Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

ÀWỌN Ọ̀DỌ́ BÉÈRÈ PÉ

Kí Ló Dé Tó Jẹ́ Ọ̀rọ̀ Tí Ò Dáa Ló Máa Ń Jáde Lẹ́nu Mi Ṣáá?

Kí Ló Dé Tó Jẹ́ Ọ̀rọ̀ Tí Ò Dáa Ló Máa Ń Jáde Lẹ́nu Mi Ṣáá?

 “Nígbà míì, mo máa ń lè ṣọ́ ọ̀rọ̀ tí màá sọ, àmọ́ ìgbà míì wà tó máa ń dà bíi pé ẹnu mi kàn ń da ọ̀rọ̀ sílẹ̀ láìjẹ́ pé mo kọ́kọ́ ronú ohun tí mo fẹ́ sọ!”​—James.

 “Tí ọkàn mi bá wà lókè, ṣe ni mo máa ń sọ̀rọ̀ láìronú, tí ara mi bá sì tún balẹ̀, mo máa ń sọ̀rọ̀ jù. Ká kúkú sọ pé gbogbo ìgbà lẹnu mi máa ń wa rọ́ọ̀fù.”​—Marie.

 Bíbélì sọ pé: “Ahọ́n jẹ́ . . . iná” àti pé, “Ẹ wo bí iná tí kò tó nǹkan ṣe lè jó igbó kìjikìji run!” (Jémíìsì 3:5, 6) Ṣé ẹnu ẹ máa ń kó ẹ sí wàhálà? Tó bá rí bẹ́ẹ̀, àpilẹ̀kọ yìí lè ràn ẹ́ lọ́wọ́.

 Kí ló dé tó jẹ́ ọ̀rọ̀ tí ò dáa ló máa ń tẹnu mi jáde?

 Àìpé. Bíbélì sọ pé: “Gbogbo wa ni a máa ń kọsẹ̀ lọ́pọ̀ ìgbà. Tí ẹnì kan kì í bá ṣi ọ̀rọ̀ sọ, á jẹ́ pé ẹni pípé ni.” (Jémíìsì 3:2) A kì í mọ̀ ọ́n rìn, kí orí má mì. Torí pé aláìpé ni wá, ó máa ń jẹ́ ká kọsẹ̀ tá a bá ń rìn, ó sì tún máa ń jẹ́ kí ọ̀rọ̀ tí ò dáa ti ẹnu wa jáde.

 “Níwọ̀n ìgbà tó ti jẹ́ pé ọpọlọ aláìpé àti ahọ́n aláìpé ni mo ní, a jẹ́ pé mo gọ̀ tí mo bá ń sọ pé mo lè darí wọn láìṣe àṣìṣe kankan.”​—Anna.

 Téèyàn bá ń sọ̀rọ̀ jù. Bíbélì sọ pé: “Tí ọ̀rọ̀ bá ti pọ̀, àṣìṣe ò ní ṣàì wáyé.” (Òwe 10:19) Àwọn tó máa ń sọ̀rọ̀ jù, tí kì í sì í fetí sílẹ̀ dáadáa sábà máa ń sọ̀rọ̀ tí kò dáa tó máa múnú bí àwọn míì.

 “Kì í ṣe gbogbo ìgbà làwọn tó ní làákàyè máa ń sọ̀rọ̀. Nínú gbogbo èèyàn tó tíì gbé ayé yìí, Jésù ló ní làákàyè jù lọ, síbẹ̀, ó máa ń dákẹ́ nígbà míì tí kò ní sọ̀rọ̀.”​—Julia.

 Fífi ọ̀rọ̀ kanni lábùkù. Bíbélì sọ pé: “Ọ̀rọ̀ téèyàn sọ láìronú dà bí ìgbà tí idà gúnni.” (Òwe 12:18) Àpẹẹrẹ kan lára àwọn ọ̀rọ̀ téèyàn lè so láìronú ni ọ̀rọ̀ tẹ́nì kan sọ láti fi kan ẹlòmíì lábùkù tàbí láti wọ́ onítọ̀hún nílẹ̀. Táwọn èèyàn bá sọ irú ọ̀rọ̀ bẹ́ẹ̀ tán, wọ́n lè sọ pé, “Ṣebí mo kàn ń ṣeré ni!” Àmọ́ kéèyàn máa wọ́ àwọn míì nílẹ̀ kì í ṣọ̀rọ̀ eré. Bíbélì sọ pé ká mú “ọ̀rọ̀ èébú . . . títí kan gbogbo ohun tó lè ṣeni léṣe” kúrò lọ́dọ̀ wa.​—Éfésù 4:31.

 “Alágbárí ni mí, mo sì tún máa ń fẹ́ pa àwọn míì lẹ́rìn-ín. Èyí lè mú mi kan àwọn míì lábùkù, ó sì sábà máa ń kó mi sí wàhálà.”​—Oksana.

Ẹyin lohùn, tó bá ti bọ́, kò ṣeé kó, bó ṣe jẹ́ pé téèyàn bá tẹ ọṣẹ ìfọyín jáde, kò ṣeé fà pa dà sínú ike ẹ̀ mọ́

 Bó o ṣe lè ṣọ́ ẹnu ẹ

 Ó lè má rọrùn láti kọ́ bí wàá ṣe máa ṣọ́ ẹnu ẹ, àmọ́ àwọn ìlànà Bíbélì lè ràn ẹ́ lọ́wọ́. Bí àpẹẹrẹ, wo àwọn ìlànà tó tẹ̀ lé e yìí.

 “Ẹ sọ ohun tí ẹ ní í sọ ní ọkàn yín, . . . kí ẹ sì dákẹ́ jẹ́ẹ́.”​—Sáàmù 4:4.

 Ìgbà míì, ohun tó dáa jù láti fèsì ọ̀rọ̀ ni kéèyàn má sọ nǹkan kan. Ọ̀dọ́bìnrin kan tó ń jẹ́ Laura sọ pé: “Bọ́rọ̀ ṣe rí lára mi tínú bá ń bí mi lọ́wọ́ lè yàtọ̀ sí bó ṣe máa rí tára mi bá wálẹ̀. Lẹ́yìn tínú mi bá rọ̀, inú mi sábà máa ń dùn pé mi ò sọ ọ̀rọ̀ tó fẹ́ wá sí mi lẹ́nu.” Kódà, ìṣẹ́jú àáyá mélòó kan tó o bá fi dákẹ́ lè kó ẹ yọ tó ò fi ní sọ ohun tí kò yẹ.

 “Ṣebí etí máa ń dán ọ̀rọ̀ wò, bí ahọ́n ṣe ń tọ́ oúnjẹ wò?”​—Jóòbù 12:11.

 Tó ò bá fẹ́ kábàámọ̀, á dáa kó o kọ́kọ́ fi àwọn ìbéèrè yìí yiiri ọ̀rọ̀ tó wà lọ́kàn ẹ wò kó o tó sọ ọ́:

  •   Ṣé òótọ́ ni? Ṣé ọ̀rọ̀ onínúure ni? Ṣó pọn dandan kí n sọ ọ́?​—Róòmù 14:19.

  •   Báwo ló ṣe máa rí lára mi tí ẹnì kan bá sọ bẹ́ẹ̀ sí mi?​—Mátíù 7:12.

  •   Ṣé ó máa fi hàn pé mo ka èrò ẹnì kejì sí?​—Róòmù 12:10.

  •   Ṣé irú àkókò yìí ló yẹ kí n sọ ọ́?​—Oníwàásù 3:7.

 “Ẹ jẹ́ kí ìrẹ̀lẹ̀ máa mú kí ẹ gbà pé àwọn míì sàn jù yín lọ.”​—Fílípì 2:3.

 Ìmọ̀ràn yìí máa ràn ẹ́ lọ́wọ́ láti máa ní èrò tó dáa sáwọn míì, ìyẹn sì máa jẹ́ kó máa ṣọ́ ẹnu ẹ, kó o sì máa ronú kó o tó sọ̀rọ̀. Tó bá sì wá jẹ́ pé ẹ̀pa ò bóró mọ́, tó o ti sọ̀rọ̀ tí ò dáa, ìrẹ̀lẹ̀ máa jẹ́ kó o tètè tọrọ àforíjì! (Mátíù 5:​23, 24) Kó o wá pinnu pé wàá túbọ̀ máa ṣọ́ ẹnu ẹ.