Àkọsílẹ̀ Mátíù 6:1-34

  • ÌWÀÁSÙ ORÍ ÒKÈ (1-34)

    • Má ṣe òdodo àṣehàn (1-4)

    • Bí o ṣe lè gbàdúrà (5-15)

      • Àdúrà àwòkọ́ṣe (9-13)

    • Ààwẹ̀ (16-18)

    • Ìṣúra ní ayé àti ọ̀run (19-24)

    • Ẹ má ṣàníyàn mọ́ (25-34)

      • Ẹ máa wá Ìjọba náà lákọ̀ọ́kọ́ (33)

6  “Kí ẹ rí i pé ẹ ò ṣe òdodo yín níwájú àwọn èèyàn, torí kí wọ́n lè rí yín;+ àìjẹ́ bẹ́ẹ̀, ẹ ò ní rí èrè kankan lọ́dọ̀ Baba yín tó wà ní ọ̀run.  Torí náà, tí o bá ń ṣe ìtọrẹ àánú,* má ṣe fun kàkàkí ṣáájú ara rẹ, bí àwọn alágàbàgebè ṣe ń ṣe nínú àwọn sínágọ́gù àti láwọn ojú ọ̀nà, kí àwọn èèyàn lè kan sáárá sí wọn. Lóòótọ́ ni mo sọ fún yín, wọ́n ti gba èrè wọn ní ẹ̀kúnrẹ́rẹ́.  Àmọ́ tí ìwọ bá ń ṣe ìtọrẹ àánú, má ṣe jẹ́ kí ọwọ́ òsì rẹ mọ ohun tí ọwọ́ ọ̀tún rẹ ń ṣe,  kí ìtọrẹ àánú tí o ṣe lè wà ní ìkọ̀kọ̀. Baba rẹ tó ń rí ohun tó wà ní ìkọ̀kọ̀ sì máa san ọ́ lẹ́san.+  “Bákan náà, tí ẹ bá ń gbàdúrà, ẹ má ṣe bíi ti àwọn alágàbàgebè,+ torí tí wọ́n bá ń gbàdúrà, wọ́n máa ń fẹ́ dúró nínú àwọn sínágọ́gù àti ní ìkóríta àwọn ọ̀nà tó bọ́ sí gbangba, kí àwọn èèyàn lè rí wọn.+ Lóòótọ́ ni mo sọ fún yín, wọ́n ti gba èrè wọn ní ẹ̀kúnrẹ́rẹ́.  Àmọ́ tí o bá ń gbàdúrà, lọ sínú yàrá àdáni rẹ, lẹ́yìn tí o bá ti ilẹ̀kùn rẹ, gbàdúrà sí Baba rẹ tó wà ní ìkọ̀kọ̀.+ Baba rẹ tó ń rí ohun tó wà ní ìkọ̀kọ̀ sì máa san ọ́ lẹ́san.  Tí o bá ń gbàdúrà, má sọ ohun kan náà ní àsọtúnsọ, bí àwọn èèyàn orílẹ̀-èdè ṣe máa ń ṣe, torí wọ́n rò pé àdúrà àwọn máa gbà torí bí wọ́n ṣe ń lo ọ̀rọ̀ púpọ̀.  Torí náà, ẹ má ṣe bíi tiwọn, torí Baba yín mọ àwọn ohun tí ẹ nílò,+ kódà kí ẹ tó béèrè lọ́wọ́ rẹ̀.  “Torí náà, ẹ máa gbàdúrà lọ́nà yìí:+ “‘Baba wa tí ń bẹ ní ọ̀run, kí orúkọ+ rẹ di mímọ́.*+ 10  Kí Ìjọba rẹ dé.+ Kí ìfẹ́ rẹ+ ṣẹ ní ayé,+ bíi ti ọ̀run. 11  Fún wa ní oúnjẹ òòjọ́ wa lónìí;+ 12  kí o sì dárí àwọn gbèsè wa jì wá, bí àwa náà ṣe dárí ji àwọn tó jẹ wá ní gbèsè.+ 13  Má sì mú wa wá sínú ìdẹwò,+ ṣùgbọ́n gbà wá* lọ́wọ́ ẹni burúkú náà.’+ 14  “Torí tí ẹ bá dárí ẹ̀ṣẹ̀ àwọn èèyàn jì wọ́n, Baba yín ọ̀run náà máa dárí jì yín;+ 15  àmọ́ tí ẹ kò bá dárí ẹ̀ṣẹ̀ àwọn èèyàn jì wọ́n, Baba yín ò ní dárí àwọn ẹ̀ṣẹ̀ yín jì yín.+ 16  “Tí ẹ bá ń gbààwẹ̀,+ ẹ má fajú ro mọ́ bíi ti àwọn alágàbàgebè, torí wọ́n máa ń bojú jẹ́* kí àwọn èèyàn lè rí i pé wọ́n ń gbààwẹ̀.+ Lóòótọ́ ni mo sọ fún yín, wọ́n ti gba èrè wọn ní ẹ̀kúnrẹ́rẹ́. 17  Àmọ́ tí ìwọ bá ń gbààwẹ̀, fi òróró pa orí rẹ, kí o sì bọ́jú rẹ, 18  kó má bàa hàn sí àwọn èèyàn pé ò ń gbààwẹ̀, Baba rẹ tó wà ní ìkọ̀kọ̀ nìkan ni kó hàn sí. Baba rẹ tó ń rí ohun tó wà ní ìkọ̀kọ̀ sì máa san ọ́ lẹ́san. 19  “Ẹ má to ìṣúra pa mọ́ fún ara yín ní ayé mọ́,+ níbi tí òólá* ti ń jẹ nǹkan run, tí nǹkan ti ń dípẹtà, tí àwọn olè ń fọ́lé, tí wọ́n sì ń jalè. 20  Kàkà bẹ́ẹ̀, ẹ to ìṣúra pa mọ́ fún ara yín ní ọ̀run,+ níbi tí òólá kò ti lè jẹ nǹkan run, tí nǹkan ò ti lè dípẹtà,+ tí àwọn olè kò ti lè fọ́lé, kí wọ́n sì jalè. 21  Torí ibi tí ìṣúra yín bá wà, ibẹ̀ ni ọkàn yín náà máa wà. 22  “Ojú ni fìtílà ara.+ Tí ojú rẹ bá mú ọ̀nà kan,* gbogbo ara rẹ máa mọ́lẹ̀ yòò.* 23  Àmọ́ tí ojú rẹ bá ń ṣe ìlara,*+ gbogbo ara rẹ máa ṣókùnkùn. Tó bá jẹ́ òkùnkùn ni ìmọ́lẹ̀ tó wà nínú rẹ lóòótọ́, òkùnkùn yẹn mà pọ̀ o! 24  “Kò sí ẹni tó lè sin ọ̀gá méjì; àfi kó kórìíra ọ̀kan, kó sì nífẹ̀ẹ́ ìkejì+ tàbí kó fara mọ́ ọ̀kan, kó má sì ka ìkejì sí. Ẹ ò lè sin Ọlọ́run àti Ọrọ̀.+ 25  “Torí náà, mo sọ fún yín pé: Ẹ yéé ṣàníyàn+ nípa ẹ̀mí* yín, ní ti ohun tí ẹ máa jẹ tàbí tí ẹ máa mu tàbí nípa ara yín, ní ti ohun tí ẹ máa wọ̀.+ Ṣé ẹ̀mí* ò ṣe pàtàkì ju oúnjẹ lọ ni, tí ara sì ṣe pàtàkì ju aṣọ lọ?+ 26  Ẹ fara balẹ̀ kíyè sí àwọn ẹyẹ ojú ọ̀run;+ wọn kì í fúnrúgbìn tàbí kárúgbìn tàbí kí wọ́n kó nǹkan jọ sínú ilé ìkẹ́rùsí, síbẹ̀ Baba yín ọ̀run ń bọ́ wọn. Ṣé ẹ ò wá níye lórí jù wọ́n lọ ni? 27  Èwo nínú yín ló lè fi ìgbọ̀nwọ́* kan kún ìwàláàyè rẹ̀, tó bá ń ṣàníyàn?+ 28  Bákan náà, kí ló dé tí ẹ̀ ń ṣàníyàn nípa ohun tí ẹ máa wọ̀? Ẹ kẹ́kọ̀ọ́ lára àwọn òdòdó lílì inú pápá, bí wọ́n ṣe ń dàgbà; wọn kì í ṣe làálàá, wọn kì í sì í rànwú;* 29  àmọ́ mò ń sọ fún yín pé, a ò ṣe Sólómọ́nì+ pàápàá lọ́ṣọ̀ọ́ nínú gbogbo ògo rẹ̀ bí ọ̀kan lára àwọn yìí. 30  Tó bá jẹ́ pé báyìí ni Ọlọ́run ṣe ń wọ ewéko pápá láṣọ, tó wà lónìí, tí a sì sọ sínú ààrò lọ́la, ṣé kò wá ní wọ̀ yín láṣọ jù bẹ́ẹ̀ lọ, ẹ̀yin tí ìgbàgbọ́ yín kéré? 31  Torí náà, ẹ má ṣàníyàn láé,+ kí ẹ wá sọ pé, ‘Kí la máa jẹ?’ tàbí, ‘Kí la máa mu?’ tàbí, ‘Kí la máa wọ̀?’+ 32  Torí gbogbo nǹkan yìí ni àwọn orílẹ̀-èdè ń wá lójú méjèèjì. Baba yín ọ̀run mọ̀ pé ẹ nílò gbogbo nǹkan yìí. 33  “Torí náà, ẹ máa wá Ìjọba náà àti òdodo Rẹ̀ lákọ̀ọ́kọ́, gbogbo nǹkan mìíràn yìí la sì máa fi kún un fún yín.+ 34  Torí náà, ẹ má ṣàníyàn láé nípa ọ̀la,+ torí ọ̀la máa ní àwọn àníyàn tirẹ̀. Wàhálà ọjọ́ kọ̀ọ̀kan ti tó fún un.

Àlàyé Ìsàlẹ̀ Ìwé

Tàbí “ìtọrẹ fún àwọn aláìní.” Wo Àlàyé Ọ̀rọ̀.
Tàbí “kí a bọ̀wọ̀ fún orúkọ rẹ; kí a ka orúkọ rẹ sí mímọ́.”
Tàbí “dá wa nídè.”
Tàbí “wọn kì í túnra ṣe.”
Tàbí “kòkòrò.”
Tàbí “bá ríran kedere.”
Tàbí “kún fún ìmọ́lẹ̀.”
Ní Grk., “bá burú.”
Tàbí “ọkàn.”
Tàbí “ọkàn.”
Tàbí “ṣe òwú.”