Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

ÀWỌN Ọ̀DỌ́ BÉÈRÈ PÉ

Kí Ni Mo Lè Ṣe Tí Mo Bá Ṣàìgbọràn Sáwọn Òbí Mi?

Kí Ni Mo Lè Ṣe Tí Mo Bá Ṣàìgbọràn Sáwọn Òbí Mi?

 Ó fẹ́rẹ̀ẹ́ jẹ́ pé gbogbo òbí ló máa ń fún àwọn ọmọ wọn lófin nínú ilé. Wọ́n lè ní òfin nípa aago tó yẹ kí àwọn ọmọ máa wọlé, iye àkókò tí wọ́n lè lò lórí ẹ̀rọ alágbèéká àti bí wọ́n ṣe ń hùwà, àti bẹ́ẹ̀ bẹ́ẹ̀ lọ.

 Ká sọ pé o ṣàìgbọràn sí ọ̀kan nínú àwọn òfin yẹn ńkọ́? Ohun tó ti ṣẹlẹ̀ ti ṣẹlẹ̀, síbẹ̀, o lè ṣe ohun tí kò ní jẹ́ kí ọ̀rọ̀ náà burú ju bó ṣe yẹ lọ. Àpilẹ̀kọ yìí máa kọ́ ẹ bó o ṣe lè ṣe bẹ́ẹ̀.

 Ohun tí kò yẹ kó o ṣe

  •   Táwọn òbí ẹ ò bá mọ̀ pé o ti ṣe ohun kan tí kò dáa, ó lè máa ṣe ẹ́ bíi pé kó o má sọ̀rọ̀ náà síta.

  •   Tí wọn ò bá mọ̀ pé o ti ṣàìgbọràn, ó lè ṣe ẹ́ bíi pé kó o wá àwáwí tàbí kó o di ẹ̀bi ru ẹlòmíì.

 Kò sí èyí tó o ṣe nínú ẹ̀ tó dáa. Kí nìdí? Torí pé tó o bá bo ohun tó o sẹ mọ́lẹ̀ tàbí tí o kàn ń ṣàwáwí, ìyẹn máa fi hàn pé oò tíì dàgbà dénú. Ìyẹn máa jẹ́ káwọn òbí ẹ̀ máa wò ó pé oò tí mọ ohun tó tọ́ láti ṣe.

 “Irọ́ ò lè yanjú ìṣòro rárá. Torí pé tó bá yá, àṣírí máa pa dà tú síta, ìyà téèyàn sì máa jẹ máa pọ̀ ju èyí tó máa jẹ tó bá ti sòótọ́ látilẹ̀.”—Diana.

 Ọ̀nà tó dáa jù tó o lè gbà ṣe é

  •   Gba ẹ̀bi ẹ lẹ́bi. Bíbélì sọ pé: “Ẹni tó bá ń bo àwọn ẹ̀ṣẹ̀ rẹ̀ mọ́lẹ̀ kò ní ṣàṣeyọrí.” (Òwe 28:13) Àwọn òbí ẹ mọ̀ pé o kì í ṣe ẹni pípé. Àmọ́ wọ́n fẹ́ kó o jẹ́ olóòótọ́.

     “Ó dájú pé àwọn òbí ẹ máa fàánú hàn sí ẹ tó o bá ń sòótọ́. Tó o bá jẹ́wọ́ ohun tó o ṣe, àwọn òbí ẹ á túbọ̀ fọkàn tán ẹ.”​—⁠Olivia.

  •   Tọrọ àforíjì. Bíbélì sọ pé: ‘Ẹ gbé ìrẹ̀lẹ̀ wọ̀.’ (1 Pétérù 5:⁠5) Ó gba ìrẹ̀lẹ̀ kéèyàn tó sọ pé “ẹ má bínú,” kéèyàn sì gbìyànjú láti má ṣe àwáwí kankan.

     “Tó bá ti mọ́ èèyàn lára láti máa ṣàwáwí, ńṣe ni onítọ̀hún máa ba ẹ̀rí ọkàn rẹ̀ jẹ́. Tó bá yá, ẹ̀rí ọkàn náà ò ní dà á láàmú mọ́ tó bá ṣe ohun tí kò dáa.”—Heather.

  •    Fara mọ́ ìbáwí tí wọ́n bá fún ẹ. Bíbélì sọ pé: “Fetí sí ìbáwí.” (Òwe 8:33) Má ṣe máa kùn tí wọ́n ba bá ẹ wí, fara mọ́ ohun tí àwọn òbí ẹ bá sọ.

     “Tó ò bá kí ń fara mọ́ ìbáwí tí wọ́n bá fún ẹ, ó máa mú kí nǹkan burú sí i. Gbìyànjú láti fara mọ́ ìbáwí tí wọ́n bá fún ẹ, dípò tí wàá fi máa ronú nípa àǹfààní tí wọ́n fi dù ẹ́.”—Jason.

  •   Sapá láti ṣe ohun tó máa jẹ́ kí wọ́n fọkàn tán ẹ́. Bíbélì sọ pé: “Ẹ bọ́ ìwà àtijọ́ sílẹ̀, èyí tó bá ọ̀nà ìgbésí ayé yín ti tẹ́lẹ̀ mu.” (Éfésù 4:22) Bẹ̀rẹ̀ sí í hùwà rere tó máa jẹ́ kí àwọn òbí ẹ fọkàn tán ẹ.

     “Tó o bá ń ṣe ìpinnu tó dáa, tó o sì ń ṣe àwọn ohun tó máa jẹ́ kí àwọn òbí ẹ ríi pé o ò ní ṣe irú àṣìṣe bẹ́ẹ̀ mọ́, wọ́n á túbọ̀ fọkàn tán ẹ.”​—⁠Karen.

 Àbá: Ṣe ju ohun táwọn òbí ẹ béèrè lọ́wọ́ ẹ, kí wọ́n lè mọ̀ pé ẹni tó ṣeé gbára lé ni ẹ́. Bí àpẹẹrẹ, tó o bá jáde lọ síbì kan, pe àwọn òbí rẹ lórí fóònù kó o sì jẹ́ kí wọ́n mọ̀ tó o bá ti ń bọ̀ nílé, kódà tó ò bá ní pẹ́ níta. Ìyẹn máa jẹ́ kí wọ́n mọ̀ pé o fẹ́ káwọn túbọ̀ fọkàn tán ẹ.