀ ń sín níwín fẹ́ fipá bá àwọn ọkùnrin méjì kan tó ṣèbẹ̀wò sí ìlú náà lò pọ̀, ohun tó ṣẹlẹ̀ yìí ló fà á tí Jèhófà fi pa ìlú náà run. (Jẹ́nẹ́sísì 19:4-​13) Bákan náà, nínú òfin tí Ọlọ́run fún Mósè ní nǹkan bí ẹgbẹ̀rún mẹ́ta ààbọ̀ [3,500] ọdún sẹ́yìn, Ọlọ́run dẹ́bi fún ìbálòpọ̀ láàárín ìbátan, títí kan fífipá bá mọ̀lẹ́bí ẹni lò.​—Léfítíkù 18:6.

  •   Ojúlùmọ̀ làwọn tó sábà máa ń fipá báni ṣèṣekúṣe. Ìwé Talking Sex With Your Kids sọ pé: “Èyí tó pọ̀ jù nínú àwọn tí wọ́n fipá bá lòpọ̀ ní kì í ṣe àjèjì sí ẹni tó fipá bá wọn lò pọ̀ wọ́n ti máa ní láti mọra rí.”

  •   Tọkùnrin tobìnrin ni wọ́n máa ń fipá bá ṣèṣekúṣe. Ní orílẹ̀-èdè Amẹ́ríkà, ìdá kan nínú mẹ́wàá àwọn tí wọ́n ń fipá bá lòpọ̀ ló jẹ́ ọkùnrin. Gẹ́gẹ́ bí àjọ Rape, Abuse & Incest National Network (RAINN) ṣe sọ, àwọn ọkùnrin tí wọ́n ń fipá bá lò pọ̀ “lè máa bẹ̀rù pé àwọn lè di ọkùnrin tó ń bá ọkùnrin lò pọ̀ tàbí kí wọ́n máa rò ó pé àwọn ‘ò kì í ṣe ọkùnrin.’”

  •   Kò yà wá lẹ́nu bí ìfipá báni ṣèṣekúṣe ṣe gbilẹ̀ yìí. Bíbélì ti sọ tẹ́lẹ̀ pé ní “àwọn ọjọ́ ìkẹyìn” ọ̀pọ̀ èèyàn yóò di “aláìní ìfẹ́ni àdánidá” wọn yóò sì ya “òǹrorò” àti “aláìní ìkóra-ẹni-níjàánu.” (2 Tímótì 3:​1-3) Àwọn àmì yìí sì fara hàn kedere lára àwọn tí wọ́n ń bá àwọn èèyàn ṣèṣekúṣe.

  •   Kì í ṣe ẹni tí wọ́n fipá bá ṣèṣekúṣe ló jẹ̀bi. Kò sí ẹni tó lẹ́tọ̀ọ́ sí pé kí wọ́n bá òun ṣèṣekúṣe. Ẹni tó fipá bá èèyàn ṣèṣekúṣe gan-an ni ọ̀daràn. Àmọ́, o lè ṣe nǹkan tí kò ní jẹ́ kí wọ́n fipá bá ẹ ṣèṣekúṣe.

 Ohun tó o lè ṣe

  •   Múra sílẹ̀. Rí i dájú pé ò ti mọ ohun tí wà á ṣe tí ẹnìkan bá fẹ́ fipá bá ọ ṣèṣekúṣe ì bá à jẹ́ àfẹ́sọ́nà rẹ tàbí mọ̀lẹ́bí rẹ. Ọ̀dọ́bìnrin kan tó ń jẹ́ Erin dábàá pé láti múra sílẹ̀ fún ewu ìfipá báni ṣèṣekúṣe èyíkéyìí, o lè ṣè ìdánrawò àwọn ohun tó o máa ṣe tí o bá kíyèsí pé ẹnì kan fẹ́ fipá bá ẹ ṣèṣekúṣe. Erin wá sọ pé: “Lóòótọ́ ó lè má nítumọ̀ sí ẹ, àmọ́ tọ́rọ̀ náà bá délẹ̀ tán, wàá rí i pé ó gbéṣẹ́ torí kò ní ṣòro fún ẹ láti sá kúrò níbẹ̀.”

     Bíbélì sọ pé: “Nítorí náà, ẹ máa ṣọ́ra lójú méjèèjì pé bí ẹ ṣe ń rìn kì í ṣe gẹ́gẹ́ bí aláìlọ́gbọ́n ṣùgbọ́n gẹ́gẹ́ bí ọlọ́gbọ́n, . . . nítorí pé àwọn ọjọ́ burú.”​—Éfésù 5:​15, 16.

     Bi ara rẹ pé: ‘Kí ni màá ṣe tí ẹnì kan bá fọwọ́ kàn mí lọ́nà tí mi ò nífẹ̀ẹ́ sí?’

  •   Mọ ohun tí wàá ṣe. Àjọ RAINN dábàá pé “ó yẹ kí ìwọ àti ìdílé tàbí ọ̀rẹ́ rẹ ní ọ̀nà kan tí ẹ fi máa bá ara yín sọ̀rọ̀ tí ẹlòmíì kò ní mọ̀, torí tí o bá wà ní ipò kan tó ń ni ẹ́ lára wàá lè pe ìdílé tàbí ọ̀rẹ́ rẹ, tí àwọn tó wà lọ́dọ̀ rẹ kò sì ní mọ ohun tí ẹ̀ ń sọ, ẹni tó o bá pè yìí á lè wá pè ọ́ tàbí mú ọ kúrò níbẹ̀.” O lè dáàbò ara rẹ tí o bá ń yẹra fún àwọn ipò tó lè wu ọ́ léwu.

     Bíbélì sọ pé: “Afọgbọ́nhùwà ni ẹni tí ó ti rí ìyọnu àjálù, tí ó sì bẹ̀rẹ̀ sí fi ara rẹ̀ pa mọ́, ṣùgbọ́n aláìní ìrírí gba ibẹ̀ kọjá, yóò sì jìyà àbájáde rẹ̀.”​—Òwe 22:3.

     Bi ara rẹ pé: ‘Kí ni ohun tí màá ṣe tí mo bá wà ní ipò tó lè wu mí léwu?’

    Rí i pé gbogbo ìgbà ló máa ń mọ ohun tí wàá ṣe bí ipò nǹkan ò bá dára

  •   Pinnu ohun tí wàá ṣe má sì yẹ ìpinnu rẹ. Bí àpẹẹrẹ, tí o bá ń fẹ́ ẹnì kan sọ́nà, ó yẹ kí ìwọ àti àfẹ́sọ́nà rẹ̀ jọ sọ̀rọ̀ nípa ọ̀nà tó bójú mu tí ẹ jọ máa gbà bá ara yín lò. Tí àfẹ́sọ́nà rẹ kò bá fara mọ́ ìpinnu rẹ yìí, ṣe ni kó o wá ẹlòmíì tó máa lè fara mọ́ ìpinnu tó o bá ṣe.

     Bíbélì sọ pé: “Ìfẹ́ . . . kì í hùwà lọ́nà tí kò bójú mu, kì í wá àwọn ire tirẹ̀ nìkan.”​—1 Kọ́ríńtì 13:​4, 5.

     Bi ara rẹ pé: ‘Kí làwọn nǹkan tí mo lè fàyè gbà? Kí ni ẹnì kan lè ṣe fún mi tó máa fi hàn pé ẹni náà ti ń kọjá àyè rẹ̀?’