Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

ÀWỌN Ọ̀DỌ́ BÉÈRÈ PÉ

Kí Nìdí Tí Kò Fi Yẹ Kí O Máa Ṣe Bí Àwọn Tí Ò Ń Wò Nínú Fíìmù Tàbí Lórí Tẹlifíṣọ̀n?​—Apá 1: Fún Àwọn Ọ̀dọ́bìnrin

Kí Nìdí Tí Kò Fi Yẹ Kí O Máa Ṣe Bí Àwọn Tí Ò Ń Wò Nínú Fíìmù Tàbí Lórí Tẹlifíṣọ̀n?​—Apá 1: Fún Àwọn Ọ̀dọ́bìnrin

Irú ìwà wo làwọn tó máa ń wà nínú fíìmù tàbí lórí tẹlifíṣọ̀n máa ń hù?

  Wo àwọn ọ̀rọ̀ yìí, kó o sì dáhùn àwọn ìbéèrè tó tẹ̀ lé e.

Abala 1

Abala 2

Ẹni tí kò gbọ́n

Ọmọlúwàbí

Aláìgbọràn

Ẹni tó ń pa òfin mọ́

Oníṣekúṣe

Oníwà rere

Òṣónú èèyàn

Ẹni tí orí ẹ̀ pé

Olófòófó

Ọlọ́gbọ́n

Ẹlẹ̀tàn

Olóòótọ́

  1.   Èwo nínú àwọn ọ̀rọ̀ yìí lo lè fi ṣàpèjúwe àwọn ọmọbìnrin tó o máa ń rí nínú fíìmù, lórí Tẹlifíṣọ̀n tàbí nínú ìpolówó?

  2.   Èwo nínú àwọn ọ̀rọ̀ yìí ni wàá fi ṣàpèjúwe irú ẹni tí ìwọ fẹ́ kí àwọn èèyàn mọ̀ ẹ́ sí?

 Ó ṣeé ṣe kó jẹ́ pé inú Abala 1 lo ti mú ìdáhùn ìbéèrè àkọ́kọ́, tó o sì mú ìdáhùn ìbéèrè kejì nínú Abala 2. Tó bá rí bẹ́ẹ̀, á jẹ́ pé ẹni gidi ló wù ẹ́ kó o jẹ́, ẹni tó wúlò ju àwọn ọ̀dọ́ tó o máa ń rí lórí tẹlifíṣọ̀n, nínú fíìmù tàbí nínú ìpolówó. Ohun tó ń wù ẹ́ yìí náà ló ń wu àwọn ọ̀dọ́ míì! Wo ìdí tó fi rí bẹ́ẹ̀.

 “Àwọn ọmọbìnrin tó ti ń lé lọ́mọ ọdún mẹ́tàlá (13) tó máa ń wà nínú fíìmù máa ń ya aláìgbọràn àti ọmọ burúkú. Àwọn fíìmù náà máa ń mú kó dà bíi pé gbogbo wa ni kò ṣeé fọkàn tán, tá a sì máa ń sọ ọ̀rọ̀ tí kò tó nǹkan di ńlá torí pé a fẹ́ káwọn èèyàn fojú tó dáa wò wá.”​—Erin.

 “Àwọn ọmọbìnrin tó ti ń lé lọ́mọ ọdún mẹ́tàlá tó máa ń wà nínú fíìmù tàbí lórí tẹlifíṣọ̀n máa ń fẹ́ pe àfíyèsí sí ara wọn, ọ̀rọ̀ ìmúra wọn àti bí wọ́n ṣe rí máa ń ká wọn lára jù, ọ̀rọ̀ ọkùnrin máa ń kó sí wọn lórí, wọ́n sì máa ń wá bí wọ́n á ṣe di gbajúmọ̀.”​—Natalie.

 “Kò sígbà tí àwọn ọmọbìnrin inú fíìmù kì í mutí, tí wọn kì í bá àwọn ọkùnrin ṣèṣekúṣe, tí wọn kì í sì í ṣàìgbọràn sáwọn òbí wọn. Ojú agbawèrèmẹ́sìn tàbí ojú ẹni tí kò dákan mọ̀ ni wọ́n máa fi ń wo ọmọbìnrin tí kò bá ṣe àwọn nǹkan yìí.”​—Maria.

 Bi ara rẹ pé: ‘Ǹjẹ́ bí mo ṣe ń múra, bí mo ṣe ń hùwà àti bí mo ṣe ń sọ̀rọ̀ fi irú ẹni tí mo jẹ́ gan-an hàn àbí ṣe ni mo kàn ń fara wé àwọn tí mò ń rí nínú fíìmù, lórí tẹlifíṣọ̀n tàbí nínú ìpolówó?’

Ohun tó yẹ kó o mọ̀

  •    Ọ̀pọ̀ àwọn tó ń ṣe bí àwọn èèyàn tó wà nínú fíìmù tàbí lórí tẹlifíṣọ̀n rò pé àwọn ń ṣe ohun tó dáa, wọn ò mọ̀ pé ìwà oníwà làwọn ń kọ́. Ọ̀dọ́bìnrin kan tó ń jẹ́ Karen sọ pé: “Mo rí i pé àbúrò mi obìnrin ti ń ṣe bíi tiwọn. Ó máa ń ṣe bíi pé kò sí nǹkan míì tó kan òun, àfi ọ̀rọ̀ aṣọ àti ọ̀rọ̀ ọkùnrin. Orí ẹ̀ pé, mo sì mọ̀ pé ó ní àwọn nǹkan míì tó nífẹ̀ẹ́ sí, àmọ́ ó máa ń ṣe bí ẹni tí kò mọ nǹkan kan torí ó rò pé ohun tí òun lè ṣe nìyẹn láti dà bí àwọn ọmọbìnrin tó kù.’ Kò sì tíì ju ọmọ ọdún méjìlá lọ o!”

     Bíbélì sọ pé: “Kí ẹ̀yin kí ó má sì ṣe gẹ́gẹ́ bí ìwà àti àṣà ti ayé yìí.”​—Róòmù 12:2 Bíbélì Mímọ́.

  •   Kì í ṣe gbogbo ọmọbìnrin ló fẹ́ máa hùwà bíi ti àwọn tí wọ́n ń rí nínú fíìmù tàbí lórí tẹlifíṣọ̀n. Alexis tó jẹ́ ẹni ọdún mẹ́ẹ̀ẹ́dógún (15) sọ pé: “Àwọn ọmọbìnrin tó máa ń wà nínú fíìmù tàbí lórí tẹlifíṣọ̀n máa ń hùwà bí ẹni tí ò gbọ́n, wọ́n máa ń hùwà bí ọmọdé, ọ̀rọ̀ ara wọn ló sì máa ń ṣe pàtàkì jù sí wọn, àmọ́ èyí tó pọ̀ jù nínú àwa obìnrin kì í hùwà bẹ́ẹ̀, ohun tó tọ́ la máa ń ṣe. A láwọn nǹkan míì tá a fẹ́ fi ayé wa ṣe ju ká kàn máa ro ọ̀rọ̀ ọkùnrin.”

     Bíbélì sọ pé: “Àwọn ènìyàn tí ó dàgbà dénú, . . . kọ́ agbára ìwòye wọn láti fi ìyàtọ̀ sáàárín ohun tí ó tọ́ àti ohun tí kò tọ́.”​—Hébérù 5:14.

  •   Ṣe ni wọ́n ń fi àwọn tí ò ń rí lórí tẹlifíṣọ̀n polówó ọjà, àwọn ọlọ́jà ló sì ń jàǹfààní, kì í ṣe àwọn ọmọbìnrin tó ń wò wọ́n. Àwọn ilé iṣẹ́ ńláńlá, títí kan àwọn tó ń tẹ̀wé jáde, àwọn tó ń ṣe aṣọ, ilé iṣẹ́ ìmọ̀ ẹ̀rọ àtàwọn tó ń ṣe fíìmù àti orin mọ̀ pé àwọn máa rí owó pa dáadáa lára àwọn ọ̀dọ́, torí náà, kí wọ́n tó pé ọmọ ọdún mẹ́tàlá ni wọ́n ti máa ń fojú sí wọn lára. Ìwé náà,12 Going on 29 sọ pé: “Àwọn tó ń polówó ọjà sọ pé àwọn ọmọ tí kò tíì pé ọdún mẹ́tàlá kò lè di gbajúmọ̀ tí wọn ò bá ní àwọn ohun tó ṣẹ̀ṣẹ̀ dé, bí aṣọ, ohun ọ̀ṣọ́, nǹkan ìṣaralóge àtàwọn ohun tí ìmọ̀ ẹ̀rọ gbé jáde bíi fóònù. Gbogbo ìgbà ni àwọn ọmọ yìí ń rí ìpolówó ọjà tó fani mọ́ra, wọn ò sì tíì mọ̀ pé ẹ̀tàn lásán ni.”

     Bíbélì sọ pé: “Ohun gbogbo tí ń bẹ nínú ayé​—ìfẹ́kúfẹ̀ẹ́ ara àti ìfẹ́kúfẹ̀ẹ́ ojú àti fífi àlùmọ́ọ́nì ìgbésí ayé ẹni hàn sóde lọ́nà ṣekárími​—kò pilẹ̀ṣẹ̀ láti ọ̀dọ̀ Baba, ṣùgbọ́n ó pilẹ̀ṣẹ̀ láti ọ̀dọ̀ ayé.”​—1 Jòhánù 2:​16.

 Ohun tó o lè ronú lé: Tó o bá ń ronú ṣáá nípa àwọn aṣọ tàbí bàtà tó gbajúmọ̀ jù láàárín àwọn èèyàn, ta lo rò pé ó ń jèrè jù nínú ìwọ àti iléeṣẹ́ tó ṣe wọ́n jáde? Tó o bá sọ pé o gbọ́dọ̀ ní fóònù tó ṣẹ̀ṣẹ̀ wọjà yẹn torí pé àwọn ẹgbẹ́ rẹ ń lò ó, ta lo rò pé ó ń jèrè? Ṣé o rò pé ọ̀rọ̀ ẹ ló jẹ àwọn tó ń polówó ọjà lógún jù ni àbí tara wọn?

Ohun tí o lè ṣe

  •    Ronú jinlẹ̀ nípa ohun tí ò ń rí lórí tẹlifíṣọ̀n tàbí nínú ìpolówó, má kàn dédé máa fara wé wọn. Bó o ṣe ń dàgbà sí i ni wàá túbọ̀ máa rí i pé gbogbo ohun tó ń dán kọ́ ni wúrà. Ronú jinlẹ̀ lórí ipa tí àwọn ọ̀dọ́ tí ò ń rí lórí tẹlifíṣọ̀n àti nínú fíìmù lè ní lórí rẹ. Alana tó jẹ́ ọmọ ọdún mẹ́rìnlá (14) sọ pé: “Lórí tẹlifíṣọ̀n tàbí nínú fíìmù, àwọn ọmọbìnrin máa ń ṣe ara lóge ju bó ṣe yẹ lọ, wọ́n á wá kun gbogbo ojú. Ọ̀pọ̀ ọ̀dọ́ ni kò mọ̀ pé oge àṣejù kò yẹ àwọn, ṣe ni wọ́n máa ń rí bí ẹni tó ń wá nǹkan lójú méjèèjì.”

  •   Mọ irú ẹni tó o fẹ́ jẹ́, kó o sì máa sapá láti jẹ́ bẹ́ẹ̀. Bí àpẹẹrẹ, ronú nípa àwọn ànímọ́ tó o yàn níbẹ̀rẹ̀ àpilẹ̀kọ yìí, èyí tó o fẹ́ kí àwọn èèyàn mọ̀ ẹ́ mọ́. O ò ṣe kúkú bẹ̀rẹ̀ sí í sapá báyìí kó o lè ní àwọn ànímọ́ yẹn tàbí kó o jẹ́ kó túbọ̀ máa hàn nínú ìwà rẹ? Bíbélì sọ pé: “Ẹ . . . fi àkópọ̀ ìwà tuntun wọ ara yín láṣọ, èyí tí a ń sọ di tuntun nípasẹ̀ ìmọ̀ pípéye ní ìbámu pẹ̀lú àwòrán Ẹni tí ó dá a”​—kì í ṣe ní ìbámu pẹ̀lú àwòrán ohun tí wọ́n ń ṣe nínú fíìmù tàbí nínú ìpolówó.​—Kólósè 3:​10.

  •   Fara wé àwọn èèyàn tó jẹ́ àpẹẹrẹ rere. Ó lè jẹ́ àwọn kan nínú ìdílé rẹ, bíi mọ́mì ẹ, ẹ̀gbọ́n tàbí àbúrò mọ́mì ẹ. Ó tún lè jẹ́ àwọn ọ̀rẹ́ rẹ obìnrin tàbí àwọn tó o mọ̀ tí wọ́n níwà àgbà. Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ní ọ̀pọ̀ obìnrin tó jẹ́ àpẹẹrẹ rere nínú ìjọ Kristẹni.​—Títù 2:​3-5.

 Àbá: Ka ìwé Tẹ̀ Lé Àpẹẹrẹ Ìgbàgbọ́ Wọn, kó o lè kẹ́kọ̀ọ́ nípa àwọn èèyàn kan nínú Bíbélì tí wọ́n jẹ́ àpẹẹrẹ rere, tí àwọn obìnrin sì lè tẹ̀ lé àpẹẹrẹ wọn. Lára wọn ni Rúùtù, Hánà, Ábígẹ́lì, Ẹ́sítérì, Màríà àti Màtá. Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà la ṣe ìwé Tẹ̀ Lé Àpẹẹrẹ Ìgbàgbọ́ Wọn, ó sì wà lórí ìkànnì www.pr418.com/yo.