Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

ÀWỌN Ọ̀DỌ́ BÉÈRÈ PÉ

Ṣé Gbogbo Nǹkan Ni Mo Máa Ń Fẹ́ Ṣe Láìṣe Àṣìṣe Kankan?

Ṣé Gbogbo Nǹkan Ni Mo Máa Ń Fẹ́ Ṣe Láìṣe Àṣìṣe Kankan?

 Tí o bá máa ń

  •   fẹ́ gba gbogbo máàkì tán nínú ìdánwò ẹ níléèwé

  •   fẹ́ sá fún ṣíṣe ohun tó ò ṣe rí torí pé o ò fẹ́ ṣàṣìṣe rárá

  •   wo gbogbo àwọn tó ń fi ibi tó o kù sí hàn ẹ́ bí ẹni pé wọ́n ń bà ẹ́ lórúkọ jẹ́

 . . . , a jẹ́ pé ìdáhùn ẹ sí ìbéèrè tó wà lókè yìí lè jẹ́ bẹ́ẹ̀ ni. Àmọ́ kí ló burú níbẹ̀?

 Kí ló burú níbẹ̀?

 Kò sóhun tó burú nínú kéèyàn máa gbìyànjú láti ṣe gbogbo ohun tó lè ṣe kí nǹkan lè dáa. Àmọ́, ìwé Perfectionism​—What’s Bad About Being Too Good? sọ pé, “Kéèyàn máa ṣe ìwọ̀n tó lè ṣe káwọn ohun tó ń ṣe lè yọrí sí rere yàtọ̀ pátápátá sí kéèyàn máa fi taratara lé ohun tí ọwọ́ ẹ̀ ò lè tó.” Ìwé náà fi kún un pé: “Téèyàn bá fẹ́ máa ṣe gbogbo nǹkan láìṣe àṣìṣe rárá, onítọ̀hún a kàn para ẹ̀ ni, torí ká sòótọ́, kò sẹ́ni tó pé.”

 Ohun tí Bíbélì náà sọ nìyẹn. Ó ní: “Kò sí olódodo kankan ní ilẹ̀ ayé [tó máa] ń ṣe rere.” (Oníwàásù 7:​20) Torí pé aláìpé ni ẹ́, àwọn ohun tó o bá ṣe lè má dáa tán nígbà míì.

 Ṣó nira fún ẹ láti gbà pé òótọ́ lọ̀rọ̀ yẹn? Tó bá nira fún ẹ, wo ọ̀nà mẹ́rin tó lè gbà ṣàkóbá fún ẹ tó o bá fẹ́ máa ṣe gbogbo nǹkan láìṣe àṣìṣe kankan.

  1.   Ojú tó o fi ń wo ara ẹ. Ohun tí ọwọ́ wọn ò lè tó làwọn tí kì í fẹ́ ṣàṣìṣe máa ń lé, ìjákulẹ̀ ló sì máa ń gbẹ̀yìn ẹ̀. Ọ̀dọ́bìnrin kan tó ń jẹ́ Alicia sọ pé, “Ká sòótọ́, kì í ṣe gbogbo nǹkan náà la lè mọ̀ ọ́n ṣe dáadáa, tá a bá sì wá ń fojú kéré ara wa torí pé gbogbo nǹkan kọ́ la mọ̀ ọ́n ṣe, a ò ní lè fi ìdánilójú ṣe nǹkan kan mọ́. Ṣe nìyẹn sì máa ń múni rẹ̀wẹ̀sì.”​—Alicia

  2.   Ojú tó o fi ń wo ìmọ̀ràn rere táwọn míì gbà ẹ́. Lójú àwọn tó máa ń fẹ́ ṣe gbogbo nǹkan láìṣe àṣìṣe kankan, ṣe ló máa ń dà bí ẹni fẹ́ bà wọ́n lórúkọ jẹ́ téèyàn bá fi ibi tí wọ́n kù sí hàn wọ́n, tó sì gbà wọ́n nímọ̀ràn. Ọ̀dọ́kùnrin kan tó ń jẹ́ Jeremy sọ pé: “Kì í dùn mọ́ mi nínú rárá tí wọ́n bá bá mi wí.” Ó wá sọ pé, “Téèyàn bá fẹ́ máa ṣe gbogbo nǹkan láìṣe àṣìṣe rárá, kò ní jẹ́ kéèyàn rántí pé ó níbi tágbára èèyàn mọ, èèyàn ò sì ní máa gbàmọ̀ràn àwọn míì.”

  3.   Ojú tó o fi ń wo àwọn míì. Àwọn tó máa ń fẹ́ ṣe gbogbo nǹkan láìṣe àṣìṣe kankan máa ń rí sí àwọn míì, ìdí tí wọ́n sì fi ń ṣe bẹ́ẹ̀ rèé. Anna tó jẹ́ ọmọ ọdún méjìdínlógún [18] sọ pé, “Tó o bá ń retí pé kó o ṣe gbogbo nǹkan láìṣe àṣìṣe, ohun tí wàá máa retí káwọn míì ṣe náà nìyẹn. Tí wọ́n bá wá ń ṣàṣìṣe, inú ẹ ò ní máa dùn sí wọn.”

  4.   Ojú tí àwọn míì fi ń wò ẹ́. Tó o bá ń retí ohun tó pọ̀ jù lọ́wọ́ àwọn ẹlòmíì, má ṣe jẹ́ kó yà ẹ́ lẹ́nu tí àwọn èèyàn bá bẹ̀rẹ̀ sí í sá fún ẹ! Beth tó ti dàgbà díẹ̀ sọ pé, “Ó máa ń máyé súni téèyàn bá ń bá ẹni tí kì í fẹ́ ṣàṣìṣe kankan ṣiṣẹ́. Kò sẹ́ni tó máa ń fẹ́ dúró ní sàkáání irú ẹni bẹ́ẹ̀!”

 Ṣé nǹkan wà tó o lè ṣe?

 Bíbélì sọ pé: “Ẹ jẹ́ kí ìfòyebánilò yín di mímọ̀.” (Fílípì 4:5) Àwọn tó jẹ́ afòyebánilò kì í retí ohun tó pọ̀ jù lọ́wọ́ ara wọn àti lọ́wọ́ àwọn ẹlòmíì.

 “Ìṣòro tá à ń kojú láyé yìí tó lọ́tọ̀. Ṣó wá yẹ kéèyàn tún dì kún ìṣòro ara ẹ̀, kó fẹ́ máa ṣe gbogbo nǹkan láìṣe àṣìṣe kankan? Èèyàn á kàn ṣera ẹ̀ léṣe lásán ni!”​—Nyla.

 Bíbélì sọ pé: “Jẹ́ ẹni tí ó mẹ̀tọ́mọ̀wà ní bíbá Ọlọ́run rẹ rìn!” (Míkà 6:8) Àwọn tó mẹ̀tọ́mọ̀wà máa ń mọ ibi tí agbára wọn mọ. Wọn kì í ṣe ohun tó ju agbára wọn lọ, wọn kì í sì í lò kọjá àkókò tí wọ́n bá mọ̀ pé agbára àwọn lè gbé nídìí iṣẹ́ kan.

 “Tí mo bá fẹ́ kí inú mi máa dùn pé mò ń ṣiṣẹ́ mi dáadáa, iṣẹ́ tí mo bá mọ̀ pé agbára mi á gbé ni mo máa ń dáwọ́ lé. Mi kì í ṣe kọjá agbára mi.”​—Hailey.

 Bíbélì sọ pé: “Gbogbo ohun tí ọwọ́ rẹ bá rí láti ṣe, fi agbára rẹ ṣe é.” (Oníwàásù 9:​10) Torí náà, kì í ṣe pe wàá wá di ọ̀lẹ torí pé o ò fẹ́ máa ṣe gbogbo nǹkan láìṣe àṣìṣe. Kò yẹ kó o fiṣẹ́ ṣeré, síbẹ̀ ó yẹ kó o máa ṣe ohun méjì tá a sọ lókè yìí bó o ṣe ń ṣiṣẹ́ kára: Àkọ́kọ́, máa fòye báni lò, ìyẹn ni pé kó o má retí ohun tó pọ̀ jù lọ́wọ́ ara ẹ. Èkejì, mẹ̀tọ́ mọ̀wà, ìyẹn ni pé kó o mọ ibi tí agbára ẹ mọ.

 “Ọwọ́ tó ṣe pàtàkì gan-an ni mo fi máa ń mú iṣẹ́ mi, tọkàntọkàn sì ni mo máa ń ṣe é. Mo mọ̀ pé kò sí bí àṣìṣe ò ṣe ní wáyé, àmọ́ inú mi máa ń dùn pé gbogbo ọkàn mi ni mo fi ṣe é.”​—Joshua.