Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

ÀWỌN Ọ̀DỌ́ BÉÈRÈ PÉ

Báwo Ni Mo Ṣe Lè Máa Jẹ Oúnjẹ Tó Ṣara Lóore?

Báwo Ni Mo Ṣe Lè Máa Jẹ Oúnjẹ Tó Ṣara Lóore?

 Ìwọ náà mọ̀ pé oúnjẹ tí kò ṣara lóore máa ń ṣàkóbá fún ìlera èèyàn. Àwọn tí oúnjẹ tí kò ṣara lóore bá mọ́ lára nígbà tí wọ́n wà lọ́dọ̀ọ́ máa ń bá a lọ títí wọ́n á fi dàgbà, torí náà, àti ìsìnyí ni kó o ti jẹ́ kó mọ́ ẹ lára láti máa jẹ oúnjẹ tó ṣara lóore.

 Irú oúnjẹ wo ló ń ṣara lóore?

 Bíbélì sọ fún wa pé ká “má ṣe jẹ́ aláṣejù,” èyí sì kan bí a ṣe ń jẹun. (1 Tímótì 3:11) Tá a bá fi ìlànà Bíbélì yìí sọ́kàn, a máa rí i pé . . .

  •   Oríṣiríṣi oúnjẹ ló máa ń ṣara lóore. Irú bíi wàrà, bọ́tà tàbí àwọn oúnjẹ tó ní èròjà purotéènì, èso, ewébẹ̀ àti oríṣiríṣi ọkà. Ọ̀pọ̀ èèyàn kì í jẹ àwọn oúnjẹ yìí torí wọ́n rò pé ó máa mú káwọn sanra. Ṣùgbọ́n, téèyàn ò bá jẹ àwọn oúnjẹ yìí, ó lè ṣàkóbá fún ara ẹ̀.

     Gbìyànjú ẹ̀ wò: Tó o bá fẹ́ mọ̀ nípa àwọn oúnjẹ tó ní èròjà tó ń ṣara lóore, wádìí tàbí kó o lọ rí dọ́kítà rẹ. Bí àpẹẹrẹ:

     Èròjà Carbohydrate máa ń fún ara lókun. Èròjà purotéènì máa ń dènà àrùn, ó sì máa ń jẹ́ káwọn sẹ́ẹ̀lì ara wa ṣiṣẹ́ dáadáa. Tí ọ̀rá kò bá pọ̀ jù lára, ó máa ń dènà àrùn ọkàn, èyí á sì jẹ́ kára wa dá ṣáṣá.

     Mo máa ń gbìyànjú láti jẹ oúnjẹ tó ṣara lóore. Mi ò rò pé ó burú téèyàn bá ń jẹ nǹkan dídùn bíi súìtì lẹ́ẹ̀kọ̀ọ̀kan. Àmọ́, á dáa ká máa jẹ oúnjẹ tó ṣara lóore. Ká sì máa wà ní ìwọ̀ntún-wọ̀nsì.”—Brenda.

    Tí óunjẹ ò bá ní àwọn èròjà tó dáa nínú, ó dà bí àga tí ẹsẹ̀ ẹ̀ kan ti kán

  •   Oúnjẹ tó ṣara lóore kì í ṣàkóbá fún ara. Téèyàn ò bá jẹun kánú tàbí tí kò jẹun nígbà tó yẹ, tó wá jẹ oúnjẹ púpọ̀ nígbà tí ebi ń pa á tàbí téèyàn ò bá kìí jẹ nǹkan tó fẹ́ràn lẹ́ẹ̀kọ̀ọ̀kan, ó lè ṣàkóbá fún ara.

     Gbìyànjú ẹ̀ wò: Kíyè sí oúnjẹ tó ò ń jẹ fún odindi oṣù kan. Ìgbà mélòó lo jẹ oúnjẹ tí kò ṣara lóore? Àwọn nǹkan wo lo lè ṣe kó o lè máa jẹ oúnjẹ tó ṣara lóore?

     Tẹ́lẹ̀, ó lásìkò tí mo máa ń jẹ ounjẹ tó lè mú kéèyàn sanra àti ìgbà tí mo máa ń jẹ oúnjẹ tí kì í mú kéèyàn sanra. Àmọ́ nígbà tó yá, mi ò ṣe bẹ́ẹ̀ mọ́, mo wá pinnu pé mi ò ní jẹ àjẹjù, mi ò sì ní jẹun tí mo bá ti yó. Ó ṣe díẹ̀ kó tó mọ́ mi lára, àmọ́ ní báyìí, mo ti ń jẹ oúnjẹ tó ṣara lóore.”—Hailey

 Báwo ni mo ṣe lè máa jẹ oúnjẹ tó ṣara lóore déédéé?

  •   Ronú ṣáájú. Bíbélì sọ pé: “Àwọn ohun tí òṣìṣẹ́ kára gbèrò láti ṣe máa ń yọrí sí rere.” (Òwe 21:5) Tó o bá fẹ́ máa jẹ oúnjẹ tó ṣara lóore, ronú nípa ẹ̀ dáadáa.

     Ó máa ń gba ìsapá kéèyàn tó lè jẹ oúnjẹ tó ṣara lóore, àmọ́ oúnjẹ tá a bá sè nílé ló dáa jù. Kò rọrùn ṣùgbọ́n ó máa ṣe wá láǹfààní, ó tún máa jẹ́ ká ṣọ́wó ná.”—Thomas

  •   Pinnu oúnjẹ tó ṣara lóore tí wàá máa jẹ. Bíbélì sọ pe: “Má ṣe jẹ́ kí ọgbọ́n tó gbéṣẹ́ . . . bọ́ mọ́ ọ lọ́wọ́.” (Òwe 3:21) Ọgbọ́n tó gbéṣẹ́ máa ràn ẹ́ lọ́wọ́ láti ṣe ìpinnu tó dáa kó o lè mọ àwọn oúnjẹ tó ṣara lóore tí wàá máa jẹ.

     Lójoojúmọ́, mo máa ń fi oúnjẹ tó ṣara lóore rọ́pò èyí tí kò ṣara lóore. Bí àpẹẹrẹ, dípò kí n jẹ súìtì, mo máa ń jẹ ápù. Kò pẹ́ tí mo fi bẹ̀rẹ̀ sí í jẹ oúnjẹ tó ṣara lóore!”Kia.

  •   Ní àfojúsùn tó bọ́gbọ́n mu. Bíbélì sọ pé: “Máa fi ayọ̀ jẹ oúnjẹ rẹ.” (Oníwàásù 9:7) Ti pé ò ń jẹ oúnjẹ tó ṣara lóore ò túmọ̀ sí pé o ò ní lè jẹ àwọn oúnjẹ tó o fẹ́ràn tàbí kó o máa dààmú ní gbogbo ìgbà tó o bá fẹ́ jẹun. Tó ò bá tiẹ̀ fẹ́ sanra, rántí pé ohun tó ṣe pàtàkì jù ni bó o ṣe máa ní ìlera tó dáa. Ní àfojúsùn tó bọ́gbọ́n mu nípa oúnjẹ tó ṣara lóore.

     “Lẹ́nu àìpẹ́ yìí, mo sapá láti dín bí mo ṣe sanra kù, àmọ́ ní gbogbo ìgbà yẹn, mi ò fi ebi pa ara mi, mi ò sá fún àwọn oúnjẹ kan tàbí kí n bínú síra mi torí pé mo jẹ súìtì. Mo mọ̀ pé ó máa gba ìsapá tí mi ò bá fẹ́ sanra jù àmọ́ ìsapá náà tó bẹ́ẹ̀, ó jù bẹ́ẹ̀ lọ.”—Melanie.