Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

ÀWỌN Ọ̀DỌ́ BÉÈRÈ PÉ

Báwo Ni Mo Ṣe Lè Lóye Àwọn Òbí Mi?

Báwo Ni Mo Ṣe Lè Lóye Àwọn Òbí Mi?

 Ìbéèrè nípa èdèkòyédè

  •   Èwo nínú àwọn òbí rẹ lẹ jọ sábà máa ń ni èdèkòyédè?

    •  Bàbá

    •  Ìyá

  •   Báwo ni èdèkòyédè ṣe máa ń wáyé láàárín yín sí?

    •  Kì í sábà wáyé

    •  Lẹ́ẹ̀kọ̀ọ̀kan

    •  Ní gbogbo ìgbà

  •   Báwo ni èdèkòyédè náà ṣe máa ń le tó?

    •  A tètè máa ń yanjú ẹ̀ tí àlááfíà sì máa jọba.

    •  A máa yanjú ẹ̀ àmọ́ á jẹ́ lẹ́yìn ọ̀pọ̀ àríyànjiyàn.

    •  Bá a ti ẹ̀ jiyàn pàápàá ìyẹn ò ní kó yanjú.

 Tí o kò bá kí ń lóye àwọn òbí rẹ, o lè máa rò ó pé ó yẹ kí wọ́n wá nǹkan ṣe sí i kí àyípadà lè wà. Bí wàá ṣe rí i nínú àpilẹ̀kọ yìí, wàá rí àwọn nǹkan tó o lè ṣe láti dín èdèkòyédè náà kù. Lákọ̀ọ́kọ́ ná, wo . . .

 Ìdí tí èdèkòyédè fi máa ń wáyé

  •   Bó o ṣe ń ronú. Bó o ṣe ń dàgbà, wà á máa ronú lórí àwọn nǹkan tó o máa ń ṣe nígbà tó o ṣì wà lọ́mọdé. Èyí á mú kó o bẹ̀rẹ̀ sí ní ronú lórí àwọn nǹkan tó o rò pé ó yẹ kó o ṣe, àmọ́ tó ṣeéṣe kó ta ko ohun táwọn òbí rẹ fẹ́. Àmọ́ ṣá o, Bíbélì sọ pé: “Bọlá fún baba rẹ àti ìyá rẹ.”​—Ẹ́kísódù 20:12.

     Òótọ́ ọ̀rọ̀: Kéèyàn tó lè yẹra fún ìbínú ó gba pé kónítọ̀hún gbọ́n kó sì tún dàgbà dénú.

  •   Òmìnira. Bó o ṣe ń dàgbà, ó ṣeé ṣe káwọn òbí rẹ fún ẹ lómìnira sí i. Àmọ́ ìṣòro ibẹ̀ ni pé, ó lè má pọ̀ tó bó o ṣe fẹ́ àbí kó má tètè yá bó o ṣe rò, ìyẹn sì lè yọrí sí èdèkòyédè. Síbẹ̀, Bíbélì sọ pé: “Ẹ jẹ́ onígbọràn sí àwọn òbí.”​—Éfésù 6:1.

     Òótọ́ ọ̀rọ̀: Lọ́pọ̀ ìgbà, ọwọ́ tó o fi ń mú òmìnira táwọn òbí rẹ ń fún ọ, ló máa sọ bí wọ́n á ṣe máa fún ọ lómìnira sí i.

 Ohun tó o lè ṣe

  •   Gbájú mọ́ ojúṣe rẹ. Kàkà tí wàá fi máa dá àwọn òbí rẹ lẹ́bi, àbí kó o máa bá wọn jà, o ò ṣe kúkú wo ohun tó o lè ṣe tí wàá fi wá àlááfíà. Ọ̀dọ́kùnrin kan tó ń jẹ́ Jeffrey sọ pé, “Kì í ṣe ohun táwọn òbí bá sọ ló sábà máa ń fa ìjà, bí èèyàn bá ṣe fèsì ló máa ń fà á, ọ̀rọ̀ pẹ̀lẹ́ máa ń mú kí ìbínú rọlẹ̀ ni.”

     Bíbélì sọ pé: “Níwọ̀n bí ó bá ti jẹ́ pé ọwọ́ yín ni ó wà, ẹ jẹ́ ẹlẹ́mìí àlàáfíà.”​—Róòmù 12:18.

  •   Tẹ́tí sílẹ̀. Samantha ọmọ ọdún mẹ́tàdínlógún [17] sọ pé, “Kò rọrùn fún mi láti máa fetí sílẹ̀, àmọ́ táwọn òbí bá rí i pé ò ń tẹ́tí sí wọn, ó ṣeé ṣe kí àwọn náà fẹ́ gbọ́ ọ̀rọ̀ rẹ.”

     Bíbélì sọ pé: “Yára nípa ọ̀rọ̀ gbígbọ́, lọ́ra nípa ọ̀rọ̀ sísọ.”​—Jákọ́bù 1:19.

    Bí iná ni aáwọ̀ rí, béèyàn kò bá tètè wá nǹkan ṣe sí i ó máa di nǹkan ńlá

  •   Ẹ máa ronú pa pọ̀. Ìwọ àti àwọn òbí rẹ lè jọ yanjú aáwọ̀ àárín yín. Ṣe ni kó o gba ohun tí àwọn òbí rẹ bá ń sọ torí ire rẹ ni wọ́n ń wá. Ọ̀dọ́kùnrin kan tó ń jẹ́ Adam sọ pẹ́, “Tí òbí bá ń bá ọmọ wí lórí nǹkan kan, ohun tó máa ṣe ọmọ náà láǹfààní ni òbí máa ń rò, àwọn ọmọ náà á sì máa rò ohun tó dára jù fún àwọn, torí náà, èrò àwọn méjèèjì bára mu.”

     Bíbélì sọ pé: “Kí a máa lépa àwọn ohun tí ń yọrí sí àlàáfíà.”​—Róòmù 14:19.

  •   Máa fòye báni lò. Ọ̀dọ́bìnrin kan tó ń jẹ́ Sarah sọ pé: “O máa ń ràn mí lọ́wọ́ tí mo bá rántí pé bí mo ṣe ní ìṣòro tèmi làwọn òbí mi náà ní tiwọn.” Ọmọbìnrin kan tó ń jẹ́ Carla náà sọ pé, “Mo máa ń fi ọ̀rọ̀ àwọn òbí mi ro ara mi wò, mo màá ń rò ó pé, báwo ló ṣe máa rí tó bá jẹ́ èmi ni mò ń tọ́jú àwọn ọmọ, tí mo sì tún ní ìṣòro tèmi náà? Ṣe ire àwọn ọmọ mi ló máa jẹ mí lógún?”

     Bíbélì sọ pé: “Kí ẹ má ṣe máa mójú tó ire ara ẹni nínú kìkì àwọn ọ̀ràn ti ara yín nìkan, ṣùgbọ́n ire ara ẹni ti àwọn ẹlòmíràn pẹ̀lú.”​—Fílípì 2:4.

  •   Jẹ́ onígbọràn. Lákòótán, ohun tí Bíbélì fẹ́ kó o ṣe nìyẹn. (Kólósè 3:​20) Tó o bá sì fara mọ́ ọ, nǹkan á rọrùn fún ọ. Ọmọbìnrin kan tó ń jẹ́ Karen sọ pé: “Ọ̀kan mi máa ń balẹ̀ tí mo bá ti ṣe ohun tí àwọn òbí mi fẹ́, wọ́n ti ṣe wàhálà gan-an nítorí mi, ó sì yẹ kí n san án pa dà fún wọn.” Tá a bá jẹ́ onígbọràn, kò ní sí wàhálà láàárín àwa àti àwọn òbí wa!

     Bíbélì sọ pé: “Níbi tí igi kò bá sí, iná a kú.”​—Òwe 26:20.

 Ìmọ̀ràn kan rèé. Tó bá jẹ́ pé o ò kì i fẹ́ bá èèyàn sọ̀rọ̀, o ò ṣe máa kọ èrò rẹ sílẹ̀, tàbí kó o tẹ àtẹ̀jíṣẹ́. Ọ̀dọ́ kan tó ń jẹ́ Alyssa sọ pé, “Ohun tí mo máa ń ṣe nìyẹn nígbà tí mi ò bá lè sọ nǹkan tó wà lọ́kàn mi síta, ó sì ràn mí lọ́wọ́ gan-an ni, torí màá lè sọ ohun tó wà lọ́kàn mi láì pariwo, mi ò sì ní sọ ohun tí màá kábàámọ̀ rẹ̀ tó bá yá.”