Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

ÀWỌN Ọ̀DỌ́ BÉÈRÈ PÉ

Ṣé Mo Lè Yan Orin Tó Bá Ṣáà Ti Wù Mí?

Ṣé Mo Lè Yan Orin Tó Bá Ṣáà Ti Wù Mí?

 “Tí n bá ti fẹ́ bẹ̀rẹ̀ ìgbòkègbodò mi láàárọ̀, mo máa ń gbọ́ orin. Tí n bá wọnú ọ̀kọ̀, mo máa ń gbọ́ orin. Kódà tí n bá wà nílé tí mò ń sinmi, tí mò ń tún ilé ṣe tàbí kàwé, orin ni mo máa ń gbọ́. Gbogbo ìgbà ni mo máa ń gbọ́ orin.”​—Carla.

 Ṣé bí Carla ṣe fẹ́ràn orin gan-an ni ìwọ náà ṣe fẹ́ràn ẹ̀? Tó bá rí bẹ́ẹ̀, àpilẹ̀kọ yìí máa ràn ẹ́ lọ́wọ́ láti mọ àwọn àǹfààní tó wà nínú gbígbọ́ orin, bó o ṣe lè yẹra fún ewu tó wà níbẹ̀ àti bó o ṣe lè fọgbọ́n yan irú orin tí wàá máa gbọ́.

 Àwọn àǹfààní tó wà níbẹ̀

 Kéèyàn máa gbọ́ orin dà bí ìgbà tí èèyàn ń jẹun. Bóyá èèyàn ń gbọ́ orin tàbí ó ń jẹun, ohun tó dáa jù ni pé kéèyàn ṣe èyí tó dáa, kó sì jẹ́ ní ìwọ̀ntúnwọ̀nsì. Àwọn àǹfààní tó wà nínú orin rèé:

  •   Orin lè múnú ẹ dùn.

     “Lọ́jọ́ tí inú mi ò bá dùn, tí mo bá ti gbọ́ orin tí mo fẹ́ràn, ńṣe ni ara mi á yá gágá lójú ẹsẹ̀.”​—Mark.

  •   Orin lè jẹ́ kó o rántí àwọn ohun tó ti ṣẹlẹ̀ sẹ́yìn.

     “Lọ́pọ̀ ìgbà, tí n bá ti gbọ́ àwọn orin kan, ó máa ń jẹ́ kí n rántí àwọn ohun tó ṣẹlẹ̀ nígbà kan, inú mi sì máa ń dùn pé mo gbọ́ irú orin bẹ́ẹ̀.”​—Sheila.

  •   Orin máa ń jẹ́ kí ìṣọ̀kan àwa àtàwọn ẹlòmíì lágbára.

     “Bí mo ṣe ń gbọ́ táwọn àlejò tó wá sí àpéjọ àgbáyé àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà ń kọrin ìparí ní àpéjọ náà, ńṣe ni orí mi wú tí omijé sì ń bọ́ lójú mi. Èdè wa yàtọ̀ síra lóòótọ́, àmọ́ orin tá a jọ kọ yẹn mú ká wà níṣọ̀kan.”​—Tammy.

  •   Orin lè jẹ́ kó o ní àwọn ànímọ́ tó ṣeyebíye.

     “Tó o bá ń kọ́ bí wọ́n ṣe ń lo ohun èlò orin kan, o lè wá di ẹni tó ń fara balẹ̀ ṣe nǹkan, tó sì ní sùúrù. Torí pé díẹ̀díẹ̀ ni wàá mọ ohun èlò orin yẹn lò. Bó o bá ṣe ń fi ohun èlò orin náà dánra wò ni wàá máa mọ̀ ọ́n lò.”​—Anna.

 Ǹjẹ́ o mọ̀? Ìwé Sáàmù ló gùn jù lọ nínú àwọn ìwé tó wà nínú Bíbélì, àádọ́jọ orin [150] ló sì wà nínú ẹ̀.

Bó o ṣe máa ń fọgbọ́n yan irú oúnjẹ tí wàá jẹ ni kó o máa fọgbọ́n yan irú orin tí wàá máa gbọ́

 Àwọn ewu tó wà níbẹ̀

 Àwọn orin kan dà bí oúnjẹ tí wọ́n da májèlé sí, ó lè pa èèyàn. Jẹ́ ká wo ìdí tó fi rí bẹ́ẹ̀.

  •   Àwọn orin kan ní ọ̀rọ̀ ìṣekúṣe nínú.

     “Ó jọ pé gbogbo àwọn orin tó gbajúmọ̀ ló dá lórí ìṣekúṣe. Àwọn èèyàn ò tiẹ̀ fi bò mọ́.”​—Hannah.

     Bíbélì sọ pé: “Kí a má tilẹ̀ mẹ́nu kan àgbèrè àti ìwà àìmọ́ onírúurú gbogbo tàbí ìwà ìwọra láàárín yín.” (Éfésù 5:3) Bi ara rẹ pé, ‘Ṣé irú orin tí mò ń gbọ́ fi hàn pé mò ń tẹ̀ lé ìmọ̀ràn yìí?’

  •   Àwọn orin kan lè kó ìbànújẹ́ bá ẹ.

     “Nígbà míì tí oorun bá dá lójú mi lóru, mo máa ń tẹ́tí sí àwọn orin tó máa ń jẹ́ kí n ronú nípa àwọn nǹkan tó lè bà mí lọ́kàn jẹ́. Orin burúkú máa ń gbé èròkerò sọ́kàn mi.”​—Tammy.

     Bíbélì sọ pé: “Ju gbogbo ohun mìíràn tí a ní láti ṣọ́, fi ìṣọ́ ṣọ́ ọkàn-àyà rẹ.” (Òwe 4:​23) Bi ara rẹ pé, ‘Ṣé irú orin tí mò ń gbọ́ máa ń gbé èròkerò sí mi lọ́kàn?’

  •   Àwọn orin kan lè sọ ẹ́ di oníbìínú èèyàn.

     “Ewu tí mi ò tètè fura sí ni àwọn orin tó jẹ́ kí inú máa bí mi àti èyí tó jẹ́ kí n máa kórìíra ara mi. Mo rí i pé inú mi kì í dùn tí n bá ti gbọ́ irú àwọn orin bẹ́ẹ̀ tán. Àwọn ara ilé mi pàápàá kíyè sí i bẹ́ẹ̀.”​—John.

     Bíbélì sọ pé: “Ẹ mú gbogbo wọn kúrò lọ́dọ̀ yín, ìrunú, ìbínú, ìwà búburú, ọ̀rọ̀ èébú, àti ọ̀rọ̀ rírùn kúrò lẹ́nu yín.” (Kólósè 3:8) Bi ara rẹ pé, ‘Ṣé orin tí mò ń gbọ́ ti jẹ́ kí n di onínú fùfù tàbí ẹni tó burú gan-an sí àwọn èèyàn?’

 Kí ló yẹ kó o fi sọ́kàn? Máa fọgbọ́n yan irú orín tí wàá máa gbọ́. Ohun tí ọ̀dọ́bìnrin kan tó ń jẹ́ Julie ṣe nìyẹn, ó sọ pé: “Gbogbo ìgbà ni mo máa ń ṣàyẹ̀wò àwọn orin tí mò ń gbọ́, tí n bá ti rí èyí tí ò dáa nínú wọn, ńṣe ni màá yọ ọ́ dànù. Lóòótọ́ kò rọrùn, àmọ́ mo mọ̀ pé ohun tó yẹ kí n ṣe nìyẹn.”

 Ọ̀dọ́bìnrin kan tó ń jẹ́ Tara náà ti ń ṣe bíi ti Julie. Ó sọ pé: “Nígbà míì, wọ́n máa gbé orin tó ní àwọn àlùjó tó dùn gan-an sáfẹ́fẹ́ lórí rédíò, àmọ́ tí n bá ti gbọ́ ọ̀rọ̀ orin náà tí mo sì rí i pé kò dáa, ńṣe ni màá tètè yí ìkànnì rédíò náà síbòmíì. Ohun tí mò ń ṣe yìí dà bí ìgbà tí mo tọ́ oyin wò tán tí mo wá dà á nù! Tí mo bá lè pinnu pé mi ò ní gbọ́ orin tó dá lórí ìṣekúṣe, kò ní ṣòro fún mi láti sá fún ṣíṣe ìṣekúṣe ṣáájú ìgbéyàwó. Mí ò fẹ́ máa ronú pé irú orin tí mò ń gbọ́ ò lè ní ipa búburú lórí mi.”