Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

ÀWỌN Ọ̀DỌ́ BÉÈRÈ PÉ

Ṣé Ká Fira Wa Sílẹ̀? (Apá 1)

Ṣé Ká Fira Wa Sílẹ̀? (Apá 1)

 Oore ńlá ló máa ń jẹ́ nígbà míì táwọn méjì tó ń fẹ́ra bá fira wọn sílẹ̀. Wo ohun tó ṣẹlẹ̀ sí ọmọbìnrin kan tó ń jẹ́ Jill. Ó sọ pé: “Nígbà tá a bẹ̀rẹ̀ sí í fẹ́ra, inú mi máa ń dùn pé ẹni tí mò ń fẹ́ máa ń fẹ́ mọ ibi tí mo wà, ohun tí mò ń ṣe àti ọ̀dọ̀ ẹni tí mo wà. Àmọ́, ó bá a débi pé kò fẹ́ kí n da nǹkan pọ̀ pẹ̀lú ẹlòmíì, àfi òun nìkan ṣáá. Kódà, ó máa ń jowú tó bá rí èmi àtàwọn aráalé mi pọ̀, àgàgà dádì mi. Nígbà tó yá, a ò fẹ́ra mọ́. Ara wá tù mí, ṣe ló dà bí ìgbà tí wọ́n gbé ẹrù kan tó wúwo kúrò lọ́rùn mi!”

 Irú nǹkan tó ṣẹlẹ̀ sí Sarah náà nìyẹn. John lorúkọ ọmọkùnrin tó ń fẹ́. Sarah bẹ̀rẹ̀ sí í kíyè sí i pé ọ̀rọ̀ ẹnu John ò dáa, ó ṣòroó tẹ́ lọ́rùn, ó sì máa ń ráwọn èèyàn fín. Sarah rántí ohun kan tó ṣẹlẹ̀, ó ní, “Ọjọ́ kan wà tá a jọ ń lọ síbì kan, ó sì pẹ́ kó tó délé wa. Ó ti tó wákàtí mẹ́ta tí mo ti ń dúró dè é! Nígbà tó dé, mọ́mì mi ló lọ ṣílẹ̀kùn fún un. Àmọ́ kò kí wọn, ọ̀dọ̀ mi ló ń bọ̀ tààràtà, ó wá sọ fún mi pé: ‘Jẹ́ ká lọ, a ti pẹ́.’ Dípò kó sọ pé ‘Òun ti pẹ́,’ ó ní, ‘A ti pẹ́.’ Èmi tiẹ̀ retí pé kó ní kí n máà bínú, kó sì ṣàlàyé ohun tó fà á tó fi pẹ́. Èyí tó tiẹ̀ dùn mí jù ni bó ṣe fojú pa mọ́mì mi rẹ́!”

 Ti pé ẹni tó ò ń fẹ́ ṣe ohun tí ò dáa lẹ́ẹ̀kan ṣoṣo ò ní kó o wá sọ pé o ò ṣe mọ́. (Sáàmù 130:3) Àmọ́ ti ohun tó ṣẹlẹ̀ sí Sarah yàtọ̀. Sarah ti rí i pé John ò mọ̀wà hù, kò ṣẹ̀ṣẹ̀ máa ṣe é, ìyẹn ló mú kó sọ pé òun ò ṣe mọ́.

 Bíi ti Jill àti Sarah, tíwọ náà bá rí i pé ọ̀rọ̀ ìwọ àti ẹni tó ò ń fẹ́ ò wọ̀ mọ́ ńkọ́, pé kì í ṣẹni tó o lè fẹ́ sílé? Má kàn gbójú fò ó o! Ó lè má rọrùn lóòótọ́, àmọ́ ó lè jẹ́ ohun tó máa dáa jù ni pé kẹ́ ẹ fira yín sílẹ̀. Òwe 22:3 sọ pé: “Afọgbọ́nhùwà ni ẹni tí ó ti rí ìyọnu àjálù, tí ó sì bẹ̀rẹ̀ sí fi ara rẹ̀ pa mọ́.”

 Ó lè má rọrùn láti fira yín sílẹ̀ lóòótọ́. Àmọ́ téèyàn bá ti bá ẹnì kan ṣègbéyàwó, ó ti gbé tiẹ̀ nìyẹn. Torí náà, bọ́rọ̀ ò bá wọ̀ mọ́, ó sàn kéèyàn jẹ̀rora ẹ̀ fúngbà díẹ̀ ju kó fagídí tọrùn bọ̀ ọ́, kó wá máa jẹ̀ka àbámọ̀ títí lọ tó bá yá!