Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

ÀWỌN Ọ̀DỌ́ BÉÈRÈ PÉ

Báwo Ni Mi Ò Ṣe Ní Jẹ́ Káwọn Ojúgbà Mi Mú Kí N Ṣèṣekúṣe?

Báwo Ni Mi Ò Ṣe Ní Jẹ́ Káwọn Ojúgbà Mi Mú Kí N Ṣèṣekúṣe?

 “Nígbà tí mo wà níléèwé, bí ẹnì kan bá sọ pé òun ti ní ìbálòpọ̀ rí, á ṣe àwa yòókù bíi pé kí àwa náà ṣe bẹ́ẹ̀ ká má bàa gbẹ́yìn. Ó ṣe tán, kò sẹ́ni tó fẹ́ kí tòun yàtọ̀.”​—Elaine, ọmọ ọdún mọ́kànlélógún [21].

 Ṣó ti ṣe ẹ́ rí bíi pé kó o ní ìbálòpọ̀​—torí pé ó jọ pé gbogbo èèyàn ló ń ṣe bẹ́ẹ̀?

 Ṣó ti ṣe ẹ́ rí bíi pé kó o ní ìbálòpọ̀ torí pé ẹnì kan tó o fẹ́ràn ń fẹ́ kẹ́ ẹ jọ ní ìbálòpọ̀?

 Tó bá rí bẹ́ẹ̀, àpilẹ̀kọ yìí á ràn ẹ́ lọ́wọ́ káwọn míì tàbí ìfẹ́ ọkàn rẹ má bàa mú kó o ṣèṣekúṣe, á sì jẹ́ kó o lè ṣe yíyàn tó dáa.

 Irọ́ àti òótọ́

 IRỌ́: Gbogbo èèyàn ló ń ní ìbálòpọ̀ (àfi èmi).

 ÒÓTỌ́: Nínú ìwádìí kan, méjì lára àwọn ọmọ ọdún méjìdínlógún mẹ́ta tí wọ́n fọ̀rọ̀ wá lẹ́nu wò ló sọ pé àwọn ti ní ìbálòpọ̀ rí. Ìyẹn túmọ̀ sí pé, àwọn tó pọ̀ ni ò tíì ní ìbálòpọ̀, kódà wọ́n ju ìdá mẹ́ta nínú mẹ́wàá lọ tí ò tíì ní ìbálòpọ̀. Kì í ṣe “gbogbo èèyàn” ló ń ní ìbálòpọ̀.

 IRỌ́: Ìbálòpọ̀ á jẹ́ kí àjọṣe wa sunwọ̀n sí i.

 ÒÓTỌ́: Bó tilẹ̀ jẹ́ pé àwọn ọkùnrin kan lè máa sọ bẹ́ẹ̀ kí wọ́n lè mú kí obìnrin kan ní ìbálòpọ̀ pẹ̀lú àwọn, irọ́ tó jìnnà sóòótọ́ nìyẹn. Lọ́pọ̀ ìgbà, ṣe ni ọkùnrin máa ń já obìnrin jù sílẹ̀ lẹ́yìn tó bá ti ní ìbálòpọ̀ pẹ̀lú rẹ̀, tí inú obìnrin tó rò pé ọkùnrin náà nífẹ̀ẹ́ òun kò sì ní já òun kulẹ̀, á sì wá bà jẹ́. a

 IRỌ́: Bíbélì sọ pé ìbálòpọ̀ ò dáa.

 ÒÓTỌ́: Bíbélì jẹ́ ká ní èrò tó dáa nípa ìbálòpọ̀ ṣùgbọ́n ó sọ pé ọkùnrin àti obìnrin tó ti ṣègbéyàwó nìkan ló lè ní ìbálòpọ̀.​—Jẹ́nẹ́sísì 1:28; 1 Kọ́ríńtì 7:3.

 IRỌ́: Ìgbésí ayé á nira fún mi tí mo bá ń tẹ̀ lé ìlànà Bíbélì.

 ÒÓTỌ́: Tó o bá dúró dìgbà tó o ṣègbéyàwó kó o tó ní ìbálòpọ̀, wàá túbọ̀ láyọ̀ torí pé, o ò ní ní ìdààmú, àbámọ̀ àti àìbalẹ̀ ọkàn táwọn tó ń ní ìbálòpọ̀ láìṣègbéyàwó máa ń ní.

 Òótọ́ ibẹ̀ ni pé: Dídúró di ẹ̀yìn ìgbéyàwó kéèyàn tó ní ìbálòpọ̀ kò pa ẹnikẹ́ni lára rí. Ṣùgbọ́n níní ìbálòpọ̀ ṣáájú ìgbéyàwó ti ṣèpalára tó pọ̀.

 Bó o ṣe lè borí ìṣekúṣe

  •   Túbọ̀ kórìíra ohun tí kò tọ́. Bíbélì sọ pé àwọn tó dàgbà “ti kọ́ agbára ìfòyemọ̀ wọn nípa bí wọ́n ṣe ń lò ó láti fi ìyàtọ̀ sáàárín ohun tó tọ́ àti ohun tí kò tọ́.” (Hébérù 5:14) Wọ́n mọ ohun tó tọ́ yàtọ̀ sí ohun tí kò tọ́, torí náà wọn ò jẹ́ gbà láti ṣèṣekúṣe.

     “Mò ń sapá gidigidi láti ṣe ohun tó tọ́ kí n sì ní orúkọ rere, mi ò sì ní ṣe ohun tó máa bà mí lórúkọ jẹ́.”​—Alicia, ọmọ ọdún mẹ́rìndínlógún [16].

     Ohun tó yẹ kó o ronú lé: Kí lo fẹ́ káwọn èèyàn máa sọ nípa ẹ? Ṣó wá yẹ kó o gbàgbé nípa ìyẹn kó o lè rí ojúure ẹlòmíì?

  •   Ro ohun tó máa tẹ̀yìn ẹ̀ yọ. Bíbélì sọ pé: “Ohun tí èèyàn bá gbìn, òun ló máa ká.” (Gálátíà 6:7) Ronú nípa ìyípadà tó ṣeé ṣe kó bá ìgbésí ayé rẹ àti ti onítọ̀hún tó o bá gbà pé kó bá ẹ lò pọ̀. b

     “Ọkàn àwọn tó ń bára wọn lò pọ̀ láìṣègbéyàwó máa ń dá wọn lẹ́bi, wọ́n máa ń kábàámọ̀, wọ́n sì máa ń rò pé àwọn ti dẹni ẹ̀tẹ́​—ká má ṣẹ̀ṣẹ̀ sọ ti pé wọ́n lé lóyún ẹ̀sín tàbí àrùn téèyàn ń kó nípasẹ̀ ìbálòpọ̀.”​—Sienna, ọmọ ọdún mẹ́rìndínlógún [16].

     Ohun tó yẹ kó o ronú lé: Ìwé Sex Smart béèrè pé: “Bí àwọn ọ̀rẹ́ rẹ bá ń sún ẹ pé kó o ṣe ohun tó lè kó ẹ sí wàhálà, ṣé irú àwọn tó yẹ kó o máa bá rìn nìyẹn, ṣé ìmọ̀ràn wọn ló sì yẹ kó o máa tẹ́tí sí?”

  •   Ní èrò tó tọ́. Kò sí ohun tó burú nínú ìbálòpọ̀. Bíbélì tiẹ̀ sọ pé kí àwọn méjì tó jọ ṣègbéyàwó máa gbádùn ìbálòpọ̀.​—Òwe 5:​18, 19.

     “Ìbálòpọ̀ jẹ́ ọ̀kan lára ohun rere tí Ọlọ́run dá. Ṣùgbọ́n àwọn tí Ọlọ́run ṣètò rẹ̀ fún nìkan ló fẹ́ kí wọ́n máa gbádùn rẹ̀, ìyẹn àwọn tó ti ṣègbéyàwó.”​—Jeremy, ọmọ ọdún mẹ́tàdínlógún [17].

     Ohun tó yẹ kó o ronú lé: Tó o bá ṣègbéyàwó lọ́jọ́ kan, ìwọ náà á ní ìbálòpọ̀. Wàá sì lè gbádùn rẹ̀ dáadáa, láìsí irú àwọn àbájáde búburú tá a ti sọ̀rọ̀ rẹ̀ nínú àpilẹ̀kọ̀ yìí.

a Ṣùgbọ́n ọkùnrin nìkan kọ́ ló máa ń rọ obìnrin pé kó bá òun lò pọ̀ o. Ọ̀pọ̀ ìgbà ló jẹ́ pé àwọn obìnrin ló máa ń mú kí àwọn ọkùnrin bá àwọn lò pọ̀.

b Lára ohun tó lè yọrí sí ní oyún ẹ̀sín, bí ọjọ́ orí àwọn tó bára wọn lò pọ̀ bá ṣe rí sì tún lé mú kí wọ́n rú òfin tó kan níní ìbálòpọ̀ pẹ̀lú ọmọdé.