Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

ÀWỌN Ọ̀DỌ́ BÉÈRÈ PÉ

Báwo Ni Mo Ṣe Lè Bọ́ Lọ́wọ́ Ẹ̀dùn Ọkàn Tá Ò Bá Fẹ́ra Wa Mọ́?

Báwo Ni Mo Ṣe Lè Bọ́ Lọ́wọ́ Ẹ̀dùn Ọkàn Tá Ò Bá Fẹ́ra Wa Mọ́?

 Steven sọ pé, “Nígbà tí èmi àti ọ̀rẹ́bìnrin mi fira wa sílẹ̀, ṣe ni ìbànújẹ́ dorí mi kodò pátápátá. Inú mi ò tíì bà jẹ́ tó bẹ́ẹ̀ rí láyé mi.”

 Ṣé irú ẹ̀ ti ṣe ẹ́ rí? Tó bá ti ṣe ẹ́ rí, a jẹ́ pé àpilẹ̀kọ yìí máa ràn ẹ́ lọ́wọ́.

 Bó ṣe máa ń rí

 Tí àwọn méjì tó ń fẹ́ra sọ́nà ò bá fẹ́ra mọ́, àwọn méjèèjì ló máa ń dùn.

  •   Tó bá jẹ́ ìwọ lo sọ pé kẹ́ ẹ máà fẹ́ra mọ́, ó ṣeé ṣe kó jẹ́ bọ́rọ̀ ṣe rí lára Jasmine ló rí lára tìẹ náà. Jasmine sọ pé, “Mo mọ̀ pé mo ti ba ẹni tí mo nífẹ̀ẹ́ nínú jẹ́, èrò yẹn ò sì jẹ́ kí ọkàn mi balẹ̀ rárá. Mi ò gbàdúrà kírú ẹ̀ tún ṣẹlẹ̀ sí mi mọ́.”

  •   Tó bá jẹ́ pé ìwọ kọ́ lo sọ pé kẹ́ ẹ máà fẹ́ra mọ́, ó ṣeé ṣe kó ṣe ẹ́ bíi tàwọn kan, tí wọ́n sọ pé níbi tó dun àwọn dé, ṣe ló dà bíi pé èèyàn àwọn kú. Ọ̀dọ́bìnrin kan tó ń jẹ́ Janet sọ pé, “Ẹ̀dùn ọkàn tí mo ní kì í ṣe kékeré. Ó kọ́kọ́ ń ṣe mí bí àlá pé a ò fẹ́ra mọ́. Mo gbìyànjú ká ṣì lè máa fẹ́ra, kò bọ́ sí i. Inú wá bẹ̀rẹ̀ sí í bí mi, inú mi ò sì dùn rárá. Nígbà tó yá, lẹ́yìn nǹkan bí ọdún kan, mo gba kámú.”

 Òótọ́ ibẹ̀ ni pé: Tí ìwọ àti àfẹ́sọ́nà ẹ ò bá fẹ́ra mọ́, ó lè bà ẹ́ nínú jẹ́ gan-an, ó sì lè mú kó o sorí kọ́. Bí ọ̀kan lára àwọn tó kọ Bíbélì ṣe sọ ló rí, ó sọ pé: “Ẹ̀mí tí ìdààmú bá ń mú kí àwọn egungun gbẹ.”​—Òwe 17:22.

 Ohun tó o lè ṣe

  •  Bá àgbàlagbà kan tó o fọkàn tán sọ̀rọ̀. Bíbélì sọ pé: “Alábàákẹ́gbẹ́ tòótọ́ a máa nífẹ̀ẹ́ ẹni ní gbogbo ìgbà, ó sì jẹ́ arákùnrin tí a bí fún ìgbà tí wàhálà bá wà.” (Òwe 17:17) Tó o bá sọ bó ṣe ń ṣe ẹ́ fún òbí ẹ tàbí àgbàlagbà kan tó jẹ́ ọ̀rẹ́ ẹ, wọ́n máa tọ́ ẹ sọ́nà kó o lè fi ojú tó tọ́ wo ọ̀rọ̀ náà.

     “Àìmọye oṣù ni mo fi ya ara mi láṣo, tí mi ò sọ bó ṣe ń ṣe mí fún ẹnì kankan. Àmọ́ àwọn ọ̀rẹ́ máa ń ṣèrànwọ́ nírú àkókò yìí. Ìgbà tí mo tó sọ tinú mi fún wọn lara tó tù mí díẹ̀.”​—Janet.

  •  Kẹ́kọ̀ọ́ nínú ohun tó ṣẹlẹ̀. Òwe míì nínú Bíbélì sọ pé: “Ní ọgbọ́n, ní òye.” (Òwe 4:5) Táwọn ohun kan bá ṣẹlẹ̀ sí wa, ó máa ń jẹ́ ká mọ irú ẹni tá a jẹ́ dáadáa, ó sì máa ń jẹ́ ká mọ bá a ṣe ń hùwà táwọn èèyàn bá já wa kulẹ̀.

     “Nígbà tí èmi àti ọ̀rẹ́bìnrin mi ò fẹ́ra mọ́, ọ̀rẹ́ mi kan bi mí pé, ‘Kí lo kọ́ nínú ohun tó ṣẹlẹ̀ láàárín ẹ̀yin méjèèjì, báwo ló sì ṣe lè ràn ẹ́ lọ́wọ́ tó o bá ń fẹ́ ẹlòmíì sọ́nà lọ́jọ́ iwájú?’”​—Steven.

  •  Gbàdúrà. Bíbélì sọ pé: “Ju ẹrù ìnira rẹ sọ́dọ̀ Jèhófà fúnra rẹ̀, òun fúnra rẹ̀ yóò sì gbé ọ ró.” (Sáàmù 55:22) Tó o bá ń gbàdúrà, ó máa jẹ́ kí ẹ̀dùn ọkàn ẹ dín kù, a sì jẹ́ kó o fi ojú míì wo ohun tó ṣẹlẹ̀ láàárín ìwọ àti àfẹ́sọ́nà ẹ.

     “Máa gbàdúrà léraléra. Jèhófà mọ bó ṣe dùn ẹ́ tó, ọ̀rọ̀ náà sì yé e dáadáa jù ẹ́ lọ.”​—Marcia.

  •  Máa ran àwọn míì lọ́wọ́. Bíbélì sọ pé: “Ẹ má ṣe máa mójú tó ire ara ẹni nínú kìkì àwọn ọ̀ràn ti ara yín nìkan, ṣùgbọ́n ire ara ẹni ti àwọn ẹlòmíràn pẹ̀lú.” (Fílípì 2:4) Tó o bá ṣe ń ran àwọn míì lọ́wọ́, ojú tó o fi ń wo ohun tó ṣẹlẹ̀ sí ẹ á máa yí pa dà.

     “Tí èèyàn àti àfẹ́sọ́nà ẹ̀ ò bá fẹ́ra mọ́, ó máa kọ́kọ́ dà bíi pé ayé ti fẹ́ pa rẹ́. Ó máa ń duni gan-an ju kéèyàn fara pa lọ. Àmọ́ mo rí i pé tó bá yá, ó máa tán lára. Sùúrù ló gbà, díẹ̀díẹ̀ ló ń tán lára mi.”​—Evelyn.