Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

ÀWỌN Ọ̀DỌ́ BÉÈRÈ

Kí Ni Mo Lè Ṣe tí Òbí Mi Bá Ń Ṣàìsàn?

Kí Ni Mo Lè Ṣe tí Òbí Mi Bá Ń Ṣàìsàn?

 Ọ̀pọ̀ ọ̀dọ́ lara àwọn òbí wọn ṣì le, tí wọn ò sì tíì nílò ìtọ́jú, torí ó lè jẹ́ pé ó dẹ̀yìn ọ̀pọ̀lọpọ̀ ọdún tára àwọn òbí náà bá ti dara àgbà, kí àìsàn tó dé.

 Àmọ́ ká sọ pé ọ̀dọ́ ṣì ni ẹ́ tí dádì tàbí mọ́mì ẹ fi bẹ̀rẹ̀ sí í ṣàìsàn tó le ńkọ́? Wo ohun táwọn ọ̀dọ́ méjì tírú ẹ̀ ṣẹlẹ̀ sí sọ.

 Ohun tó ṣẹlẹ̀ sí Emmaline

 Àrùn kan tó ń jẹ́ Ehlers-Danlos syndrome (EDS) ń ṣe mọ́mì mi. Àwọn oríkèé ara, awọ ara àtàwọn òpó ẹ̀jẹ̀ inú ara ni àrùn yìí máa ń bà jẹ́, ó sì máa ń roni lára gan-an.

 Àìsàn yìí ò gbóògùn, ara mọ́mì ò sì yá rárá. Ṣe ló ń burú sí i láti ọdún mẹ́wàá sẹ́yìn. Kódà, ìgbà míì wà tí ẹ̀mí wọn fẹ́rẹ̀ẹ́ bọ́ torí pé ẹ̀jẹ̀ ara wọn lọlẹ̀ gan-an tàbí tí ìrora wọn dé góńgó débi pé ó ń ṣe wọ́n bíi kí wọ́n tiẹ̀ kú.

 Ẹlẹ́rìí Jèhófà ni èmi àtàwọn ará ilé mi, àwọn ará ìjọ wa sì dúró tì wá gan-an, wọn ò fi ìkankan nínú wa sílẹ̀! Bí àpẹẹrẹ, lẹ́nu àìpẹ́ yìí, ọmọbìnrin kan tó fẹ́rẹ̀ẹ́ tó mi lọ́jọ́ orí fi káàdì kan ránṣẹ́ sí ìdílé wa. Ó lóun fẹ́ jẹ́ ká mọ̀ pé òun nífẹ̀ẹ́ wa, ká sì jẹ́ kó dá wa lójú pé òun máa dúró tì wá. A ti dọ̀rẹ́ ara wa, ó sì ń múnú mi dùn!

 Ìrànlọ́wọ́ tí Bíbélì ń ṣe fún mi ò kéré. Bí àpẹẹrẹ, ọ̀kan lára ẹsẹ Ìwé Mímọ́ tí mo fẹ́ràn jù ni Sáàmù 34:18 tó sọ pé: “Jèhófà sún mọ́ àwọn oníròbìnújẹ́ ní ọkàn-àyà.” Òmíì ni Hébérù 13:6 tó sọ pé: “Jèhófà ni olùrànlọ́wọ́ mi; èmi kì yóò fòyà.”

 Ẹsẹ Ìwé Mímọ́ tí mo mẹ́nu bà ṣìkejì yẹn nítumọ̀ sí mi gan-an. Ohun tó máa ń dẹ́rù bà mí jù ni pé mọ́mì lè kú lọ́jọ́ kan. Mo nífẹ̀ẹ́ wọn gan-an, mo sì máa ń dúpẹ́ lójoojúmọ́ pé a ṣì jọ wà. Ẹsẹ Bíbélì yẹn jẹ́ kí n mọ̀ pé ohun yòówù kó ṣẹlẹ̀, Ọlọ́run máa dúró tì mí, torí náà, kò sídìí tó fi yẹ kí n máa bẹ̀rù.

 Nǹkan míì tún wà tó máa ń dẹ́rù bà mí. Ṣé ẹ rí i, tí obìnrin kan bá ní irú àrùn yìí, tó wá bímọ, ọmọ náà máa kó o lára ẹ̀. Ohun tó fà á tí mọ́mì mi fi ní àrùn yẹn nìyẹn, wọ́n kó o látara ìyá wọn. Ẹ sì ti mọ ohun tó túmọ̀ sí fún èmi náà, mo ti kó o lára mọ́mì. Àmọ́ Hébérù 13:6 fi dá mi lójú pé Jèhófà máa tún jẹ́ “olùrànlọ́wọ́ mi” lọ́tẹ̀ yìí.

 Ohun tí mò ń ṣe báyìí ni pé mo mọyì ohun tí mo ní lọ́wọ́lọ́wọ́, mi ò da ara mi láàmú nípa ohun tó ti ṣẹlẹ̀ kọjá, mi ò sì yọ ara mi lẹ́nu nípa ohun tó máa ṣẹlẹ̀. Ká sòótọ́, tí mo bá ń rántí àwọn ohun tí mọ́mì máa ń ṣe tẹ́lẹ̀ àmọ́ tí wọn ò lè ṣe mọ́ báyìí, ó máa ń bà mí nínú jẹ́. Àmọ́ Bíbélì sọ pé àwọn àdánwò tá à ń kojú jẹ́ “fún ìgbà díẹ̀,” ó sì “fúyẹ́” tá a bá fi wé ìgbà tá a máa wà láàyè títí láé, tá ò sì ní ṣàìsàn mọ́.​—2 Kọ́ríńtì 4:​17; Ìṣípayá 21:​1-4.

 Ronú nípa èyí: Kí ló ń jẹ́ kí Emmaline mọ́kàn, kó sì máa retí pé nǹkan ṣì máa dáa? Kí ló lè jẹ́ kí ìwọ náà mọ́kàn tí nǹkan bá nira fún ẹ, kó o sì máa retí pé nǹkan ṣì máa dáa?

 Ohun tó ṣẹlẹ̀ sí Emily

 Ìgbà tí mo wà nílé ẹ̀kọ́ girama ni ìṣesí dádì mi kọ́kọ́ yí pa dà bìrí, tí wọ́n bẹ̀rẹ̀ sí í soríkọ́. Àfi bíi pé kì í ṣe dádì tí mo mọ̀ tẹ́lẹ̀! Àtìgbà yẹn ni ìbànújẹ́ ti máa ń dorí dádì mi kodò, tí ẹ̀rù máa ń bà wọ́n láìnídìí, tí wọ́n á sì dédé máa kọ́kàn sókè. Ó ti tó ọdún mẹ́ẹ̀ẹ́dógún [15] báyìí tí wọ́n ti ń bá a yí. Ó máa ń dùn wọ́n gan-an pé àwọn ò láyọ̀, ìbànújẹ́ ni ṣáá, bẹ́ẹ̀ kò sóhun tó fà á, inú wọn kàn máa ń bà jẹ́ náà ni!

 Ẹlẹ́rìí Jèhófà ni wá, àwọn ará ìjọ wa sì dúró tì wá gbágbáágbá. Èèyàn dáadáa ni wọ́n, ọ̀rọ̀ wa sì yé wọn dáadáa. Ẹnikẹ́ni ò ṣe ohunkóhun rí tó máa jẹ́ kí dádì mi máa rò pé àwọn ò wúlò nínú ìjọ. Ohun tó ń ṣe dádì mi yìí ò rọrùn, àmọ́ wọ́n ń fara dà á, ìyẹn sì ti jẹ́ kí n túbọ̀ nífẹ̀ẹ́ wọn gan-an ju ti tẹ́lẹ̀ lọ.

 Mo rántí ìgbà tí àìsàn yìí ò tíì máa ṣe dádì, tí wọn kì í kọ́kàn sókè, tára ò máa ni wọ́n, mo rántí ìgbà tínú wọn ṣì máa ń dùn. Ọ̀rọ̀ wọn wá dà bí ẹni ń bá ẹni tí ò rí jà, ó máa ń ká mi lára gan-an kí n máa rí bí wọ́n ṣe ń jẹ̀rora lójoojúmọ́.

 Láìka gbogbo ìyẹn sí, dádì ń sapá gan-an kí wọ́n má bàa gbé e sára. Lẹ́nu àìpẹ́ yìí, nígbà tọ́rọ̀ náà dé góńgó, wọ́n pinnu pé àwọn á máa ka Bíbélì lójoojúmọ́, ì báà tiẹ̀ jẹ́ ẹsẹ mélòó kan. Ó sì ràn wọ́n lọ́wọ́ gan-an. Ohun kékeré lèèyàn máa pe ohun tí wọ́n ń ṣe yẹn, àmọ́ ohun tó ń gbẹ̀mí ẹni là ni. Ohun tí dádì ṣe lásìkò yẹn kí wọ́n lè fara dà á wú mi lórí gan-an.

 Ẹsẹ Ìwé Mímọ́ kan tí mo fẹ́ràn ni Nehemáyà 8:​10, tó sọ pé: “Ìdùnnú Jèhófà ni odi agbára yín.” Òótọ́ pọ́ńbélé lọ̀rọ̀ yẹn. Tí mo bá wà nípàdé, tí mo ń fetí sílẹ̀, tí mo sì ń lóhùn sí i, ó máa ń mú kí n láyọ̀ gan-an, ó sì máa ń tù mí nínú. Jálẹ̀ irú àwọn ọjọ́ yẹn, ṣe lára mi máa ń yá gágá. Mo ti kọ́ ọ lára dádì mi pé ohun yòówù ká máa bá fínra, Jèhófà kì í dá wa dáa. Ó máa dúró tì wá.

 Ronú nípa èyí: Báwo ni Emily ṣe ń ran dádì ẹ̀ lọ́wọ́ nígbà tí wọ́n ń ṣàìsàn? Ìrànlọ́wọ́ wo lo lè ṣe fún ẹni tó máa ń soríkọ́?