Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Ètò Kíka Bíbélì

Ètò Kíka Bíbélì

Inú Bíbélì la ti lè rí ọgbọ́n tó dáa jù lọ téèyàn lè fi gbé ayé. Tó a bá ń kà á, tó ò ń ronú lé e lórí, tó o sì ń fi ohun tó o kọ́ sílò, “ọ̀nà rẹ máa yọrí sí rere.” (Jóṣúà 1:8; Sáàmù 1:1-3) Wàá tún mọ Ọlọ́run àti Jésù Ọmọ rẹ̀, ìmọ̀ tó o ní yìí á sì jẹ́ kó o rí ìgbàlà.​—Jòhánù 17:3.

Ibo ló yẹ kó o ti bẹ̀rẹ̀ sí í ka àwọn ìwé inú Bíbélì? Ohun kan wà tó o lè ṣe. Ìtòlẹ́sẹẹsẹ Bíbélì kíka yìí á jẹ́ kó o lè máa ka àwọn ìwé Bíbélì bí wọ́n ṣe tẹ̀ léra wọn tàbí ní ìsọ̀rí ìsọ̀rí. Bí àpẹẹrẹ, o lè ka àwọn apá kan tó o yàn kó o lè mọ ìtàn bí Ọlọ́run ṣe bá àwọn ọmọ Ísírẹ́lì àtijọ́ lò. O sì tún lè ka apá míì láti mọ bí ìjọ Kristẹni ṣe bẹ̀rẹ̀ ní ọgọ́rùn-ún ọdún kìíní, tó sì ń pọ̀ sí i. Tó o bá ń ka àwọn orí tá a yàn síbẹ̀ lójoojúmọ́, wàá parí Bíbélì lódindi láàárín ọdún kan.

Ìbáà jẹ́ ètò Bíbélì kíkà ojoojúmọ́ lò ń wá tàbí ti ọdọọdún tàbí èyí tó wà fẹ́ni tó ṣẹ̀ṣẹ̀ fẹ́ máa ka Bíbélì, ètò Bíbélì kíkà yìí máa wúlò fún ẹ. Wa ìtòlẹ́sẹẹsẹ Bíbélì kíka tó ṣeé tẹ̀ yìí jáde, kó o sì bẹ̀rẹ̀ lónìí.