Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

ÀWỌN Ọ̀DỌ́ BÉÈRÈ PÉ

Kí Nìdí Táwọn Ẹgbẹ́ Mi Ò Fi Gba Tèmi?

Kí Nìdí Táwọn Ẹgbẹ́ Mi Ò Fi Gba Tèmi?

 “Àfi kó o ṣe ohun táá jẹ́ káwọn èèyàn gba tìẹ, àìjẹ́ bẹ́ẹ̀, o ò ní lọ́rẹ̀ẹ́, o ò sì ní ráyé wá. Kódà tó bá yá, kò ní sẹ́ni táá rí tìẹ rò, á wá kù ẹ́ ku ìwà ẹ.”—Carl.

 Ṣé àsọdùn ni? Ó lè jọ bẹ́ẹ̀. Àmọ́, ohunkóhun tó bá gbà làwọn kan máa ṣe kí ohun tí Carl sọ yìí má bàa ṣẹlẹ̀ sí wọn. Tó bá jẹ́ ìwọ ni, kí ni wàá ṣe? Àpilẹ̀kọ yìí máa ràn ẹ́ lọ́wọ́ láti mọ ọ̀nà tó dáa tó o lè gbà yan ọ̀rẹ́.

 Kí nìdí táwọn èèyàn fi ń fẹ́ káyé gba tiwọn?

  •   Torí wọn ò fẹ́ káyé gbá wọn sẹ́gbẹ̀ẹ́ kan. “Mo rí fọ́tò àwọn ọ̀rẹ́ mi lórí ìkànnì àjọlò níbi tí wọ́n ti lọ gbádùn ara wọn láìsọ fún mi. Ńṣe ló jẹ́ kí n bẹ̀rẹ̀ sí í ṣe kàyéfì pé, kí ló ń ṣelẹ̀ gan-an, ó sì bẹ̀rẹ̀ sí í ṣe mí bíi pé wọn ò fẹ́ràn mi àti pé mi ò já mọ́ nǹkan kan lójú wọn.”—Natalie.

      RÒ Ó WÒ NÁ: Ṣé àwọn ọ̀rẹ́ ẹ ti pa ẹ́ tì rí? Kí lo ṣe kí wọ́n lè pa dà gba tìẹ?

  •   Torí wọn ò fẹ́ dá yàtọ̀. “Àwọn òbí mi sọ pé mi ò tíì tẹ́ni tó ń lo fóònù. Táwọn ọ̀rẹ́ mi bá ní kí n fáwọn ní nọ́ńbà mi, tí mo sì ní mi ò ní fóònù, wọ́n á ní:‘Hàà! Lọ́mọ ọdún mélòó?’ Tí mo bá sọ pé mẹ́tàlá (13), ńṣe ni wọ́n máa wò mí bí ẹni tí nǹkan ń ṣe.”—Mary.

     RÒ Ó WÒ NÁ: Ǹjẹ́ ohun kan wà táwọn òbí ẹ ò gbà kó o ṣe, tó wá mú kó o dá yàtọ̀? Kí lo rí ṣe sọ́rọ̀ náà?

  •   Torí wọn ò fẹ́ kí wọ́n halẹ̀ mọ́ wọn. “Àwọn ọmọléèwé kì í fẹ́ràn àwọn tí ìwà wọn, ọ̀rọ̀ wọn tàbí ìjọsìn wọn bá yàtọ̀. Tí wọn ò bá sì ti gba tìẹ, wọ́n máa dájú sọ ẹ́, wọ́n sì lè máa fi ẹ́ ṣe yẹ̀yẹ́.”​—Olivia.

     RÒ Ó WÒ NÁ: Ṣé wọ́n ti hùwà àìdáa sí ẹ rí torí pé àwọn ọ̀rẹ́ ẹ ò gba tìẹ? Kí lo ṣe sí i?

  •   Torí wọn ò fẹ́ kí okùn ọ̀rẹ́ wọn já. “Mo máa ń ṣe gbogbo ohun tó bá gbà kí n lè tẹ́ àwọn tí mò ń bá rìn lọ́rùn. Mo máa ń sọ̀rọ̀ bíi tiwọn. Màá rẹ́rìn-ín bọ́rọ̀ náà kò bá tiẹ̀ pààyàn lẹ́rìn-ín. A sì jọ máa ń fàwọn èèyàn ṣe yẹ̀yẹ́, bó tiẹ̀ jẹ́ pé mo mọ̀ pé ó máa dun ẹni náà.”​—Rachel.

     RÒ Ó WÒ NÁ: Ṣé ó wù ẹ́ gan-an káwọn ojúgbà ẹ gba tìẹ? Ǹjẹ́ o ti fìgbà kan rí fìwà ẹ pa mọ́ káwọn èèyàn lè gba tìẹ?

 Ohun tó yẹ kó o mọ̀

  •   Ewu wà nínú kéèyàn máa fara wé àwọn míì káyé lè gba tiẹ̀. Kí nìdí? Ìdí ni pé àwọn èèyàn máa ń mọ̀ tẹ́nì kan bá ń díbọ́n. Ọmọ ogún (20) ọdún kan tó ń jẹ́ Brian sọ ohun tó ṣẹlẹ̀ nígbà kan pé: “Àwọn ọmọ kíláàsì mi kì í gba tèmi tí mo bá ń díbọ́n. Èyí jẹ́ kí n rí i pé ó yẹ káwọn èèyàn mọ irú ẹni tó o jẹ́ gan an, torí àwọn èèyàn máa mọ̀ tó o bá ń ṣàfarawé.”

     OHUN TÓ YẸ KÓ O ṢE: Kí làwọn ohun tó o kà sí pàtàkì? Bíbélì sọ pé: “Máa wádìí dájú àwọn ohun tó ṣe pàtàkì jù.” (Fílípì 1:10) Torí náà bi ara rẹ pé, ‘Èwo ló ṣe pàtàkì jù​—ṣé káwọn tí ìwà wọn yàtọ̀ sí tèmi gba tèmi ni, àbí kí n jẹ́ kí wọ́n mọ irú ẹni tí mo jẹ́ gan an?’

     “Kò sí àǹfààní nínú fífi ìwà ẹ pa mọ́. Dípò káwọn èèyàn gba tìẹ, ńṣe ni wọ́n á máa sá fún ẹ, ìyẹn ò sì ní jẹ́ kó o sunwọ̀n sí i.”—James.

  •   O ò ní lè ṣe bó ṣe wù ẹ́ tó o bá ń fẹ́ káwọn èèyàn gba tìẹ. Bó o ṣe ń fẹ́ láti tẹ́ àwọn míì lọ́rùn lè sọ ẹ́ di ẹni tó ń ṣojú ayé. Ọ̀dọ́kùnrin kan tó ń jẹ́ Jeremy sọ pé: “Gbogbo ohun tó bá gbà ni mo máa ń ṣe káwọn ọ̀rẹ́ mi lè gba tèmi, ì báà tiẹ̀ lè bà mí lórúkọ jẹ́. Mo wá dà bíi bọ́ọ̀lù tí wọ́n ń gbá síbí sọ́hùn-ún. Àwọn ọ̀rẹ́ mi ló sì ń pinnu ohun tí màá ṣe fún mi.”

     OHUN TÓ YẸ KÓ O ṢE: Máa tẹ̀ lé àwọn ìlànà ìwà rere tó o mọ̀, dípò tí wàá fi máa ṣe bí ọ̀gà tó ń gbé àwọ̀ aláwọ̀ wọ̀. Ó bọ́gbọ́n mu bí Bíbélì ṣe sọ pé: “Má ṣe ohun kan torí pé gbogbo àwọn tó kù ń ṣe é.”—Ẹ́kísódù 23:​2, Bíbélì Holy Bible—Easy-to-Read Version.

     “Gbogbo ohun tó ń wù wọ́n ni mò ń sapá láti ṣe, irú bí orin tí wọ́n ń gbọ́, géèmù tí wọ́n ń gbá, aṣọ tí wọ́n ń wọ̀, fíìmù tí wọ́n ń wò àti bí wọ́n ṣe ń ṣara lóge . . . Mo ṣáà fẹ́ dà bíi wọn. Ó jọ pé wọ́n rí ohun tí mò ń ṣe. Kódà gbogbo àwọn tó mọ̀ mí ló rí i, èmi náà sì mọ̀. Ibi tọ́rọ̀ náà já sí ò pé mi rárá, wọn ò gba tèmi, mi ò rẹ́ni fojú jọ, kódà mi ò níyì lójú ara mi mọ́. Mi ò sì níwà tara mi. Ohun tó ṣẹlẹ̀ yìí jẹ́ kó yé mi pé, kì í ṣe gbogbo ẹni tó o bá pàdé ló máa gba tìẹ. Ìyẹn ò sọ pé kó o má lọ́rẹ̀ẹ́ o, àmọ́ ṣe sùúrù, bó o ṣe ń dàgbà sí i, wàá túbọ̀ mọ àwọn tó yẹ kó o yàn lọ́rẹ̀ẹ́.”—Melinda.

  •   Tó o bá ń fẹ́ káwọn èèyàn gba tìẹ, ó lè ṣàkóbá fún ẹ. Ọkùnrin kan tó ń jẹ́ Chris gbà pé òótọ́ lọ̀rọ̀ yìí torí ohun tó ṣẹlẹ̀ sí ará ilé rẹ̀ kan. Chris sọ pé “Torí ó fẹ́ káwọn ọ̀rẹ́ ẹ̀ gba tiẹ̀ ló ṣe ń ṣe àwọn ohun tí kì í ṣe tẹ́lẹ̀, irú bíi lílo oògùn olóró. Nígbà tó yá, ìwà yìí di bárakú fún un, díẹ̀ ló sì kù kó bayé ẹ̀ jẹ́ tán.”

     OHUN TÓ YẸ KÓ O ṢE: Yẹra fún àwọn tí ọ̀rọ̀ àti ìwà wọn fi hàn pé wọn kì í ṣe ọmọlúàbí. Bíbélì sọ pé: “Ẹni tó ń bá ọlọ́gbọ́n rìn yóò gbọ́n, àmọ́ ẹni tó ń bá òmùgọ̀ da nǹkan pọ̀ yóò rí láburú.”—Òwe 13:20.

     “Kò sóhun tó burú nínú kó o fẹ́ káwọn èèyàn gba tìẹ. Àmọ́ má ṣe jẹ́ kó mú ẹ ṣe ohun tó o mọ̀ pé kò tọ́. Àwọn ọ̀rẹ́ tòótọ́ máa fẹ́ràn irú ẹni tó o jẹ́ gan an.”—Melanie.

     Ìmọ̀ràn: Tó o bá fẹ́ ní àwọn ọ̀rẹ́ tuntun, má kàn yan àwọn tó jẹ́ pé ohun tó wù ẹ́ ló ń wu àwọn náà. Kàkà bẹ́ẹ̀, yan àwọn tó jẹ́ pé ohun kan náà lẹ jọ gbà gbọ́, tí ìwà àti ìṣe yín sì bára mu.

    Bó ṣe jẹ́ pé kì í ṣe gbogbo aṣọ ló lè bá ẹ lára mu, bákan náà, kì í ṣe gbogbo àwọn tó o fẹ́ mú lọ́rẹ̀ẹ́ ló lè mú kí ìwà ẹ dára sí i