Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

ÀWỌN Ọ̀DỌ́ BÉÈRÈ PÉ

Ohun Tó Yẹ Kí N Mọ̀ Nípa Sìgá Mímu?

Ohun Tó Yẹ Kí N Mọ̀ Nípa Sìgá Mímu?

 “Níbi tí mò ń gbé, ó ṣọ̀wọ́n kéèyàn tó rí ọmọ ọdún mẹ́ẹ̀ẹ́dọ́gbọ̀n (25tí kò tíì mu sìgá rí.”​—Julia.

Nínú àpilẹ̀kọ yìí

 Ohun tó yẹ kó o mọ̀

  •   Sìgá mímu máa ń pààyàn. Èròjà olóró ni Nicotine, ó jẹ́ ọ̀kan pàtàkì nínú àwọn èròjà tí wọ́n fi ń ṣe sìgá, ó sì tètè máa ń di bárakú fún èèyàn. Àjọ tó ń rí sí bí wọ́n ṣe ń kápá àìsàn, tí wọ́n sì ń dènà ẹ̀ ní Amẹ́ríkà sọ pé, “tábà inú sìgá wà lára ohun tó ń fa ikú àìtọ́jọ́ àti àìsàn kárí ayé.”

     “Ibi tí wọ́n ti ń yàwòrán bí inú ẹ̀yà ara ṣe rí ni mo ti ń ṣiṣẹ́ nílé ìwòsàn. Mo sì ti rí ìpalára tí mímu sìgá ti fà fàwọn èèyàn kan tí mo ṣàyẹ̀wò fún. Ó máa ń yà mí lẹ́nu gan-an tí mo bá rí i bí ìdọ̀tí tó wà nínú òpó tó ń gbé ẹ̀jẹ̀ jáde látinú ọkàn àwọn tó ń mu sìgá ṣe pọ̀ tó. Torí pé àgọ́ ara mi ṣeyebíye sí mi, mi ò jẹ́ sún mọ́ ìdí sìgá mímu.”​—Theresa.

     Ǹjẹ́ o mọ̀? Ẹgbẹ̀rún méje (7000) kẹ́míkà ló wà nínú sìgá, èyí tó pọ̀ jù nínú ẹ̀ ló sì lè ṣàkóbá fún ẹ̀yà ara. Lọ́dọọdún, ọ̀pọ̀ mílíọ̀nù èèyàn ló ń kú nítorí àìsàn tí sìgá mímu ń fà.

  •   Kẹ́míkà tó ń ṣàkóbá fún ara wà nínú sìgá tò ń lo bátìrì. Sìgá kan wà tí wọ́n ṣe báyìí tó jẹ́ pé bátìrì ló ń lò. Sìgá yìí ń ba ẹ̀dọ̀ jẹ́, ó sì ti pa àwọn míì láì tọ́jọ́. Bẹ́ẹ̀ sì rèé, ọ̀pọ̀ nínú àwọn sìgá yìí ló ní èròjà nicotine bíi ti sìgá gangan. Ìwé kan tó sọ̀rọ̀ nípa sìgá tó ń lo bátìrì yìí sọ pé èròjà nicotine tètè máa ń di bárakú fáwọn èèyàn “ó lè jẹ́ kí lílo àwọn oògùn olóró míì di bárakú fáwọn ọ̀dọ́.”

     “Torí pé àwọn sìgá tó ń lo bátìrì ní òórùn dídùn, àwọn ọmọdé àtàwọn ọmọ tí ò tíì pé ogun ọdún fẹ́ràn ẹ̀ gan-an. Ṣe ni wọ́n rò pé kò lè pa wọ́n lára torí pé ó dùn.”​—Miranda.

     Ǹjẹ́ o mọ̀? Ooru tó ń jáde nínú sìgá tó ń lo bátìrì kì í ṣe omi lásán, àwọn èròjà olóró tó lè ba ẹ̀dọ̀ jẹ́ ló wà nínú ẹ̀.

 Àwọn ewu tó wà nínú mímu sìgá

  1.  (1) Kì í jẹ́ kí ọpọlọ ṣiṣẹ́ dáadáa, kì í jẹ́ kéèyàn lè pọkàn pọ̀, ó sì máa ń fa ìrẹ̀wẹ̀sì pàápàá fáwọn ọmọdé

  2.  (2) Ó máa ń ba eyín àti èrìgì jẹ́

  3.  (3) Ó máa ń jẹ́ kí ẹ̀dọ̀ wú, ó sì máa ń fa àrùn ọkàn

     Ikọ́ fée tó ń burú sí i

     Ó máa ń fa èébì, ó sì ń jẹ́ kí inú dàrú

 Ohun tó o lè ṣe

  •   Mọ ohun tó jẹ́ òótọ́. Má ṣe máa gba gbogbo ọ̀rọ̀ gbọ́. Bí àpẹẹrẹ, àwọn kan máa ń sọ pé kò léwu téèyàn bá ń mu sìgá oníbátìrì àti pé ó máa ń mára tuni. Kó o lè ṣèpinnu tó tọ́, á dáa kó o ṣèwádìí kó o lè mọ ewu tó wà nínú ẹ̀.

     Ìlànà Bíbélì: “Aláìmọ̀kan máa ń gba gbogbo ọ̀rọ̀ gbọ́, àmọ́ aláròjinlẹ̀ máa ń ronú lórí ìgbésẹ̀ kọ̀ọ̀kan.”​—Òwe 14:15.

     “Tó o bá ronú lórí ewu tó wà nínú mímu sìgá, wàá rí i pé ohun tó lè pa wọ́n lára làwọn ojúgbà ẹ àtàwọn gbajúgbajà fi ń ṣayọ̀.”​—Evan.

     Ohun tó yẹ kó o ronú lé: Ṣe inú àwọn ọ̀dọ́ tó ń mu sìgá ń dùn lóòótọ́? Ṣé wọ́n ń múra sílẹ̀ láti kojú ìṣòro èyíkéyìí tó bá yọjú ní báyìí àti lọ́jọ́ iwájú? Àbí ṣe ni wọ́n ń gbin wàhálà fúnra wọn de ọjọ́ iwájú?

  •    Máa ṣe àwọn nǹkan tó máa jẹ́ kó o borí àníyàn. Bí àpẹẹrẹ, máa ṣe eré ìmárale, máa kàwé, kó o sì máa wà pẹ̀lú àwọn ọ̀rẹ́ tó máa jẹ́ kí ìwà ẹ dáa. Tó bá jẹ́ pé àwọn nǹkan gidi yìí lò ń fi àkókò ẹ ṣe, kò ní máa ṣe ẹ́ bíi pé kó o fi sìgá pàrònú rẹ́.

     Ìlànà Bíbélì: “Àníyàn inú ọkàn máa ń mú kó rẹ̀wẹ̀sì, àmọ́ ọ̀rọ̀ rere máa ń mú kó túra ká.”​—Òwe 12:25.

     “Èrò àwọn kan ni pé táwọn bá ń mu sìgá, ó máa jẹ́ káwọn lè pàrònú rẹ́. Àmọ́, òótọ́ ibẹ̀ ni pé ìgbà díẹ̀ ló fi máa mára tù wọ́n, àkóbá tó máa wà títí lọ ló máa ṣe fún ara wọn. Àwọn nǹkan gidi míì wà tèèyàn lè ṣe láti borí àníyàn.”​—Angela

     Ohun tó yẹ kó o ronú lé: Àwọn nǹkan wo lo lè ṣe láti borí àníyàn? Kó o lè mọ ohun tó yẹ kó o ṣe, ka àpilẹ̀kọ “Báwo Ni Mo Ṣe Lè Borí Àníyàn?” lábẹ́ ọ̀wọ́ àpilẹ̀kọ “Àwọn Ọ̀dọ́ Béèrè Pé”

Téèyàn bá ń fi àwọn oògùn tó lè di bárakú pàrònú rẹ́, ṣe ló máa dà bí ìgbà tí ẹnì kan bá bẹ́ sínú òkun torí kó lè sá fún òjò, ṣe ló máa dá kún ìṣòro ẹ̀.

  •    Mọ ohun tó o lè ṣe táwọn ọ̀dọ́ bíi tìẹ bá fẹ́ kó o ṣe ohun tí ò dáa. Àwọn ọmọ iléèwé ẹ, àwọn tó ò ń rí nínú fíìmù, ètò tẹlifíṣọ̀n àti lórí ìkànnì àjọlò lè jẹ́ kó o rò pé ṣe lèèyàn ń gbádùn ara ẹ̀ tó bá ń mu sìgá àti pé kò sí ohun tó burú níbẹ̀.

     Ìlànà Bíbélì: “Àmọ́ àwọn tó dàgbà . . . ti kọ́ agbára ìfòyemọ̀ wọn nípa bí wọ́n ṣe ń lò ó láti fi ìyàtọ̀ sáàárín ohun tó tọ́ àti ohun tí kò tọ́.”​—Hébérù 5:14.

     “Nígbà tí mo wà níléèwé, àwọn ọmọ kíláàsì mi máa ń fọ̀wọ̀ mi wọ̀ mí torí pé mi ò kì í mu sìgá. Àwọn gan-an ló wá ń gbèjà mi táwọn míì bá ní kí n wá mu sìgá. Ó lè má rọrùn láti sọ, àmọ́ o ò ní kó sínú wàhálà tó o bá ṣe bẹ́ẹ̀.”​—Anna.

     Ohun tó yẹ kó o ronú lé: Tàwọn ọ̀rẹ́ ẹ bá ní kó o ṣe ohun tí ò dáa, ṣé o máa ń gbọ́ tiwọn? Ṣé o lè rántí ìgbà kan táwọn ọ̀rẹ́ ẹ fẹ́ kó o ṣe ohun tí ò dáa àmọ́ tó o kọ̀ jálẹ̀? Kó o lè mọ ohun tó yẹ kó o ṣe, ka àkòrí náà “Mímúra Sílẹ̀ De Ìṣòro” tó wà ní orí 15 ìwé Àwọn Ìbéèrè Tí Àwọn Ọ̀dọ́ Ń Béèrè​—Àwọn Ìdáhùn Tí Ó Gbéṣẹ́, Apá Kejì.

  •   Àwọn tó níwà tó dáa ni kó o mú lọ́rẹ̀ẹ́. Tó bá jẹ́ pé àwọn tí kì í mu sìgá ló mú lọ́rẹ̀ẹ́, kò ní máa ṣe ẹ́ bíi pé kó o mu sìgá.

     Ìlànà Bíbélì: “Ẹni tí ó ń bá ọlọ́gbọ́n rìn yóò gbọ́n ṣùgbọ́n ẹni tí ń bá aláìgbọ́n kẹ́gbẹ́ ń pa ara rẹ̀ lára.”​—Òwe 13:20, Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní.

     “Ó dáa kéèyàn bá àwọn tó ń kó ara wọn níjàánu tí wọ́n sì jẹ́ olóòótọ́ ṣọ̀rẹ́. Tó o bá rí bí nǹkan ṣe ń lọ dáadáa fún wọn, ìyẹn á jẹ́ kó o fẹ́ dà bíi tiwọn.”​—Calvin.

     Ohun tó yẹ kó o ronú lé: Ṣé àwọn ọ̀rẹ́ ẹ máa ń jẹ́ kó rọrùn fún ẹ láti gbé ìgbésí ayé ọmọlúàbí, tàbí ṣe ni wọ́n máa ń fi ẹ́ ṣe yẹ̀yẹ́?

 Ṣé igbó mímu léwu?

 Ọ̀pọ̀ èèyàn ló máa ń sọ pé igbó mímu ò léwu. Àmọ́ irọ́ gbuu nìyẹn!

  •   Igbó mímu lè di bárakú fáwọn ọ̀dọ́ tó bá ń mu ún. Ìwádìí fi hàn pé igbó lé mú kí ọpọlọ má ṣiṣẹ́ dáadáa, ẹni náà ò sì ní lè ronú bó ṣe yẹ.

  •   Àjọ tó ń rí sí lílo oògùn nílòkulò tó sì ń bójú tó ọ̀rọ̀ ọpọlọ lórílẹ̀-èdè Amẹ́ríkà sọ pé, “lọ́pọ̀ ìgbà, àwọn tó bá ń mú igbó kì í ní àjọṣe tó dáa pẹ̀lú àwọn èèyàn, wọ́n kì í ṣe dáadáa nílé ìwé àti níbi iṣẹ́, ìgbésí ayé wọn kì í sì í nítumọ̀.”

     “Nígbàkigbà tí ẹ̀dùn ọkàn bá bá mi, ó máa ń ṣe mí bíi kí n mu igbó kí n lè fi pàrònú rẹ́. Àmọ́ nígbà tí mo ronú lórí ohun tó máa tẹ̀yìn ẹ̀ yọ irú bí, owó tó máa ná mi, bó ṣe máa kó bá ìlera mi àti pé ó lè di bárakú fún mi, ìyẹn jẹ́ kí n rí i pé ṣe ni igbó kàn máa dá kún ìṣòro mi.”​—Judah.