Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

ÀWỌN Ọ̀DỌ́ BÉÈRÈ PÉ

Kí Nìdí Tó Fi Yẹ Kó O Yẹra fún Wíwo Àwòrán Ìṣekúṣe?

Kí Nìdí Tó Fi Yẹ Kó O Yẹra fún Wíwo Àwòrán Ìṣekúṣe?

 Ṣé o lè ṣe é?

 Tó o bá ń lo íńtánẹ́ẹ̀tì déédéé, kò sí kó o má já lu oríṣiríṣi àwòrán ìṣekúṣe. Ọmọ ọdún mẹ́tàdínlógún [17] kan tó ń jẹ́ Hayley sọ pé: “Kò dìgbà tó o bá wá a kó o tó rí i, ńṣe ló dà bíi pé àwòrán ìṣekúṣe gan-an ló ń wá ẹ.”

 Kódà, wíwo àwòrán ìṣekúṣe máa ń dẹkùn mú àwọn tó ti pinnu láti má ṣe wò ó. Ọmọ ọdún méjìdínlógún [18] kan tó ń jẹ́ Greg sọ pé: “Mo máa ń sọ fún ara mi pé, mi ò ní wò ó, àmọ́ mo pàpà wò ó. Kò sẹ́ni tó lè fi ìdánilójú sọ pé kò lè ṣẹlẹ̀ sí òun.”

 Ibi tọ́rọ̀ wá burú sí ni pé ó rọrùn láti rí àwọn àwòrán ìṣekúṣe lónìí ju ti tẹ́lẹ̀ lọ. Ó tiẹ̀ ti wá ṣeé ṣe fún ẹnì kan láti fi àwòrán ìhòòhò ara rẹ̀ ránṣẹ́ sí ẹlòmíì.

 Òótọ́ ibẹ̀: Nǹkan ti wá burú gan-an nísinsìnyí ju ti ìgbà ayé àwọ́n òbí wa. Láìka èyí sí, ǹjẹ́ ó ṣeé ṣe láti yẹra fún wíwo àwòrán ìṣekúṣe?​—Sáàmù 97:10.

 Ó ṣeé ṣe tó bá fẹ́ ṣe bẹ́ẹ̀. Lákọ̀ọ́kọ́, o gbọ́dọ̀ gbà nínú ọkàn rẹ pé wíwo àwòrán ìṣekúṣe kò dáa. Ẹ jẹ́ ká wò díẹ̀ lára èrò òdì táwọn èèyàn ní nípa wíwo àwòrán ìṣekúṣe àti ohun tó jẹ́ òótọ́ ọ̀rọ̀.

 Èrò òdì àti òótọ́ ọ̀rọ̀

 Èrò òdì: Wíwo àwòrán ìṣekúṣe kò lè pa mí lára.

 Òótọ́ ọ̀rọ̀: Bí mímu sìgá ṣe máa ń ba ẹ̀dọ̀fóró jẹ́, bẹ́ẹ̀ náà ni wíwo àwòrán ìṣekúṣe máa ń ba ẹ̀rí ọkàn jẹ́. Ńṣe ló máa ń sọ èèyàn dìdàkudà. Ó tún máa ń tàbùkù sí ẹ̀bùn ìbálòpọ̀ tí Ọlọ́run fi mọ sáàárín àwọn tọkọtaya, èyí tí wọ́n fi ń fìfẹ́ hàn síra wọn. (Jẹ́nẹ́sísì 2:​24) Bọ́jọ́ ṣe ń gorí ọjọ́, ẹni náà kò ní ka nǹkan burúkú sí bàbàrà mọ́. Bí àpẹẹrẹ, àwọn olùṣèwádìí sọ pé àwọn ọkùnrin tó bá ti jingíri sínú wíwo àwòrán ìṣekúṣe kì í rí ohun tó burú nínú lílu àwọn obìnrin tàbí ṣíṣe wọn ṣúkaṣùka.

Bíbélì sọ pé àwọn kan ti “ré kọjá gbogbo agbára òye ìwà rere.” (Éfésù 4:19) Ẹ̀rí ọkàn irú àwọn ẹni bẹ́ẹ̀ ti kú pátápátá débi pé wọn kì í kábàámọ̀ ìwàkiwà èyíkéyìí tí wọ́n bá hù.

 Èrò òdì: Wíwo àwòrán ìṣekúṣe lè kọ́ èèyàn nípa ìbálòpọ̀.

 Òótọ́ ọ̀rọ̀: Wíwo àwòrán ìṣekúṣe máa ń sọni di aláìnítẹ̀ẹ́lọ́rùn. Ẹni tó bá ń wo àwòrán ìṣekúṣe máa ń rí àwọn ẹlòmíì bíi pé wọn kò wúlò fún nǹkan míì ju ìbálòpọ̀ lọ. Ìwádìí kan tiẹ̀ fi hàn pé àwọn tó bá ń wo àwòrán ìṣekúṣe lóòrèkóòrè kì í gbádùn ìbálòpọ̀ tó bí wọ́n ṣe rò lẹ́yìn tí wọ́n bá ṣègbéyàwó.

Bíbélì sọ pé àwọn Kristẹni gbọ́dọ̀ sá fún àwọn ìwà bí “àgbèrè, ìwà àìmọ́, ìdálọ́rùn fún ìbálòpọ̀ takọtabo, ìfẹ́-ọkàn tí ń ṣeni lọ́ṣẹ́, àti ojúkòkòrò.” Àwọn nǹkan wọ̀nyí ni wíwo àwòrán ìṣekúṣe máa ń gbé lárugẹ.​—Kólósè 3:5.

 Èrò òdì: Ìtìjú àtisọ̀rọ̀ nípa ìbálòpọ̀ ló ń ṣe àwọn tí kì í wo àwòrán ìṣekúṣe.

 Òótọ́ ọ̀rọ̀: Àwọn tí kì í wo àwòrán ìṣekúṣe máa ń ní èrò tó dáa nípa ìbálòpọ̀. Wọ́n gbà pé ìbálòpọ̀ jẹ́ ẹ̀bùn tí Ọlọ́run fún àwọn tọkọtaya kí ìfẹ́ àárín wọn lè túbọ̀ jinlẹ̀ sí i. Àwọn tó bá ní irú èrò yìí máa ń gbádùn ìbálòpọ̀ lẹ́yìn tí wọ́n bá ṣègbéyàwó.

Bíbélì kì í fọ̀rọ̀ sábẹ́ ahọ́n sọ tó bá kan ọ̀rọ̀ ìbálòpọ̀. Bí àpẹẹrẹ, ó gba àwọn ọkọ níyànjú pé: “Máa yọ̀ pẹ̀lú aya ìgbà èwe rẹ . . . Kí o máa yọ ayọ̀ púpọ̀ jọjọ nínú ìfẹ́ rẹ̀ nígbà gbogbo.”​—Òwe 5:​18, 19.

 Bí o ṣe lè yẹra fún wíwo àwòrán ìṣekúṣe

 Tó o bá rí i pé ó ṣòro fún ẹ láti yẹra fún wíwo àwòrán ìṣekúṣe ńkọ́? Abala ibi tí mo kọ èrò mi sí tí àkọlé rẹ̀ jẹ́ “Bí O Ṣe Lè Yẹra Fún Wíwo Àwòrán Ìṣekúṣe” lè ràn ẹ́ lọ́wọ́.

 Jẹ́ kó dá ẹ lójú pé o borí ìdẹwò láti wo àwòrán ìṣekúṣe. Ó tún lè jáwọ́ tó bá jẹ́ pé o ti máa ń wò ó tẹ́lẹ̀. Ó dájú pé, ó máa ṣe ẹ́ láǹfààní tó bá ṣe bẹ́ẹ̀.

 Wo àpẹẹrẹ Calvin tó ti ń wo àwòrán ìṣekúṣe látìgbà tó ti wà lọ́mọ ọdún mẹ́tàlá [13]. Ó sọ pé: “Mo mọ̀ pé kò dáa, àmọ́ mi ò kàn lè jáwọ́ nínú rẹ̀. Tí mo bá ti wá wò ó tán, ńṣe ni inú ara mi á máa bí mi. Nígbà tó yá, dádì mi mọ̀, kí n má purọ́, ìgbà yẹn lara tó tù mí! Wọ́n wá fún mi ní ìrànlọ́wọ́ tí mo nílò.”

 Calvin ti kọ́ bó ṣe máa jáwọ́ nínú wíwo àwòrán ìṣekúṣe. Ó sọ pé: “Mo kábàámọ̀ pé mo máa ń wo àwòrán ìṣekúṣe tẹ́lẹ̀ torí pé àwọn àwòrán náà ṣì máa ń wá sọ́kàn mi. Lẹ́ẹ̀kọ̀ọ̀kan, ó ṣì máa ń ṣe mí bíi pé kí n lọ wo àwọn àwòrán ìṣekúṣe. Àmọ́ mo máa ń rántí pé tí mo bá ṣe nǹkan lọ́nà tí Jèhófà fẹ́, màá láyọ̀, ọkàn mi á mọ́, màá sì ní ọjọ́ ọ̀la tó dáa.”