Sí Àwọn Ará Fílípì 4:1-23

  • Ìṣọ̀kan, ayọ̀, èrò tí ó tọ́ (1-9)

    • Ẹ má ṣe máa ṣàníyàn nípa ohunkóhun (6, 7)

  • Pọ́ọ̀lù mọyì ẹ̀bùn àwọn ará Fílípì (10-20)

  • Ìkíni tó fi parí ọ̀rọ̀ rẹ̀ (21-23)

4  Nítorí náà, ẹ̀yin ará mi tí mo nífẹ̀ẹ́, tó sì ń wù mí láti rí, ẹ̀yin tí ẹ jẹ́ ìdùnnú mi àti adé mi,+ ẹ dúró gbọn-in+ ní ọ̀nà yìí nínú Olúwa, ẹ̀yin ará mi ọ̀wọ́n.  Mo rọ Yúódíà, mo sì rọ Síńtíkè pé kí wọ́n ní èrò kan náà nínú Olúwa.+  Bẹ́ẹ̀ ni, mo fẹ́ kí ìwọ náà, gẹ́gẹ́ bí alábàáṣiṣẹ́ tòótọ́,* máa ṣèrànwọ́ fún àwọn obìnrin yìí, wọ́n ti sapá* pẹ̀lú mi nítorí ìhìn rere, pẹ̀lú Kílẹ́mẹ́ǹtì àti àwọn yòókù tí a jọ ń ṣiṣẹ́, àwọn tí orúkọ wọn wà nínú ìwé ìyè.+  Ẹ máa yọ̀ nígbà gbogbo nínú Olúwa. Lẹ́ẹ̀kan sí i, mo sọ pé, Ẹ máa yọ̀!+  Ẹ jẹ́ kí gbogbo èèyàn rí i pé ẹ̀ ń fòye báni lò.+ Olúwa wà nítòsí.  Ẹ má ṣe máa ṣàníyàn nípa ohunkóhun,+ àmọ́ nínú ohun gbogbo nípasẹ̀ àdúrà àti ìrawọ́ ẹ̀bẹ̀ pẹ̀lú ìdúpẹ́, ẹ máa sọ àwọn ohun tí ẹ̀ ń tọrọ fún Ọlọ́run;+  àlàáfíà Ọlọ́run+ tó kọjá gbogbo òye yóò sì máa ṣọ́ ọkàn yín+ àti agbára ìrònú yín* nípasẹ̀ Kristi Jésù.  Paríparí rẹ̀, ẹ̀yin ará, ohunkóhun tó jẹ́ òótọ́, ohunkóhun tó ṣe pàtàkì, ohunkóhun tó jẹ́ òdodo, ohunkóhun tó jẹ́ mímọ́,* ohunkóhun tó yẹ ní fífẹ́, ohunkóhun tí à ń sọ̀rọ̀ rẹ̀ dáadáa, ohunkóhun tó bá dára, ohunkóhun tó bá yẹ fún ìyìn, ẹ máa ronú* lórí àwọn nǹkan yìí.+  Àwọn ohun tí ẹ kọ́, tí ẹ tẹ́wọ́ gbà, tí ẹ gbọ́, tí ẹ sì rí lọ́dọ̀ mi, ẹ máa fi wọ́n sílò,+ Ọlọ́run àlàáfíà yóò sì wà pẹ̀lú yín. 10  Mo yọ̀ gidigidi nínú Olúwa pé ní báyìí ẹ ti jẹ́ kí ọ̀rọ̀ mi pa dà máa jẹ yín lọ́kàn.+ Bó tiẹ̀ jẹ́ pé ọ̀rọ̀ mi ń jẹ yín lọ́kàn tẹ́lẹ̀, ẹ ò rí àyè láti fi hàn bẹ́ẹ̀. 11  Kì í ṣe torí pé mi ò ní ohun tí mo nílò ni mo ṣe ń sọ̀rọ̀ yìí, torí mo ti kọ́ bí èèyàn ṣe ń nítẹ̀ẹ́lọ́rùn pẹ̀lú ohun tó bá ní* nínú ipòkípò tí mo bá wà.+ 12  Mo mọ bí èèyàn ṣe ń gbé nínú àìní,*+ mo sì mọ bí èèyàn ṣe ń gbé nínú ọ̀pọ̀. Nínú ohun gbogbo àti ní ipòkípò, mo ti kọ́ àṣírí bí a ṣe ń jẹ àjẹyó àti bí a ṣe ń wà nínú ebi, bí a ṣe ń ní púpọ̀ àti bí a ṣe ń jẹ́ aláìní. 13  Mo ní okun láti ṣe ohun gbogbo nípasẹ̀ ẹni tó ń fún mi lágbára.+ 14  Síbẹ̀, ẹ ṣe dáadáa bí ẹ ṣe ràn mí lọ́wọ́ nínú ìpọ́njú mi. 15  Kódà, ẹ̀yin ará Fílípì náà mọ̀ pé lẹ́yìn tí ẹ kọ́kọ́ gbọ́ ìhìn rere, nígbà tí mo kúrò ní Makedóníà, kò sí ìjọ kan tó bá mi dá sí ọ̀rọ̀ fífúnni àti gbígbà, àfi ẹ̀yin nìkan;+ 16  torí nígbà tí mo wà ní Tẹsalóníkà, ẹ fi nǹkan tí mo nílò ránṣẹ́ sí mi, kì í ṣe ẹ̀ẹ̀kan péré, ẹ̀ẹ̀mejì ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ ni. 17  Kì í ṣe pé mò ń wá ẹ̀bùn, ohun rere tó máa mú èrè púpọ̀ sí i wá fún yín ni mò ń wá. 18  Àmọ́, mo ní ohun gbogbo tí mo nílò, kódà mo ní jù bẹ́ẹ̀ lọ. Mo ti ní ànító, ní báyìí tí àwọn ohun tí ẹ fi rán Ẹpafíródítù+ ti dé ọwọ́ mi, wọ́n dà bí òórùn dídùn,+ ẹbọ tó ṣe ìtẹ́wọ́gbà, tó sì wu Ọlọ́run gidigidi. 19  Nítorí náà, Ọlọ́run mi tí ọrọ̀ rẹ̀ kò lópin máa pèsè gbogbo ohun tí ẹ nílò pátápátá+ nípasẹ̀ Kristi Jésù. 20  Ọlọ́run wa àti Baba ni kí ògo jẹ́ tirẹ̀ títí láé àti láéláé. Àmín. 21  Ẹ bá mi kí gbogbo àwọn ẹni mímọ́ nínú Kristi Jésù. Àwọn ará tó wà pẹ̀lú mi kí yín. 22  Gbogbo ẹni mímọ́, ní pàtàkì àwọn tó jẹ́ ti agbo ilé Késárì,+ kí yín. 23  Kí inú rere àìlẹ́tọ̀ọ́sí Jésù Kristi Olúwa wà pẹ̀lú ẹ̀mí tí ẹ fi hàn.

Àlàyé Ìsàlẹ̀ Ìwé

Ní Grk., “alájọru àjàgà tòótọ́.”
Tàbí “ṣiṣẹ́ kára.”
Tàbí “èrò yín.”
Tàbí “ṣàṣàrò.”
Tàbí “tó mọ́.”
Tàbí “ní ẹ̀mí ohun-moní-tómi.”
Tàbí “pẹ̀lú ìpèsè bín-ń-tín.”