Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

ÀWỌN Ọ̀DỌ́ BÉÈRÈ PÉ

Ṣé Ẹ̀kọ́ Ẹfolúṣọ̀n Tọ̀nà àbí Ẹlẹ́dàá Kan Wà?​—Apá 1: Kí Nìdí Tó Fi Yẹ Ká Gbà Pé Ọlọ́run Wà?

Ṣé Ẹ̀kọ́ Ẹfolúṣọ̀n Tọ̀nà àbí Ẹlẹ́dàá Kan Wà?​—Apá 1: Kí Nìdí Tó Fi Yẹ Ká Gbà Pé Ọlọ́run Wà?

 Ṣé ẹ̀kọ́ ẹfolúṣọ̀n tọ̀nà àbí Ẹlẹ́dàá kan wà?

 Ṣé o gbà pé Ọlọ́run ló dá ohun gbogbo? Tó o bá gbà bẹ́ẹ̀, mọ̀ pé kì í ṣe ìwọ nìkan, ọ̀pọ̀ ọ̀dọ́ náà ló gbà bẹ́ẹ̀ (títí kan àwọn tó ti dàgbà). Àmọ́ àwọn kan sọ pé ṣe ni àgbáálá ayé àtàwọn ohun alààyè ṣàdédé wà láìsí Ẹlẹ́dàá kankan tàbí Ẹni Gíga Jù Lọ tó dá wọn.

 Ǹjẹ́ o mọ̀? Lọ́pọ̀ ìgbà táwọn tí èrò wọn yàtọ̀ síra lórí ọ̀rọ̀ yìí bá ń jiyàn, ohun tí wọ́n gbà gbọ́ ló máa ń yá wọn lára láti sọ, kódà bí wọn ò tiẹ̀ mọ ìdí tí wọ́n fi gbà á gbọ́.

  •   Àwọn kan gbà pé Ọlọ́run ló dá ohun gbogbo torí ohun tí wọ́n fi kọ́ wọn ní ṣọ́ọ̀ṣì nìyẹn.

  •   Ọ̀pọ̀ èèyàn gbà pé ohun alààyè kàn ṣàdédé wà ni, torí pé ohun tí wọ́n kọ́ wọn níléèwé nìyẹn.

 Àwọn àpilẹ̀kọ yìí máa mú kí ìgbàgbọ́ tó o ní pé Ọlọ́run ni Ẹlẹ́dàá lágbára sí i, wà á sì lè ṣàlàyé ìdí tó o fi gbà bẹ́ẹ̀. Àmọ́, ó yẹ kó o kọ́kọ́ bi ara rẹ ní ìbéèrè pàtàkì kan:

 Kí nìdí tí mo fi gbà pé Ọlọ́run wà?

 Kí nìdí tí ìbéèrè yìí fi ṣe pàtàkì? Ìdí ni pé Bíbélì rọ̀ ẹ́ pé kó o lo “agbára ìmọnúúrò” rẹ, ìyẹn ni pé kó o má a ronú jinlẹ̀. (Róòmù 12:1) Èyí túmọ̀ sí pé ìgbàgbọ́ tó o ní pé Ọlọ́run wà kò gbọ́dọ̀ jẹ́ torí

  •  ohun tó o kàn rò (Mo kàn ronú pé ẹnì kan gbọ́dọ̀ wà tí agbára rẹ̀ ju ti ẹnikẹ́ni lọ)

  •  ohun táwọn ẹlòmíì ń ṣe (Àárín àwọn èèyàn tó nífẹ̀ẹ́ ìsìn ni mò ń gbé)

  •  pohun tí wọ́n fi kọ́ ẹ (Láti kékeré làwọn tó tọ́ mi dàgbà ti kọ́ mi láti gbà pé Ọlọ́run wà)

 Dípò bẹ́ẹ̀, ó yẹ kó dá ìwọ fúnra rẹ lójú pé Ọlọ́run wà, ó sì yẹ kó o ní ìdí pàtàkì tó o fi gbà bẹ́ẹ̀.

 Torí náà, kí ló mú kó dá ẹ lójú pé Ọlọ́run wà? Apá tá a pè ní ibi tí mo kọ èrò mi sí, tó ní àkòrí náà “Kí Nìdí Tí Mo Fi Gbà Pé Ọlọ́run Wà?” máa mú kó túbọ̀ dá ẹ lójú. Tó o bá tún wo ohun táwọn ọ̀dọ́ míì sọ nípa ọ̀rọ̀ yìí, ó máa ràn ẹ́ lọ́wọ́.

 “Tí mo bá wà ní kíláàsì tí mò ń fetí sí olùkọ́ wa bó ṣe ń ṣàlàyé bí àwọn ẹ̀yà ara wa ṣe ń ṣiṣẹ́, ṣe ló túbọ̀ ń mú kó dá mi lójú pé Ọlọ́run wà. Ẹ̀yà ara kọ̀ọ̀kan ló ní iṣẹ́ tirẹ̀, àní títí dórí èyí tó kéré jù lọ, ọ̀pọ̀ ìgbà ló sì jẹ́ pé a kìí mọ̀ pé wọ́n ń ṣiṣẹ́. Ọ̀nà tí ara wa yìí ń gbà ṣiṣẹ́ kàmàmà lóòótọ́!”​—Teresa.

 “Tí mo bá rí ilé gogoro, ọkọ̀ òkun ńlá tí wọ́n fi ń gbafẹ́ tàbí mọ́tò, mo máa ń bi ara mi pé, ‘Ta ló kọ́ ilé yìí tàbí ta ló ṣe ọkọ̀ yìí?’ Bí àpẹẹrẹ, ó ní láti jẹ́ pé àwọn èèyàn tó ní òye ló ṣe mọ́tò, torí pé ọ̀pọ̀ nǹkan kéékèèké tó wà nínú rẹ̀ ló gbọ́dọ̀ ṣiṣẹ́ pa pọ̀ kí mọ́tò yẹn tó lè ṣiṣẹ́. Tó bá sì wá jẹ́ pé ẹnì kan ló ṣe mọ́tò jáde, a jẹ́ pé ẹnì kan ló dá àwa èèyàn náà nìyẹn.”​—Richard.

 “Téèyàn bá mọ̀ pé ọgọ́rọ̀ọ̀rún ọdún ló gba àwọn èèyàn tó ní òye jù lọ kí wọ́n tó lè lóye èyí tó kéré jù lára àwọn nǹkan tó wà ní àgbáálá ayé, kò ní bọ́gbọ́n mu nígbà náà láti ronú pé ṣe ni àgbáálá ayé wa yìí kàn ṣàdédé wà láìsí onílàákàyè kan tó dá a.”​—Karen.

 “Bí mo ṣe ń kẹ́kọ̀ọ́ nípa ìmọ̀ sáyẹ́ǹsì sí i, bẹ́ẹ̀ ló ṣe túbọ̀ ń hàn sí mi pé ẹ̀kọ́ ẹfolúṣọ̀n ò lẹ́sẹ̀ ńlẹ̀. Bí àpẹẹrẹ, mo ronú nípa bí ayé, oòrùn, òṣùpá àtàwọn ìràwọ̀ ṣe wà lójú ibi tó yẹ kí wọ́n wà gẹ́lẹ́, tí wọ́n sì wà létòlétò, bí ẹ̀dá èèyàn ṣe ṣàrà ọ̀tọ̀, títí kan bó ṣe máa ń wù wá láti mọ irú ẹni tá a jẹ́, bá a ṣe dáyé àti ohun tó máa ṣẹlẹ̀ lọ́jọ́ ọ̀la. Àwọn tó ṣagbátẹrù ẹ̀kọ́ ẹfolúṣọ̀n ti gbìyànjú láti fi àwọn ohun tó ń ṣẹlẹ̀ sí ẹranko ṣàlàyé àwọn nǹkan yìí, àmọ́ wọn ò lè ṣàlàyé ìdí tí èèyàn fi yàtọ̀ sí ẹranko. Lójú tèmi, ó rọrùn láti gbà pé Ẹlẹ́dàá kan wà ju kéèyàn gbà ẹ̀kọ́ ẹfolúṣọ̀n gbọ́.”​—Anthony.

 Bí mo ṣe lè ṣàlàyé ohun tí mo gbà gbọ́

 Táwọn ọmọ kíláàsì rẹ bá ń fi ọ́ ṣe yẹ̀yẹ́ torí pé o gba ohun tó ò lè rí gbọ́ ńkọ́? Tàbí kí lo máa sọ tí wọ́n bá ní ìmọ̀ sáyẹ́ǹsì ti fìdí ẹ̀kọ́ ẹfolúṣọ̀n múlẹ̀?

 Lákọ̀ọ́kọ́, jẹ́ kí ohun tó o gbà gbọ́ dá ẹ lọ́jú. Má ṣe jẹ́ kí wọ́n kó ẹ láyà jẹ, má sì tijú. (Róòmù 1:​16) Rántí pé:

  1.   Ìwọ nìkan kọ́ lo gbà pé Ọlọ́run wà, ọ̀pọ̀ èèyàn ló ṣì gbà bẹ́ẹ̀. Kódà àwọn kan tí òye wọn jinlẹ̀, tí wọ́n sì ní ìmọ̀ ìwé wà lára wọn. Bí àpẹẹrẹ, àwọn onímọ̀ sáyẹ́ǹsì kan gbà pé Ọlọ́run wà.

  2.   Nígbà míì táwọn èèyàn kan bá sọ pé àwọn ò gbà pé Ọlọ́run wà, ohun tí wọ́n ní lọ́kàn ni pé àwọn ò rí ohun tó wà fún. Dípò kí wọ́n fi ẹ̀rí ti ohun tí wọ́n gbà gbọ́ lẹ́yìn, ṣe ni wọ́n máa ń ṣe lámèyítọ́ pé, “Tó bá jẹ́ pé Ọlọ́run wà, kí ló dé tó fi gbà kí ìyà máa jẹ wá?” Nípa bẹ́ẹ̀, dípò kí wọ́n sọ̀rọ̀ síbi tọ́rọ̀ wà, bí nǹkan ṣe rí lára wọn ni wọ́n á máa sọ.

  3.   Ó máa ń wu àwa èèyàn láti sin Ọlọ́run. (Mátíù 5:3) Èyí ló fà á tó fi yẹ ká gbà pé Ọlọ́run wà. Torí náà, tí ẹnì kan bá sọ pé kò sí Ọlọ́run, òun fúnra rẹ̀ ló máa ṣàlàyé ìdí tó fi gbà bẹ́ẹ̀, kì í ṣe ìwọ.​— Róòmù 1:​18-​20.

  4.   Ó bọ́gbọ́n mu láti gbà pé Ọlọ́run wà. Èyí bá òtítọ́ tí wọ́n ti fìdí rẹ̀ múlẹ̀ mu pé kò sí ohun alààyè kankan tó kàn ṣàdédé wà. Kò sì sí ẹ̀rí kankan tó fi hàn pé ara àwọn ohun tí kò lẹ́mìí ni ohun alààyè ti wá.

 Kí lo máa wá sọ tẹ́nì kan bá sọ pé ìgbàgbọ́ tó o ní pé Ọlọ́run wà kò lẹ́sẹ̀ nílẹ̀? Wo ohun to ṣeé ṣe káwọn kan sọ.

 Tẹ́nì kan bá sọ pé: “Àwọn tí ò kàwé nìkan ló gbà pé Ọlọ́run wà.”

 O lè sọ pé: “Ṣé o gbà pé bẹ́ẹ̀ lọ̀rọ̀ rí lóòótọ́? Èmi ò gbà bẹ́ẹ̀. Kódà, nígbà tí wọ́n bi èyí tó ju ẹgbẹ̀jọ [1,600] lára àwọn ọ̀jọ̀gbọ́n nínú ìmọ̀ sáyẹ́ǹsì tó wà láwọn yunifásítì tó lórúkọ nípa ohun tí wọ́n gbà gbọ́, ìdá mẹ́ta wọn ló gbà pé Ọlọ́run wà. a Ṣé wà á wá sọ pé àwọn ọ̀jọ̀gbọ́n yìí ò ní làákàyè torí pé wọ́n gbà pé Ọlọ́run wà?”

 Tẹ́nì kan bá sọ pé: “Tó bá jẹ́ pé Ọlọ́run wà, kí ló dé tí ìyà tó pọ̀ báyìí fi ń jẹ wá?”

 O lè sọ pé: “Ṣé ohun tó o ní lọ́kàn ni pé ohun tí Ọlọ́run ń ṣe sí ìyà tó ń jẹ wá kò yé ẹ ni àbí ṣe lo rò pé kò rí nǹkan kan ṣe sí i? [Jẹ́ kó fèsì.] Mo ti rí àlàyé tó kún rẹ́rẹ́ nípa ohun tó fà á tí ìyà fi pọ̀ láyé tó báyìí. Àmọ́, kéèyàn tó lè lóye ọ̀rọ̀ náà dáadáa, ó gba pé kó mọ àwọn ẹ̀kọ́ bíi mélòó kan nínú Bíbélì. Ṣé wàá fẹ́ mọ̀ sí i?”

 Àpilẹ̀kọ tó kàn máa jẹ́ ká rí ìdí tí ẹ̀kọ́ ẹfolúṣọ̀n fi lè ṣàlàyé bí a ṣe dé ayé lọ́nà tó ń tẹ́ni lọ́rùn.

a Orísun: Ìwé “Religion and Spirituality Among University Scientists,” láti ọwọ́ Elaine Howard Ecklund. Ẹgbẹ́ Social Science Research Council ló tẹ̀ ẹ́ jáde ní February 5, ọdún 2007.