Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

ÀWỌN Ọ̀DỌ́ BÉÈRÈ PÉ

Báwo Ni Mo Ṣe Lè Rẹ́ni Tó Dáa Fi Ṣe Àwòkọ́ṣe?

Báwo Ni Mo Ṣe Lè Rẹ́ni Tó Dáa Fi Ṣe Àwòkọ́ṣe?

 “Tí mo bá ń kojú ìṣòro ní ilé ìwé, ohun tó máa ń ràn mí lọ́wọ́ ni pé, mo máa ń ronú nípa ẹnì kan tí mo fẹ́ràn, tí òun náà ti kojú irú ìṣòro yẹn rí, àpẹẹrẹ ẹni yẹn ni màá wá tẹ̀ lé. Tí èèyàn bá ní ẹnì kan tó máa ń tẹ̀lé àpẹẹrẹ rẹ̀, ó máa rọrùn fún un láti kojú àwọn ìṣòro rẹ̀.”​—Haley.

 Tó o bá ní ẹnì kan tó máa ń tẹ̀lé àpẹẹrẹ rẹ̀, ó máa jẹ́ kó o yẹra fún ìṣòro, ọwọ́ rẹ á sì tẹ àwọn àfojúsùn rẹ. Kí èyí tó lè ṣe é ṣe, àfi kó o yan ẹni tó dára.

 Kí nìdí tó fi yẹ kó o fara balẹ̀ yan ẹnì kan?

  •   Ẹni tó o bá yàn máa nípa lórí ìwà rẹ.

     Bíbélì sọ fún àwọn Kristẹni pé kí wọ́n ṣàkíyèsí àwọn tó jẹ́ àwòfiṣàpẹẹrẹ, ó ní: “Bí ẹ sì ti ń fẹ̀sọ̀ ṣàgbéyẹ̀wò bí ìwà wọ́n ti rí, ẹ máa fara wé ìgbàgbọ́ wọn.”​—Hébérù 13:7.

     Àbá: Àwọn tó o bá ń fara wé lè mú kó o máa hùwà dáadáa tàbí hùwà burúkú, torí náà àwọn tó ní ìwà dáadáa ni kó o máa tẹ̀lé àpẹẹrẹ wọn, kì í ṣe àwọn tó jẹ́ ìlúmọ̀ọ́ká tàbí àwọn ẹgbẹ́ rẹ.

     “Ọ̀pọ̀ ẹ̀kọ́ ni mo ti kọ́ lára Adam tí òun náà jẹ́ Kristẹni bíi tèmi​—bó ṣe máa ń hùwà àti àwọn nǹkan tó máa ń ṣe. Ìyàlẹ́nu ló jẹ́ fún mi pé mo ṣì máa ń rántí àwọn nǹkan tó sọ àti àwọn nǹkan tó ṣe. Òun fúnra rẹ̀ kò mọ àwọn ẹ̀kọ́ tí mo rí kọ́ lára òun.”​—Colin.

  •   Irú àwọn tó o bá ń tẹ̀lé àpẹẹrẹ wọn máa nípa lórí bó o ṣe ń ronú àti bí nǹkan ṣe máa ń rí lára rẹ.

     Bíbélì sọ pé: “Kí a má ṣì yín lọ́nà. Ẹgbẹ́ búburú a máa ba ìwà rere jẹ́.”​—1 Kọ́ríńtì 15:33.

     Àbá: Yan ẹni tó ní àwọn ànímọ́ dáadáa, kì í kàn ṣe ẹni tó kàn dùn ún wò lójú. Àìjẹ́ bẹ́ẹ̀, ṣe lò ń kan ìlẹ̀kùn ìjákulẹ̀.

     “Má ṣe máa fi ara rẹ wé àwọn ẹlòmíì nígbà gbogbo, bóyá nítorí ẹwà wọn tàbí àwọn nǹkan míì, tó o bá ń ṣe bẹ́ẹ̀, ṣe la á máa ṣe ẹ́ bí i pé ìrísí rẹ kò dáa tó.”​—Tamara

     Ohun tó yẹ kó o ronú lé: Ewu wo ló wà níbẹ̀ tí mo bá yan eléré ìdárayá tàbí olórin kan láti máa tẹ̀lé àpẹẹrẹ rẹ̀?

  •   Ẹni tó o bá yàn lọ́rẹ̀ẹ́ máa pinnu bóyá ọwọ́ rẹ máa tẹ àwọn àfojúsùn rẹ.

     Bíbélì sọ pé: “Ẹni tí ó bá ń bá àwọn ọlọ́gbọ́n rìn yóò gbọ́n.”​—Òwe 13:20.

     Àbá: Yan àwọn tó ní irú àwọn ìwà tíwọ náà máa fẹ́ máa hù. Bó o ṣe ń wò wọ́n, ó ṣeé ṣe kó o kọ́ àwọn nǹkan tó o lè ṣe kí ọwọ́ rẹ tó lè tẹ àwọn àfojúsùn rẹ.

     “Dípò kó o kàn sọ pé ‘Mo fẹ́ máa hùwà lọ́nà tó bójú mú,’ o lè sọ pé, ‘Mo fẹ́ máa hùwà lọ́nà tó bójú mu bíi Jane. Gbogbo ìgbà ló máa ń tètè dé, ó sì máa ń ṣe iṣẹ́ rẹ̀ dáadáa.’”​—Miriam.

     Kókó ọ̀rọ̀ ni pé: Tó o bá fẹ́ ní àwọn ìwà dáadáa tó wù ẹ́ pé kó o ní, o ní láti yan èèyàn dáadáa tó o lè tẹ̀lé àpẹẹrẹ rẹ̀.

Ọwọ́ rẹ ò ní pẹ́ tẹ àwọn àfojúsùn rẹ tó o bá rí ẹni tó dáa tó o lè tẹ̀lé àpẹẹrẹ rẹ̀!

 Bó o ṣe lè yàn

 Oríṣi ọ̀nà méjì lo lè gbà yan ẹni tí wà á máa tẹ̀lé àpẹẹrẹ rẹ̀.

  1.   O lè yan ànímọ́ kan tí wà á fẹ́ ní. Lẹ́yìn náà, wá ẹnì kan tó o fẹ́ràn tí òun náà ní irú ànímọ́ yẹn.

  2.   O lè yan ẹnì kan tó o fẹ́ràn, kó o sì yan ànímọ́ kan tẹ́ni yẹn ní tí ìwọ náà máa fẹ́ láti ní.

     Ìwé tó o lè kọ èrò rẹ sí wà nínú àpilẹ̀kọ yìí, ó máa ràn ẹ́ lọ́wọ́ láti ṣe bẹ́ẹ̀.

 Àwọn tó o lè máa tẹ̀lé àpẹẹrẹ wọn ni:

  •  Àwọn tẹ́ ẹ jọ jẹ́ ẹgbẹ́. “Ọ̀rẹ́ mi tó dáa jù ni ẹni tí mo fẹ́ fìwà jọ. Kò sígbà tí kì í ráyè fún ẹlòmíì, ọ̀rọ̀ wọn sì máa ń jẹ ẹ́ lógún. Mo jù ú lọ, àmọ́ mo rí àwọn ìwà dáadáa kan tó máa ń hù, ó sì máa ń wù mí pé kí èmi náà tẹ̀lé àpẹẹrẹ rẹ̀.”​—Miriam.

  •  Àwọn àgbàlagbà. Ó lè jẹ́ àwọn òbí rẹ̀ tàbí àwọn tí ìgbàgbọ́ yín jọ bára mu. “Kí n sòótọ́, àpẹẹrẹ ẹni tó dáa tí mo lè tẹ̀lé ni tàwọn òbí mi. Wọ́n ní àwọn ànímọ́ tó dáa. Àwọn náà máa ń ṣe àṣìṣe, àmọ́ mo ti rí i pé olóòótọ́ ni wọ́n. Bí èmi náà ṣe fẹ́ rí nìyẹn tí mo bá dàgbà.”​—Annette.

  •  Èèyàn inú Bíbélì. “Mo ti yan àwọn kan tí mo fẹ́ máa tẹ̀lé àpẹẹrẹ wọn nínú Bíbélì, àwọn bíi Tímótì, Rúùtù, Jóòbù, Pétérù, ọmọdébìnrin Ísírẹ́lì náà, ó nídìí tí mo fi yan ẹnì kọ̀ọ̀kan wọn. Bí mo ṣe ń kẹ́kọ̀ọ́ sí i nípa àwọn tó wà nínú Bíbélì, ṣe ni wọ́n tún ń dà bí ẹni gidi sí mi. Ohun míì tí mo tún gbádùn gan-an ni ìtàn àwọn tó wà nínú ìwé Tẹ̀ Lé Àpẹẹrẹ Ìgbàgbọ́ Wọn, àti ‘Atọ́ka Àwòkọ́ṣe’ tó wà nínú ìwé Àwọn Ìbéèrè Tí Àwọn Ọ̀dọ́ Ń Béèrè​—Àwọn Ìdáhùn Tí Ó Gbéṣẹ́”​—Melinda.

 Àbá: Má kàn yan ẹnì kan péré. Àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù sọ fún àwọn Kristẹni bíi tiẹ̀ pé: ‘Kí ẹ tẹ ojú yín mọ́ àwọn tí ń rìn ní ọ̀nà tí ó bá àpẹẹrẹ tí ẹ rí nínú wa mu.’​—Fílípì 3:17.

 Ǹjẹ́ o mọ̀? Ìwọ náà lè jẹ́ àwòkọ́ṣe fún ẹlòmíì! Bíbélì sọ pé: “Di àpẹẹrẹ fún àwọn olùṣòtítọ́ nínú ọ̀rọ̀ sísọ, nínú ìwà, nínú ìfẹ́, nínú ìgbàgbọ́, nínú ìwà mímọ́..”​—1 Tímótì 4:12.

 “O lè máa ṣiṣẹ́ lórí àwọn ibi tó o kù sí, kó o sì tún máa ran àwọn míì lọ́wọ́ kí àwọn náà lè sunwọ̀n sí i. Oò mọ àwọn tó ń wò ẹ́, oò sì mọ ohun tó o máa sọ tó máa tún ìgbésí ayé ẹnì kan ṣe.”​—Kiana.