Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

ÀWỌN Ọ̀DỌ́ BÉÈRÈ PÉ

Kí Ló Yẹ Kí N Mọ̀ Nípa Fífọ̀rọ̀ Ránṣẹ́ Lórí Fóònù?

Kí Ló Yẹ Kí N Mọ̀ Nípa Fífọ̀rọ̀ Ránṣẹ́ Lórí Fóònù?
  • :-) Téèyàn bá fọgbọ́n lo ọ̀rọ̀ àtẹ̀jíṣẹ́, ó lè jẹ́ kéèyàn mọ bí nǹkan ṣe ń lọ sí fáwọn ọ̀rẹ́ ẹ̀.

  • :-( Tó ò bá fọgbọ́n lò ó, ó lè da àárín yín rú, ó sì lè mú kí wọ́n máa fojú àbùkù wò ẹ́.

 Irú ẹni tó yẹ kó o fọ̀rọ̀ ránṣẹ́ sí

 Fọ́pọ̀ ọ̀dọ́, fífọ̀rọ̀ ránṣẹ́ lórí fóònù kò ṣeé fọwọ́ rọ́ sẹ́yìn nínú ètò ìbánisọ̀rọ̀. Á jẹ́ kó o lè máa kàn sí gbogbo àwọn tó wà lórí àkọsílẹ̀ rẹ, ìyẹn táwọn òbí ẹ bá gbà fún ẹ.

 “Dádì ò máa ń fẹ́ kémi àtàbúrò mi obìnrin báwọn ọmọkùnrin sọ̀rọ̀ lórí fóònù, àfi tó bá máa jẹ́ lórí fóònù àjùmọ̀lò tó wà ní yàrá ìgbàlejò, táwọn míì sì wà níbẹ̀.”​—Lenore.

 Ohun tó yẹ kó o mọ̀: O lè kóra ẹ sínú ewu tó bá jẹ́ pé ẹnikẹ́ni tó o bá ṣáà ti rí lo máa ń fún ní nọ́ńbà ẹ.

 “Tó o bá ń fún gbogbo ẹni tó o bá rí ní nọ́ńbà ẹ, àfàìmọ̀ lo ò ní gba àtẹ̀jíṣẹ́ tàbí àwòrán tó ò fẹ́.”​—Scott.

 “Tó o bá ń fọ̀rọ̀ ránṣẹ́ sẹ́ni tí kì í ṣe ọkùnrin tàbí obìnrin bíi tìẹ ní gbogbo ìgbà, ìfẹ́ ẹ̀ lè bẹ̀rẹ̀ sí í gbà ẹ́ lọ́kàn kíákíá.”​—Steven.

 Bíbélì sọ pé: “Afọgbọ́nhùwà ni ẹni tí ó ti rí ìyọnu àjálù, tí ó sì bẹ̀rẹ̀ sí fi ara rẹ̀ pa mọ́.” (Òwe 22:3) Tó o bá kíyè sára, o ò ní kó sínú ìbànújẹ́.

 Ohun tó ṣẹlẹ̀ sẹ́nì kan: “Èmi àtọmọkùnrin kan jọ ń ṣọ̀rẹ́, a sì máa ń fọ̀rọ̀ ránṣẹ́ síra wa déédéé. Èrò tèmi ni pé kò kúkú ju ọ̀rẹ́ lásán lọ. Mi ò mọ̀ ọ́n lọ́ràn, àfìgbà tó sọ fún mi pé ọkàn òun ti ń fà mọ́ mi. Nígbà tí mo ronú pa dà sẹ́yìn, mo wá rí i pé kò yẹ kí n máa wà pẹ̀lú ẹ̀ kí n sì máa fọ̀rọ̀ ránṣẹ́ sí i tó bí mo ṣe ṣe.”​—Melinda.

 Rò ó wò ná: Báwo lo ṣe rò pé ọ̀rẹ́ àárín Melinda àtọmọkùnrin yẹn ṣe máa rí lẹ́yìn tó sọ fún un póun nífẹ̀ẹ́ ẹ̀?

 Ohun tó yẹ: Kí ló yẹ kí Melinda ti máa ṣe tẹ́lẹ̀ kọ́rọ̀ òun àtọmọkùnrin yẹn má bàa kọjá pé wọ́n kàn ń bára wọn ṣọ̀rẹ́?

 Irú ọ̀rọ̀ tó yẹ kó o kọ ránṣẹ́

 Fífọ̀rọ̀ ránṣẹ́ ò ṣòro rárá, bí ẹní fàkàrà jẹ̀kọ ni, ó sì máa ń dùn mọ́ ẹni tí wọ́n fi ránṣẹ́ sí náà, ìyẹn ò wá ní jẹ́ kó o rántí pé ẹni tó o fọ̀rọ̀ ránṣẹ́ sí lè ṣi ọ̀rọ̀ tó o kọ lóye.

 Ohun tó yẹ kó o mọ̀: Èèyàn lè ṣi ọ̀rọ̀ tí wọ́n fi ránṣẹ́ lórí fóònù lóye.

 “Èèyàn ò lè mọ bọ́rọ̀ ṣe rí lára ẹni tó fọ̀rọ̀ ránṣẹ́ sí, kódà tó bá fàwọn àwòrán orí fóònù tó ń fi ìmọ̀lára téèyàn ní hàn sí i. Ẹni tí wọ́n fọ̀rọ̀ ránṣẹ́ sí lè ṣì í lóye.”​—Briana.

 “Mo mọ àwọn ọmọbìnrin tí wọ́n ti bara wọn lórúkọ jẹ́ táwọn èèyàn sì sọ pé wọ́n máa ń tage torí irú ọ̀rọ̀ tí wọ́n fi ránṣẹ́ sáwọn ọmọkùnrin.”​—Laura.

 Bíbélì sọ pé: “Àwọn èèyàn rere máa ń ronú kí wọ́n tó fèsì.” (Òwe 15:​28, ìtumọ̀ Bíbélì Good News Translation) Kí lẹsẹ Bíbélì yẹn kọ́ wa? Máa tún irú ọ̀rọ̀ tó o kọ kà kó o tó fi ránṣẹ́!

 Ìgbà tó yẹ kó o fọ̀rọ̀ ránṣẹ́

 Tó o bá lo làákàyè, ìwọ náà lè láwọn òfin tí wàá máa tẹ̀ lé tó o bá ń fọ̀rọ̀ ránṣẹ́ lórí fóònù.

 Ohun tó yẹ kó o mọ̀: Tó ò bá kíyè sára nípa bó o ṣe ń fọ̀rọ̀ ránṣẹ́, àwọn èèyàn lè máa wò ẹ́ bí ẹni tí kì í ṣọmọlúwàbí, o sì lè máa lé àwọn ọ̀rẹ́ ẹ sá dípò kí wọ́n máa fà mọ́ ẹ.

 “Èèyàn kì í pẹ́ gbàgbé ìlànà tó bá ń fọ̀rọ̀ ránṣẹ́. Lọ́jọ́ kan, bí mo ṣe ń bẹ́nì kan tá a jọ ń jẹun sọ̀rọ̀, bẹ́ẹ̀ ni mo tún ń tẹ ọ̀rọ̀ àtẹ̀jíṣẹ́ sẹ́lòmíì.”​—Allison.

 “Ó léwu téèyàn bá ń fọ̀rọ̀ ránṣẹ́ nígbà tó ń wakọ̀. Téèyàn ò bá wo ibi tó ń lọ, jàǹbá ọkọ̀ lè ṣẹlẹ̀.”​—Anne.

 Bíbélì sọ pé: “Ohun gbogbo ni ìgbà tí a yàn kalẹ̀ wà fún, . . . ìgbà dídákẹ́ jẹ́ẹ́ àti ìgbà sísọ̀rọ̀.” (Oníwàásù 3:1, 7) Ọ̀rọ̀ tá à ń sọ lẹ́nu nìkan kọ́ ni ìlànà yìí kàn, ó kan ọ̀rọ̀ tá à ń kọ ránṣẹ́ náà.

 Béèyàn ṣe ń fọ̀rọ̀ ránṣẹ́

 Irú ẹni tó yẹ kó o fọ̀rọ̀ ránṣẹ́ sí

  •  ;-)Máa tẹ̀ lé ìlànà táwọn òbí ẹ fún ẹ.​—Kólósè 3:20.

  •  ;-)Mọ irú àwọn tí wàá máa fún ní nọ́ńbà ẹ. Tó o bá fohùn pẹ̀lẹ́ sọ fẹ́nì kan pó ò ní jẹ́ kó mọ ohun kan nípa ọ̀rọ̀ ayé ẹ, títí kan nọ́ńbà fóònù ẹ, ìlànà tí wàá máa tẹ̀ lé tó o bá dàgbà lo fi ń kọ́ra yẹn.

  •  ;-)Má máa fọ̀rọ̀ àtẹ̀jíṣẹ́ báàyàn tage kọ́rọ̀ àárín yín má lọ kọjá ibi tó yẹ. Tí ìfẹ́ ẹ bá lọ gbà á lọ́kàn, ìbànújẹ́ àti ìjákulẹ̀ ló máa fà fún un.

 “Àwọn òbí mi mọ̀ mí sẹ́ni tí kì í lo fóònù lọ́nà tí ò dáa, torí náà, wọ́n jẹ́ kí n máa fọgbọ́n pinnu fúnra mi, àwọn tí màá fi nọ́ńbà wọn sórí fóònù mi.”​—Briana.

Irú ọ̀rọ̀ tó yẹ kó o kọ ránṣẹ́

  •  ;-)Kó o tó bẹ̀rẹ̀ sí í tẹ ọ̀rọ̀ tó o fẹ́ fi ránṣẹ́, bi ara ẹ pé, ‘Ṣé ọ̀rọ̀ àtẹ̀jíṣẹ́ ló yẹ kí n fi sọ irú ọ̀rọ̀ yìí?’ Ó ṣeé ṣe kó jẹ́ pé kẹ́ ẹ jọ sọ̀rọ̀ lórí fóònù ló máa dáa jù tàbí kẹ́ ẹ jọ ríra sọ̀rọ̀.

  •  ;-)Má ṣe fọ̀rọ̀ tó ò lè báàyàn sọ ránṣẹ́ sí i. Sarah ọmọ ọdún mẹ́tàlélógún [23] sọ pé: “Tó ò bá ti lè bónítọ̀hún sọ ọ́, má ṣe fi ránṣẹ́ sí i.”

 “Tẹ́nì kan bá fi àwòrán tó ń mú ọkàn fà sí ìṣekúṣe ránṣẹ́ sí ẹ, sọ fáwọn òbí ẹ. Ìyẹn máa dáàbò bò ẹ́, ó sì máa jẹ́ káwọn òbí ẹ fọkàn tán ẹ.”​—Sirvan.

Ìgbà tó yẹ kó o fọ̀rọ̀ ránṣẹ́

  •  ;-)Pinnu ìgbà tó o máa pa fóònù ẹ tì tó ò ní lò ó. Ọmọbìnrin kan tó ń jẹ́ Olivia sọ pé: “Mi ò máa ń jẹ́ kí fóònù mi wà lọ́dọ̀ mi tá a bá ń jẹun tàbí tí mo bá ń kẹ́kọ̀ọ́.” “Ṣe ni mo máa ń pa á tá a bá wà nípàdé kó máa bàa máa ṣe mí bíi kí n yẹ̀ ẹ́ wò.”

  •  ;-)Máa fọ̀rọ̀ rora ẹ wò. (Fílípì 2:4) Má máa kọ̀rọ̀ ránṣẹ́ lórí fóònù tó o bá ń bẹ́nì kan sọ̀rọ̀ lọ́wọ́.

 “Mo ti ṣòfin fúnra mi, ìkan lára ẹ̀ ni pé mi ò ní kọ̀rọ̀ ránṣẹ́ tí mo bá wà láààrín àwọn ọ̀rẹ́ mi, àfi tó bá pọn dandan. Mi ò sì máa ń fáwọn tí mi ò tíì mọ̀ dáadáa ní nọ́ńbà mi.”​—Janelly.