Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

ÀWỌN Ọ̀DỌ́ BÉÈRÈ PÉ

Báwo Ni Mo Ṣe Lè Kọ́ Béèyàn Ṣe Ń Pọkàn Pọ̀?

Báwo Ni Mo Ṣe Lè Kọ́ Béèyàn Ṣe Ń Pọkàn Pọ̀?

 Kí nìdí tí mi ò fi lè pọkàn pọ̀?

 “Mi ò lè ka ìwé tó pọ̀ bí mo ṣe máa ń ṣe tẹ́lẹ̀. Kìí tiẹ̀ wù mí láti ka ìpínrọ̀ tó gùn mọ́.”​—⁠Elaine.

 “Tí mo bá kíyè sí i pé fídíò tí mò ń wò kò yára tó, mo máa ń jẹ́ kí fídíò náà yára kí n lè tètè wò ó tán.”​—⁠Miranda.

 “Tí mo bá tiẹ̀ ń pọkàn pọ̀ sórí ohun pàtàkì kan, àmọ́ tí fóònù mi lọ kú, gbogbo nǹkan tó máa gbà mí lọ́kàn ni pé, ‘Ta ló ń fọ̀rọ̀ ránṣẹ́ sí mi?’”—Jane.

 Ṣe ẹ̀rọ ìgbàlódé lè mú kó ṣòro láti pọkàn pọ̀? Àwọn kan sọ pé, bẹ́ẹ̀ ni. Nicholas Carr tó jẹ́ òǹkọ̀wé àti agbaninímọ̀ràn nílé iṣẹ́ kọ̀wé pé: “Bá a ṣe ń lo íńtánẹ́ẹ̀tì sí i, bẹ́ẹ̀ náà ni ọpọlọ wa a ṣe máa ro tibi ro tọ̀hún, ìyẹn ni pé ọpọlọ wa á bẹ̀rẹ̀ sí yára ronú lórí ìsọfúnni lọ́nà tó já fáfá gan-an, àmọ́ a ò ní lè pọkàn pọ̀ sí i.” a

 Ẹ jẹ́ ká sọ̀rọ̀ nípa apá mẹ́ta tó ṣeé ṣe kí ẹ̀rọ ìgbàlódé ṣàkóbá fún bó o ṣe ń pọkàn pọ̀.

  •   Tó o bá ń sọ̀rọ̀. Obìnrin kan tórúkọ ẹ̀ ń jẹ́ Maria sọ pé: “Nígbà táwọn èèyàn bá tiẹ̀ ń bára wọn sọ̀rọ̀ lójúkojú, wọ́n sábà máa ń fọ̀rọ̀ ránṣẹ́ lórí fóònù tàbí gbá géèmù, wọ́n tiẹ̀ lè máa wo ìkànnì àjọlò tó wà lórí fóònù wọn, ìyẹn ò sì ní jẹ́ kí wọ́n lè pọkàn pọ̀ sọ́dọ̀ ẹni tí wọ́n jọ ń sọ̀rọ̀.”

  •   Tó o bá wà ní kíláàsì. Ìwé Digital Kids sọ pé: “Ọ̀pọ̀ akẹ́kọ̀ọ́ tó máa ń lo ẹ̀rọ ìgbàlódé nígbà tí wọ́n bá ń ṣiṣẹ́ kíláàsì ni wọ́n sábà máa ń lo ẹ̀rọ náà láti fọ̀rọ̀ ránṣẹ́, ka ìsọfúnni lórí íńtánẹ̀ẹ̀tì tàbí kí wọ́n wo ìsọfúnni tí kò ní ohunkóhun ṣe pẹ̀lú iṣẹ́ ilé ìwé wọn.”

  •   Tó o bá ń kẹ́kọ̀ọ́. Chris tó jẹ́ ẹni ọdún méjìlélógún (22) sọ pé: “Ó ṣòro gan-an fún mi láti gbójú kúrò lórí fóònù mi ní gbogbo ìgbà tí nǹkan bá wọlé sórí ẹ̀.” Tó o bá jẹ́ akẹ́kọ̀ọ́ nílé ìwé, wákàtí kan tó yẹ kó o lò fún iṣẹ́ àṣetiléwá lè di wákàtí mẹ́ta tàbí jù bẹ́ẹ̀ lọ tó o bá jẹ́ kí ẹ̀rọ ìgbàlódé pín ọkàn rẹ níyà.

 Kókó ibẹ̀: Ó máa ṣòro láti pọkàn pọ̀ tó o bá jẹ́ kí ẹ̀rọ ìgbàlódé pín ọkàn ẹ níyà kó sì máa darí ẹ.

Ẹni tí kò pọkàn pọ̀ dà bí ẹni tó gun kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ tó ya ẹhànnà, ibikíbi tó bá wù ú ló máa gbé ẹ lọ

 Bó o ṣe lè túbọ̀ pọkàn pọ̀

  •   Tó o bá ń bá ẹlòmíì sọ̀rọ̀. Bíbélì sọ pé: ‘Ẹ máa wá ire àwọn ẹlòmíì, kì í ṣe tiyín nìkan.’ (Fílípì 2:⁠4) Máa fetí sílẹ̀ dáadáa kó o lè fi hàn pé o gba tàwọn ẹlòmíì rò. Máa wo ojú ẹni tó ò ń bá sọ̀rọ̀, má sì jẹ́ kí ẹ̀rọ ìgbàlódé pín ọkàn ẹ níyà.

     “Tó o bá ń bá èèyàn sọ̀rọ̀, gbìyànjú láti má ṣe máa wo fóònù ẹ. Pọkàn pọ̀ sọ́dọ̀ ẹni tó ò ń bá sọ̀rọ̀ kó o lè fi hàn pé o bọ̀wọ̀ fún-un.”​—⁠Thomas.

     ÀBÁ: Tó o bá ń bá ẹnì kan sọ̀rọ̀, máa fi fóònù ẹ síbi tó ò ti ní rí i. Àwọn olùṣèwádìí sọ pé, irinṣẹ́ tí kò ní jẹ́ kéèyàn pọkàn nígbà téèyàn bá ń sọ̀rọ̀ tàbí tó bá ń ṣe nǹkan ni fóònù jẹ́.

  •   Tó o bá wà ní kíláàsì. Bíbélì sọ pé: “Ẹ kíyè sí bí ẹ ṣe ń fetí sílẹ̀.” (Lúùkù 8:18) Tó o bá fi ìlànà yìí sọ́kàn, ká tiẹ̀ sọ pé wọ́n fún ẹ láyè láti lọ sórí íńtánẹ́ẹ̀tì nínú kíláàsì, má ṣe ka àtẹ̀jíṣẹ́ orí fóònù, má ṣe gbá géèmù tàbí kó o máa fọ̀rọ̀ ránṣẹ́ lórí íńtánẹ́ẹ̀tì nígbà tó yẹ kó o pọkàn pọ̀ sórí ohun tó ò ń kọ́.

     “Rí i pé o túbọ̀ ń pọkàn pọ̀ nínú kíláàsì. Máa ṣàkọsílẹ̀ ohun tẹ́ ẹ̀ ń kọ́. Tó bá ṣeé ṣe, máa jókòó sọ́wọ́ iwájú nínú kíláàsì kó o lè yẹra fún ohun tó lè pín ọkàn ẹ níyà.”​—⁠Karen.

     ÀBÁ: Dípò tí wàá fi máa ṣàkọsílẹ̀ lórí kọ̀ǹpútà, máa ṣàkọsílẹ̀ sórí ìwé. Ìwádìí fi hàn pé ọkàn ẹ ò ní pínyà, wàá sì lè rántí ohun tó o kọ́ dáadáa.

  •   Tó o bá ń kẹ́kọ̀ọ́. Bíbélì sọ pé: “Ní ọgbọ́n, ní òye.” (Òwe 4:⁠5) Ìkẹ́kọ̀ọ́ ju kéèyàn máa yára ka ìsọfúnni kan kó bàa lè yege ìdánwò, ó gba pé kéèyàn ronú jinlẹ̀ gan-an.

     “Tí mo bá ń kẹ́kọ̀ọ́, mo máa ń yí ohun fóònù mi walẹ̀ kí n lè pọkàn pọ̀ sórí ohun tí mò ń ṣe. Mi ò kí ń wo àtẹ̀jíṣẹ́ tàbí ìsọfúnni èyíkéyìí tó bá wọlé. Tí mo bá kíyè sí ohun kan tí kò yẹ kí n gbàgbé, màá kọ ọ́ sílẹ̀.”​—⁠Chris.

     ÀBÁ: Rí i pé àyíká ibi tó o ti ń kẹ́kọ̀ọ́ jẹ́ kó o lè pọkàn pọ̀. Jẹ́ kí ibẹ̀ mọ́, kí ẹrù má sì pọ̀ níbẹ̀.

a Látinú ìwé The Shallows​—⁠What the Internet Is Doing to Our Brains.

Ẹni tí kò pọkàn pọ̀ dà bí ẹni tó gun kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ tó ya ẹhànnà, ibikíbi tó bá wù ú ló máa gbé ẹ lọ