Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

ÀWỌN Ọ̀DỌ́ BÉÈRÈ PÉ

Ṣé Mo Lè Jẹ́jẹ̀ẹ́ Láti Má Ṣe Ní Ìbálòpọ̀ Ṣáájú Ìgbéyàwó?

Ṣé Mo Lè Jẹ́jẹ̀ẹ́ Láti Má Ṣe Ní Ìbálòpọ̀ Ṣáájú Ìgbéyàwó?

 Kí ni ẹ̀jẹ́ láti má ṣe ní ìbálópọ̀ ṣáájú ìgbéyàwó?

 Ẹ̀jẹ́ láti má ṣe ní ìbálòpọ̀ ni àkọ́sílẹ̀ tí àwọn kan ṣe pé àwọn kò ní ní ìbálòpọ̀ káwọn tó ṣègbéyàwó.

 Láti nǹkan bí ọdún 1990 làwọn èèyàn ti bẹ̀rẹ̀ sí í jẹ́ ẹ̀jẹ́ yìí nígbà tí Southern Baptist Convention ti orílẹ̀-èdè Amẹ́ríkà ṣe ìfilọ́lẹ̀ ètò kan tí wọ́n pè ní ‘Ìfẹ́ Tòótọ́ Máa Ń Ní Sùúrù.’ Wọ́n ṣètò yìí láti máa kọ́ àwọn ọ̀dọ́ láwọn ẹ̀kọ́ Bíbélì àtàwọn ìwà ọmọlúàbí tó yẹ kí wọ́n máa hù kí wọ́n lè fún wọn níṣìírí láti yẹra fún ìbálòpọ̀ ṣáájú ìgbéyàwó.

 Kò pẹ́ sígbà yẹn ni wọ́n dá ètò míì tó fara jọ èyí sílẹ̀. Nínú ètò yìí, wọ́n máa ń fún àwọn tó jẹ́jẹ̀ẹ́ náà ní òrùka fàdákà kan tó máa jẹ́ àmì (táá sì máa rán wọn létí) ẹ̀jẹ́ tí wọ́n jẹ́ pé àwọn máa yẹra fún ìbálòpọ̀ ṣáájú ìgbéyàwó.

 Ǹjẹ́ ẹ̀jẹ́ yìí gbéṣẹ́?

 Èrò táwọn èèyàn ní nípa ẹ̀jẹ́ yìí yàtọ̀ síra.

  •   Christine C. Kim àti Robert Rector, tí wọ́n jẹ́ olùṣèwádìí sọ pé “ìwádìí ti fi hàn pé, ẹ̀jẹ́ yìí ti mú kí ìṣekúṣe dín kù láàárín àwọn ọ̀dọ́.”

  •   Ìwádìí míì tí àjọ Guttmacher tẹ̀ jáde fi hàn pé “tó bá kan ọ̀rọ̀ lílọ́wọ́ sí ìwà ìṣekúṣe, kò sí ìyàtọ̀ láàárín àwọn tó jẹ́jẹ̀ẹ́ láti má ṣe ní ìbálòpọ̀ ṣáájú ìgbéyàwó àtàwọn tí kò jẹ́jẹ̀ẹ́.”

 Kí nìdí tí èrò àwọn èèyàn fi yàtọ̀?

  •   Ìwádìí kan ṣe ìfiwéra láàárín àwọn tó jẹ́jẹ̀ẹ́ àti àwọn tí kò jẹ́jẹ̀ẹ́ àmọ́ tí èrò wọn nípa ìbálòpọ̀ yàtọ̀ sí táwọn tó jẹ́jẹ̀ẹ́.

  •   Ìwádìí míì ṣe ìfiwéra láàárín àwọn tó jẹ́jẹ̀ẹ́ tí èrò wọn nípa ìbálòpọ̀ jọra pẹ̀lú tàwọn tí kò jẹ́jẹ̀ẹ́.

 Kí ni ìwádìí kejì yìí fi hàn? Dókítà kan tó ń jẹ́ Janet Rosenbaum tó jẹ́ ògbóǹkangí nínú ọ̀rọ̀ ìlera àwọn ọ̀dọ́ sọ pé, lẹ́yìn ọdún márùn-ún “kì í sí ìyàtọ̀ láàárín àwọn tó jẹ́jẹ̀ẹ́ àtàwọn tí kò jẹ́jẹ̀ẹ́ tó bá kan ọ̀rọ̀ níní ìbálòpọ̀.”

 Èrò tó tọ̀nà

 Ká sòótọ́, ohun tó dáa ni àwọn tó ṣètò ẹ̀jẹ́ yìí ní lọ́kàn. Àmọ́ ìṣòro tó wà níbẹ̀ ni pé ẹ̀jẹ́ náà kì í kọni ní ìwà rere tó máa mú kéèyàn yẹra fún ìṣekúṣe. Dókítà Rosenbaum sọ pé ọ̀pọ̀ àwọn tó jẹ́jẹ̀ẹ́ pé àwọn kò ní lájọṣepọ̀ ṣáájú ìgbéyàwó “kì í fi tọkàntara fara mọ́ ẹ̀jẹ́ náà.” Ó wá fi kún un pé, “ìpinnu tó tọkàn wá tẹ́nì kan ṣe ló ń mú kó yẹra fún ìṣekúṣe, kì í ṣe torí pé ẹnìkan dara pọ̀ mọ́ ètò tó ń mú kéèyàn jẹ́jẹ̀ẹ́.”

 Irú ìpinnu tó tọkàn wá bẹ́ẹ̀ ni Bíbélì rọ̀ wá pé ká ní, kì í ṣe pé kéèyàn kàn buwọ́ lu ìwé pé òun kò ní lájọṣepọ̀ ṣáájú ìgbéyàwó. Bíbélì sì ń ràn wá lọ́wọ́ ká lè “kọ́ agbára ìwòye [wa] láti fi ìyàtọ̀ sáàárín ohun tí ó tọ́ àti ohun tí kò tọ́.” (Hébérù 5:​14) Ó ṣe tán, kì í ṣe torí kéèyàn lè yẹra fún àrùn tàbí oyún nìkan ló ń mú ká yẹra fún ìbálòpọ̀ ṣáájú ìgbéyàwó, àmọ́ ó jẹ́ ọ̀nà tá à ń gbà fi hàn pé a bọ̀wọ̀ fún Ẹlẹ́dàá wa tó ṣètò ìgbéyàwó.​—Mátíù 5:​19; 19:​4-6.

 Àǹfààní wa làwọn ìlànà inú Bíbélì wà fún. (Aísáyà 48:17) Gbogbo èèyàn láìka ọjọ́ orí wọn lè pinnu látọkàn wá pé àwọn máa tẹ̀ lé òfin Ọlọ́run tó sọ pé ká “sá fún àgbèrè.” (1 Kọ́ríńtì 6:​18) Nígbà tí wọ́n bá wá ṣègbéyàwó, wọ́n á lè gbádùn ara wọn dáadáa láì kábàámọ̀, torí àbámọ̀ ló sábà máa gbẹ́yìn àwọn tó bá lọ́wọ́ sí ìbálòpọ̀ ṣáájú ìgbéyàwó.