Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

ÀWỌN Ọ̀DỌ́ BÉÈRÈ PÉ

Ṣó Dáa Kéèyàn Máa Ṣe Ohun Tó Pọ̀ Lẹ́ẹ̀kan Náà

Ṣó Dáa Kéèyàn Máa Ṣe Ohun Tó Pọ̀ Lẹ́ẹ̀kan Náà

 Ṣé o lè ṣe ohun tó pọ̀ lẹ́ẹ̀kan náà?

 Ṣé o lè ṣe ohun tó pọ̀ lẹ́ẹ̀kan náà? Ọ̀pọ̀ rò pé àwọn ọ̀dọ́ ní òye tó pọ̀ nípa ìmọ̀ ẹ̀rọ, wọ́n sì lè ṣe ohun tó pọ̀ lẹ́ẹ̀kan náà ju àwọn àgbàlagbà tó ṣẹ̀ṣẹ̀ ń kọ́ bí wọ́n ṣe ń lo àwọn ẹ̀rọ ìgbàlódé lọ. Àmọ́ ṣé òótọ́ ni?

 ÒÓTỌ́ tàbí IRỌ́?

  •   Tó o bá ń ṣe ohun tó pọ̀ lẹ́ẹ̀kan náà, o ò ní fi àkókò ṣòfò.

  •   Tó o bá fi kọ́ra, o lè mọ béèyàn ṣe ń ṣe ohun tó pọ̀ lẹ́ẹ̀kan náà.

  •   Àwọn ọ̀dọ́ lè ṣe ohun tó pọ̀ lẹ́ẹ̀kan náà ju àwọn àgbàlagbà lọ.

 Tó o bá sọ pé “òótọ́” ni ọ̀kọ̀ọ̀kan àwọn gbólóhùn yìí, ó ṣeé ṣe kíwọ náà ti gba àwọn “ìtàn àròsọ nípa béèyàn ṣe ń ṣe ọ̀pọ̀ nǹkan lẹ́ẹ̀kan náà” gbọ́.

 Ìtàn àròsọ nípa béèyàn ṣe ń ṣe ọ̀pọ̀ nǹkan lẹ́ẹ̀kan náà

 Ṣé o rò pé o lè ṣe nǹkan méjì lẹ́ẹ̀kan náà? Ó ṣeé ṣe kó o lè ṣe nǹkan méjì lẹ́ẹ̀kan náà tí ọ̀kan lára ohun tí ò ń ṣe kò bá nílò àfiyèsí tó pọ̀. Bí àpẹẹrẹ, tó o bá ń gbọ́ orin bó o ṣe ń tún yàrá ẹ ṣe, ó ṣeé ṣe kí yàrá ẹ mọ́ bó o ṣe fẹ́.

 Àmọ́ tó o bá ń ṣe iṣẹ́ méjì pọ̀ tí ọ̀kọ̀ọ̀kan wọn sì gba pé kó o pọkàn pọ̀, ó ṣeé ṣe kó o má lè ṣe àwọn méjèèjì dáadáa. Obìnrin kan tó ń jẹ́ Katherine sọ pé kéèyàn máa ṣe ohun tó pọ̀ lẹ́ẹ̀kan náà túmọ̀ sí pé: “Kéèyàn ba gbogbo nǹkan jẹ́ lẹ́ẹ̀kan náà.”

 “Bí mo ṣe ń bá ẹnì kan sọ̀rọ̀ lọ́wọ́ ni mo gba àtẹ̀jíṣẹ́ kan tí mo gbọ́dọ̀ fèsì. Mo gbìyànjú láti ṣe méjèèjì lẹ́ẹ̀kan náà. Ohun tó ṣẹlẹ̀ ni pé mi ò gbọ́ gbogbo ohun tẹ́ni náà ń sọ, mi ò sì kọ gbogbo ọ̀rọ̀ tí mo fẹ́ fi ránṣẹ́ náà dáadáa.”​—Caleb.

 Sherry Turkle tó jẹ́ ọ̀jọ̀gbọ́n nípa ìmọ̀ ẹ̀rọ sọ pé: “Tá a bá rò pé a lè ṣe ohun tó pọ̀ lẹ́ẹ̀kan náà, . . . a ò ní lè pọkàn pọ̀ sórí gbogbo iṣẹ́ náà lẹ́yọ kọ̀ọ̀kan, a ò sì ní lè ṣe é yanjú. Tá a bá ń ṣe ohun tó pọ̀ lẹ́ẹ̀kan náà, ṣe ló máa ń jí ọpọlọ wa sílẹ̀, àá sì máa ronú pé à ń ṣiṣẹ́ náà dáadáa láìmọ̀ pé ṣe ló ń burú sí i.” a

 “Lọ́pọ̀ ìgbà, mo máa ń rò pé mo lè máa fọ̀rọ̀ ránṣẹ́ kí n sì máa bá ẹlòmíì sọ̀rọ̀ lẹ́ẹ̀kan náà. Àfìgbà tí mo sọ̀rọ̀ tó yẹ kí n fi ránṣẹ́ fún ẹni tí mò ń bá sọ̀rọ̀, mo sì fi ọ̀rọ̀ tó yẹ kí n sọ ránṣẹ́ lórí fóònù!”​—Tamara.

 Àwọn tó máa ń ṣe ohun tó pọ̀ lẹ́ẹ̀kan náà máa ń mú kí nǹkan nira fún ara wọn ju bó ṣe yẹ lọ. Bí àpẹẹrẹ, ó máa ń gbà wọ́n ní ọ̀pọ̀ àkókò kí wọ́n tó parí iṣẹ́ àṣetiléwá wọn. Nígbà míì, wọ́n lè rò pé àwọn ti ṣe iṣẹ́ àṣetiléwá àwọn tán, kí wọ́n ṣẹ̀ṣẹ̀ wá rí i pé àfi káwọn tún un ṣe. Ohun tó máa ń ṣẹlẹ̀ ni pé àkókò tó máa ń ṣẹ́ kù fáwọn tó ń ṣe ọ̀pọ̀ nǹkan lẹ́ẹ̀kan náà kì í tó nǹkan torí lọ́pọ̀ ìgbà, ó máa ń gba pé kí wọ́n tún nǹkan náà ṣe.

 Ìdí nìyẹn tí Thomas Kersting tó jẹ́ olùtọ́jú àrùn ọpọlọ àti agbaninímọ̀ràn nílé ẹ̀kọ́ fi sọ pé: “Tá a bá fi ọpọlọ èèyàn wé àpótí ìkówèésí, ńṣe ni ọpọlọ ẹni tó ń ṣe ọ̀pọ̀ nǹkan lẹ́ẹ̀kan náà dà bí àpótí ìkówèésí tó dọ̀tí tó sì rí wúruwùru.” b

 “Tó o bá ń ṣe ọ̀pọ̀ nǹkan lẹ́ẹ̀kan náà, wàá máa gbójú fo àwọn ìsọfúnni tó ṣe pàtàkì. Ó ṣeé ṣe kíyẹn mú kó o ṣiṣẹ́ kára ju bó ti yẹ lọ kó o sì máa fàkókò tó o rò pé ó máa fi pa mọ́ ṣòfò.”​—Teresa.

Kéèyàn máa ṣe ohun tó pọ̀ lẹ́ẹ̀kan náà dà bí ìgbà téèyàn ń wa ọkọ̀ lójú ọ̀nà méjì lẹ́ẹ̀kan náà

 Ọ̀nà tó dáa jù

  •   Kọ́ bí wàá ṣe máa pọkàn pọ̀ sórí iṣẹ́ kan ṣoṣo lẹ́ẹ̀kan náà. Ìyẹn lè má rọrùn tó bá jẹ́ pé ó ti mọ́ ẹ lára láti máa ṣe ọ̀pọ̀ nǹkan lẹ́ẹ̀kan náà, bíi kó o máa kàwé kó o sì tún máa fọ̀rọ̀ ránṣẹ́ lórí fóònù. Àmọ́ Bíbélì sọ pé ká “máa wádìí dájú àwọn ohun tó ṣe pàtàkì jù.” (Fílípì 1:10) Kì í ṣe gbogbo iṣẹ́ tá à ń ṣe ló ṣe pàtàkì bákan náà. Torí náà, pinnu èyí tó ṣe pàtàkì jù, kó o sì pọkàn pọ̀ sórí ẹ̀ títí tó o fi máa parí ẹ̀.

     “A lè fi ọkàn tí kò pa pọ̀ wé ọmọdé tó fẹ́ràn kó máa ṣe ohun tó wù ú. Ó lè ṣe wá bíi pé ká fi í sílẹ̀ kó máa ṣe bó ti fẹ́, síbẹ̀ ó ṣe pàtàkì pé ká dá a lẹ́kun nígbà míì.”​—Maria.

  •   Má fàyè gba ohun tó lè pín ọkàn ẹ níyà. Tó o bá ń kàwé, ṣó máa ń ṣe ẹ́ bíi pé kó o máa tẹ fóònù ẹ? Tó bá rí bẹ́ẹ̀, lọ fi sí yàrá míì. Pa tẹlifíṣọ̀n, má sì ronú ohunkóhun nípa ìkànnì àjọlò! Bíbélì sọ pé: “Ẹ má ṣe jẹ́ kí àkókò kan kọjá láìjẹ́ pé ẹ lò ó bí ó ti yẹ.”​—Kólósè 4:​5, Bibeli Ìròyìn Ayọ̀.

     “Mo ti kíyè sí i pé ohun tó dáa jù ni kí n máa pọkàn pọ̀ sórí ohun kan ṣoṣo lẹ́ẹ̀kan náà. Inú mi máa ń dùn tí mo bá parí ohun kan tẹ̀ lé òmíì bó ṣe wà nínú àkọsílẹ̀ àwọn ohun tí mo fẹ́ ṣe. Kí n sòótọ́, ó máa ń tẹ́ mi lọ́rùn gan-an.”​—Onya.

  •   Má ṣe jẹ́ kí ohunkóhun gbà ẹ́ lọ́kàn tí ìwọ àti ẹnì kan bá ń sọ̀rọ̀. Ìwà àfojúdi ni tó o bá ń wo fóònù rẹ nígbà tí ìwọ àti ẹnì kan jọ ń sọ̀rọ̀, irú ìjíròrò bẹ́ẹ̀ kì í sì í yọrí sí rere. Bíbélì sọ pé ohun tá a fẹ́ kí àwọn èèyàn ṣe sí wa ni káwa náà máa ṣe sí wọn.​—Mátíù 7:12.

     “Nígbà míì tí mo bá ń bá àbúrò mi sọ̀rọ̀, ṣe ló máa ń fọ̀rọ̀ ránṣẹ́ lórí fóònù tàbí kó máa ṣe nǹkan míì lórí fóònù rẹ̀. Inú máa ń bí mi gan-an! Àmọ́, òótọ́ ibẹ̀ ni pé, èmi náà máa ń ṣe bẹ́ẹ̀ lẹ́ẹ̀kọ̀ọ̀kan!”​—David.

a Látinú ìwé Reclaiming Conversation.

b Látinú ìwé Disconnected.