Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

ÀWỌN Ọ̀DỌ́ BÉÈRÈ PÉ

Ṣé Ẹ̀kọ́ Ẹfolúṣọ̀n Tọ̀nà àbí Ẹlẹ́dàá Kan Wà?​—Apá 4: Báwo Ni Mo Ṣe Lè Ṣàlàyé Ohun Tí Mo Gbà Gbọ́ Nípa Ìṣẹ̀dá?

Ṣé Ẹ̀kọ́ Ẹfolúṣọ̀n Tọ̀nà àbí Ẹlẹ́dàá Kan Wà?​—Apá 4: Báwo Ni Mo Ṣe Lè Ṣàlàyé Ohun Tí Mo Gbà Gbọ́ Nípa Ìṣẹ̀dá?

O gbà gbọ́ pé Ẹlẹ́dàá kan wà, àmọ́ o ò fẹ́ sọ bẹ́ẹ̀ lójú àwọn tí ẹ jọ wà níléèwé rẹ. Ó lè jẹ́ pé ẹ̀kọ́ ẹfolúṣọ̀n wà nínú àwọn ìwé tí wọ́n fi ń kọ́ yín ní kíláàsì, ẹ̀rù wá ń bà ẹ́ pé àwọn olùkọ́ àtàwọn ọmọ iléèwé rẹ lè máa fi ẹ́ ṣe yẹ̀yẹ́. Báwo lo ṣe lè fi ìgboyà sọ̀rọ̀, kó o sì ṣàlàyé ohun tó o gbà gbọ́ nípa ìṣẹ̀dá?

 O lè ṣe é!

 O lè máa rò ó pé: ‘Mi ò lè ṣàlàyé ọ̀rọ̀ nípa sáyẹ́ǹsì àti ẹfolúṣọ̀n dáadáa.’ Ọmọbìnrin kan tó ń jẹ́ Danielle ti ronú bẹ́ẹ̀ rí. Ó sọ pé: “Inú mi kì í dùn tí mo bá ti rántí pé ọ̀rọ̀ yẹn á mú kí n tako olùkọ́ mi àtàwọn ọmọ kíláàsì mi.” Diana náà gbà bẹ́ẹ̀, ó ní, “Tí wọ́n bá ti ń jiyàn lórí ọ̀rọ̀ yẹn, tí wọ́n ń fi sáyẹ́ǹsì ṣàlàyé ẹ̀, ṣe ni gbogbo ẹ̀ máa ń dàrú mọ́ mi lójú.”

 Ṣùgbọ́n mọ̀ pé, kó o bá wọn jiyàn kó o sì borí kọ́ ló ṣe pàtàkì. Ó sì yẹ kínú ẹ dùn pé kò dìgbà tó o bá tó di ọ̀gá nídìí ìmọ̀ sáyẹ́ǹsì kó o tó lè ṣàlàyé ìdí tí ìwọ fi rò pé ó bọ́gbọ́n mu ká gbà pẹ́ ẹnì kan ló dá gbogbo nǹkan tó wà láyé.

 Àbá: Ṣàlàyé ohun kan tó bọ́gbọ́n mu tí Bíbélì sọ nínú Hébérù 3:4: “Olúkúlùkù ilé ni a kọ́ láti ọwọ́ ẹnì kan, ṣùgbọ́n ẹni tí ó kọ́ ohun gbogbo ni Ọlọ́run.”

 Ọmọbìnrin kan tó ń jẹ́ Carol ṣàlàyé ohun tó rò nípa ìlànà inú ìwé Hébérù 3:4, ó ní: “Ká sọ pé o wà nínú aginjù kan. O ò pàdé ẹnì kankan, ó sì dájú pé kò séèyàn nítòsí. Bó o ṣe ń rìn lọ, o wolẹ̀, lo bá rí igi ìtayín kan. Kí lo máa parí èrò sí? Ohun tí ọ̀pọ̀ èèyàn máa sọ ni pé, ‘Ẹnì kan ti débí.’ Tá a bá gbà pé ọlọ́gbọ́n èèyàn kan ló ṣe igi ìtayín kékeré yẹn, kí ni ká wá sọ nípa àgbáyé yìí àti gbogbo ohun tó wà nínú rẹ̀!”

 Tẹ́nì kan bá sọ pé: “Tó bá jẹ́ pé ẹnì kan ló dá wa, ta ló wá dá Ẹni yẹn?”

 O lè dáhùn pé: “Torí pé a ò mọ gbogbo nǹkan nípa Ẹlẹ́dàá ò túmọ̀ sí pé kò sí Ẹlẹ́dàá. Bí àpẹẹrẹ, o lè má mọ nǹkan kan nípa ẹni tó ṣe fóònù rẹ, àmọ́ o ṣì gbà pé ẹnì kan ló ṣe é, àbí? [Jẹ́ kó fèsì.] Ọ̀pọ̀ nǹkan wà tí a lè mọ̀ nípa Ẹlẹ́dàá. Tó o bá fẹ́ mọ̀ nípa rẹ̀, inú mi á dùn láti sọ ohun tí mo ti kọ́ nípa rẹ̀ fún ẹ.”

 Múra sílẹ̀

 Bíbélì sọ pé kí o ‘wà ní ìmúratán nígbà gbogbo láti ṣe ìgbèjà níwájú olúkúlùkù ẹni tí ó bá fi dandan béèrè lọ́wọ́ rẹ ìdí fún ìrètí tí ń bẹ nínú rẹ, ṣùgbọ́n kí o máa ṣe bẹ́ẹ̀ pa pọ̀ pẹ̀lú inú tútù àti ọ̀wọ̀ jíjinlẹ̀.’ (1 Pétérù 3:​15) Torí náà, kíyè sí ohun méjì​—ohun tó o máa sọ àti bí o ṣe máa sọ ọ́.

  1.   Ohun tó o máa sọ. Ìfẹ́ tó o ní fún Ọlọ́run ṣe pàtàkì, ó sì lè mú kó o sọ fún àwọn ẹlòmíì nípa Ọlọ́run. Tó o bá kàn ń sọ fún wọn nípa bí o ṣe nífẹ̀ẹ́ Ọlọ́run tó, ìyẹn nìkan ò tó láti jẹ́ kí wọ́n gbà pé Ọlọ́run ló dá gbogbo nǹkan. Ó máa dáa kó o lo àwọn ohun kan tí Ọlọ́run dá bí àpẹẹrẹ láti ṣàlàyé ìdí tó fi bọ́gbọ́n mu ká gbà pé Ẹlẹ́dàá kan wà.

  2.   Bí o ṣe máa sọ ọ́. Jẹ́ kí ohun tó o fẹ́ sọ dá ẹ lójú, àmọ́ má sọ̀rọ̀ tí kò dáa sí ẹnikẹ́ni, má sì ṣe bíi pé o mọ̀ jù wọ́n lọ. Tí o kò bá bẹnu àtẹ́ lu ohun tí wọ́n gbà gbọ́, tó o sì gbà pé wọ́n lẹ́tọ̀ọ́ láti pinnu ohun tí wọ́n fẹ́ gbà gbọ́, ó ṣeé ṣe kí wọ́n ronú lórí ohun tó o sọ.

     “Ó ṣe pàtàkì kéèyàn má sọ̀rọ̀ burúkú sí wọn, kó má sì ṣe bíi pé òun mọ gbogbo nǹkan tán. Téèyàn bá ń sọ̀rọ̀ bíi pé òun mọ̀ jù wọ́n lọ, wọn ò ní gbọ́ ọ̀rọ̀ ẹ̀.”​—Elaine.

 Àwọn ohun tó lè ràn ẹ́ lọ́wọ́ kó o lè ṣàlàyé ohun tó o gbà gbọ́

Tó o bá múra sílẹ̀ kó o lè ṣàlàyé ohun tó o gbà gbọ́, ṣe ló máa dà bí ìgbà tó o múra dáadáa torí pé òjò lè rọ̀

 Alicia tó ti lé lọ́mọ ọdún mẹ́tàlá sọ pé: “Téèyàn ò bá múra sílẹ̀, ṣe ló máa rọra dákẹ́ táwọn míì bá ń sọ̀rọ̀ kí wọ́n má báa dójú tì í.” Bí Alicia ṣe sọ, ó yẹ kéèyàn múra sílẹ̀ tó bá fẹ́ ṣàṣeyọrí. Jenna sọ pé, “Tí mo bá fẹ́ ṣàlàyé ohun tí mo gbà gbọ́ nípa ìṣẹ̀dá, ohun tó lè mú kí n ṣàlàyé ẹ̀ dáadáa ni tí mo bá ti ronú nípa àpẹẹrẹ kan tó rọrùn tí mo lè lò láti fi ti ọ̀rọ̀ mi lẹ́yìn.”

 Ibo lo ti lè rí irú àwọn àpẹẹrẹ bẹ́ẹ̀? Àwọn ìtẹ̀jáde wọ̀nyí ti ran ọ̀pọ̀ ọ̀dọ́ lọ́wọ́ kí wọ́n lè ṣàṣeyọrí:

  •  Ìwé náà, Was Life Created?

  •  Ìwé náà, The Origin of Life​—Five Questions Worth Asking

  •  Fídíò náà, The Wonders of Creation Reveal God’s Glory

  •  Ọ̀wọ́ àpilẹ̀kọ tá a pè ní “Ta Ló Ṣiṣẹ́ Àrà Yìí?” nínú ìtẹ̀jáde Jí! (Tẹ “ta ló ṣiṣẹ́ àrà yìí” [fi àmì àyọkà sí i] síbi tí èèyàn ti lè wá ọ̀rọ̀ ní ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower.)

  •  Lo ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower láti ṣèwádìí sí i.

 O tún lè wo àwọn àpilẹ̀kọ tó ṣáájú nínú ọ̀wọ́ yìí, ìyẹn “Ṣé Ẹ̀kọ́ Ẹfolúṣọ̀n Tọ̀nà àbí Ẹlẹ́dàá Kan Wà?”

  1.  Apá 1: Kí Nìdí Tó Fi Yẹ Ká Gbà Pé Ọlọ́run Wà?

  2.  Apá 2: Ṣé Ó Yẹ Kó O Kàn Gbà Pé Òótọ́ ni Ẹ̀kọ́ Ẹfolúṣọ̀n?

  3.  Apá 3: Kí Nìdí Tó Fi Yẹ Kó O Gbà Pé Ọlọ́run Ló Dá Ohun Gbogbo?

 Ìmọ̀ràn: Yan àwọn àpẹẹrẹ tó dá ìwọ gangan lójú. Wàá tètè rántí wọn, ohun tó o bá sì sọ á lè dá ẹ lójú. O lè fi ohun tó o fẹ́ ṣàlàyé nípa ìgbàgbọ́ ẹ dánra wò.