Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

ÀWỌN Ọ̀DỌ́ BÉÈRÈ PÉ

Báwo Ni Mo Ṣe Lè Yẹra fún Èrò Tí Kò Tọ́?

Báwo Ni Mo Ṣe Lè Yẹra fún Èrò Tí Kò Tọ́?

 Irú ojú wo lo fi ń wo ara rẹ?

  •   Eni tó lérò tó dáa

     “Mo ń sapá kí n lè láyọ̀ kí n má sì máa tètè bínú. Ó wù mí kí n máa rẹ́rìn-ín músẹ́, kínú mi sì máa dùn lójoojúmọ́.”—Valerie.

  •   Ẹni tó lérò tí ò dáa

     “Ohun tó kọ́kọ́ máa ń wá sí mi lọ́kàn nígbà tí nǹkan tó dáa bá ṣẹlẹ̀ ni pé, kò lè jóòótọ́ àbí pé bóyá èèṣì ni.”—Rebecca.

  •   Ẹni tó fara mọ́ bí nǹkan bá ṣe rí gan-an

     “Tí mo bá lérò tó dáa nípa nǹkan, tí kò sì rí bí mo ṣe fẹ́, ó máa ń dùn mí gan-an. Tí mo bá sì lérò tí kò dáa, àmọ́ tọ́rọ̀ ò rí bí mo ṣe rò, kò sígbà tí màá láyọ̀. Torí náà, bí mo ṣe jẹ́ ẹni tó máa ń fara mọ́ bí nǹkan bá ṣe rí gan-an máa ń jẹ́ kí n lè lóye bọ́rọ̀ bá ṣe rí gẹ́lẹ́.”—Anna.

 Kí nìdìí tó fi ṣe pàtàkì?

 Bíbélì sọ pé “ẹni tí inú rẹ̀ ń dùn máa ń jẹ àsè nígbà gbogbo.” (Òwe 15:15) Ó ṣe kedere pé ẹni tó bá ní èrò tó tọ́ nípa ìgbésí ayé máa ń láyọ̀ ju ẹni tó ń lérò tí kò dáa. Yàtọ̀ síyẹn, ẹni tó bá ń ronú lọ́nà tó tọ́ tètè máa ń lọ́rẹ̀ẹ́. Àmọ́, kò sẹ́ni tó máa fẹ́ ṣọ̀rẹ́ ẹni tínú ẹ̀ máa ń bà jẹ́, tó sì máa ń ro èrò tí kò tọ́ nígbà gbogbo .

 Síbẹ̀, tó o bá tiẹ̀ máa ń lérò tó dáa, ìyẹn ò ní kó o má láwọn ìṣòro kan nígbèésí ayé. Bí àpẹẹrẹ:

  •   Kò sígbà tó ò ní máa gbọ́ ìròyìn nípa ogun, ìpániláyà tàbí ìwà ọ̀daràn.

  •   Ìṣòro ìdílé lè máa bá ẹ fínra.

  •   Ìwọ náà máa ń ṣàṣìṣe, o sì láwọn kùdìẹ̀-kudiẹ tó yẹ kó o borí.

  •   Ọ̀rẹ́ ẹ lè sọ ohun kan tàbí kó ṣe ohun kan tó dùn ẹ́.

 Dípò tí wàá fi gbọ́kàn kúrò lórí ìṣòro yìí tàbí tí wàá jẹ́ kó gbà ẹ́ lọ́kàn, ńṣe ni kó o ní èrò tó tọ́ nípa ẹ̀. Tó o bá ń ní èrò tó dáa, kò ní jẹ́ kó o máa ronú lọ́nà tí kò yẹ, wàá lè máa fojú tó tọ́ wo ìṣòro ìgbésí ayé, kò sì ní sú ẹ.

Kò sí bí ìṣòro ìgbésí àyé ṣe nira tó, fọkàn balẹ, ó máa tó dópin

 Ohun tó o lè ṣe

  •   Gbà pé o lè ṣàṣìṣe.

     Bíbélì sọ pé: “Kò sí olódodo kan láyé tí ń ṣe rere, tí kò lẹ́ṣẹ̀.” (Oníwàásù 7:20, Bibeli Ìròhìn Ayọ̀) Torí pé o máa ń ṣàṣìṣe kò túmọ̀ sí pé o ò wúlò, ńṣe nìyẹn ń jẹ́ kó o mọ̀ pé o ò kì í ṣẹni pípé.

     Bó o ṣe lè ní èrò tó tọ́: Sapá kó o lè ṣàtúnṣe àwọn ibi tó o kù sí, àmọ́ má gbàgbé pé o ò kì í ṣẹni pípé. Ọ̀dọ́kùnrin kan tó ń jẹ́ Caleb sọ pé “Mo máa ń sapá kí n lè gbọ́kàn kúrò lórí àwọn àṣìṣe mi kí n má bàa rẹ̀wẹ̀sì, dípò ìyẹn ṣe ni mo máa ń kẹ́kọ̀ọ́ lára wọn kí n lè ṣàtúnṣe.”

  •   Má ṣe fara wé ẹlòmíì.

     Bíbélì sọ pé: “Ẹ má ṣe jẹ́ kí á di agbéraga, kí a má ṣe máa bá ara wa díje, kí a má sì máa jowú ara wa.” (Gálátíà 5:26) Tó o bá ń wo àwọn fọ́tò ibi àpèjẹ tí wọn ò pè ẹ́ sí lórí ìkànnì àjọlò, ńṣe lá máa dùn ẹ́ tínú á sì máa bí ẹ gan-an. Inú tiẹ̀ lè bí ẹ débi pé wàá gbà pé àwọn ọ̀rẹ́ ẹ ò nífẹ̀ẹ́ ẹ.

     Bó o ṣe lè ní èrò tó tọ́: Fi sọkàn pé gbogbo àpèjẹ kọ́ ni wọ́n á máa pè ẹ́ sí. Yàtọ̀ síyẹn, kì í ṣe gbogbo ohun tẹ́nì kan jẹ́ la máa ń rí nínú àwọn fọ́tò tí wọ́n máa ń gbé sórí ìkànnì àjọlò. Ọ̀dọ́ kan tó ń jẹ́ Alexis sọ pé “Àwọn ìṣẹ̀lẹ̀ tó dáa nígbésí ayé nìkan làwọn èèyàn sábà máa ń gbé sórí ìkànnì àjọlò, wọn ò kì í gbé àwọn ìṣẹlẹ̀ tí kò fi bẹ́ẹ̀ lárinrin síbẹ̀.”

  •   Jẹ́ kí àlàáfíà jọba nínú ìdílé rẹ.

     Bíbélì sọ pé: “Tó bá ṣeé ṣe, nígbà tó bá ti jẹ́ pé ọwọ́ yín ló wà, ẹ jẹ́ ẹlẹ́mìí àlááfíà.” (Róòmù 12:18) Kò sí bó o ṣe lè yí ìwà ẹlòmíì pa dà pátápátá, àmọ́ o lè yíwà tìẹ pa dà. O lè pinnu pé wà á jẹ́ ẹlẹ́mìí àlááfíà.

     Bó o ṣe lè ní èrò tó tọ́: Má ṣe dá kún ìṣoro tó wà nínú ìdílé rẹ, àmọ́ jẹ́ kí àlááfíà jọba nínú ìdílé rẹ bó ṣe yẹ kó rí láàárín ìwọ àtọ̀rẹ́ ẹ. Ọ̀dọ́ kan tó ń jẹ́ Melinda sọ pé “Aláìpé ni gbogbo wa, kò sígbà tá ò ní máa ṣẹ ara wa, àmọ́ ọwọ́ wa ló wà bóyá a máa jẹ́ ẹlẹ́mìí àlááfíà tàbí a ò ní jẹ́ bẹ́ẹ̀.”

  •   Jẹ́ ẹni tó moore.

     Bíbélì sọ pé: “Ẹ máa dúpẹ́.” (Kólósè 3:15) Tó o bá lẹ́mìí ìmoore, wàá lè pọkan pọ̀ sórí àwọn ohun rere tó ń ṣẹlẹ̀ láyé ẹ dípò tí wàá fi máa ronú nípa àwọn ohun tó ò nífẹ̀ẹ́ sí.

     Bó o ṣe lè ní èrò tó tọ́: Mọ ìṣòro tó o ní, àmọ́ máa ronú lórí àwọn ohun rere tó ń ṣẹlẹ̀ láyé ẹ. Ọ̀dọ́bìnrin kan tó ń jẹ́ Rebecca sọ pé “Mo ni ìwé kan tí mo máa ń kọ àwọn ohun rere tó ṣẹlẹ̀ sí mi lọ́joojúmọ́ sí, kí n lè máa rántí pé bí mo tiẹ̀ níṣòro, àwọn ohun rere wà tó yẹ kí n máa ronú nípa ẹ̀.”

  •   Irú ọ̀rẹ́ wo lo ní?

     Bíbélì sọ pé: “Ẹgbẹ́ búburú ń ba ìwà rere jẹ́.” (1 Kọ́ríntì 15:33) Tó bá jẹ́ pé ẹni tó máa ń ṣàríwísí, tó máa ń bú èèyàn tàbí tó máa ń bínú lo yàn lọ́rẹ̀ẹ́, kò sígbà tó ò ní máa hùwà bíi tiwọn.

     Bó o ṣe lè ní èrò tó tọ́: Nígbà táwọn ọ̀rẹ́ ẹ bá níṣòro tó le koko, ó lè mú kí wọ́n banú jẹ́, wọ́n sì lè ní ẹ̀dùn ọkàn fúngbà díẹ̀. Ṣe gbogbo ohun tó o lè ṣe láti ràn wọ́n lọ́wọ́ nírú àkókò bẹ́ẹ̀, àmọ́, má ṣe jẹ́ kí ìṣòro wọn bò ẹ́ mọ́lẹ̀. Ọ̀dọ́bìnrin kan tórúkọ rẹ̀ ń jẹ́ Michelle sọ pé “Kò yẹ kọ́ jẹ́ àwọn tó máa ń ronú lọ́nà tí kò tọ́ làá máa bá kẹ́gbẹ́.”

 Ka púpọ̀ sí i nípa ẹ̀

 Bíbélì sọ pé “àkókò tí nǹkan le gan-an, tó sì nira” là ń gbé. (2 Tímótì 3:1) Kò rọrùn kéèyàn lérò tó dáa nínú àyé tó kún fún ìṣòro tá à ń gbé yìí. Ka orí kọkànlá nínú ìwé Bíbélì Kọ́ Wa tí àkórí rẹ̀ sọ pé “Kí Nìdí Tí Ìyà Fi Pọ̀ Láyé?” lórí ìkànnì jw.org.