Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

ÀWỌN Ọ̀DỌ́ BÉÈRÈ PÉ

Ṣé Ká Fira Wa Sílẹ̀? (Apá 2)

Ṣé Ká Fira Wa Sílẹ̀? (Apá 2)

 Kọ́kọ́ mọ bó ṣe yẹ kó o sọ irú ọ̀rọ̀ bẹ́ẹ̀, ibi tó yẹ kó o ti sọ ọ́, àti àkókò tó yẹ kó o sọ ọ́. Bíi báwo?

 Ronú nípa bó o ṣe máa fẹ́ kéèyàn sọ irú ọ̀rọ̀ bẹ́ẹ̀ fún ẹ. (Mátíù 7:​12) Ṣé ìṣojú àwọn ẹlòmíì lo ti máa fẹ́ kó sọ ọ́ fún ẹ? Bóyá ni.

 Kì í ṣe orí fóònù ló yẹ kéèyàn ti sọ fún ẹni tó ń fẹ́ pé òun ò ṣe mọ́ tàbí kó fọ̀rọ̀ ránṣẹ́ sí i, àfi tí ò bá sọ́gbọ́n míì téèyàn lè dá. Kàkà bẹ́ẹ̀, ṣe ló yẹ kó o wá àkókò tó dáa àti ibi tó bójú mu tẹ́yin méjèèjì ti lè sọ̀rọ̀ yìí, torí kì í ṣe ọ̀rọ̀ kékeré.

 Tó bá wá tó àsìkò àti sọ̀rọ̀, kí ló yẹ kó o sọ? Àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù rọ àwọn Kristẹni pé kí wọ́n máa bá ara wọn “sọ òtítọ́.”​—Éfésù 4:​25.

 Torí náà, ohun tó dáa jù ni pé kó o má fọ̀rọ̀ sábẹ́ ahọ́n sọ, àmọ́ fọgbọ́n sọ ọ́. Ṣàlàyé ìdí tó o fi rò pé kò ní ṣeé ṣe fún ẹ láti fẹ́ ẹ, kó o sì jẹ́ kó ṣe kedere.

 Kì í ṣe kó o wá máa to gbogbo àṣìṣe ẹ̀ níkọ̀ọ̀kan tàbí kó o máa sọ gbogbo ohun tó ṣe sí ẹ tí ò dáa. Kódà, dípò tí wàá fi máa dá a lẹ́bi pé, “O ò ṣe tibí” tàbí “O kì í ṣe tọ̀hún,” ó máa sàn kó o sọ̀rọ̀ lọ́nà tó fi bí nǹkan ṣe rí lára ẹ hàn. Bí àpẹẹrẹ, o lè sọ pé, “Mo fẹ́ ẹni tó lè . . .” tàbí “Mo rò pé á dáa kí kálukú máa lọ nílọ ẹ̀ torí pé . . .”

 Irú àkókò yìí kọ́ ni wàá máa ṣe “mẹ-in mẹ-in” tàbí tí wàá jẹ́ kó yí ẹ lérò pa dà. Rántí pé ó ní ohun pàtàkì tó o rí tó o fi fẹ́ sọ pé o ò ṣe mọ́. Torí náà, ṣọ́ra tó o bá ri i pé ẹni tẹ́ ẹ jọ ń fẹ́ra fẹ́ dọ́gbọ́n yí ẹ lérò pa dà kẹ́ ẹ má bàa fira yín sílẹ̀. Ọ̀dọ́bìnrin kan tó ń jẹ́ Lori sọ pé, “Lẹ́yìn tí èmi àti bọ̀bọ́ tí mò ń fẹ́ fira wa sílẹ̀, ó bẹ̀rẹ̀ sí í ṣe bí ẹni tí ọ̀fọ̀ ṣẹ̀. Ó dà bíi pé torí kí n lè máa káàánú ẹ̀ ló fi ń ṣe bẹ́ẹ̀. Ó dùn mí pé a ò fẹ́ra mọ́ lóòótọ́. Àmọ́ mi ò tìtorí ohun tó ń ṣe yí ìpinnu mi pa dà.” Ó yẹ kíwọ náà mọ ohun tó o fẹ́ bíi ti Lori. Dúró lórí ọ̀rọ̀ ẹ. Jẹ́ kí bẹ́ẹ̀ kọ́ rẹ jẹ́ bẹ́ẹ̀ kọ́.​—Jákọ́bù 5:​12.