Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Tí Àwọn Òbí Mi Bá Fẹ́ Kọ Ara Wọn Sílẹ̀ Ńkọ́?

Tí Àwọn Òbí Mi Bá Fẹ́ Kọ Ara Wọn Sílẹ̀ Ńkọ́?

Ohun tó o lè ṣe

 Sọ àwọn ohun tó ń bà ẹ́ lẹ́rù fún ẹnì kan. Jẹ́ kí àwọn òbí rẹ mọ bó ṣe ń dùn ẹ́ tó tàbí kó o jẹ́ kí wọ́n mọ̀ pé o ò mọ ohun tó o lè ṣe sí i. Ó ṣeé ṣe kí wọ́n ṣàlàyé nǹkan tó ń ṣẹlẹ̀ fún ẹ, kí ọkàn rẹ sì lè balẹ̀ díẹ̀.

 Tí àwọn òbí rẹ kò bá lè ràn ẹ́ lọ́wọ́, o lè lọ fọ̀rọ̀ lọ ọ̀rẹ́ rẹ kan tó sún mọ́ Ọlọ́run.—Òwe 17:17.

 Ju gbogbo rẹ̀ lọ, mọ̀ dájú pé Baba rẹ ọ̀run máa tẹ́tí gbọ́ ẹ torí òun ni “Olùgbọ́ àdúrà.” (Sáàmù 65:2) Sọ gbogbo ohun tó wà lọ́kàn rẹ fún un ‘nítorí ó bìkítà fún ọ.’—1 Pétérù 5:7.

Ohun tí kò yẹ kó o ṣe

Ṣe ni bíborí ìbànújẹ́ tí ìkọ̀sílẹ̀ àwọn òbí rẹ fà dà bí ìgbà téèyàn kán lápá tó sì ń jinná. Ó lè dùn ẹ́ gan-an o, àmọ́ ìbànújẹ́ yẹn ṣì máa lọ

 Má ṣe fi ẹnikẹ́ni sínú. Daniel tí àwọn òbí rẹ̀ fi ara wọn sílẹ̀ nígbà tó wà lọ́mọ ọdún méje sọ pé: “Tara wọn nìkan ni àwọn òbí mi ń rò, wọn ò tiẹ̀ ro tiwa rárá, wọn ò ro àkóbá tí ohun tí wọ́n ṣe máa ṣe fún wa.”

 Tí Daniel ò bá jẹ́ kí ìbínú yẹn tán kó sì mú ọ̀rọ̀ náà kúrò lọ́kàn, ìpalára wo ló lè ṣe fún un?—Ojútùú: Ka Òwe 29:22.

  Kí nìdí tó fi máa dáa kí Daniel dárí ji àwọn òbí rẹ̀ tó ṣe ohun tó dùn ún yìí?—Ojútùú: Ka Éfésù 4:31, 32.

 Má ṣe ohun tó máa pa ẹ́ lára. Ọmọ kan tó ń jẹ́ Denny sọ pé: “Inú mi bà jẹ́ gan-an nígbà táwọn òbí mi kọra wọn sílẹ̀. Mo bẹ̀rẹ̀ sí í ní ìṣòro nílé ìwé, mo sì fìdí rẹmi lọ́dún kan. Lẹ́yìn ìyẹn, . . . mo di oníjàngbọ̀n nínú kíláàsì wa, mo sì máa ń jà.”

 Kí lo rò pé Denny fẹ́ ṣe tó fi sọ ara rẹ̀ di oníjàngbọ̀n nínú kíláàsì, tó sì ń jà?

 Báwo ni ìlànà tó wà nínú Gálátíà 6:7 ṣe lè ran àwọn èèyàn bíi Denny lọ́wọ́ láti má ṣe ohun tó máa pa wọ́n lára?

 Ọgbẹ́ ọkàn máa ń pẹ́ kó tó kúrò. Àmọ́ tí nǹkan bá ti bẹ̀rẹ̀ sí í lọ déédéé, ará rẹ á bẹ̀rẹ̀ sí í balẹ̀.