Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

ÀWỌN Ọ̀DỌ́ BÉÈRÈ PÉ

Kí Ló Yẹ Kí N Mọ̀ Nípa Eré Ìdárayá?

Kí Ló Yẹ Kí N Mọ̀ Nípa Eré Ìdárayá?

 Eré ìdárayá lè ṣe ẹ́ láǹfààní tàbí kó pa ẹ́ lára. Irú eré tó o bá ṣe, bó o bá ṣe ṣe é àti bí àkókò tó o fi ṣe eré ọ̀hún bá ṣe pọ̀ tó ló máa pinnu.

 Àǹfààní wo ló lè ṣe ẹ́?

 Tó o bá ń ṣe eré ìdárayá, ó máa jẹ́ kí ìlera rẹ dáa. Bíbélì sọ pé, “Eniyan a máa rí anfaani. . .tí ó bá ń ṣe eré ìdárayá.” (1 Tímótì 4:8, Bibeli Ìròyìn Ayọ̀) Ọ̀dọ́kùnrin kan tó ń jẹ́ Ryan sọ pé, “Eré ìdárayá máa ń mú kí ara jí pépé, torí èèyàn máa sá síbí sá sọ́hùn-ún. Ó dáa ju kéèyàn kàn jókòó sínú ilé kó máa gbá géèmù.”

 Eré ìdárayá máa jẹ́ kó o lè bá àwọn ẹlòmíì ṣiṣẹ́ pọ̀, kó o sì máa kó ara ẹ níjàánu. Bíbélì lo àpèjúwe kan tó dá lórí eré ìdárayá láti fi kọ́ wa lẹ́kọ̀ọ́ kan. Ó sọ pé: “Gbogbo àwọn sárésáré nínú eré ìje ní ń sáré, ṣùgbọ́n ẹnì kan ṣoṣo ní ń gba ẹ̀bùn náà.” Ó wá sọ pé: “Olúkúlùkù ènìyàn tí ń kó ipa nínú ìdíje a máa lo ìkóra-ẹni-níjàánu nínú ohun gbogbo.” (1 Kọ́ríńtì 9:​24, 25) Kí la rí kọ́? Kéèyàn tó lè ṣe eré ìdárayá kan bí wọ́n ṣe ń ṣe é, ó gba kéèyàn kó ara rẹ̀ níjàánu, kó sì fọwọ́ sowọ́ pọ̀ pẹ̀lú àwọn tó kù. Ọ̀dọ́bìnrin kan tó ń jẹ́ Abigail sọ pé òun fara mọ́ ọn, ó ní, “Eré ìdárayá ti jẹ́ kí n mọ béèyàn ṣe ń fọwọ́ sowọ́ pọ̀ pẹ̀lú àwọn míì, ká sì gbọ́ra wa yé.”

 Eré ìdárayá máa ń mú káwọn èèyàn túbọ̀ rẹ́. Eré ìdárayá máa ń gba pé káwọn èèyàn ṣe nǹkan pọ̀. Ọ̀dọ́kùnrin kan tó ń jẹ́ Jordan sọ pé, “Ó fẹ́rẹ̀ẹ́ má sí eré ìdárayá tí ò ní gba pé káwọn tó ń ṣe é bára wọn díje lọ́nà kan ṣá, àmọ́ téèyàn ò bá mú un le kankan, tó kà á sí pé òun àtàwọn ọ̀rẹ́ òun kàn ń gbafẹ́ ni, ó máa jẹ́ kí gbogbo wọn gbádùn ẹ̀ gan-an, wọ́n á sì túbọ̀ rẹ́.”

 Ìpalára wo ló lè ṣe fún ẹ?

 Irú eré ìdárayá tó ò ń ṣe. Bíbélì sọ pé: “Jèhófà tìkára rẹ̀ ń ṣàyẹ̀wò olódodo àti ẹni burúkú, dájúdájú, ọkàn Rẹ̀ kórìíra ẹnikẹ́ni tí ó bá nífẹ̀ẹ́ ìwà ipá.”​—Sáàmù 11:5.

 Àwọn eré ìdárayá kan wà tó máa gba pé kéèyàn hùwà ipá. Bí àpẹẹrẹ, ọ̀dọ́bìnrin kan tó ń jẹ́ Lauren kíyè sí i pé: “Ohun tó máa ń wà lọ́kàn àwọn tó máa ń kan ẹ̀ṣẹ́ ni pé kí wọ́n lu ẹnì kejì bolẹ̀. Àmọ́ àwa Kristẹni kì í jà, torí náà, ṣé ó yẹ ká máa wo àwọn tí wọ́n ń kó ẹ̀ṣẹ́ bora wọn, ká lá à ń gbafẹ́?”

 Ohun tó yẹ kó o ronú lé: Ṣé o ti ń rò ó pé kò sóhun tó burú nínú kó o máa ṣe eré ìdárayá oníwà ipá tàbí kó o máa wò ó, kó o máa wá sọ lọ́kàn ẹ pé o ò lè torí ìyẹn lọ máa hùwà ipá? Tọ́rọ̀ bá rí bẹ́ẹ̀, rántí ohun tí Sáàmù 11:5 sọ, pé Jèhófà kórìíra ẹni tó “nífẹ̀ẹ́ ìwà ipá,” kì í ṣe ẹni tó ń ṣe é nìkan.

 Bó o ṣe ń ṣe é. Bíbélì sọ pé: ‘Ẹ má ṣe ohunkóhun láti inú ẹ̀mí asọ̀ tàbí láti inú ìgbéra-ẹni-lárugẹ, ṣùgbọ́n pẹ̀lú ìrẹ̀lẹ̀ èrò inú, kí ẹ máa kà á sí pé àwọn ẹlòmíràn lọ́lá jù yín lọ.’​—Fílípì 2:3.

 Ó dájú pé tó bá ti jẹ́ pé àwùjọ méjì ló jọ ń ṣe eré kan, wọ́n á bára wọn díje lọ́nà kan ṣá. Àmọ́ tọ́rọ̀ bá ti ń di pé ‘dandan ni kí n borí,’ eré ọ̀hún ò ní dùn mọ́. Ọ̀dọ́kùnrin kan tó ń jẹ́ Brian sọ pé, “Tá a bá ń ṣeré ìdárayá, téèyàn ò bá ṣọ́ra, kò ní mọ ìgbà tó máa bẹ̀rẹ̀ sí í bá ẹnì kejì díje. Béèyàn bá ṣe ń mọ eré náà ṣe ló yẹ kó túbọ̀ sapá láti jẹ́ onírẹ̀lẹ̀.”

 Ohun tó yẹ kó o ronú lé: Ọ̀dọ́kùnrin kan tó ń jẹ́ Chris sọ pé, “Ọ̀sọ̀ọ̀sẹ̀ la máa ń gbá bọ́ọ̀lù, a sì máa ń ṣèṣe.” Torí náà, bi ara rẹ pé, ‘Àwọn nǹkan wo ló lè mú kẹ́ ẹ ṣèṣe tẹ́ ẹ bá ń ṣeré ìdárayá? Kí ni mo lè ṣe ká má bàa ṣèṣe?’

 Àkókò tó o fi ṣe eré náà. Bíbélì sọ pé: “Máa wádìí dájú àwọn ohun tí ó ṣe pàtàkì jù.”​—Fílípì 1:​10.

 Mọ ohun tó yẹ kó o fi sí ipò àkọ́kọ́, ohun tó jẹ mọ́ ìjọsìn Ọlọ́run ló yẹ kó wà nípò àkọ́kọ́. Ọ̀pọ̀ géèmù ló máa ń gba èèyàn lákòókò, ì báà jẹ́ pé ṣe lèèyàn ń wò ó tàbí ó ń gbá a. Ọ̀dọ́bìnrin kan tó ń jẹ́ Daria sọ pé, “Mọ́mì mi máa ń bá mi jà torí mo máa ń pẹ́ nídìí géèmù, wọ́n á ní nǹkan gidi ló yẹ kí n máa fi àkókò yẹn ṣe.”

Téèyàn bá gbájú mọ́ eré ìdárayá ju bó ṣe yẹ lọ, ṣe ló máa dà bí ẹni ń rọ́ iyọ̀ sí oúnjẹ

 Ohun tó yẹ kó o ronú lé: Táwọn òbí ẹ bá ń gbà ẹ́ nímọ̀ràn nípa ohun tó yẹ kó o fi sípò àkọ́kọ́, ṣé o máa ń fetí sí wọn? Ọ̀dọ́bìnrin kan tó ń jẹ́ Trina sọ pé: “Témi àtàwọn àbúrò mi bá ń wo eré ìdárayá, tá a wá torí ìyẹn pa iṣẹ́ pàtàkì tó yẹ ká ṣe tì, mọ́mì máa rán wa létí pé yálà a wo àwọn tó ń ṣeré yẹn tàbí a ò wò wọ́n, wọ́n ń gba owó tiwọn. Wọ́n á wá bi wá pé, ‘Àmọ́ ta ló ń sanwó fún ẹ̀yin?’ Ohun tí mọ́mì ní lọ́kàn mi pé àwọn tó ń ṣeré ìdárayá ti níṣẹ́ tiwọn. Àmọ́ tá ò bá ṣe iṣẹ́ àṣetiléwá wa, tá a sì pa àwọn ojúṣe míì tì, a ò ní lè bójú tó ara wa lọ́jọ́ iwájú. Kókó ọ̀rọ̀ mọ́mì ni pé kò yẹ ká jẹ́ kí eré ìdárayá gbà wá lọ́kàn, yálà à ń ṣe é ni tàbí à ń wò ó.”