ÀWỌN Ọ̀DỌ́ BÉÈRÈ PÉ
Kí Nìdí Tó Fi Yẹ Kí N Tọrọ Àforíjì?
Kí lo máa ṣe táwọn nǹkan yìí bá ṣẹlẹ̀?
Olùkọ rẹ bá ẹ wí torí pé o hùwà tí ò dáa nínú kíláàsì.
Ṣé wàá tọrọ àforíjì lọ́wọ́ olùkọ́ rẹ—tó o bá tiẹ̀ rò pé ṣe ló gba ọ̀rọ̀ náà sódì?
Ọ̀rẹ́ rẹ gbọ́ pé o bú òun.
Ṣé wàá tọrọ àforíjì lọ́wọ́ ọ̀rẹ́ rẹ—tó o bá tiẹ̀ gbà pé ohun tó o sọ ò burú?
O bínú sí bàbá rẹ, o sì sọ̀rọ̀ àrífín sí i.
Ṣé wàá tọrọ àforíjì lọ́wọ́ bàbá rẹ—tó o bá tiẹ̀ gbà pé òun ló mú inú bí ẹ?
Bẹ́ẹ̀ ni ni ìdáhùn sí àwọn ìbéèrè mẹ́tẹ̀ẹ̀ta. Ṣùgbọ́n kí nìdí tó fi yẹ kó o tọrọ àforíjì, tó o bá tiẹ̀ rò pé ọwọ́ ẹ kọ́ ni gbogbo ẹ̀bi wà?
Kí nìdí tó fi yẹ kó o tọrọ àforíjì?
Ẹni tó bá tọrọ àforíjì fi hàn pé òtítọ́ jinlẹ̀ nínú òun. Tó o bá ń fi hàn pé o mọ ẹ̀bi rẹ lẹ́bi torí ohun tó o sọ tàbí torí ohun tó o ṣe, ò ń fi hàn pé o ti ń ní àwọn ànímọ́ pàtàkì tó o máa nílò tó o bá dàgbà.
“Ìwà ìrẹ̀lẹ̀ àti sùúrù lè mú ká tọrọ àforíjì ká sì wá tẹ́tí sí ohun tí ẹlòmíì fẹ́ sọ.”—Rachel.
Tó o bá tọrọ àforíjì, á mú kó o lè ṣe àtúnṣe. Àwọn èèyàn tó bá ń sọ pé “Máà bínú” ń fi hàn pé àlàáfíà jẹ àwọn lógún ju kí wọ́n dá ara wọn láre tàbí kí wọ́n fi àṣìṣe ẹlòmíì hàn.
“Tó ò bá tiẹ̀ rò pé ìwọ lo jẹ̀bi, bó o ṣe máa yanjú ọ̀rọ̀ náà ló yẹ kó jẹ ọ́ lógún. Kò ná èèyàn ní nǹkan kan láti sọ pé ‘Forí jì mí,’ ṣùgbọ́n ó lè tún ohun tó ti bà jẹ́ ṣe.”—Miriam.
Tó o bá tọrọ àforíjì, ara máa tù ẹ́. Ẹrù tó wúwo láti gbé ni ẹ̀dùn ọkàn téèyàn máa ń ní tó bá sọ̀rọ̀ tàbí hùwà tí ò dáa sí ẹlòmíì. Ṣùgbọ́n, tó o bá tọrọ àforíjì, ó ti gbé ẹrù yẹn kúrò léjìká ẹ nìyẹn. a
“Àwọn ìgbà míì wà tí mo máa ń fìbínú sọ̀rọ̀ sí màmá tàbí bàbá mi. Ó máa ń dùn mí, ṣùgbọ́n ó máa ń ṣòro fún mi láti tọrọ àforíjì. Àmọ́, tí mo bá tọrọ àforíjì, ará máa ń tù mí torí pé àlàáfíà á tún pa dà jọba nínú ilé.”—Nia.
Ṣé òótọ́ ni kì í rọrùn láti tọrọ àforíjì? Bẹ́ẹ̀ ni! Dena, ọ̀dọ́mọbìnrin kan tó ti ní láti tọrọ àforíjì léraléra torí pé ó hùwà tí ò dáa sí mọ́mì rẹ̀, sọ pé: “Kò rọrùn láti sọ pé ‘Ẹ máà bínú.’ Ṣe ni ọkàn mi máa ń bà jẹ́ tí mi ò sì ní lé sọ nǹkan kan!”
Bó o ṣe lè sọ pé “Máà bínú”
Tó bá ṣeé ṣe, tọrọ àforíjì ní ojúkojú. Tó o bá tọrọ àforíjì ní ojúkojú, onítọ̀hún á rí i pé tinútinú lo fi kábàámọ̀ ohun tó o ṣe. Ṣùgbọ́n tó bá jẹ́ pé ṣe lo tẹ àtẹ̀jíṣẹ́ láti fi bẹ̀ ẹ́, ó lè má fi bẹ́ẹ̀ rí bó ṣe dùn ẹ́ tó. Kódà, tó o bá fi àwòrán ojú tó fi ẹ̀dùn ọkàn hàn ránṣẹ́ pẹ̀lú àtẹ̀jíṣẹ́ náà, ó lè dà bíi pé ẹ̀bẹ̀ orí ahọ́n lásán ni, kò dénú ẹ.
Ìmọ̀ràn: Tó ò bá lè tọrọ àforíjì ní ojúkojú, ó lè pè sórí fóònù tàbí kó o fi káàdì tó o kọ ọ̀rọ̀ sí ránṣẹ́. Ọ̀nà yòówù kó o gbà tọrọ àforíjì, mọ irú ọ̀rọ̀ tí wàá sọ.
Ìlànà Bíbélì: “Ọkàn olódodo máa ń ṣe àṣàrò kí ó tó dáhùn.”—Òwe 15:28.
Tètè tọrọ àforíjì. Tó ò bá tètè tọrọ àforíjì, ọ̀rọ̀ náà lè burú ju bó ṣe rí tẹ́lẹ̀ lọ, àárín ìwọ àti ẹni tó ṣẹ̀ ọ́ ò sì ní gún.
Ìmọ̀ràn: Ní àfojúsùn—bí àpẹẹrẹ, ‘Màá tọrọ àforíjì lónìí.’ Pinnu ìgbà tó dáa jù lọ kó o ṣe bẹ́ẹ̀; má sì ṣe jẹ́ kí ọjọ́ yẹn yẹ̀.
Ìlànà Bíbélì: “Tètè yanjú ọ̀rọ̀.”—Mátíù 5:25.
Tọrọ àforíjì látọkàn wá. Tó o bá sọ pé: “Máà bínú pé bí ọ̀rọ̀ náà ṣe rí lára ẹ nìyẹn” ìyẹn kì í ṣe ẹ̀bẹ̀! Ọ̀dọ́mọbìnrin kan tó ń jẹ́ Janelle sọ pé: “Bí ẹni tó o ṣẹ̀ bá rí i pé o mọ ẹ̀bi rẹ lẹ́bi, ó máa bọ̀wọ̀ fún ẹ.”
Ìmọ̀ràn: Tọrọ àforíjì pátápátá. Má ṣe sọ pé, “Àwa méjèèjì la jọ lẹ̀bi, màá tọrọ àforíjì tèmi, kíwọ náà yáa tọrọ àforíjì tìẹ.”
Ìlànà Bíbélì: “Ẹ jẹ́ kí a máa lépa àwọn ohun tó ń mú kí àlàáfíà wà.”—Róòmù 14:19.
a Tó o bá ba nǹkan ẹlòmíì jẹ́ tàbí tó o sọ ọ́ nù, ó máa dára bó o ṣe ń tọrọ àforíjì kó o wá bí wàá ṣe tún ohun tó o bà jẹ́ ṣe tàbí kó o sanwó ohun tó o sọ nù.