Lẹ́tà sí Àwọn Ará Kólósè 1:1-29

  • Ìkíni (1, 2)

  • Pọ́ọ̀lù dúpẹ́ nítorí ìgbàgbọ́ àwọn ará Kólósè (3-8)

  • Àdúrà pé kí wọ́n máa dàgbà sí i nípa tẹ̀mí (9-12)

  • Ipa àrà ọ̀tọ̀ tí Kristi kó (13-23)

  • Iṣẹ́ àṣekára tí Pọ́ọ̀lù ṣe fún ìjọ (24-29)

1  Pọ́ọ̀lù, àpọ́sítélì Kristi Jésù nípa ìfẹ́ Ọlọ́run pẹ̀lú Tímótì+ arákùnrin wa,  sí àwọn ẹni mímọ́ àti àwọn arákùnrin olóòótọ́ nínú Kristi ní Kólósè: Kí ẹ ní inú rere àìlẹ́tọ̀ọ́sí àti àlàáfíà látọ̀dọ̀ Ọlọ́run tó jẹ́ Baba wa.  Gbogbo ìgbà la máa ń dúpẹ́ lọ́wọ́ Ọlọ́run Baba Olúwa wa Jésù Kristi, nígbà tí a bá ń gbàdúrà fún yín,  torí a ti gbọ́ nípa ìgbàgbọ́ tí ẹ ní nínú Kristi Jésù àti ìfẹ́ tí ẹ ní sí gbogbo ẹni mímọ́,  nítorí ìrètí tí a fi pa mọ́ dè yín ní ọ̀run.+ Ẹ ti gbọ́ nípa ìrètí yìí tẹ́lẹ̀ nípasẹ̀ ọ̀rọ̀ òtítọ́ tó jẹ́ ìhìn rere  tó dé ọ̀dọ̀ yín. Bí ìhìn rere náà ṣe ń so èso, tó sì ń gbilẹ̀ ní gbogbo ayé,+ bẹ́ẹ̀ náà ló ń ṣe láàárín yín láti ọjọ́ tí ẹ ti gbọ́, tí ẹ sì ti mọ inú rere àìlẹ́tọ̀ọ́sí Ọlọ́run ní òtítọ́ àti lọ́nà tó péye.  Ohun tí ẹ ti kọ́ nìyẹn lọ́dọ̀ Épáfírásì+ olùfẹ́, ẹrú ẹlẹgbẹ́ wa, ẹni tó jẹ́ òjíṣẹ́ olóòótọ́ fún Kristi nítorí wa.  Ó ti jẹ́ ká gbọ́ nípa ìfẹ́ yín lọ́nà ti ẹ̀mí.*  Ìdí nìyẹn tó fi jẹ́ pé, láti ọjọ́ tí a ti gbọ́ nípa rẹ̀, a ò dákẹ́ àdúrà lórí yín,+ a sì ń bẹ̀bẹ̀ pé kí ẹ lè ní ẹ̀kúnrẹ́rẹ́ ìmọ̀ tó péye+ nípa ìfẹ́ Ọlọ́run nínú gbogbo ọgbọ́n àti òye tẹ̀mí,+ 10  kí ẹ lè máa rìn lọ́nà tó yẹ Jèhófà* láti ṣe ìfẹ́ rẹ̀ ní kíkún, bí ẹ ṣe ń so èso nínú gbogbo iṣẹ́ rere, tí ìmọ̀ tó péye tí ẹ ní nípa Ọlọ́run sì ń pọ̀ sí i;+ 11  kí agbára rẹ̀ ológo sì fún yín ní gbogbo agbára tí ẹ nílò,+ kí ẹ lè fara dà á ní kíkún pẹ̀lú sùúrù àti ìdùnnú, 12  bí ẹ ṣe ń dúpẹ́ lọ́wọ́ Baba tó mú kí ẹ kúnjú ìwọ̀n láti pín nínú ogún àwọn ẹni mímọ́+ nínú ìmọ́lẹ̀. 13  Ó gbà wá lọ́wọ́ àṣẹ òkùnkùn,+ ó sì mú wa lọ sínú ìjọba Ọmọ rẹ̀ ọ̀wọ́n, 14  ẹni tí a tipasẹ̀ rẹ̀ gba ìtúsílẹ̀ nípa ìràpadà, ìyẹn ìdáríjì àwọn ẹ̀ṣẹ̀ wa.+ 15  Òun ni àwòrán Ọlọ́run tí a kò lè rí,+ àkọ́bí nínú gbogbo ẹ̀dá; + 16  nítorí ipasẹ̀ rẹ̀ ni a dá gbogbo ohun mìíràn ní ọ̀run àti ní ayé, àwọn ohun tí a lè rí àti àwọn ohun tí a kò lè rí,+ ì báà jẹ́ ìtẹ́ tàbí ipò olúwa tàbí ìjọba tàbí àṣẹ. Gbogbo ohun mìíràn ni a dá nípasẹ̀ rẹ̀+ àti nítorí rẹ̀. 17  Bákan náà, ó wà ṣáájú gbogbo ohun mìíràn,+ ipasẹ̀ rẹ̀ ni a gbà mú kí gbogbo ohun mìíràn wà, 18  òun sì ni orí fún ara, ìyẹn ìjọ.+ Òun ni ìbẹ̀rẹ̀, àkọ́bí nínú àwọn òkú,+ kí ó lè di ẹni àkọ́kọ́ nínú ohun gbogbo; 19  nítorí ó wu Ọlọ́run láti mú kí ohun gbogbo pé sínú rẹ̀,+ 20  kí ó sì lè tipasẹ̀ rẹ̀ mú gbogbo ohun mìíràn pa dà bá ara rẹ̀ rẹ́,+ ì báà jẹ́ àwọn ohun tó wà ní ayé tàbí àwọn ohun tó wà ní ọ̀run, bí ó ṣe fi ẹ̀jẹ̀ tó ta sílẹ̀ lórí òpó igi oró* mú àlàáfíà wá.+ 21  Ní tòótọ́, ẹ̀yin tí ẹ ti di àjèjì àti ọ̀tá nígbà kan rí torí pé àwọn iṣẹ́ burúkú ni èrò yín dá lé, 22  ẹ̀yin ló pa dà mú bá ara rẹ̀ rẹ́ báyìí nípasẹ̀ ẹran ara ẹni tó fi ara rẹ̀ lélẹ̀ fún ikú, kó lè mú yín wá síwájú rẹ̀ ní mímọ́ àti láìní àbààwọ́n àti láìní ẹ̀sùn kankan,+ 23  kìkì pé kí ẹ dúró nínú ìgbàgbọ́,+ kí ẹ fìdí múlẹ̀ lórí ìpìlẹ̀ náà,+ kí ẹ sì fẹsẹ̀ múlẹ̀ ṣinṣin,+ kí ẹ má yà kúrò nínú ìrètí ìhìn rere tí ẹ gbọ́, tí a sì ti wàásù láàárín gbogbo ẹ̀dá tó wà lábẹ́ ọ̀run.+ Torí ìhìn rere yìí la ṣe yan èmi Pọ́ọ̀lù láti di òjíṣẹ́.+ 24  Ní báyìí, mò ń yọ̀ nínú ìyà tí mò ń jẹ lórí yín,+ mo sì ń ní ìpọ́njú Kristi tí mi ò tíì ní nínú ẹran ara mi nítorí ara rẹ̀,+ ìyẹn ìjọ.+ 25  Mo di òjíṣẹ́ ìjọ yìí nítorí iṣẹ́ ìríjú+ tí Ọlọ́run fún mi nítorí yín láti wàásù ọ̀rọ̀ Ọlọ́run ní kíkún, 26  àṣírí mímọ́+ tí a fi pa mọ́ láti àwọn ètò àwọn nǹkan* tó ti kọjá+ àti láti àwọn ìran tó ti kọjá. Àmọ́ ní báyìí, a ti fi han àwọn ẹni mímọ́ rẹ̀,+ 27  ìyẹn àwọn tó wu Ọlọ́run pé kí wọ́n mọ ọrọ̀ ológo nípa àṣírí mímọ́ yìí láàárín àwọn orílẹ̀-èdè,+ àṣírí yìí ni Kristi tó wà ní ìṣọ̀kan pẹ̀lú yín, ìyẹn ìrètí ògo rẹ̀.+ 28  Òun ni à ń kéde, tí à ń gba gbogbo èèyàn níyànjú nípa rẹ̀, tí a sì ń kọ́ gbogbo èèyàn nínú gbogbo ọgbọ́n, kí a lè mú ẹnì kọ̀ọ̀kan wá ní pípé ní ìṣọ̀kan pẹ̀lú Kristi.+ 29  Nípa bẹ́ẹ̀, mò ń ṣiṣẹ́ kára, mo sì ń sapá bí agbára rẹ̀ ṣe ń ṣiṣẹ́ gidigidi nínú mi.+

Àlàyé Ìsàlẹ̀ Ìwé

Ní Grk., “nínú ẹ̀mí.”
Tàbí “àsìkò.”