Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

ÀWỌN Ọ̀DỌ́ BÉÈRÈ PÉ

Ṣó Yẹ Kí N Mú Àwọn Míì Lọ́rẹ̀ẹ́ Yàtọ̀ Sáwọn Tá A Ti Jọ Ń Ṣọ̀rẹ́?

Ṣó Yẹ Kí N Mú Àwọn Míì Lọ́rẹ̀ẹ́ Yàtọ̀ Sáwọn Tá A Ti Jọ Ń Ṣọ̀rẹ́?

 “Ara máa ń tù mí tí mo bá ti wà láàárín àwọn tèmi; ṣe ló máa ń nira fún mi gan-an láti mú àwọn míì lọ́rẹ̀ẹ́.”​—Alan.

 “Àwọn ọ̀rẹ́ tí mo ní ò pọ̀ rárá, mo sì fẹ́ràn ẹ̀ bẹ́ẹ̀. Torí kò mọ́ mi lára láti máa bá àwọn tí mi ò mọ̀ sọ̀rọ̀.”​—Sara.

 Ṣé irú ohun tó ń ṣe Alan àti Sara yìí máa ń ṣe ẹ́? Ṣó ti láwọn kan tẹ́ ẹ jọ jẹ́ ọ̀rẹ́, tẹ́ ẹ sì ti mọwọ́ ara yín, tí kò wá jẹ́ kó wù ẹ́ láti lọ́rẹ̀ẹ́ tuntun?

 A jẹ́ pé àpilẹ̀kọ yìí kàn ẹ́ nìyẹn!

 Ìṣòro tó wà nínú kéèyàn ní àwọn kan pàtó tó ń bá ṣọ̀rẹ́

 Kò burú kéèyàn láwọn kan tí wọ́n jọ jẹ́ ọ̀rẹ́, tí wọ́n sì mọwọ́ ara wọn. Irú àwọn téèyàn bá jọ jẹ́ ọ̀rẹ́ yẹn máa ń jẹ́ kéèyàn rẹ́ni fojú jọ, ó sì máa ń jẹ́ kéèyàn mọ̀ pé òun láwọn tó gba tòun láìka irú ẹni tóun jẹ́ sí.

 “Ó máa ń múnú ẹni dùn téèyàn bá láwọn tó fẹ́ràn ẹ̀, tí wọ́n sì jọ mọwọ́ ara wọn. Ó máa ń wu àwa tá a jẹ́ ọ̀dọ́ pé ká ṣáà ní àwọn ọ̀rẹ́ tó gba tiwa.”​—Karen, ọmọ ọdún 19.

 Ṣé o mọ̀ pé, àwọn àpọ́sítélì méjìlá [12] tí Jésù ní wà lára àwọn tó jẹ́ ọ̀rẹ́ rẹ̀? Àmọ́ mẹ́ta nínú àwọn àpọ́sítélì yẹn, ìyẹn Pétérù, Jákọ́bù àti Jòhánù, ló sún mọ́ Jésù jù.​—Máàkù 9:2; Lúùkù 8:​51.

 Àmọ́, tó bá jẹ́ pé ìwọ̀nba àwọn ọ̀rẹ́ kan nìkan lèèyàn ní, tí kì í bá àwọn míì da nǹkan kan pọ̀ rárá, ó lè fa ìṣòro. Bí àpẹẹrẹ:

  •   Ó lè máà jẹ́ kó o láwọn ọ̀rẹ́ gidi míì.

     “Tó bá jẹ́ àwọn tí ìṣe yín jọra nìkan lò ń bá ṣọ̀rẹ́, àwọn nǹkan kan wà tó ò ní mọ̀ láyé yìí, o ò sì ní mọ àwọn èèyàn gidi míì.”​—Evan, ọmọ ọdún 21.

  •   Ó lè jẹ́ kó o dà bí ẹni tí kò ka àwọn míì sí.

     “Tó bá jẹ́ pé ó ti láwọn kan pàtó tẹ́ ẹ jọ ń ṣọ̀rẹ́, o lè mú káwọn míì máa rò pé o ò fẹ́ máa dá sí àwọn èèyàn tó kù.”​—Sara, ọmọ ọdún 17.

  •   Ó lè mú kó o máa halẹ̀ mọ́ àwọn míì.

     “Èèyàn fúnra ẹ̀ lè má halẹ̀ mọ́ ẹlòmíì, àmọ́ tí àwọn tẹ́ ẹ jọ ń ṣọ̀rẹ́ bá ṣe bẹ́ẹ̀ fẹ́nì kan, o lè má sọ pé o ò fara mọ́ ọn, o tiẹ̀ lè máa fi onítọ̀hún rẹ́rìn-ín.”​—James, ọmọ ọdún 17.

  •   Ó lè kó ẹ sí wàhálà, pàápàá tó bá jẹ́ pé àforí àfọrùn, o ṣáà fẹ́ dọ̀rẹ́ àwọn kan pàtó.

     “Táwọn kan bá jọ ń bára wọn ṣọ̀rẹ́, tẹ́nì kan péré bá ti yàyàkuyà láàárín wọn, ó lè kó àwọn yòókù ṣe ohun tí ò dáa.”​—Martina, ọmọ ọdún 17.

 Ohun tó o lè ṣe

  •   Ronú nípa ìwà ẹ.

     Bi ara ẹ pé: ‘Irú àwọn ìwà wo ló wù mí kí n máa hù? Ṣé àwọn tí mò ń bá ṣọ̀rẹ́ jẹ́ kó rọrùn fún mi láti máa hu irú ìwà yìí àbí wọ́n máa ń fẹ́ kí n ṣohun tó yàtọ̀? Ṣé màá ṣì máa bá wọn ṣọ̀rẹ́, tí mo bá tiẹ̀ rí i pé wọ́n máa kó bá mi?’

     Ìlànà Bíbélì: “Ẹgbẹ́ búburú a máa ba ìwà rere jẹ́.”​—1 Kọ́ríńtì 15:33.

     “Tó bá jẹ́ àwọn tí ìwà wọn yàtọ̀ sí tìẹ lò ń bá ṣọ̀rẹ́, o lè wá rí i pé àwọn ohun tí o kò ronú pé wàá ṣe irú ẹ̀ láé ni wàá bẹ̀rẹ̀ sí í ṣe.”​—Ellen, ọmọ ọdún 14.

  •   Ronú nípa ohun tó o kà sí pàtàkì.

     Bi ara ẹ pé: ‘Ṣé màá ṣe ohun tí kò yẹ kí n ṣe torí mi ò fẹ́ ba àárín èmi àti àwọn tá a jọ ń ṣọ̀rẹ́ jẹ́? Kí ni màá ṣe tí ọ̀rẹ́ mi kan bá ṣe ohun tí ò dáa?’

     Ìlànà Bíbélì: “Gbogbo àwọn tí mo ní ìfẹ́ni fún ni mo ń fi ìbáwí tọ́ sọ́nà.”​—Ìṣípayá 3:​19.

     “Tí ẹnì kan nínú àwọn tẹ́ ẹ jọ ń ṣọ̀rẹ́ bá lọ ṣe ohun tí ò dáa, ó lè máa ṣe ẹ́ bíi pé tó o bá fẹjọ́ ẹ̀ sùn, ṣe lo dalẹ̀ ẹ̀, torí pé o ò fẹ́ kí ọ̀rẹ́ tẹ́ ẹ̀ ń ṣe bà jẹ́.”​—Melanie, ọmọ ọdún 22.

  •   Bá àwọn míì ṣọ̀rẹ́.

     Bi ara ẹ pé: ‘Yàtọ̀ sáwọn tá a ti jọ ń ṣọ̀rẹ́, ṣé ó máa ṣe mí láǹfààní tí mo bá ń bá àwọn míì ṣọ̀rẹ́, bí mi ò tiẹ̀ mọ̀ wọ́n tẹ́lẹ̀?’

     Ìlànà Bíbélì: “Ẹ má ṣe máa mójú tó ire ara ẹni nínú kìkì àwọn ọ̀ràn ti ara yín nìkan, ṣùgbọ́n ire ara ẹni ti àwọn ẹlòmíràn pẹ̀lú.”​—Fílípì 2:4.

     “Àwọn èèyàn lè má gba tàwọn ọ̀dọ́ kan, bẹ́ẹ̀ ó lè jẹ́ pé ohun tójú àwọn ọ̀dọ́ yìí ń rí nílé kì í ṣe kékeré. Àmọ́ tó o bá sún mọ́ wọn, wàá rí i pé lọ́nà kan, àwọn náà dùn bá ṣọ̀rẹ́.”​—Brian, ọmọ ọdún 19.

 Òótọ́ ibẹ̀ ni pé: Kò sóhun tó burú kéèyàn láwọn kan pàtó tó ń bá ṣọ̀rẹ́. Lẹ́sẹ̀ kan náà, ó máa ṣe ẹ́ láǹfààní tó o bá ń bá àwọn míì ṣọ̀rẹ́. Bíbélì sọ pé: “Ẹni tí ó . . . ń bomi rin àwọn ẹlòmíràn ní fàlàlà, a ó bomi rin òun náà ní fàlàlà.”​—Òwe 11:25.