Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

ÀWỌN Ọ̀DỌ́ BÉÈRÈ PÉ

Kí Ló Yẹ Kí N Ṣe Lẹ́yìn Tí Mo Bá Ṣèrìbọmi?—Apá 1: Máa Ṣe Àwọn Ohun Táá Jẹ́ Kó O Túbọ̀ Sún Mọ́ Ọlọ́run

Kí Ló Yẹ Kí N Ṣe Lẹ́yìn Tí Mo Bá Ṣèrìbọmi?—Apá 1: Máa Ṣe Àwọn Ohun Táá Jẹ́ Kó O Túbọ̀ Sún Mọ́ Ọlọ́run

 Béèyàn bá ní nǹkan iyebíye bíi mọ́tò, ó gbọ́dọ̀ máa bójú tó o látìgbàdégbà, kó má bàa bà jẹ́. Bẹ́ẹ̀ náà ni àjọṣe wa pẹ̀lú Jèhófà ṣe rí, a gbọ́dọ̀ máa ṣìkẹ́ ẹ̀ látìgbàdégbà kó má bàa bà jẹ́. Àmọ́ báwo la ṣe lè jẹ́ kí àjọṣe wa pẹ̀lú Jèhófà máa sunwọ̀n sí i lẹ́yìn tá a bá ṣèrìbọmi?

Nínú àpilẹ̀kọ yìí

 Máa kẹ́kọ̀ọ́ Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run

 Ẹsẹ Bíbélì: “Ẹ máa so èso nínú gbogbo iṣẹ́ rere, tí ìmọ̀ tó péye tí ẹ ní nípa Ọlọ́run sì ń pọ̀ sí i.”—Kólósè 1:10.

 Ohun tó túmọ̀ sí: Lẹ́yìn tó o bá ṣèrìbọmi, má dáwọ́ Bíbélì kíkà dúró, kó o sì rí i pé ò ń ronú lórí ohun tó o bá kà.—Sáàmù 25:4; 119:97.

 Ohun tó ṣeé ṣe kó ṣẹlẹ̀: Nígbà míì, ó lè má wù ẹ́ láti kẹ́kọ̀ọ́. O lè máa rò ó pé o ò lè ráyè ṣe irú ìkẹ́kọ̀ọ́ bẹ́ẹ̀.

 Ohun tó o lè ṣe: Túbọ̀ ṣèwádìí nípa àwọn ẹ̀kọ́ Bíbélì kan tó o nífẹ̀ẹ́ sí. Pinnu ìgbà tó o máa kẹ́kọ̀ọ́ àti ọ̀nà tó o máa gbà ṣe é. Tó o bá ṣe bẹ́ẹ̀, ìkẹ́kọ̀ọ́ náà ò ní sú ẹ. Rántí pé ìdí tó o fi ń kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì ni pé o fẹ́ túbọ̀ nífẹ̀ẹ́ Jèhófà àti Ọ̀rọ̀ rẹ̀. Tó o bá ń kẹ́kọ̀ọ́ lọ́nà yìí, wàá gbádùn ohun tó ò ń kọ́, ìkẹ́kọ̀ọ́ náà á sì ṣe ẹ́ láǹfààní.—Sáàmù 16:11.

 Àbá: Tó o bá fẹ́ gbádùn ìkẹ́kọ̀ọ́ ẹ dáadáa, wá ibi tó pa rọ́rọ́ tí ohunkóhun ò ti ní pín ọkàn ẹ níyà.

 Tó o bá fẹ́ mọ̀ sí i

 Máa gbàdúrà sí Jèhófà

 Ẹsẹ Bíbélì: “Ẹ má ṣe máa ṣàníyàn nípa ohunkóhun, àmọ́ nínú ohun gbogbo nípasẹ̀ àdúrà àti ìrawọ́ ẹ̀bẹ̀ pẹ̀lú ìdúpẹ́, ẹ máa sọ àwọn ohun tí ẹ̀ ń tọrọ fún Ọlọ́run.”—Fílípì 4:6.

 Ohun tó túmọ̀ sí: Ó yẹ ká máa bá Ọlọ́run sọ̀rọ̀ ká sì ma tẹ́tí sí i. O lè tẹ́tí sí i tó o bá ń ka Ọ̀rọ̀ ẹ̀, o sì lè bá a sọ̀rọ̀ tó o bá ń gbàdúrà. Lára àwọn nǹkan tó o lè gbàdúrà fún láwọn nǹkan tó o nílò, má sì gbàgbé láti dúpẹ́ fáwọn nǹkan tí Ọlọ́run ti ṣe fún ẹ.

 Ohun tó ṣeé ṣe kó ṣẹlẹ̀: O lè máa sọ ohun kan náà nínú àdúrà rẹ, kó o sì máa ṣiyèméjì pé bóyá ni Jèhófà ń tẹ́tí sí ẹ tàbí pé kò rí tìẹ rò.—Sáàmù 10:1.

 Ohun tó o lè ṣe: Jálẹ̀ ọjọ́ kan, máa ronú lórí àwọn nǹkan tó o lè gbàdúrà fún. Tó bá jẹ́ pé o ò sí nípò tó o ti lè gbàdúrà lákòókò yẹn, o lè fi àwọn ohun náà sọ́kàn kó o sì gbàdúrà nípa wọn tó bá yá. Máa sọ àwọn ohun tó ń jẹ ẹ́ lọ́kàn fún Jèhófà, kó o sì rántí gbàdúrà fáwọn míì.—Fílípì 2:4.

 Àbá: Tó bá ń ṣe ẹ́ bíi pé ohun kan náà lò ń sọ nínú àdúrà ẹ, sọ fún Jèhófà nípa ẹ̀. Ó fẹ́ gbọ́ gbogbo ohun tó ń jẹ ẹ́ lọ́kàn, títí kan èyí tó ní í ṣe pẹ̀lú àdúrà ẹ.—1 Jòhánù 5:14.

 Tó o bá fẹ́ mọ̀ sí i

 Máa sọ ohun tó o gbà gbọ́ fáwọn míì

 Bíbélì sọ pé: “Máa kíyè sí ara rẹ àti ẹ̀kọ́ rẹ nígbà gbogbo. . . . Tí o bá ń ṣe é, wàá lè gba ara rẹ àti àwọn tó ń fetí sí ọ là.”—1 Tímótì 4:16.

 Ohun tó túmọ̀ sí: Tó o bá ń sọ ohun tó o gbà gbọ́ fáwọn míì, ìgbàgbọ́ tìẹ náà á máa lágbára sí i. O lè tipa bẹ́ẹ̀ gba ara ẹ àtàwọn tó ń fetí sí ẹ là.

 Ohun tó ṣeé ṣe kó ṣẹlẹ̀: Nígbà míì, ó lè má wù ẹ́ láti sọ ohun tó o gbà gbọ́ fáwọn míì, ẹ̀rù tiẹ̀ lè máa bà ẹ́ láti ṣe bẹ́ẹ̀, pàápàá níléèwé.

 Ohun tó o lè ṣe: Pinnu pé o ò ní jẹ́ kí èrò tí kò tọ́ àti ìbẹ̀rù dí ẹ lọ́wọ́ láti sọ ohun tó o gbà gbọ́. Àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù sọ pé: “Síbẹ̀ tí kò bá ti inú mi wá [láti kéde ìhìn rere] iṣẹ́ ìríjú kan ṣì wà ní ìkáwọ́ mi.”—1 Kọ́ríńtì 9:16, 17.

 Àbá: Táwọn òbí ẹ bá fọwọ́ sí i, wá ẹnì kan nínú ìjọ tí òtítọ́ jinlẹ̀ nínú ẹ̀ tó lè ràn ẹ́ lọ́wọ́ láti máa sọ ohun tó o gbà gbọ́.—Òwe 27:17.

 Tó o bá fẹ́ mọ̀ sí i

 Máa lọ sípàdé déédéé

 Bíbélì sọ pé: “Ká gba ti ara wa rò ká lè máa fún ara wa níṣìírí láti ní ìfẹ́ àti láti ṣe àwọn iṣẹ́ rere, ká má ṣe máa kọ ìpàdé wa sílẹ̀.”—Hébérù 10:24, 25.

 Ohun tó túmọ̀ sí: Ìdí tá a fi ń lọ sípàdé ni pé a fẹ́ jọ́sìn Jèhófà. Àmọ́ àǹfààní méjì míì wà tá a máa rí tá a bá ń lọ sípàdé. Lákọ̀ọ́kọ́, wàá rí ìṣírí gbà látọ̀dọ̀ àwọn ara. Ìkejì, ìwọ náà á lè fún àwọn míì níṣìírí tó o bá wá sípàdé tó o sì ṣiṣẹ́ tàbí dáhùn nípàdé náà.—Róòmù 1:11, 12.

 Ohun tó ṣeé ṣe kó ṣẹlẹ̀: Nígbà míì, a lè má pọkàn pọ̀ nípàdé, ìyẹn sì lè mú ká pàdánù àwọn ìsọfúnni tó lè ṣe wá láǹfààní. Nígbà míì, a lè jẹ́ kí àwọn nǹkan míì bí iṣẹ́ iléèwé dí wa lọ́wọ́ láti máa wá sí gbogbo ìpàdé.

 Ohun tó o lè ṣe: Pinnu pé gbogbo ìpàdé ni wàá máa lọ láìpa iṣẹ́ iléèwé ẹ tì, wàá sì pọkàn pọ̀ kó o lè gbádùn gbogbo ìpàdé náà. Bákan náà, pinnu pé wàá máa dáhùn nípàdé. Lẹ́yìn tí ìpàdé bá parí, gbìyànjú láti gbóríyìn fún ó kéré tán ọ̀kan lára àwọn tó ṣiṣẹ́ nípàdé náà, kó o sì sọ ohun tó o gbádùn nínú iṣẹ́ ẹ̀.

 Àbá: Máa múra gbogbo ìpàdé sílẹ̀. Wa JW Library® sórí fóònù rẹ, kó o sì máa lo apá tá a pè ní “Meetings” láti fi múra ohun tá a máa jíròrò nípàdé sílẹ̀.

 Tó o bá fẹ́ mọ̀ sí i