Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

ÀWỌN Ọ̀DỌ̀ BÉÈRÈ PÉ

Báwo Ni Mo Ṣe Lè Ṣàkóso Ìbínú Mi?

Báwo Ni Mo Ṣe Lè Ṣàkóso Ìbínú Mi?

 Ìbéèrè

  •  Báwo lo ṣe máa ń tètè bínú sí?

    •  mi ò kì í bínú

    •  lẹ́ẹ̀kọ̀ọ̀kan

    •  ojoojúmọ́

  •  Báwo ni ìbínú rẹ ṣe máa ń le tó?

    •  mi ò kì í fi bẹ́ẹ̀ bínú

    •  mo máa ń bínú

    •  mo máa ń bínú gan-an

  •  Ta lo máa ń bínú sí?

    •  àwọn òbí rẹ

    •  àwọn àbúrò rẹ

    •  àwọn ọ̀rẹ́ rẹ

 Tó o bá rí i pé ó yẹ kó o ṣàkóso ìbínú rẹ, àpilẹ̀kọ yìí máa ràn ẹ́ lọ́wọ́! Lákọ̀ọ́kọ́, ṣàyẹ̀wò àwọn ìdí tó fi ṣe pàtàkì pé kó o máa sinmẹ̀dọ̀ tẹ́nì kan bá múnú bí ẹ.

 Ìdí tó fi ṣe pàtàkì

 Ìlera rẹ̀. Òwe 14:30 sọ pé: “Ọkàn-àyà píparọ́rọ́ ni ìwàláàyè ẹ̀dá alààyè ẹlẹ́ran ara.” Yàtọ̀ sí ìyẹn, ìwé Journal of Medicine and Life sọ pé, “ìbínú lè fa àìsàn ọkàn fún èèyàn.”

 Àwọn ọ̀rẹ́ rẹ. Bíbélì sọ pé: “Má ṣe bá ẹnikẹ́ni tí ó bá fi ara fún ìbínú kẹ́gbẹ́; má sì bá ènìyàn tí ó máa ń ní ìrufùfù ìhónú wọlé.” (Òwe 22:24) Torí náà tó o bá ń bínú, má jẹ́ kó yà ẹ́ lẹ́nu táwọn èèyàn bá ń sá fún ẹ. Ọ̀dọ́bìnrin kan tó ń jẹ́ Jasmine sọ pé, “tí o kò bá kí ń ṣàkóso ìbínú rẹ, o kò ní ní ọ̀rẹ́ gidi.”

 Irú ojú táwọn èèyàn á fi máa wò ẹ́. Ethan tó jẹ́ ọmọ ọdún mẹ́tàdínlógún [17] sọ pé: “Àwọn èèyàn á mọ̀ tó o bá ti ń bínú jù, ojú tí wọ́n á sì máa fi wò ẹ́ nìyẹn.” Bí ara rẹ pé, ‘Irú ojú wo ni mo fẹ́ káwọn èèyàn máa fi wò mí​—ṣé bí ẹni jẹ́jẹ́ ni àbí aríjàgbá?’ Bíbélì sọ pé: “Ẹni tí ó bá lọ́ra láti bínú pọ̀ yanturu ní ìfòyemọ̀, ṣùgbọ́n ẹni tí ó bá jẹ́ aláìnísùúrù ń gbé ìwà òmùgọ̀ ga.”​—Òwe 14:29.

Kò sẹ́ni tó máa fẹ́ bá ẹni tí kì í pẹ́ bínú ṣọ̀rẹ́

 Ohun tó o lè ṣe

 Ṣàyẹ̀wò àwọn ẹsẹ Ìwé Mímọ́ yìí àti àwọn àlàyé tó tẹ̀ lé e, kó o wá bi ara rẹ ní àwọn ìbéèrè tó wà nísàlẹ̀ yìí.

  •   Òwe 29:22: “Ènìyàn tí ó fi ara fún ìbínú ń ru asọ̀ sókè, ẹnikẹ́ni tí ó sì fi ara fún ìhónú ní ọ̀pọ̀ ìrélànàkọjá.”

     “Nígbà tí mo ṣì kéré, ó máa ń ṣòro fún mi láti ṣàkóso ìbínú mi. Àwọn ẹbí bàbá mi náà sì ní irú ìṣòro yìí. A ti kà á sí àrùn ìdílé wa. Ó máa ń ṣòro fún wa láti ṣàkóso ìbínú wa!”​—Kerri.

     Ṣe inú máa ń tètè bí mi? Táwọn èèyàn bá yìn mí torí pé mo hùwà tó dáa, ṣé ó wá yẹ kí n ka èyí tí kò dáa tí mo hù níwà sí àjogúnbá?

  •   Òwe 15:1: “Ìdáhùn kan, nígbà tí ó bá jẹ́ lọ́nà pẹ̀lẹ́, máa ń yí ìhónú padà, ṣùgbọ́n ọ̀rọ̀ tí ń fa ìrora máa ń ru ìbínú sókè.”

     “Ohun tó o lè ṣe ni pé kó o kọ́ bí o ṣe lè máa ṣàkóso ìbínú rẹ. Tó o bá ń fi ọ̀nà pẹ̀lẹ́ bá àwọn èèyàn lò, tó sì jẹ́ pé ibi táwọn èèyàn dáa sí lò ń wò, o ò ní tètè máa bínú mọ́.”​—Daryl.

     Kí nìdí tó fi jẹ́ pé ọ̀rọ̀ tí mo bá kọ́kọ́ sọ nígbà tínú ń bí mi kì í dáa?

  •   Òwe 26:20: “Níbi tí igi kò bá sí, iná a kú.”

     “Tí mo bá fèsì lọ́nà tó dáa, ó máa ń múnú àwọn èèyàn dùn, èyí sì máa ń jẹ́ kí ń lè bá àwọn èèyàn sọ̀rọ̀ láì sí wàhálà.”​—Jasmine.

     Báwo lọ̀rọ̀ tí mo sọ tàbí ìwà mi ṣe lè dá kún wàhálà náà?

  •   Òwe 22:3: “Afọgbọ́nhùwà ni ẹni tí ó ti rí ìyọnu àjálù, tí ó sì bẹ̀rẹ̀ sí fi ara rẹ̀ pa mọ́, ṣùgbọ́n aláìní ìrírí gba ibẹ̀ kọjá, yóò sì jìyà àbájáde rẹ̀.”

     “Nígbà míì ohun tó máa ń gbà ni pé kí n kúrò níbẹ̀, kí àyè lè wà fún mi láti ronú nípa ohun tó ṣẹlẹ̀ náà, màá sì lè yanjú rẹ̀ tí ara mi bá balẹ̀.”​—Gary.

     Ìgbà wo ló dáa jù kí o kúrò lọ́dọ̀ ẹni tó ń múnú bí ẹ láì tún dá kún ìṣòro náà?

  •   Jákọ́bù 3:2: “Gbogbo wa ni a máa ń kọsẹ̀ lọ́pọ̀ ìgbà.”

     “Ó yẹ kí àṣìṣe tá a bá ṣe dùn wá, síbẹ̀ ká kọ́gbọ́n nínú wọn. Tá a bá ti ṣe àṣìṣe, ó yẹ ká tètè ṣàtúnṣe kírú ẹ̀ má bá à wáyé mọ́.”​—Kerri.

 Ìmọ̀ràn: Ní àfojúsùn. Pinnu pé o kò ní bínú mọ́ fáwọn àkókò kan, ó lè jẹ́ bí i oṣù kan. Ní àkọsílẹ̀ tí wàá máa kọ ọ́ sí, kí o sì máa kíyèsí bí o ṣe ṣe sí.