Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

ÀWỌN Ọ̀DỌ́ BÉÈRÈ PÉ

Kí Ló Yẹ Kí N Mọ̀ Nípa Gbígbé Fọ́tò Sórí Ìkànnì?

Kí Ló Yẹ Kí N Mọ̀ Nípa Gbígbé Fọ́tò Sórí Ìkànnì?

 Ká sọ pé ò ń gbádùn ara ẹ níbì kan, o sì fẹ́ káwọn ọ̀rẹ́ ẹ mọ gbogbo ohun tó ń lọ níbẹ̀! Báwo lo ṣe máa ṣe é? Ṣé wàá

  1.   lọ fọ fọ́tò tó o yà níbẹ̀, kó o wá fi ránṣẹ́ láti iléeṣẹ́ ìfìwéránṣẹ́?

  2.   fi e-mail ránṣẹ́ sí gbogbo àwọn ọ̀rẹ́ ẹ?

  3.   gbé fọ́tò tó o yà níbẹ̀ sórí ìkànnì?

 Tó bá jẹ́ láyé ìgbà táwọn òbí ẹ àgbà ṣì kéré, àbá “A” nìkan ló ṣeé ṣe kí wọ́n tẹ̀ lé.

 Tó bá jẹ́ láyé ìgbà táwọn òbí ẹ ṣì kéré, ó ṣeé ṣe kí wọ́n tẹ̀ lé àbá “B”.

 Lóde òní, àwọn ọ̀dọ́ lè gbé fọ́tò sórí ìkànnì, torí náà, àbá “C” lọ̀pọ̀ nínú wọn máa tẹ̀ lé. Ṣé òun nìwọ náà fara mọ́? Tó bá jẹ́ òun lo fara mọ́, àpilẹ̀kọ yìí máa ràn ẹ́ lọ́wọ́ kó o lè yẹra fún àwọn ewu kan tó wà níbẹ̀.

 Àǹfààní wo ló wà níbẹ̀?

 Kì í pẹ́ rárá, ojú ẹsẹ̀ ni. “Ká sọ pé mo lọ síbì kan, tí mo sì gbádùn ẹ̀, tàbí témi àtàwọn ọ̀rẹ́ mi jọ gbádùn ara wa, mo lè gbé àwọn fọ́tò tá a yà níbi tá a lọ sórí ìkànnì lójú ẹsẹ̀ nígbà tí fàájì náà ṣì wà lára mi.”​—Melanie.

 Ó rọrùn. “Tí mo bá fẹ́ mọ ohun tó ń ṣẹlẹ̀ lágbo àwọn ọ̀rẹ́ mi, ó rọrùn gan-an láti wo àwọn fọ́tò tí wọ́n gbé sórí ìkànnì ju kí n lọ máa wo orí e-mail.”​—Jordan.

 Ó máa jẹ́ kó o lè máa gbúròó àwọn èèyàn ẹ. “Ibi táwọn ọ̀rẹ́ mi kan àtàwọn ẹbí mi ń gbé jìnnà gan-an. Tí wọ́n bá ń gbé fọ́tò wọn sórí ìkànnì déédéé, témi náà sì ń wò ó léraléra, ṣe ló máa ń ṣe mí bíi pé ojoojúmọ́ là ń ríra sójú!”​—Karen.

 Ewu wo ló wà níbẹ̀?

 Ó lè mú kó o fẹ̀mí ara ẹ wewu. Tí fóònù tàbí kámẹ́rà tó o fi ya fọ́tò bá máa ń kọ ibi tó o wà síbi fọ́tò tó o yà, tó o sì gbé irú fọ́tò bẹ́ẹ̀ sórí ìkànnì, ṣe lò ń tú àṣírí ara ẹ fáyé láìmọ̀. Ìkànnì Digital Trends sọ pé: “Táwọn èèyàn bá ń gbé fọ́tò tàbí fídíò sórí Íńtánẹ́ẹ̀tì látorí fóònù tàbí kámẹ́rà tó máa ń kọ ibi téèyàn wà gangan síbi fọ́tò náà, ó máa ń jẹ́ kó rọrùn fáwọn èèyànkéèyàn láti mọbi tí wọ́n wà.”

 Òótọ́ kan ni pé, kì í kàn ṣe ibi tó o wà làwọn ọ̀daràn kan fẹ́ mọ̀, ibi tó ò sí gan-an ni wọ́n fẹ́ mọ̀ ní tiwọn. Ìkànnì Digital Trends ròyìn ohun kan tó ṣẹlẹ̀. Nígbà kan, àwọn olè mẹ́ta fọ́ ilé méjìdínlógún [18] nígbà tí kò sẹ́nì kankan nílé. Báwo ni wọ́n ṣe mọ̀ pé kò ní séèyàn ńlé? Wọ́n lọ sórí ìkànnì ni, wọ́n wá fi kọ̀ǹpútà wádìí nípa báwọn tó ń gbé láwọn ilé yẹn ṣe rìn. Ẹrù tí iye rẹ̀ ju ẹgbẹ̀rún lọ́nà ọgọ́rùn-ún [100,000] owó dọ́là ti ilẹ̀ Amẹ́ríkà làwọn olè náà jí kó.

 Ó lè mú kó o rí ohun tí kò bójú mu. Àwọn èèyàn kan ò nítìjú, kò sóhun tí wọn ò lè gbé sórí ìkànnì kí gbogbo ayé lè rí i. Ọ̀dọ́bìnrin kan tó ń jẹ́ Sarah sọ pé: “Ibi téèyàn ti sábà máa ń rí ìríkúrìí ni tó bá ń wo àkáǹtì àwọn èèyàn tí kò mọ̀ lórí Íńtánẹ́ẹ̀tì. Ṣe ló dà bí ẹni rìn gba inú ìlú téèyàn ò dé rí láìní ohun tó lè tọ́ ọ sọ́nà. Kò sí béèyàn ò ṣe ní já síbi tí kò ní lọ́kàn láti lọ.”

 Ó lè fàkókò ẹ ṣòfò. Ọ̀dọ́bìnrin kan tó ń jẹ́ Yolanda sọ pé: “Ó máa ń rọrùn gan-an láti jókòó sídìí fóònù, kéèyàn máa wo ohun táwọn kan ṣẹ̀ṣẹ̀ gbé sórí ìkànnì, kó sì máa ka gbogbo ohun táwọn míì kọ síbẹ̀. Téèyàn ò bá ṣọ́ra, á di pé kó máa wo fóònù ẹ̀ ní ìṣẹ́jú-ìṣẹ́jú tọ́wọ́ ẹ̀ bá ti dilẹ̀, kó ṣáà lè rí ohun tó ṣẹ̀ṣẹ̀ dórí ìkànnì.”

Tó o bá ní àkáǹtì tó o lè gbé fọ́tò sí lórí ìkànnì, ó gba kó o máa kóra ẹ níjàánu

 Ọ̀dọ́bìnrin kan tó ń jẹ́ Samantha gbà pé bẹ́ẹ̀ lọ̀rọ̀ rí. Ó ní, “Àfi kí n máa ṣọ́ àkókò tí mò ń lò lórí àwọn ìkànnì yìí. Téèyàn bá máa ní àkáǹtì lórí Íńtánẹ́ẹ̀tì táá máa gbé fọ́tò sí, ó gba pé kó máa kóra ẹ̀ níjàánú.”

 Ohun tó o lè ṣe

  •   Pinnu pé wàá máa yẹra fún àwọn fọ́tò tàbí fídíò tí kò bójú mu. Bíbélì sọ pé: “Èmi kì yóò gbé ohun tí kò dára fún ohunkóhun ka iwájú mi.”​—Sáàmù 101:3.

     “Léraléra ni mo máa ń wo ohun táwọn tá a jọ jẹ́ ọ̀rẹ́ lórí ìkànnì máa ń gbé síbẹ̀, tí mo bá sì rí i pé ohun tí wọ́n ń gbé síbẹ̀ kò bójú mu, ṣe ni mo máa ń yọ wọ́n kúrò lára àwọn tó jẹ́ ọ̀rẹ́ mi.”​—Steven.

  •   Máa yẹra fún àwọn tí kì í hùwà rere bíi tìẹ, torí pé wọ́n lè ṣàkóbá fún ẹ. Bíbélì sọ pé: “Kí a má ṣì yín lọ́nà. Ẹgbẹ́ búburú a máa ba ìwà rere jẹ́.”​—1 Kọ́ríńtì 15:33.

     “Má wo àwọn fọ́tò tàbí fídíò kan lórí ìkànnì torí pé gbogbo ayé ń wò ó. Lọ́pọ̀ ìgbà, ibẹ̀ lèèyàn ti máa ń rí ìríkúrìí tàbí kó gbọ́ ìgbọ́kúgbọ̀ọ́ tàbí kó rí àwọn nǹkan míì tí kò bójú mu.”​—Jessica.

  •   Rí i pé o fètò sí i pé iye àkókò báyìí lo máa lò lórí Íńtánẹ́ẹ̀tì, kó o sì ṣọ́ iye ìgbà tí wàá máa gbé fọ́tò síbẹ̀. Bíbélì sọ pé: “Ẹ máa ṣọ́ra lójú méjèèjì pé bí ẹ ṣe ń rìn kì í ṣe gẹ́gẹ́ bí aláìlọ́gbọ́n ṣùgbọ́n gẹ́gẹ́ bí ọlọ́gbọ́n, ní ríra àkókò tí ó rọgbọ padà fún ara yín.”​—Éfésù 5:​15, 16.

     “Mo láwọn ọ̀rẹ́ kan lórí ìkànnì tó jẹ́ pé ṣe ni wọ́n máa ń rọ́ fọ́tò síbẹ̀. Mo máa ń wo àwọn ohun tí wọ́n ń gbé síbẹ̀ tẹ́lẹ̀, àmọ́ mi kì í wò ó mọ́. Ẹ̀yin náà ẹ wò ó, bí àpẹẹrẹ, kéèyàn lọ wẹ̀ létíkun, kó wá ya ogún [20] fọ́tò níbẹ̀, kó sì gbé gbogbo ẹ̀ sórí ìkànnì. Ẹ wo adúrú àkókò tó máa gbà kéèyàn tó lè wò ó tán!”​—Rebekah.

  •   Rí i pé àwọn fọ́tò tó ò ń gbé sórí ìkànnì ò jẹ́ kó máa dà bíi pé o ka ara ẹ sí pàtàkì jù. Pọ́ọ̀lù tó wà lára àwọn tó kọ Bíbélì sọ pé: “Mo sọ fún gbogbo ẹni tí ń bẹ láàárín yín níbẹ̀ láti má ṣe ro ara rẹ̀ ju bí ó ti yẹ ní rírò lọ.” (Róòmù 12:3) Má lọ rò pé àwọn fọ́tò ara ẹ àtàwọn fọ́tò ẹ míì tó ò ń gbé sórí ìkànnì á máa gbàfiyèsí àwọn ọ̀rẹ́ ẹ.

     “Fọ́tò ara wọn táwọn míì ń gbé sórí ìkànnì ò lóǹkà. Ká sọ pé ọ̀rẹ́ lèmi àti ẹnì kan, kò sí àní-àní, mo mọ ìrísí ẹ̀. Kò nílò kó ṣẹ̀ṣẹ̀ máa gbé fọ́tò ara ẹ̀ sórí ìkànnì ní gbogbo ìgbà kó lè fi rán mi létí bó ṣe rí!”​—Allison.