Sí Àwọn Ará Gálátíà 5:1-26

  • Òmìnira Kristẹni (1-15)

  • Ẹ máa rìn nípa ẹ̀mí (16-26)

    • Àwọn iṣẹ́ ti ara (19-21)

    • Èso ti ẹ̀mí (22, 23)

5  Kristi ti dá wa sílẹ̀ ká lè ní irú òmìnira yìí. Nítorí náà, ẹ dúró gbọn-in,+ ẹ má sì tọrùn bọ àjàgà ẹrú mọ́.+  Ẹ wò ó! Èmi, Pọ́ọ̀lù, ń sọ fún yín pé tí ẹ bá dádọ̀dọ́,* Kristi ò ní ṣe yín láǹfààní kankan.+  Mo tún jẹ́rìí sí i pé dandan ni fún gbogbo ẹni tó bá dádọ̀dọ́* láti pa gbogbo Òfin mọ́.+  Ẹ ti kúrò lọ́dọ̀ Kristi, ẹ̀yin tí ẹ fẹ́ kí a pè yín ní olódodo nípasẹ̀ òfin;+ ẹ ti yà kúrò nínú inú rere àìlẹ́tọ̀ọ́sí rẹ̀.  Ní tiwa, nínú ẹ̀mí, à ń dúró de òdodo tí à ń retí lójú méjèèjì, èyí tó ń wá látinú ìgbàgbọ́.  Torí nínú Kristi Jésù, ìdádọ̀dọ́* tàbí àìdádọ̀dọ́* kò ṣàǹfààní,+ ìgbàgbọ́ tó ń ṣiṣẹ́ nípasẹ̀ ìfẹ́ ló ṣàǹfààní.  Ẹ ti ń sáré dáadáa tẹ́lẹ̀.+ Ta ló dí yín lọ́wọ́ kí ẹ má ṣègbọràn sí òtítọ́ mọ́?  Irú èrò tí wọ́n fi yí yín lọ́kàn pa dà yìí kò wá látọ̀dọ̀ Ẹni tó ń pè yín.  Ìwúkàrà díẹ̀ ló ń mú gbogbo ìṣùpọ̀ wú.+ 10  Ọkàn mi balẹ̀ pé ẹ̀yin tí ẹ wà nínú Olúwa+ kò ní ronú lọ́nà míì; àmọ́, ẹni tó ń dá wàhálà sílẹ̀ fún yín,+ ẹnì yòówù kó jẹ́, yóò gba ìdájọ́ tó tọ́ sí i. 11  Ní tèmi, ẹ̀yin ará, tí mo bá ṣì ń wàásù ìdádọ̀dọ́,* kí ló dé tí wọ́n tún ń ṣe inúnibíni sí mi? Tó bá jẹ́ bẹ́ẹ̀, òpó igi oró*+ kì í ṣe ohun ìkọ̀sẹ̀ mọ́ fún àwọn tó ń ta kò mí. 12  Ó wù mí kí àwọn tó fẹ́ da àárín yín rú tẹ ara wọn lọ́dàá.* 13  Ẹ̀yin ará, a pè yín kí ẹ lè ní òmìnira; kìkì pé kí ẹ má ṣe lo òmìnira yìí láti máa ṣe ìfẹ́ ti ara,+ àmọ́ ẹ jẹ́ kí ìfẹ́ máa mú kí ẹ sin ara yín bí ẹrú.+ 14  Nítorí a ti mú gbogbo Òfin ṣẹ nínú* àṣẹ kan ṣoṣo, tó sọ pé: “Kí o nífẹ̀ẹ́ ọmọnìkejì rẹ bí ara rẹ.”+ 15  Tí ẹ bá wá ń bu ara yín jẹ, tí ẹ sì ń fa ara yín ya,+ ẹ ṣọ́ra kí ẹ má bàa pa ara yín run.+ 16  Àmọ́ mo sọ pé, Ẹ máa rìn nípa ẹ̀mí,+ ẹ kò sì ní ṣe ìfẹ́ ti ara rárá.+ 17  Nítorí ohun tí ara ń fẹ́ lòdì sí ohun tí ẹ̀mí ń fẹ́, ẹ̀mí sì lòdì sí ara; àwọn méjèèjì ta ko ara wọn, ìdí nìyẹn tí ẹ kò fi lè ṣe ohun tí ẹ fẹ́ ṣe.+ 18  Yàtọ̀ síyẹn, tí ẹ̀mí bá ń darí yín, ẹ kò sí lábẹ́ òfin. 19  Àwọn iṣẹ́ ti ara hàn kedere, àwọn sì ni ìṣekúṣe,*+ ìwà àìmọ́, ìwà àìnítìjú,*+ 20  ìbọ̀rìṣà, ìbẹ́mìílò,*+ ìkórìíra, wàhálà, owú, inú fùfù, awuyewuye, ìpínyà, ẹ̀ya ìsìn, 21  ìlara, ìmutíyó,+ àwọn àríyá aláriwo àti irú àwọn nǹkan yìí.+ Mò ń kìlọ̀ fún yín ṣáájú nípa àwọn nǹkan yìí, lọ́nà kan náà tí mo gbà kìlọ̀ fún yín tẹ́lẹ̀, pé àwọn tó bá ń ṣe àwọn nǹkan yìí kò ní jogún Ìjọba Ọlọ́run.+ 22  Àmọ́, èso ti ẹ̀mí ni ìfẹ́, ayọ̀, àlàáfíà, sùúrù,* inú rere, ìwà rere,+ ìgbàgbọ́, 23  ìwà tútù, ìkóra-ẹni-níjàánu.+ Kò sí òfin kankan tó lòdì sí irú àwọn nǹkan yìí. 24  Yàtọ̀ síyẹn, àwọn tó jẹ́ ti Kristi Jésù ti kan ẹran ara mọ́gi* pẹ̀lú ohun tí ẹran ara ń fẹ́ àti ohun tó ń wù ú.+ 25  Tí a bá wà láàyè nípa ẹ̀mí, ẹ jẹ́ kí a máa rìn létòlétò nípa ẹ̀mí.+ 26  Ẹ má ṣe jẹ́ kí a di agbéraga,+ kí a má ṣe máa bá ara wa díje,+ kí a má sì máa jowú ara wa.

Àlàyé Ìsàlẹ̀ Ìwé

Tàbí “kọlà.”
Tàbí “kọlà.”
Tàbí “ìkọlà.”
Tàbí “àìkọlà.”
Tàbí “ìkọlà.”
Tàbí “di ìwẹ̀fà,” kí wọ́n tipa bẹ́ẹ̀ di ẹni tí kò kúnjú ìwọ̀n láti tẹ̀ lé òfin tí wọ́n fọwọ́ sí.
Tàbí kó jẹ́, “kó gbogbo Òfin jọ sínú.”
Lédè Gíríìkì, por·neiʹa. Wo Àlàyé Ọ̀rọ̀.
Tàbí “ìwà ọ̀dájú.” Ní Gíríìkì, a·selʹgei·a. Wo Àlàyé Ọ̀rọ̀.
Tàbí “iṣẹ́ oṣó; lílo oògùn olóró.”
Tàbí “ìpamọ́ra.”
Tàbí “mọ́ òpó igi.” Wo Àlàyé Ọ̀rọ̀.