Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Tí Mo Bá Kórìíra Iléèwé Ńkọ́?

Tí Mo Bá Kórìíra Iléèwé Ńkọ́?

Ohun tó o nílò rèé

 Fi ojú tó dáa wo ẹ̀kọ́. Gbìyànjú láti rí bí ọ̀rọ̀ ṣe rí gan-an. Ní lọ́wọ́lọ́wọ́, ó lè má jọ pé gbogbo iṣẹ́ tẹ́ ẹ̀ ń ṣe níléèwé ló wúlò. Síbẹ̀, ẹ̀kọ́ tó o bá kọ́ nípa onírúurú iṣẹ́ á jẹ́ kí òye tó o ní nípa ilé ayé túbọ̀ jinlẹ̀ sí i. Á jẹ́ kó o lè “di ohun gbogbo fún ènìyàn gbogbo,” wàá sì lè bá onírúurú èèyàn tó yàtọ̀ síra sọ̀rọ̀. (1Kọ́ríńtì 9:22) Ó kéré tán, á jẹ́ kó o túbọ̀ lè ronú jinlẹ̀, ó sì dájú pé èyí á ràn ẹ́ lọ́wọ́ lọ́jọ́ iwájú.

Lílọ síléèwé dà bíi fífi àdá lànà nínú igbó kìjikìji, béèyàn bá ṣe gbogbo ohun tó yẹ ní ṣíṣe, ó máa ṣàṣeyọrí

 Fi ojú tó dáa wo olùkọ́ rẹ. Tó o bá rò pé olùkọ́ rẹ máa ń jẹ́ kí nǹkan sú ẹ, má fìyẹn ṣe, iṣẹ́ tó ń kọ́ yín ni kó o gbájú mọ́. Rántí pé ó ṣeé ṣe kó jẹ́ pé àìmọye ìgbà ni olùkọ́ yín ti kọ́ àwọn mìíràn níṣẹ́ tó ń kọ́ yín. Nítorí náà, ìtara tó ní nígbà tó kọ́kọ́ bẹ̀rẹ̀ sí í kọ́ni níṣẹ́ náà lè ti dín kù.

 Àbá: Máa ṣe àkọsílẹ̀, fi tọ̀wọ̀tọ̀wọ̀ béèrè ìsọfúnni púpọ̀ sí i, kó o sì máa fi ìtara kọ́ iṣẹ́ náà. Èyí lè jẹ́ kí àwọn mìíràn túbọ̀ nífẹ̀ẹ́ sí iṣẹ́ náà.

 Mọyì àwọn ohun tó o lè ṣe. Iléèwé lè jẹ́ kí ó wá mọ àwọn ẹ̀bùn àbínibí rẹ tó ti fara sin. Pọ́ọ̀lù kọ̀wé sí Tímótì pé: “Máa rú sókè bí iná, ẹ̀bùn Ọlọ́run tí ń bẹ nínú rẹ.” (2 Tímótì 1:6) Ó ṣe kedere pé Tímótì ti rí àwọn ẹ̀bùn kan gbà nípasẹ̀ ẹ̀mí mímọ́. Àmọ́ ó gbọ́dọ̀ kọ́ bó ṣe máa lo “ẹ̀bùn” yìí kó má bàa ṣòfò tàbí kó wà láìṣiṣẹ́. A mọ̀ pé Ọlọ́run kọ́ ló fi bí wàá ṣe mọ̀wé tó jíǹkí rẹ, torí ìwọ náà ní láti sapá. Síbẹ̀, àwọn ẹ̀bùn tó o ní mú ẹ dá yàtọ̀ gedegbe. Iléèwé lè jẹ́ kó o mọ àwọn ohun tó ò mọ̀ tẹ́lẹ̀ pé o lè ṣe, ó sì lè kọ́ ẹ bí wàá ṣe máa ṣe wọ́n.