Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

ÀWỌN Ọ̀DỌ́ BÉÈRÈ PÉ

Ṣé Ó Yẹ Kí N Fín Ara?

Ṣé Ó Yẹ Kí N Fín Ara?

 Kí ló ń fani lọ́kàn mọ́ra nínú ẹ̀?

 Ọ̀dọ́kùnrin kan tó ń jẹ́ Ryan sọ pé: “Mo ronú pé fífín ara máa ń rẹwà nígbà míì.”

 Irú ojú tó o fi ń wo fífín ara ló máa pinnu bóyá ó máa wù ẹ́. Bí àpẹẹrẹ ọ̀dọ́bìnrin kan tó ń jẹ́ Jillian sọ pé: “Nígbà tá a wà ní kékeré, ọmọbìnrin kan tá a jọ ń lọ sílé-ìwé pàdánù ìyà rẹ̀. Ní báyìí tá a ti wà lọ́dọ̀ọ́, ọmọbìnrin yìí fín orúkọ màmá rẹ̀ yìí sí ẹ̀yìn ọrùn rẹ̀. Mo rò pé irú bó ṣe fín orúkọ yẹn sára ti lọ wà jù.”

 Nǹkan yòówù kó fẹ́ sún ẹ láti fín ara, ronú jinlẹ̀ kó o sì ṣàṣàrò dáadáa kó o tó fin ohunkóhun síra ẹ lára! Tó bá ń wù ẹ́ láti fín nǹkan sára, àwọn ìbéèrè wo ló yẹ kó o bi ara ẹ? Àwọn ìlànà Bíbélì wo ló lè ràn ẹ́ lọ́wọ́ láti ṣe ìpinnu tó dára jù lọ?

 Àwọn ìbéèrè wo ló yẹ kó o bi ara ẹ?

 Àwọn ìpalára wo ló lè ṣe fún ìlera mi? Ìkànnì kan tó ń jẹ́ Mayo Clinic sọ pé: “Fífín ara máa ń ní nínú kí wọ́n fi nǹkan ha èèyàn lára, èèyàn sì lè tètè kó àrùn láti ibi ojú egbò yẹn, nígbà míì kòkòrò máa ń jẹ yọ káàkiri ibi tí wọ́n fín lára èèyàn. Ìgbà míì, ibi tí wọ́n fín lára yìí lè so tó bá jinná tán.” Ìkànnì yìí wá sọ síwájú sí i pé: “Tó bá jẹ́ pé abẹ́ tí wọ́n lò fún ẹnìkan tó ní àrùn inú ẹ̀jẹ̀ lára ni wọ́n lò fún ẹ, ó ṣeé ṣe kí ìwọ náà kó àrùn onítọ̀hún.”

 Irú ojú wo làwọn èèyàn á fi máa wò ẹ́? Òtítọ́ kan rè é, ìrísí rẹ ń sọ irú ẹni tó o jẹ́. Ó máa sọ bóyá o dàgbà dénú àbí ọmọdé ṣì ni ẹ, bóyá ẹni tó ṣeé fọkàn tán ni ẹ́ àbí o ò ṣeé fọkàn tán. Ọ̀dọ́bìnrin kan tó ń jẹ́ Samantha sọ pé: “Ìgbàkígbà tí n bá rí ẹni tó fínra, ojú ọ̀mùtí ni mo fi máa ń wò wọ́n.”

 Ọ̀tọ̀ lojú tí Melanie ọmọ ọdún méjìdínlógún kan fi wò ó, ó sọ pé: “Ní tèmi o, fífín ara kì í gbé ẹwà tí Ọlọ́run dá mọ́ni jáde, ṣe ló máa ń dà bíi pé àwọn tó máa ń fín ara kì í fẹ́ kẹ́ ẹ rí irú èèyàn tí wọ́n jẹ́ gan-gan.”

 Ṣé bí á ṣe máa wù ẹ́ lọ nìyẹn? Bọ́jọ́ ṣe ń gorí ọjọ́, tó ò ń sanra ju ti tẹ́lẹ̀ lọ tó o sì tún ń dàgbà sí i, ohun tó o fín sára yẹn kò ní rẹwà mọ́. Ọ̀dọ́kùnrin kan tó ń jẹ́ Joseph sọ pé: “Mo rí bí ohun tí ẹnìkan fín sára ṣe rí lẹ́yìn bí ọdún mélòó kan tó fín-in, kò ti ẹ̀ dáa rárá.

 Allen ọmọ ọdún mọ́kànlélógún sọ pé: “Ohun tó gbayì lónìí lè má gbayì lọ́la. Bẹ́ẹ̀ lọ̀rọ̀ fífín ara ṣé máa ń rí. Bó ṣe wu èèyàn nígbà tó kọ́kọ́ fín in lè máà tún wù ú mọ́ lọ́jọ́ ọ̀la.”

 Òótọ́ ni Allen sọ. Kókó ibẹ̀ gan-an ni pé bí àwọn èèyàn ṣe máa ń wo nǹkan máa ń yí pa dà tí wọ́n bá ti ń dàgbà, àwọn ohun tó wù wọ́n máa yí pa dà, ìmọ̀lára wọn máa yí pa dà, àmọ́ ohun tí wọ́n fín sára kò lè yí pa dà. Ọ̀dọ́bìnrin Teresa sọ pé: “Fífín ara kò sí lára àwọn ohun tí mo nífẹ̀ẹ́ sí torí mí ò ní fẹ́ nǹkan tí màá ṣe tí màá wá máa dá ara mi lẹ́bi tó bá di ọjọ́ iwájú.”

 Ìlànà Bíbélì wo ló wà fún un?

 Ẹni tó dàgbà dénú máa ń ronú dáadáa kó tó ṣe ìpinnu. (Òwe 21:5; Hébérù 5:​14) Torí náà, ṣàyẹ̀wò àwọn ìlànà Bíbélì yìí tá a lè lò fún fífín ara.

  •  Kólósè 3:​20: “Ẹ̀yin ọmọ, ẹ jẹ́ onígbọràn sí àwọn òbí yín nínú ohun gbogbo, nítorí èyí dára gidigidi nínú Olúwa.”

      Kí ló lè tẹ̀yìn rẹ̀ yọ tó o bá ń gbé pẹ̀lú àwọn òbí rẹ tó o sì tẹ̀ lé ìtọ́sọ́nà wọn?

  •  1 Pétérù 3:​3, 4: “Kí ọ̀ṣọ́ yín má sì jẹ́ ti irun dídì lóde ara àti ti fífi àwọn ohun ọ̀ṣọ́ wúrà sára tàbí ti wíwọ àwọn ẹ̀wù àwọ̀lékè, ṣùgbọ́n kí ó jẹ́ ẹni ìkọ̀kọ̀ ti ọkàn-àyà nínú aṣọ ọ̀ṣọ́ tí kò lè díbàjẹ́ ti ẹ̀mí ìṣejẹ́ẹ́jẹ́ẹ́ àti ti ìwà tútù.”

      Kí lo rò pé o fà á ti Bíbélì fi pe àfíyèsí sí ọ̀rọ̀ náà “ẹni ìkọ̀kọ̀ ti ọkàn-àyà”?

  •  1 Tímótì 2:9: ‘Kí àwọn obìnrin máa fi . . . ìmẹ̀tọ́mọ̀wà àti ìyèkooro èrò inú ṣe ara wọn lọ́ṣọ̀ọ́.’

      Kí ni ìtumọ̀ ọ̀rọ̀ náà “ìmẹ̀tọ́mọ̀wà”? Kí nìdí tí ìmẹ̀tọ́mọ̀wà fi fani lọ́kàn mọ́ra ju kéèyàn fín ara lọ?

  •  Róòmù 12:1: “Ẹ fi ara yín fún Ọlọ́run ní ẹbọ ààyè, mímọ́, tí ó ṣe ìtẹ́wọ́gbà, iṣẹ́ ìsìn ọlọ́wọ̀ pẹ̀lú agbára ìmọnúúrò yín.”

      Kí nìdí tí bó o ṣe ń lo ara rẹ fi ṣe pàtàkì sí Ọlọ́run?

 Níbàámu pẹ̀lú àwọn ohun tá a ṣẹ̀ jíròrò tán yìí, àwọn kan tí gbà pé àwọn kò ní fín ara àwọn. Kódà wọ́n ti ẹ̀ tún rí nǹkan tó tún dáa ju fífín ara lọ. Teresa tá a mẹ́nu bà lẹ́ẹ̀kan sọ pé: “Tó o bá nífẹ̀ẹ́ sí ọ̀rọ̀ kan, gbólóhùn kan tàbí ẹnìkan, ó lè máa sọ ọ̀rọ̀ náà tàbí fi gbólóhùn náà ṣèwà hù, tó bá sì jẹ́ pé ẹnìkan ló nífẹ̀ẹ́ ó lè sọ bó o ṣe nífẹ̀ẹ́ onítọ̀hún tó fún-un. Dípò tí wà á fi fín ohun tó o nífẹ̀ẹ́ sí sára rẹ, kúkú fi ṣèwà hù.”