Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

ÀWỌN Ọ̀DỌ́ BÉÈRÈ PÉ

Kí Nìdí Tí Kò Fi Yẹ Kí O Máa Ṣe Bí Àwọn Tí Ò Ń Wò Nínú Fíìmù Tàbí Lórí Tẹlifíṣọ̀n?​—Apá 2: Fún Àwọn Ọkùnrin

Kí Nìdí Tí Kò Fi Yẹ Kí O Máa Ṣe Bí Àwọn Tí Ò Ń Wò Nínú Fíìmù Tàbí Lórí Tẹlifíṣọ̀n?​—Apá 2: Fún Àwọn Ọkùnrin

Irú ìwà wo làwọn tó máa ń wà nínú fíìmù tàbí lórí tẹlifíṣọ̀n máa ń hù?

  Wo àwọn ọ̀rọ̀ yìí, kó o sì dáhùn àwọn ìbéèrè tó tẹ̀ lé e.

Abala 1

Abala 2

Aláìgbọràn

Ẹni tó ń bọ̀wọ̀ fúnni

Onímọtara-ẹni-nìkan

Ẹni tó ń dúró tini

Alágídí

Ẹni tó ń gba tẹni rò

Ọ̀lẹ

Ẹni tó ń ṣiṣẹ́ kára

Ẹni tí ò bìkítà

Ọmọlúwàbí

Ẹlẹ̀tàn

Olóòótọ́

  1.   Èwo nínú àwọn ọ̀rọ̀ yìí lo lè fi ṣàpèjúwe àwọn ọmọkùnrin tó o máa ń rí nínú fíìmù, lórí Tẹlifíṣọ̀n tàbí nínú ìpolówó?

  2.   Èwo nínú àwọn ọ̀rọ̀ yìí ni wàá fi ṣàpèjúwe irú ẹni tí ìwọ fẹ́ kí àwọn èèyàn mọ̀ ẹ́ sí?

 Ó ṣeé ṣe kó jẹ́ pé inú abala 1 lo ti mú ìdáhùn ìbéèrè àkọ́kọ́, tó o sì mú ìdáhùn ìbéèrè kejì nínú abala 2. Tó bá rí bẹ́ẹ̀, ìyẹn dáa. Kí nìdí? Torí ó ṣeé ṣe kó jẹ́ pé ìwà ẹ yàtọ̀ sí ti àwọn ọkùnrin tí ò ń rí lórí tẹlifíṣọ̀n tàbí nínú ìpolówó tàbí kó jẹ́ pé kì í ṣe irú ẹni tó yẹ kó o jẹ́ nìyẹn. Wo ìdí tó fi rí bẹ́ẹ̀.

  •   Àwọn tó ń ṣe fíìmù àtàwọn ètò orí tẹlifíṣọ̀n sábà máa ń mú kó dà bíi pé oníwà ipá àti ọlọ̀tẹ̀ làwọn ọkùnrin. Ìwé náà, Why Boys Don’t Talk​—and Why It Matters sọ pé àwọn ọkùnrin tó máa ń gbajúmọ̀ jù lórí tẹlifíṣọ̀n, nínú fíìmù àti nínú eré ìdárayá ni “àwọn tó lágbára tí wọ́n sì máa ń bínú fùfù. . . . Kókó ibẹ̀ ni pé ẹni tó lágídí tó sì ya aláìgbọràn làwọn èèyàn máa ń gba tiẹ̀.”

     Ohun tó o lè ronú lé: Tó bá jẹ́ pé oníjàgídíjàgan ni ẹ́, ṣé o máa lè jẹ́ ọ̀rẹ́ tó dáa, ṣé ìwọ àti ẹlòmíì á lè ṣiṣẹ́ pọ̀ dáadáa, ṣé wàá sì lè jẹ́ ọkọ rere? Tí wọ́n bá múnú bí ẹ, èwo lo rò pé ó gba agbára nínú kó o bínú tàbí kó o pa á mọ́ra? Èwo lo rò pé ó máa fi hàn pé o gbọ́n, pé o ò hùwà bí ọmọdé?

     Bíbélì sọ pé: “Ẹni tí kì í tètè bínú sàn ju alágbára lọ, ẹni tí ń kó ara rẹ̀ níjàánu sàn ju ẹni tí ó jagun gba odidi ìlú lọ.”​—Òwe 16:32, Bíbélì Ìròyìn Ayọ̀.

    Tó o bá lè pa ìbínú rẹ mọ́ra, o lágbára ju jagunjagun lọ

  •   Àwọn tó ń ṣe fíìmù àtàwọn ètò orí tẹlifíṣọ̀n máa ń mú kó dà bíi pé ọ̀rọ̀ ìbálòpọ̀ ló máa ń gba àwọn ọkùnrin lọ́kàn. Chris tó jẹ́ ọmọ ọdún mẹ́tàdínlógún (17) sọ pé: “Ṣe làwọn ọkùnrin tá a máa ń rí nínú fíìmù àti lórí tẹlifíṣọ̀n máa ń pààrọ̀ ọ̀rẹ́bìnrin bí ẹni pààrọ̀ aṣọ.” Gary tó jẹ́ ọmọ ọdún méjìdínlógún (18) náà sọ pé: “Ọ̀rọ̀ ìbálòpọ̀ ló máa ń gba àwọn ọkùnrin inú fíìmù lọ́kàn.” Bí àpẹẹrẹ, àwọn fíìmù kan máa ń mú kó dà bíi pé gbogbo ayé ọkùnrin ò ju kó lọ síbi àríyá, kó mutí, kó sì ní ìbálòpọ̀.

     Ohun tó o lè ronú lé: Ṣé irú ẹni tó o fẹ́ kí wọ́n mọ̀ ẹ́ sí nìyẹn? Ṣé ọkùnrin gidi máa ń hùwà sí àwọn obìnrin bíi pé kéèyàn bá wọn sùn nìkan ni wọ́n wà fún, àbí ṣe lá máa bọ̀wọ̀ fún wọn?

     Bíbélì sọ pé: “Kí olúkúlùkù yín mọ bí yóò ti ṣèkáwọ́ ohun èlò tirẹ̀ nínú ìsọdimímọ́ àti ọlá, kì í ṣe nínú ìdálọ́rùn olójúkòkòrò fún ìbálòpọ̀ takọtabo.”​—1 Tẹsalóníkà 4:​4, 5.

  •   Àwọn tó ń ṣe fíìmù àtàwọn ètò orí tẹlifíṣọ̀n máa ń mú kó dá bíi pé ọ̀lẹ ni àwọn ọkùnrin. Ojú ọ̀lẹ ni wọ́n máa fi ń wo ọ̀pọ̀ àwọn ọmọ ọkùnrin tó ti ń lé lọ́mọ ọdún mẹ́tàlá nínú ọ̀pọ̀ fíìmù àti ètò orí tẹlifíṣọ̀n, wọn kì í sì í wúlò. Bóyá ìdí tí àwọn àgbàlagbà kan ò fi fọkàn tán àwọn ọmọ ọkùnrin lọ títí nìyẹn. Gary tá a sọ̀rọ̀ rẹ̀ lẹ́ẹ̀kan sọ pé: “Nígbà tí mo pé ọmọ ọdún mẹ́rìndínlógún (16), ó ṣòro gan-an fún mi láti rí iṣẹ́ torí obìnrin nìkan ni àwọn ọ̀gá iṣẹ́ tó wà lágbègbè mi fẹ́ gbà síṣẹ́. Èrò wọn ni pé gbogbo ọmọ ọkùnrin tó ti ń lé lọ́mọ ọdún mẹ́tàlá ni kì í wúlò, tí wọn ò sì ṣeé fọkàn tán!”

     Ohun tó o lè ronú lé: Sé ó dáa bí àwọn tó ń ṣe fíìmù àti àwọn tó ń polówó ọjà ṣe mú kó dà bíi pé àwọn ọmọ ọkùnrin ò wúlò, wọn ò sì ṣeé fọkàn tán? Báwo lo ṣe lè fi hàn pé ìwọ yàtọ̀?

     Bíbélì sọ pé: “Má ṣe jẹ́ kí ènìyàn kankan fojú tẹ́ńbẹ́lú èwe rẹ láé. Kàkà bẹ́ẹ̀, di àpẹẹrẹ fún àwọn olùṣòtítọ́ nínú ọ̀rọ̀ sísọ, nínú ìwà, nínú ìfẹ́, nínú ìgbàgbọ́, nínú ìwà mímọ́.”​—1 Tímótì 4:​12.

Ohun tó yẹ kó o mọ̀

  •    Ohun tí ò ń wò lórí tẹlifíṣọ̀n tàbí nínú fíìmù lè nípa tó lágbára gan-an lórí ẹ. Bí àpẹẹrẹ, ohun tí ò ń rí nínú tẹlifíṣọ̀n tàbí nínú ìpolówó lè mú kó o máa rò pé ó yẹ kíwọ náà máa múra bí wọ́n ṣe ń múra káyé lè gba tìẹ. Colin tó jẹ́ ọmọ ọdún mẹ́tàdínlógún (17) sọ pé: “Tí wọ́n bá ń polówó ọjà, èèyàn á rí báwọn ọkùnrin ṣe ń múra, á sì rí i tàwọn obìnrin ń lọ́ mọ́ wọn káàkiri. Ó máa ń mú kó ṣèèyàn bíi pé kóun náà lọ ra àwọn aṣọ yẹn. Mo ti ṣe irú ẹ̀ láwọn ìgbà kan!”

     Ohun tó o lè ronú lé: Ṣé bí o ṣe ń múra fi irú ẹni tó o jẹ́ gan-an hàn, àbí ohun táwọn míì ń ṣe lo kàn ń ṣe? Tó o bá ń ná owó ẹ kó o lè máa ra aṣọ àti ohun ọ̀ṣọ́ tó ṣẹ̀ṣẹ̀ jáde, ta lo rò pé ó ń jèrè?

     Bíbélì sọ pé: “Kí ẹ̀yin kí ó má sì ṣe gẹ́gẹ́ bí ìwà àti àṣà ti ayé yìí.”​—Róòmù 12:2, Bíbélì Mímọ́.

  •   Tó o bá ń ṣe bíi ti àwọn tí ò ń rí nínú fíìmù tàbí nínú ìpolówó, àwọn obìnrin lè má gba tìẹ. Gbọ́ ohun táwọn obìnrin kan sọ:

    •  “Mo fẹ́ràn ọkùnrin tí kì í fi ìwà rẹ̀ pa mọ́ ju èyí tó ń díbọ́n kó lè gbayì lójú àwọn ẹlòmíì. Òótọ́ ibẹ̀ ni pé, tí ọkùnrin kan bá ń wá bó ṣe máa gbayì lójú àwọn ẹlòmíì ní gbogbo ìgbà, ṣe láwọn èèyàn máa kà á sí ẹni tí ò gbọ́n!”​—Anna.

    •  “Àwọn tó ń polówó ọjà máa ń mú kí àwọn ọkùnrin rò pé ó yẹ kí wọ́n ní àwọn nǹkan ìgbàlódé kan tàbí kí wọ́n múra lọ́nà kan káwọn obìnrin tó lè gba tiwọn. Àmọ́ báwọn obìnrin ṣe ń dàgbà, gbogbo ìyẹn kọ́ ló máa ń ṣe pàtàkì sí wọn. Ohun tí wọ́n máa ń wò lára ọkùnrin ni irú ẹni tó jẹ́ àti bó ṣe ń ṣe sáwọn èèyàn. Bí àpẹẹrẹ, àwọn obìnrin máa ń fẹ́ràn kí ọkùnrin jẹ́ olóòótọ́, kó má sì jẹ́ ọ̀dàlẹ̀.”​—Danielle.

    •  “Tí ọkùnrin bá tiẹ̀ múra, tó ń lo àwọn nǹkan tó ṣẹ̀ṣẹ̀ dé, agbéraga ni irú wọn sábà máa ń jẹ́, mi ò sì fẹ́ kí ohunkóhun da èmi àti irú èèyàn bẹ́ẹ̀ pọ̀. Bó bá tiẹ̀ jẹ́ pé ìwọ lo rẹwà jù láyé, a ò lè ṣọ̀rẹ́ tí ìwà rẹ ò bá dáa.”​—Diana.

     Ohun tó o lè ronú lé: Ìwé Mímọ́ ṣàpèjúwe Sámúẹ́lì pé ó “ń dàgbà sí i, ó sì túbọ̀ ń jẹ́ ẹni tí a fẹ́ràn ní ojú ìwòye Jèhófà àti ti àwọn ènìyàn.” (1 Sámúẹ́lì 2:​26) Irú àwọn ànímọ́ wo ló yẹ kó o sapá láti ní kí wọ́n lè sọ̀rọ̀ rẹ dáadáa bíi ti Sámúẹ́lì?

     Bíbélì sọ pé: “Ẹ máa bá a nìṣó bí ọkùnrin.”​—1 Kọ́ríńtì 16:13.

Ohun tí o lè ṣe

  •    Ronú jinlẹ̀ nípa ohun tí ò ń rí lórí tẹlifíṣọ̀n tàbí nínú ìpolówó, má kàn dédé máa fara wé wọn. Kíyè sí ohun ti Bíbélì sọ yìí: “Ohun gbogbo tí ń bẹ nínú ayé​—ìfẹ́kúfẹ̀ẹ́ ara àti ìfẹ́kúfẹ̀ẹ́ ojú àti fífi àlùmọ́ọ́nì ìgbésí ayé ẹni hàn sóde lọ́nà ṣekárími​—kò pilẹ̀ṣẹ̀ láti ọ̀dọ̀ Baba, ṣùgbọ́n ó pilẹ̀ṣẹ̀ láti ọ̀dọ̀ ayé.”​—1 Jòhánù 2:16.

     Àwọn ilé iṣẹ́ tẹlifíṣọ̀n àtàwọn tó ń polówó ọjà ń lo àwọn ohun tí Bíbélì mẹ́nu bà yẹn torí àǹfààní ara wọn, wọ́n wá ń mú kó dà bíi pé kò sóhun tó burú níbẹ̀. Torí náà, má kàn dédé máa tẹ̀ lé ohun tí wọ́n ń ṣe, ronú nípa ẹ̀ dáadáa. Ọgbọ́nkọ́gbọ́n ni wọ́n ń ta, bí wọ́n ṣe máa rówó ni wọ́n ń wá.

  •   Mọ irú ẹni tó o fẹ́ jẹ́, kó o sì máa sapá láti jẹ́ bẹ́ẹ̀. Bíbélì sọ pé: “Ẹ . . . fi àkópọ̀ ìwà tuntun wọ ara yín láṣọ, èyí tí a ń sọ di tuntun nípasẹ̀ ìmọ̀ pípéye ní ìbámu pẹ̀lú àwòrán Ẹni tí ó dá a”​—kì í ṣe ní ìbámu pẹ̀lú àwòrán ohun tí wọ́n ń ṣe nínú fíìmù tàbí nínú ìpolówó.​—Kólósè 3:​10.

     Kó o lè tẹ̀ lé ìmọ̀ràn yẹn, ronú nípa àwọn ànímọ́ tó o yàn níbẹ̀rẹ̀ àpilẹ̀kọ yìí, èyí tó o fẹ́ kí àwọn èèyàn mọ̀ ẹ́ mọ́. O ò ṣe kúkú bẹ̀rẹ̀ sí í sapá báyìí kó o lè ní àwọn ànímọ́ yẹn tàbí kó o jẹ́ kó túbọ̀ máa hàn nínú ìwà rẹ?

  •   Fara wé àwọn èèyàn tó jẹ́ àpẹẹrẹ rere. Bíbélì sọ pé: “Ẹni tí ó bá ń bá àwọn ọlọ́gbọ́n rìn yóò gbọ́n.” (Òwe 13:20) Àwọn ọkùnrin wo ló sún mọ́ tó o rí i pé wọ́n jẹ́ ọlọ́gbọ́n? Ó lè jẹ́ àwọn kan nínú ìdílé rẹ, bíi dádì ẹ, ẹ̀gbọ́n tàbí àbúrò dádì ẹ. Ó tún lè jẹ́ àwọn ọ̀rẹ́ rẹ ọkùnrin tàbí àwọn tó o mọ̀ tí wọ́n níwà àgbà. Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ní ọ̀pọ̀ ọkùnrin tó jẹ́ àpẹẹrẹ rere nínú ìjọ Kristẹni. Àwọn tó jẹ́ àpẹẹrẹ rere náà wà nínú Bíbélì. Lára wọn ni Títù, tó jẹ́ àpẹẹrẹ rere tí àwọn ọ̀dọ́ lè tẹ̀ lé.​—Títù 2:​6-8.

     Àbá: Ka ìwé Tẹ̀ Lé Àpẹẹrẹ Ìgbàgbọ́ Wọn, kó o lè kẹ́kọ̀ọ́ nípa àwọn èèyàn kan nínú Bíbélì tí wọ́n jẹ́ àpẹẹrẹ rere, tí àwọn ọkùnrin sì lè tẹ̀ lé àpẹẹrẹ wọn. Lára wọn ni Ébẹ́lì, Nóà, Ábúrámù, Sámúẹ́lì, Èlíjà, Jónà, Jósẹ́fù àti Pétérù.